Lati ọwọ́ọ Wálé Adébánwi, Akin Adéṣọ̀kàn, Tádé Ìpàdéọlá, Ebenezer Ọbádáre, àti Oyèníyì Òkúnoyè.

Ni nǹkan bíi ọdún mẹ́fà sẹ́yìn ni àwọn ònkọ̀wé yìí  sowọ́pọ̀ kọ àpilèkọ yìí nígbàtí wọ́n ńṣakitiyan láti wa ọna ati bu iyì fún Láńrewájú Adépọ̀jù, akéwì pàtàkì àti òǹkọ̀wé kan gbòógì ní èdè Yorùbá, nípa fífi oyè ìmọ̀-ìjìnlẹ̀, dáa lọ́lá. Àwọn òǹkọ̀wé náà wá wòye pé nísinsìnyí, àwọn ìtọ́kasí yí ṣògbérè akíkanjú akéwì àrà ọ̀tọ̀ náà, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ níbí gẹ́gẹ́ bí àfikún ìmọ̀ àti ọ̀wọ̀ tó le se ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn láǹfààní.

Láńrewájú Adépọ̀jù, ẹni tó ṣe aláìsí ní ọjọ́ kẹwàá oṣù kejìlá ọdún 2023 ní ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83], jẹ́ oníṣẹ́ ọnà pàtàkì tó ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ lójú wa. Ó kò ipa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ewì Yorùbá, ó sì ṣe jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ nínú àwọn tó ń dáàbò bo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn nípasẹ̀ iṣẹ́ ọnà rẹ̀. Adépọ̀jù kò náání àwọn ìdènà tí ipò àtàpatádìde tí wọ́n bíi sí ṣe fún ẹ̀kọ́ rẹ̀, ìmọ̀-ẹ̀kọ́ jẹẹ́ logun, ó sì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà láì fẹsẹ̀ tẹ ilé ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn tí ò ti gbiyanju ọpọlọpọ awọn iṣẹ́-ọwọ́ l’óríṣiríṣi ní ìlú Ìbàdàn, o ṣe àwárí ẹ̀bùn rẹ gẹgẹbi akéwì, l’akọkọ gẹ́gẹ́bí oṣiṣẹ ní Ilé-iṣẹ́ Igbohunsafẹfẹ ti Iwọ-Oorun ti Naijiria ti atijọ, Western Nigeria Broadcasting Service (WNBS) àti lẹhin náà gẹ́gẹ́bí oniṣẹ́ aládáni.

Adépọ̀jù di gbajúmọ̀ láàárín àwọn akéwì Yorùbá ní sáà rẹ̀. Lónìí, a leè tọ́ka sí ìdàgbàsókè púpọ̀ tí ó ti ọwọ òǹkọ̀wé yí bá èdè àti àṣà Yorùbá. Àwọn ìlọsíwájú tí ó bù iyì, ikìmì àti ọnà kún ẹwà èdè Yorùbá láti ọwọ́ akéwì yí kò kéré láàrin ìṣe akíkanjú àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Òǹkọ̀wé naa jíǹkí wá pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu orí ìtàgé tí wọ́n tẹ̀ jáde, tí wọ́n ní àkọlé bíi Ládépò Ọmọ Àdánwò, S’Àgbà Di Wèrè, àti ìwé àròfọ̀, Ìrònú Akéwì, o tún ṣe àkójọpọ̀ ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n pè ní A Glimpse of Reality. Olóògbé Adépọ̀jù mú ewì lọ́kúnkúndùn, ó sì mú àwọn iṣẹ́ rẹ̀ láwùjọ àti àwọn àbùdá rẹ̀ gbòòrò sí í. Ní pàtó, Adépọ̀jù di ọ̀kan pàtàkì pẹ̀lú irùfẹ̀ ewì tí ó jẹ́ mọ̀ ipa ọgbọ́n àti ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀, ewì tí ó jẹ mọ́ kókó-ọ̀rọ̀, tí ó ṣe kókó nínú ohùn  orin, tí ó sì fìdí múlẹ̀ nínú ìtàn ẹ̀dá. Ipa tí ìmọ̀ kó nínú iṣẹ́ Adépọ̀jù hàn tààrà nínú àgbékalẹ̀ èrò rẹ̀ ati ìgboyà tí ó fií túmọ̀ awọn iriri ati awọn iṣẹlẹ káàkiri orilẹ-ede Naijiria ati ilẹ̀ adúláwọ̀.

