Ìtìjú Dà?
Àyìndé dé tòhun tàròfọ̀ Orí Àyìndé ò ní balẹ̀ Kó má mà yí nǹkan. Ohun ojú akéwì ń rí gọntíọ Ó di dandan kí n wí Torí bára ilé ẹni bá ń jẹ kòkòrò búburú Tí kò ní jẹ́ kára ilé ó sún àsùndọ́kàn Ó dára ká tètè pariwo já gbàgede Bóya oníwà ìbàjẹ́ á sagbéjẹ́ mọ́wọ́ Kómi ó tó tẹ̀yìn wọ̀gbín lẹ́nu. Tára ilé ẹni bá ń rìnrìn ìdọ̀tí Ó lẹ́yẹ ká tètè pèpàdé àpérò Kí gbangba ó tó dẹkùn Kí kedere ó tó wá bẹ̀ ẹ́ wò. Ohun èwe ìwòyí ń dá lárà Burú, ó tún bògìrì. Òmíràn a wọṣọ a dàbí alawoku Ohun Elédùà fi pamọ́ sáyè ìkọ̀kọ̀ Tí dohun wọn ń pàtẹ̀ sí gbàgede Ìyàtọ̀ ò sí láàrin alárùn ọpọlọ atèèyàn gidi Gbogbo ọmọ ló doníhòòhò Nítorí à ń soge tí ò ní láárí Wọn a máa yan fanda nínú aṣọ ìkókó Wọn a tún máa fọwọ́ fà á sílẹ̀ lódìlódì Àwọn akọ dabo òjìji láìbìkítà Kùkúye tí wọ́n ń yọ́ mu tẹ́lẹ̀ Alákọrí wọn sọ ọ́ dohun igbangba. Wọ́n dẹni tí ń dirun bí abo. Bí alákàn ni púpọ̀ ń rìn Akọ ti sọ wọ́n di bẹ́gbẹ́ wọ̀ ọ́ Bí ọkọ̀ kan tí ń bẹ láyé ọjọ́un. Wọ́n a gàdí rìn bí ẹní sòpá Bẹ́líìtì tí wọn ò lò ni sábàbi. Àwọ̀tẹ́lẹ̀ òmíràn a ti rẹkà, ṣíọ̀! Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́ a ní ṣe ló ń pọ́n. Dúníyàn yìí ti wọ́ bí apá ajá Ìtìjú ò sí fún baálé pẹ̀lú abilékọ Bàbá tó ti wà ní bèbè sàáré Yeye tójú ti hun jọ bí ẹni ọyẹ́ mú Orin kò sárúgbó ń Gánà Ni wọn ń fojoojúmọ́ kọ. Àwọn tó yẹ ki wọn ó kọ̀wà ìbàjẹ́ Ìlú máa jó nìṣó ni wọ́n ń lù. À á ti í ṣerú èyí tayé ó fi rójú? À á ti í ṣèyí ti dúníyàn ó wà létòletò? Aṣọ ilẹ̀ yìí ò da lọ́rùn sùẹ̀gbẹ̀ Kákọ́ ó wọ bùbá àti ṣòkòtò Pẹ̀lú agbádá òun abetí ajá Ìyẹn ò jẹ́ dọ́rùn wọn láé Tilẹ̀ òkèèrè ni wọn ń gbé lárugẹ. Kóbìnrin ó rú sí ìró àti bùbá Pẹ̀lú ìpèlé tí ń fọmọ Yoòbá hàn Péńpé bí aṣọ eṣinṣin ni ràì. Kùkúyè tí wọ́n ń yọ mu tẹ́lẹ̀ Òhun ni takọtabo fi ń jagbà wàyí. Àwọn ilé ìjọsìn tó yẹ kó ṣe wàásù Korí ẹni tí ò sùnwọ̀n ó fapo Owo ni wọn ń wárí fún Lèmọ́mú òun pásítọ̀ ti jẹ dòdò Òdodo wá hán bí ojú lẹ́nu wọn. Òbí tó yẹ kó ṣèkìlọ̀ fọ́mọ Àwọn gan-an ti gbàtúẹ̀yọ̀ Ìgbà tí baba ti ń mutí Ó ti dandan kọ́mọ ó rògò mu Ìgbà tí yeye tí dàgbóde gbà Ọ̀nà dà tọ́mọ ò ní di gbéwiri. Ìtìjú wá dà?
Rántí Àná
Ẹni tó dènà fún ni kẹ́rù Ó le jagun juni lọ Ẹni tó fẹ̀mí jinkú fúnni Kò tọ́ ká fojú olóore rẹ̀ gungi. Ẹni a fẹ̀yìn tì, tí ò yẹni gbálẹ̀ Tá a dẹni ń mu dídùn ọsàn Ẹni ó fún ni lákàbà a fi gòkè Tí a dẹni ayé ń ṣe sàdáńkátà. Bí a bá n fojoojúmọ́ lù ú lọ́gọ ẹnu Kò kúkú sí laifi nínú ẹ̀. Aláìmoore pọ̀ bí erùpẹ̀ òkun Nínú ọmọ Áádámọ̀ òun Eéfà. Ọba má ṣe wá lódò Tó gbàgbé orísun ẹ.
Nípa Òǹkọ̀wé
Ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.