Nígbà mo wà lọ́mọ ọwọ́ Mo gbájú métè ìyáà mi korokoro Nígbà mo wà pẹ̀lú bàbá èmi Mo wòye ìsọ̀rọ̀sí rẹ̀ Mo wẹnu àwọn tí wọ́n gbé mi ṣiré Mo wètè àwọn tí a jọ gbé pọ̀ láṣùwàdà Mo kédè, mèdè, fèdè fọ̀ Bí wọ́n bá sọ̀rọ̀ kẹ́rẹ́ N óò gbé e sọ́pọlọ Bí wọ́n bá sì ń fèdèé wírọ̀ — Òfófó òun irọ́— léjìdà-léjìdà Tèmi ò ju kí n ti fetí sí bí wọ́n ti ń fèdèé sọ̀rọ̀ Kọ̀ pẹ́ títí Kò jìnnà púpọ̀ Mo tẹ́ni tí í pe baba ni baba Mo tẹ́ni tí í pèyé léyèé láìfọ̀tá-pè Díẹ̀díẹ̀, ọ̀rọ̀ ń jábọ́ lẹ́nu èmi lákọlákọ Kò sóókọ́ táyé ò sọ mí tán Kò sí súná tí aṣùwàdà ò pè mí Wọ́n pé “ọmọ ńlá” ni Wàhábù Wọ́n sì tún pe Èjìrẹ́ “lájẹ̀ẹ́” tí mi ò jẹ́ tẹ́lẹ̀ Lórí pé mò ń wírọ̀ bí tàwọn àgbà ìṣáájú Mò ń fọ̀ létè bí ẹni ó ti tọ́mọ ẹgbẹ̀rún ọdún Wàràwàrà lèdè ń dún lẹ́nu èmi bi òjò àsùbáà Èdè lèdè tóbìí bí mi mọ́ Ogún ìní mi lèdè mi! Òun lèdè tí mo gbọ́njú bá Òun lèdè tí mo fi kọ́rọ̀ fífọ̀ Bébi ń nà mí ní pọ̀pá N óò móókọ́ mọ̀mọ́ mi lénu Bí mo bá fẹ́ rẹ̀ǹgbẹ náà pẹ̀lú Orúkọ èyé mi náà ni n ó fi bọnu Èdè nìkan ló lè mẹ́ni ṣèyí nírọ̀rùn o jàre Èdè mi ni ogún ìní mi! Èdè Yorùbá ò ní kú!! Ọmọ Odùduwà, ẹ̀ bá jí gírí sédè ẹ̀yin Níjọ́ mo dé ilẹ̀ Árábù níjọ́sí Ẹnu wọn ni mo fi í ṣèran wò Ní bí wọ́n ti í sọ Lárúbáwá lédè Níjọ́ mo dé Mìnà lọ́dọ̀ ọmọ Dzukogi Haúsá tí ó ń fọ̀ lédè ò wínrìn Ṣé ọjọ́ mo lọ wo ọmọ Adamu Manarakis Ní Nupé lọ́hùn-ún, ni mo fẹ́ sọ ni? Àbí èdè tí Yínmínrín olùkù mi dà bolẹ̀ ní Dẹ́tà ni mo fẹ́ fọ̀? Àwọn wọ̀nyí ò fèdè bàbá wọn pa mìídìn Bí ó bá sì ṣe Gẹ̀ẹ́sì náà ni wọ́n fẹ́ fọ̀ Ọ̀gá ni Múdà wọn, ẹ gbà bẹ́ẹ̀ Ọmọ Yorùbá, ẹ ronú! Ọmọ Yorùbá, ẹ kédè ẹ̀yin Ẹ ò mèdè í sọ, ọmọ yín náà ò tún mọ̀ Kín ni ìgbẹ̀yìn èdè yìí yóò jẹ́, ẹ wá rò fún mi Èmi Akéúgbadé ò ní jẹ́ sun tẹtẹrẹ Kógún ìní mi dogún àwọn ọmọ àtọ̀húnrìnwá Torí ohun onígbá bá pegbá rẹ̀ Layé í bá a pè é Èdè mi ni ìdánimọ̀ mi! Èdè mi ni ogún ìní mi!!
Nípa Òǹkọ̀wé
Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá ni, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Bó ṣe ń kọ ewì lédè Gẹ̀ẹ́sì, ló ń kọ lédè Yorùbá.
Ẹ ṣeun.