Gẹgẹbi akéwì, iṣẹ́ Adépọ̀jù j’àǹfààní púpọ̀ nínú ìbárìn àti ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn olókìkí nínú iṣẹ́ ewì kíké, àwọn bíi Adébáyọ̀ Fálétí, Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀, àti Yẹmi Ẹlẹ́buìbọn. Ó ṣeéṣe pé èyí tó ṣe pàtàkì jùlọ nínú àwòkọ́ṣe Adépọ̀jù ni ìgboyà alailẹgbẹ tí ó fi hàn bi agbẹnusọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria lápapọ̀, paapaa jùlọ nigbati awọn ọ̀rọ̀ ẹ̀tọ́ ìlú, iṣedede àwùjọ ati ìdájọ́ ododo bá wà nínú ewu, láì jọ̀wọ́ ìfarajì rẹ̀ sí orilẹ-ede Naijiria. Àwọn ìpinnu ati iṣe rẹ bí akéwì tipa bẹ́ẹ̀ parapọ̀ lati sọ ọ di èèyàn pàtàkì káàkiri, kìí ṣe ni agbègbè àwọn Yorùbá nikan, ṣùgbọ́n níbi gbogbo ní Afirika ti ode òní tí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ohùn. Kò jẹ́ ìyàlẹ́nu nìgbà náà pe iṣẹ rẹ ti di àkòrí ìwé-ẹ̀kọ oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ mẹwa ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni awọn ile-ẹkọ giga ni Nigeria ati ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (Britain) láti bíi ọgbọn ọdun sẹhin.

Àmọ́ o, pẹ̀lú gbogbo ìfọkànsìn rẹ̀ sí iṣẹ́ ọnà ewì àti ìgbaniníyànjú fún ìdájọ́-òdodo láwùjọ, Adépọ̀jù kò gbé ìgbésí ayé ọlọ́rọ̀. Ó jẹ́ èèyàn tíí gba ìtẹ́lọ́rùn nìdí kí á lo ẹ̀bùn abínibí ẹni fun awọn idi ti olúwarẹ̀ nígbàgbọ́. Kii ṣe iyalẹnu rárá pe ìgbésí ayé rẹ ni awọn ọdun ikẹhin jẹ àwòrán ifẹ ati okiki nla ti o gbadun laarin awọn ti o mòye iṣẹ rẹ.

Kiní kan wá ba àjàò ìbáṣepọ̀ àwọn oníṣẹ́ ìmọ̀ ati awọn olùpilẹ̀ aṣa pàtàkì ní Naijiria jẹ́ – paapaa pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ ọnà àti awọn oṣere: apá rẹ̀ gùn ju’tan lọ. Eyi sáábà máa ń farahàn bi itara ni apakan, láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣẹ́ àsà, lati ṣe idanimọ ati láti ṣawari awọn àbájáde ti awọn oṣere ti o ṣiṣẹ́ síwájú ṣe lai fun wọn ni òṣùbà tó yẹ. Eyi ti jẹ ìpín ọpọlọpọ àwọn gbajúgbajà olorin ibilẹ̀ lorilẹede Naijiria, awọn oníṣẹ́ ohùn àti awọn òṣèré l’óríṣiríṣi , paapaa Haruna Iṣọla (1919-1983), Duro Ladipọ (1931-1978), Mike Ejeagha (1932–), Ayinla Ọmọwura (1943?-1980) , Fẹla Anikulapo-Kuti (1938-1997), Dan Maraya Jos (1946-2015), Dauda Epo-Akara (1945-2005), Johnson Adjan, Oliver de Coque (1947-2008) ati ọ̀pọ̀lọpọ̀ awọn miran. Àyàfi bíi àwọn àgbà òṣèré bíi Hubert Ogunde (1916-1990), Mamman Shata (1923-1999), ati Victor Uwaifo (1941-2022). Ìtùnú díẹ̀ ni pe ijọba orilẹ-ede Naijiria ti bẹ̀rẹ̀ sii kọbi ara si ọ̀rọ̀ àwọn oníṣẹ́ àṣà nípa bíbu ọla orilẹ-èdè fún wọn.

