Ayé yìí ò le 
Pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ lejò ń gàgbọn. 
Ayé yìí ò gba gìrìgìrì 
Lọ̀gà fi ń tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́jẹ́. 

Ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló láyé 
Dúníyàn ò fẹ́ gìrìgìrì. 
Ẹ̀kọ gbígbóná ń fẹ́ sùúrù 
Ìkánjú kìí gbéni débi kan 
Àbámọ́ ní ń kẹ́yìn ẹ̀. 

Bójú bá fara balẹ̀ 
A kúkú rímú. 
Ìran ọlọ́gbọ́n a tẹlẹ̀ jẹ́jẹ́. 
Ìran òmùgọ̀ a tẹ̀ ẹ́ bàṣùbàṣù. 

O jẹ́ rọra onímọ́tò yìí 
Ẹ̀mí kan ma ló ń bẹ 
Rántí àwọn èrò tó o gbé 
Bí ìwọ bá ti ṣòògùn àìkú. 

Àbí tajútajú tó o mu tí ń tọró? 
Àbí gbáná tó fà ti ń ṣiṣẹ́? 
Kí làgbọ̀nrín rẹ rí gan-an 
Tó fi ń ṣekùn gbẹndu sọ́lọ́dẹ? 
Wọ́n ní kó o dín eré kú 
Nítorí à súre tete kò le 
Sáré kọjá ilé. 
A rìn gbẹ̀rẹ̀gbẹ̀rẹ̀ lọ́nà 
Kò ní sùn nírònà. 

Àbí ẹ ti ní òkú èèyàn lọ́rùn 
Ní dẹ́rẹ́bà ń fọ̀ létè? 
Ká pẹ́ débi à ń rè 
Sàn ṣe ká kánjú re kìyáómọ̀. 

Ẹni tó bá sọ pákéwì ń pàátó 
Kó relé ìwòsàn lọ wo 
Àrà táṣídẹ́ǹtì ti fàwọn èèyàn dá 
Ó ti pẹ́ tí mo ti ń wakọ̀ 
Kò ràn án rárá ọ̀gá dẹ́rẹ́bà! 

Àpá kò lè jiná dàbí ara láéláé. 
Dẹ́rẹ́bà yìí o jẹ́ rọra 
Rántí pé ẹni tó dárí sílè 
Òun láwakọ̀ tó dáńgájíá. 

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *