Moti rinlẹ̀ ọjọ́ ti jìnà
Moti ríbi rìkísí òhun ọ̀tẹ̀
gbé ń jọ́ s’òrẹ́
Moti dé'lé ayé ọjọ́ ti pẹ́,
Moti d'ókè eèpẹ̀ ọ̀nà ti jì,
Ṣebí ojúlarí ọ̀rẹ́ ò dénú.
Ṣààsà ènìyàn ní fẹ́'ní lẹ́yìn
táà bá sí ní'lé
Ṣebí t'ẹrú t'ọmọ ní fẹ́ni lójú ẹni,
Ojúlarí ọmọ ẹ̀dá ò kú fẹ́ni,
Kò kúkú sẹ́ni tó dùn mọ́
àf'orí ẹni.
Moti dé'lé ayé ọjọ́ ti pẹ́,
Moti rinlẹ̀ ọjọ́ ti jìnà
Moti ríbi rìkísí òhun ọ̀tẹ̀
gbé ń jọ́ s'òrẹ́
Moti ri ibi òtítọ́ ti di pánda
Ayé ń lọ à ń tọ̀ ọ́
Ayé asán tí gbogbo wa ń lé kiri
Ayé hílà-hílo.
Aye ti kò f'ẹ́ni tí à ń fẹ́.
Ṣebí ilé ayé kanńà
ni ọ̀rẹ́ ti ṣekú pa ọ̀rẹ́ rẹ̀
Ilé ayé pákáleke
Ilé ayé tí baba ti p'ọmọ lẹ́kún j'ayé,
Mofẹ́ d'ogún mofẹ́ d'ọgbọ̀n
Kò kúkú séni t'ódùnmọ́
áforíẹni.
Rasaq Malik Gbọ́láhàn jẹ́ akẹ́kọ̀ gboyè nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ìwé gíga fásitì ilú Ìbàdàn. Ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn àṣà àti ìṣe, àti pé ó ní ìgbàgbọ́ pé èdè abínibí ni ọ̀nà tí a lè fi gbé ìlú lárugẹ. Ó tún jẹ́ ẹni tí ó máá ń kéwì, ó sì tún fẹ́ràn láti ma ka ìwé Yorùbá. Ó ń ṣiṣẹ́ lórí ìtàn àròkọ rẹ̀ lọ́wọ́.