Gẹgẹbi igun kan pataki láwùjọ, àwọn oníṣẹ́ àṣà máa gba idanimọ fún ṣíṣe aṣáájú nínú ìṣe ọna tuntun tabi nínú ríran ẹwà àṣà lọ́wọ́ síwájú sii lọ́nà àrà. Wọn ṣe iranlọwọ pupọ fún awujọ nipa titọju àṣà ati itankale awọn iyì ọmọnìyàn pẹ̀lú iṣẹ́ wọn. Níwọ̀n ìgbà tí ó bá jẹ́ pé àfojúsùn ìtanilọ́lá pẹ̀lú oyè àti òkìkí bá nírán iṣẹ́ tó làmìlaaka, ìlọsíwájú ilú, àti ìmúgbòòrò ìrírí ẹ̀dá ènìyàn ní pàtàkì, ó yẹ kí ààyè wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣáájú láàrin àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àṣà ní Nàìjíríà láti ni ìpín. ̀Kò yẹ kó jẹ́ ìdènà rárá láti ka àwọn ọ̀jìnnì àárín wa sí àti láti kà wọ́n yẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò kọ́ ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi tayọ ní ilé ìwé kankan, pàápàá nígbàtí àwùjọ nla ba mọ ipa àwọn olóyè ènìyàn yí.

Láńrewájú Adépọ̀jù jẹ́ akéwì Yorùbá tó kọ́ ara rẹ̀. ́ Wọ́n bíi ní abúlé Ọ̀kẹ́-Pupa ní oríko Ìbàdàn lọ́dún 1940. Níbẹ̀ ni ó ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé, ó sì fi ara rẹ̀ hàn dáadáa nípa àṣà àti ìlànà àwọn èèyàn rẹ̀. Nítorípé àwọn òbí rẹ̀ jẹ tálákà, ó ṣòro fún wọn lati ran-an lọ si ile-iwe, ṣugbọn ipinnu rẹ lati kọ́ ẹ̀kọ́ jẹ ki o wa iranlọwọ dé ọwọ́ ibatan rẹ̀ lati kọ ẹkọ ni ábẹ́lé. Ó yà gbogbogbò lẹ́nu pé ó ṣeé ṣe fún un láti mọ̀ ’wéé kà àti láti kọ́ ìwé-kíkọ láàárín àkókò ráńpẹ́. O wá lọ si Ibadan nibiti o ti ṣiṣẹ́ ni awọn akoko oriṣiriṣi gẹgẹbi oṣiṣẹ ile-epo, òǹta iwe-iroyin àti ọmọ ọ̀dọ̀. Gẹgẹ bí ọ̀dọ́mọkùnrin, ó fi ìfẹ́ ìmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn hàn nípa bí ó ti fìdítì sì ilé ìkàwé àtijọ́ Western Region ní Ìbàdàn. Ẹ̀rí pé ó mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà ni pé nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí òǹkàwé fún Ìmọ̀lẹ̀ Òórọ̀, tí ó jẹ ìwé ìròyìn nígbà náà, ó sì jẹ́ òǹkọ̀wé tí a tẹ̀ jáde.

Awọn ẹ̀bùn Adépọ̀jù kúkú wá fún un lòkìkí nígbà tí ó dé ilé-iṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́, ó sì mọ rírì ìtumọ̀ kì akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bíi Adébáyọ̀ Fálétí jẹ́ ẹni tí ó ṣe àyẹ̀wò fún òun kí wọ́n tó o gbáà sí iṣẹ́. Lẹ́yìn náà ló ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún ètò òwúrọ̀ kùtùkùtù fún àwọn akéwì Yorùbá. Ile-iṣẹ Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ ti Ìwọ̀-Òòrùn ti Naijiria ló pèsè ààyè tí ó jẹ́ kí Adépọ̀jù di alámọ̀dájú  nìdí ewi kíké lórí ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀mágbèsì àti lati fi ìdí iṣẹ-ọnà rẹ múlẹ̀. Láìpẹ́, ó di olókìkí pẹ̀lú àìmọye àwọn olólùfẹ́ rẹ ti o tan káàkiri ìhà Ìwọ̀-Òòrùn àtijọ́. Bí ọjọ ṣe ńlọ síwájú ó bẹ̀rẹ̀ sí í rí iyì iṣẹ́ rẹ̀, ní pàtàkì bí WNBS/WNTV ṣe fẹ́ẹ́ fi ẹ̀tọ́ àwòpín iṣẹ́ rẹ̀ dùn-ún. Eyi mu ki o ṣe ipinnu lati pínyà pẹlu ile igbohunsafefe náà, kí ó sì lọ ṣe ètò aladani nípa dídá LANRAD Records, silẹ. Ni ìgbà tí yóó fi tẹrí gb’aṣọ, ó ti ṣe agbejade awọn àwo-ìkọrin ati kásẹ́ẹ̀tì ohun afetigbọ bíi ọgọrun ni Ewì Hit Hot Series.

Àníyàn ewì Adépọ̀jù pọ̀ pupọ, láti orí ìmọ̀ràn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ti ó fi ìgboyà ṣe fún àwọn aṣáájú òṣèlú Nàìjíríà gẹgẹ bí agbẹnusọ àwọn aráàlú, sí ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ìwà rere àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí. Nitori ìdí èyí, ìjọba ológun maa ńyọ ọ́ lẹ́nu, pàápàá jùlọ, lábẹ́ ìjọba Ibrahim Babangida lẹ́yìn tí Adépọ̀jù, ti ṣe àwo orin ti àkọlé rẹ̀ ńjẹ́ Aye pe Meji. Bi Adepọju ṣe ri ara rẹ gẹgẹbi akewi, eyiti o máa ń tẹnumọ̀ nigbagbogbo ni ìparí ewì kọọkan, a máa yatọ gẹ́gẹ́ bi ìrònú àti ifiyesi rẹ. O rí ara rẹ bi olukọ, oludamoran, olutupalẹ ti ìwà, koko aṣa ati awọn ilana ẹsin. Nípa bẹ́ẹ̀, ó fojú inú wo iṣẹ́ akéwì gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ olóye nínú àwùjọ tí ń fi ọ̀wọ̀ àti ìlàwọ́ mú ọgbọ́n ènìyàn gbèrú síi. Kò sí àní-àní pé ó gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn èrò tó ń polongo nípa iṣẹ́ akéwì nínu iwe Ironu Akewì.

Ìdàgbàsókè Adépọ̀jù gẹ́gẹ́ bí akéwì fi ojú ìwòye rẹ̀ tí ó fi gbogbo ìgbà dàgbà sí hàn gẹ́gẹ́ bí ipa pàtàkì lórí iṣẹ́ rẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ nínú Ironu Akewì gẹ́gẹ́ bí olùgbégbèésẹ̀ àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ojú ìwòye ìbílẹ̀ laarin awọn Yorùbá. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ irisi rẹ̀ ní àyíká rẹ, bí àwọn gbajúmọ̀ àti alájọṣe pọ̀ rẹ tii gbé ayé wọn ní Nàìjíríà nípa fífi ohun èlò orin àwọn òyìnbó sínú iṣẹ́ rẹ̀. Lẹhinna, o yọ ere orin kuro ninu awọn ewi rẹ, fun awọn idi ẹ̀sìn, àti lati gbiyanju ṣafihan rẹ (orin ewi rẹ) pe o lagbara lati dá ṣe atọ́kùn àròjinlẹ.

Ó ṣeé ṣe láti sọ àsọdùn nípa ipa ẹ̀sìn nínú iṣẹ́ Adépọ̀jù. Lọ́nà kan, iṣẹ́-ọnà àti ìgbòkègbodò rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn fi ìrìnàjò àwọn Yorùbá nínú oríṣiríṣi èrò ati ẹ̀sìn hàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Mùsùlùmí ni Adépọ̀jù ti dàgbà, nígbà kan, ó ṣe dábá ìjìnlẹ̀ adahunṣe àti oríṣi ẹ̀sìn Kristẹni. Ipadabọ rẹ si ẹsin Mùsùlùmí ni ọdun 1985 dabi ẹni pe o jẹ iṣẹlẹ ẹsin ti o han julọ ninu iṣẹ rẹ. Sibẹsibẹ, bí a bá fi ojú inú wòó, a ó rii pé ó ṣòro láti sọ pàtó pé ipa tí àwọn iṣẹ́ náà tọ̀ lèyí. Bí a bá tọ ẹ̀rí ìwé ewì kan ṣoṣo tí Adépọ̀jù kọ gẹ́gẹ́ bí akéwì, ó hàn pé akéwì náà jọ àwọn akẹgbé rẹ̀ yókù, ó ṣe alábàápín ninu ìwòye àwọn Yorùbá, bí ó ti jìn tí ó sì fẹ̀ tó. Síwájú sii, a ó rí ẹ̀rí àkóyawọ́ ati mímúludùn fun gbogbo gbòò tí àwọn Yorùbá kúndùn. Ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ẹ̀sìn tí ó gba èrò púpọ̀. Ìgbékalẹ̀ tí ó jinlẹ̀ jùlọ tí kò sí yọ ẹlẹ́sìn kankan sílẹ̀ rárá wà nínú iṣẹ́ akewi Adépọ̀jù  tí ó pè ní “Oriki Olodumare.” Kò yani lẹ́nu pé, èyí jẹ́ àṣàrò kan tí ó fi iwoye Adépọ̀jù lori ẹ̀sìn fún àkókò pípẹ́ han. Ògédé pé kò sí èrò ẹlẹ́yàmẹ̀yà tààrà nípa Olódùmarè ṣe àlàyé ìtẹ́wọ́gbà tó gbòòrò tí iṣẹ́ náà ní ati òpó pàtàkì tí ó jẹ́ nínú gbogbo àwọn iṣẹ́ akewi náà.

Akitiyan àwùjọ tí kó fi ìgbà kan ṣe àì tẹsiwaju ninu iṣẹ Láńrewájú Adépọ̀jù tayọ bí akewi náà ṣe padà sínú ẹsin Mùsùlùmí. Ṣugbọn ṣáá, iṣẹ ìríjú rẹ ninu ijajagbara awujọ kò fà sẹ́yìn rara, ó sì jẹ bíi idari tàbí arọ̀ tí ojúṣe tí Adépọ̀jù rọ̀ mọ́. Iṣẹ́ Adépọ̀jù kò sáábà jọ ti òṣùwọ̀n rẹ̀ nígbà tí bá ń lépa àwọn iṣẹ́ ìṣèlú, ti òṣèlú tàbí ti ara rẹ̀. Eyi ṣe alaye idi ti ó fi jẹ pé awọn iṣẹ rẹ̀ ti o gbajumọ julọ, tí a lè fọwọ́ sọyà pé wọn jẹ aṣojú akéwì naa jẹ àwọn iṣẹ́ tí ó tọpinpin ìpọ́njú ati awọn ìrètí awọn eniyan rẹ̀. Bí “Ilu Le,” tí ó tẹ jáde ni1987, ti o jẹ ki awọn aráàlú gbé òṣùbà ati òkìkí fun u ni apa kan, tí ó sì rí ibinu ijọba ologun ti Babangida ni apa keji, jẹ iṣẹ ti o gbajumọ julọ, ó ṣeéṣe pé ó rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé o jẹ àpẹẹrẹ èyí tó dara julọ  ninu awọn iṣẹ́ ewi akewi yí ni.

Adépọ̀jù àti iṣẹ́ rẹ̀ ti fa àkíyèsí àwọn onímọ̀. Ìtẹ́wọ́gbà ti iṣẹ rẹ rí lọ́dọ̀ àwọn onímọ̀ jẹ́ àfihàn àti àpẹẹrẹ iwunilori pẹlu agbara ti ewi náà ni. Diẹ ninu awọn ifiyesi akọkọ pẹ̀lú iṣẹ rẹ (Folorunso 1990) wádìí ilowosi rẹ ninu awọn ewi ti iṣelu. Ọ̀rọ̀ àròkọ Wọle Ṣoyinka ní 1990 tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Twice Beaten: The Fate of African Cultural Producers’’, tọ́ka sí bí Adépọ̀jù ṣe yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ to lòdì sí àwọn ìjọba ológun tí ń rú’lú ní Nàìjíríà. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé mìíràn bíi Adebayọ Williams, Ayọ Olukọtun, Oyeniyi Okunoye, àti Jonathan Haynes ti ṣe àlàyé lórí àwọn ìdáwọ́lé àti ìyọnu rẹ̀ tí ó yàtọ̀, ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ìbílẹ̀, àti atọ́kùn ogún àìdẹ́kunjà rẹ̀ pẹ̀lú ìgbòkègbodò rẹ̀ títí dé òpin ijoba ologun Babangida. Àwọn ìwádìí mìíràn tọpinpin ewì àti ìdàgbàsókè iṣẹ́ ọnà Adépọ̀jù ati bí ó ti sapá kí iṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò síi nípa ìdàgbàsókè àwọn lítíréṣọ̀ ọ̀rọ̀ ẹnu àti kíkọ Yorùbá, tí ó sì fi àwọn ọ̀nà pàtàkì tí ó gbà mú kí ewì Yorùbá di àtewọgbà lápapọ̀. Àpapọ̀ àwọn ẹ̀rí wọnyi láti ọwọ àwọn ọ̀mọ̀wé jẹ́ ká mọ̀ ni pé iṣẹ́ Adépọ̀jù ṣ’ojú, ó sì ń ṣẹ̀sọ fún ewì Yorùbá àti ti Áfíríkà lóde òní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Dájúdájú, lọjọ iwaju, ipa rẹ lori èwì Áfíríkà yíò gba àkíyèsí tí ó tọ́ síi.

–Ìtúmọ̀ sí èdè Yorùbá láti ọwọ́ọ Tádé Ìpàdéọlá. Ẹ le rí ojúlówó iṣẹ́ náà kà ní orí Premium Times.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *