Orúkọ mi ni Kọ́lá Túbọ̀sún. Mo wá láti ibi kan tí a ǹpé ní Ibàdàn, níbè ni wón bí mi sí, àmọ́ ìlú Èkó ni mo gbé, ní ilẹ̀ Nàìjíríà. Ìgbà àkọ́kọ́ mi níyì ní Korea. Wọ́n ti sọ fún mi wípé mo máa n yára sọ̀rọ̀, nítorínà ni n o ṣé máa n gbìyànjú láti máa rọra sọ̀rọ̀ kí o lè yé gbogbo ènìyàn. Ìgbà àkọ́kọ́ mi nìyí ní ilẹ̀ Korea, pẹ̀lú Àsìá. Kódà, ìgbà àkọ́kọ́ mi níyì ní gbogbo ibi tí mo ti dé láti ọjọ́ tí mo ti wo ìlú yìí. Nígbà àkọ́kọ́ tí bàálù wa balẹ̀ sí Incheong, a yà sí Seoul, a sì tún kò sí Busan, Seoul ni mo sì tún ti padà sí ibí yìí. N ó lo sí Incheong ni ọlá, lẹ́yìn náà, n ó padà sí i ìlú mi. Mo tí gbádùn l’ọ́pọ̀lọpọ̀, ní pàápàá ìwà ọ̀rẹ́ àwọn ènìyàn ìlú yìí. E ṣeun.

Iṣẹ́ mi ṣẹ́yọ nínú akọ́mọlédè, èdè àti lítírésò. N ó ṣ’àlàyé bí gbogbo rẹ̀ se lọ́pọ̀ sí ònà kan, tí ẹ bá sí tìi ka ìwé àrọ̀kọ mi, ẹ ó ti mọ́ nípa iṣẹ́ mi àti àwọn oun tí mo ti ṣe ní bíi àwọn ọdún kan sẹ́yìn bótilẹ̀jẹ́pé mo sì kéré lójó ori, gẹ́gẹ́bí ẹ o tí ṣe kàà.

Ìlú Nàìjíríà wà ní ìwọ̀ oòrùn Áfíríkà. Ó sì ní tó igba ólé l’àádọ̀ta oríṣiríṣi ẹ̀yà àti ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta oríṣiríṣi èdè. Èyí máa njẹ́ ìyàlẹ́nu fún àwọn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn nítorípé wọ́n pọ̀ gidigidi ní kíkà. Àmó oun kan tí ó yẹ kí ẹ mọ̀ ni pé kìí ṣe gbogbo èdè yìí ni a máa nso, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn èdè yìí lóti n múra àti di oun ìgbàgbé. Òmíràn tilẹ̀ ti kú. Àwọn míràn ṣì wà àmọ́ wọn kò lò wọ́n mọ́ bí ó ṣe yẹ kí wọ́n lò wọy, èyí yíò fa ikú wọn b’ópé b’óyá. Ìdí èyí pín sí oríṣiríṣi. Ọ̀kan lára àwọn ìdí náà ni ìṣètò ìjọba, ọ̀kan sì tún ni ìṣètò amúnisìn èyí tí mọ máa tún ṣàlàyé síi nínú ìwé yìí, ọ̀kan nínú àwọn ìdí yìi ni ìhùwà àwọn ọmọ Nàìjíríà àti Áfríkà lápapò sí èdè abínibí wọn. Èyí sì ti ṣe okùnfà ìfàsẹyìn ní ètò ẹ̀kọ́, òṣèlú, ìgbáyé gbádùn àti gbogbo ẹ̀ka tí a ti ńlo èdè. Inú mi dùn gidigidi nígbàtí mo gbọ́ wípé èdè Korean ni èdè tí gbogbo ènìyàn gbárùkù tì ní ìlú yìí, b’ótilẹ̀jẹ́pé ọ̀pọ̀ ló kọ́ èdè gèésì, wọ́n kọ́ láti lè bá àwọn ẹlòmíràn láti ìlú míràn sọ̀rọ̀. Èdè Korean nìkan ló jẹ́ ọ̀kúnkúndùn.

Ní ìlú Nàìjíríà, èyí yàtọ gidigidi. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti pinnu wípé èdè gèésì nìkan ló ṣe kókó láì bìkítà fún èdè abínibí wọn nítorí wọn kàá sí èdè tí kòò ní ànfààní fún wọn. Àmọ́ àwọn péréte ṣin bẹ tí wọ́n ṣin rí ànfààní nínú àwọn èdè abínibí won, tí wọ́n nṣọ won sí àwọn ọmọ wọn, tí wọn sì nṣẹ iṣẹ́ wọn pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́ ìsesí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ọmọ ìlú Nàìjíríà kò bìkítà fún èdè abínibí nítorítí èdè gèésì ti darapò mó èdè wa.

Ní báyìí mo lérò wípé ó yẹ kín sàlàyé bí èdè gèésì se di olórí èdè lóri èdè abínibí ni ìlúu Nàìjíríà. Kí àwọn aláwọ̀ funfun ti Brítánì tó dé sí Nàìjíríà, a jẹ́ oríṣiríṣi ẹgbẹ́, yálà tí ó tóbi tó ìlú tàbí kéré bíi ìletò, a sì n gbé pọ̀. Sùgbón nígbàtí àwọn Brítánì dé, wọ́n kó gbogbo wa pọ̀ láti jẹ́ orílẹ̀-èdè kan — Nàìjíríà. Nítorí ìdí èyí, láti lè bá gbogbo ènìyàn sọ̀rọ̀ ní èdè kan, wọ́n ní láti jẹ́ kí èdè wọn pọn dandan fún mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn. Èyí sì ní bíi èdè gèésì ṣe wọlé. Ó dámi lójú wípé ẹ̀yin náà ní ìrírí yìí láti ọwó àwọn Japanese àti àwọn amúnisìn míràn. Àbájáde ìhùwà yìí ni wípé ó wá pọn dandan fún gbogbo wa láti kọ́ nípa èdè gèésì ní ilé ẹ̀kọ́ wa.

Àwọn Brítánì, tilẹ̀ tún máa nse oun kan nípa lílo àwọn ọba tàbí àwọn ìjòyè agbègbè ní ibòmíràn láti jẹ́ aṣojú fún àsè Brítánì, wọn á máa mú aáyan ọ̀gbùfọ̀ tí ó gbọ́ èdè gèésì àti èdè abínibí agbègbè yìí dání láti wá bá àwọn ọmọ agbègbè náà sọ̀rọ̀ nítorí wípé ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n lè gbà fi b’áwọn sọ̀rọ̀ níyì, nítorínà wọ́n f’àyè gba ìtẹ̀wé ní èdè abínibí ní àwọn agbègbè míràn. A túnmọ̀ Bíbélì, bíi àpẹrẹ, sí èdè Yorùbá, Ìgbò àti èdè ibòmíràn nítorí iṣẹ́ ìhìnrere. Àwọn ohun kàn kan bẹ́ẹ̀ náà nsẹ́yo èyí sì fún èdè abínibí ní iyì. Àwọn èdè abínibí wọ̀nyí kò sí d’ọ̀kú fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún. Àmọ́ ní kété ti àwọn amúnisìn Brítánì lo, àwọn ẹ̀tọ́ amúnisìn, ara èyí ti àwọn èdè abínibí díẹ̀ nrí ànfààní, parẹ́.

Ní ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún sẹyìn bíi 1940 sí 1950, àwọn akọ̀wé kan t’ẹ̀wé ní èdè Yorùbá, ọ̀pọ̀ ló sí t’ẹ̀wé ní èdè Ìgbò, Hausa àti àwọn èdè míràn. Bàbá nlá mi, tí ó ti pé àádọ́rin báyìí ka àwọn ìwé Yorùbá lítírésò kan nígbà tí ó wà ní èwe, àwọn ènìyàn díè ló ṣì le rántí àwọn ìwé wọnyí. Ọ̀kan lára àwọn akọ̀wé ìgbà náà tí o l’òkìkí jùlọ ni D.O Fágúnwà. Ó t’ẹ̀wé jáde ní 1940. Oríṣiríṣi irú àwọn ìwé wọnyí wà, àmọ́ lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún, nítorí ìhùwà àwọn ọmọ Nàìjíríà sí èdè wọn gẹ́gẹ́bí mọ ti sọ l’ákọkọ́ pẹ̀lú ètò ìṣúná ìlú, ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ilé ìtẹ̀wẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní yẹra fún títe ìwé ní èdè abínibí, wọn sì gbájúmò àwọn ònkòwé ti èdè gèésì. Ní àkókò yíì, ònkòwé bíi Sóyinká, Achebe, Amos Tutùolá, Buchi Emecheta, Elechi Amadi àti àwọn ònkòwé míràn nbẹ́rẹ̀ síní t’ẹ̀wé jáde ní èdè gèésì. Ní àsìkò yìí, a bẹ̀rẹ̀ sí ní túmọ̀ lítírésò Nàìjíríà, èyí ni àwọn ìwé tí a tẹ̀ jáde ní Nàìjíríà, ni ede gèésì.

Ònkòwé bí Chinua Achebe nígbà náà jiyàn wípé èdè gèésì tí òun fi n kọ̀wé jẹmọ́ awọn àsàyàn kankan nínú èdè Ìgbò, òun sì nlo oríṣiríṣi ọ̀nà láti ṣàfihàn àwọn àkànlò-èdè àti òye ti èdè Ìgbò nínú ìwé rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àríyànjiyàn ló ṣẹ́yọ bóyá a lè pe irú èyí ní ọ̀nà tí ó tó tàbí ìfarahàn ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀tàn tí àwọn amúnisìn gbìn sí ọkàn àwa ènìyàn dúdú lórí àsà waa. Níkẹyìn, èdè tí o fi n kọ̀wé yíò ṣe atọ́nà oun tí yíò ṣẹ́yo nínú ìwé re. Irú ọ̀rọ̀ yìí ní a lè rí àpẹẹrẹ rẹ̀ nínú ìwé Chinua Achebe fúnrarẹ̀, Things fall apart, èyí tí a ti túmọ sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ èdè tó lé ní àádọ̀ta àmọ́ tí a kò tíì túmọ sí èdè òun tìkalárarẹ̀ — èdè Ìgbò. Njẹ́ tí a bá wípé a lè rí afárá èdè gèésì nínú èdè Nàìjíríà, njẹ́ a lè wá so wípé èdè gèésì nìkan ni èdè Nàìjíríà bìí? Èyí jẹ́ ìbéèrè pàtàkì tí mo ti n bi ara mi leeré.

Bó tilẹ̀ jẹ́ wípé o ṣeéṣe kí èdè gèésì ti di aṣojú ẹ̀yà kan lára èdè Nàìjíríà, ìdí èyí nipé èdè gèésì ti di lílò ní Nàìjíríà fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún. Ìbéèrè tí a lè wàá máa bi ara wa lérè ni wípé, èdè Nàìjíríà mélòó ni a o kà kí a tó lè pe ara wa ní ẹlẹ́dẹ̀ gèésì tó mọ́yánlórí nítorípé lẹ́yìn odi, àwọn ènìyàn kò rí wa gẹ́gẹ́bí omo ẹlẹ́dẹ̀ nítorí a kò jẹ́ aláwọ̀ funfun l’ákọkọ́ ná, àti pé kò já mó nkankan bí ènìyàn tilẹ̀ bá ti n sọ èdè elédè. Èkejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá sì wípé èdè gèésì gan-an ni èdè wa, báwo ni a ti ṣe àwọn èdè míràn? Bí èdè gèésì bá jẹ́ aṣojú ẹ̀yà kan lára èdè Nàìjíríà, ájẹ́wípé àwọn èdè míràn nbe ní agbada.

Bí  wọ́n bá túmọ̀ Things fall apart láti ọwó Chinua Achebe sí èdè àádọ̀ta tí kò sì sí ní èdè Igbo, ájẹ́wípé nkán tíì ṣẹlẹ̀ sí ìpínlẹ wa, mo gbàgbọ́ bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé, kí Achebe tó di olóògbé, ó tiraka láti túmọ ìwé náà gẹ́gẹ́bí wọn ti so fún mi. Nítorí kò ka oun tí àwọn míràn ngbìyànjú láti ṣe pé kí wọn túmọ̀ rẹ̀ sí èdè Ìgbò nítorí ó gbàgbọ́ wípé òun ti ṣe oun tó tọ́ àti tó yẹ fún ìwé náà.

Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ mi ló dá lórí ẹ̀rọ ayárabíàṣá, àmọ́ nígbà míràn, máà tún kọ́ṣẹ́ lórí lítírésò. Nínú gbogbo èyí, àríyànjiyàn mi nipé, ìparun èdè máa n wáyé l’óríṣiríṣi ọ̀nà. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí ni àìsí ọ̀nà láti tẹ àwọn ìwé ní èdè abínibí lópòlopò. Nítorí ètò ìṣúná ti lọlẹ̀ ní àwọn ọdún 1990, àti wípé ọ̀pọ̀ ló pinnu láti má t’ẹ̀wé jáde mó, àwọn ilé ìṣẹ́ ìtẹ̀wẹ́ náà pinnu láti máṣe t’ẹ̀wé mọ́ èyí ló fàá tí kò fi sí àwọn iwe ni ede Igbo, Hausa, ati Yorùbá ní àkókò yíì ti àwọn ènìyàn lè ko tàbí tí wọn ti ka. Àbájáde èyí ni wípé èdè ọ̀pọ̀ ènìyàn ní kò ní lè mọ̀ọ́ kọ àti mọ̀ọ́ kà ní èdè abínibí wọn, èdè sì nìyí, kìí ṣ’àdédé yè sí ìran míràn láì sí ìrànwọ́ ìran àkókò.

Mo wao ngbájúmọ́ ẹ̀rọ ayárabíàṣá nítorí wípé mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, àwọn ọ̀dọ́ ìwòyí sì ngbájúmọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Gbogbo wa la ní ẹ̀rọ alágbèéká, ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, àti ẹ̀rọ ayárabíàṣá. Nígbà tí o bá lọ sí orí ìtàkùn àgbáyé, yíò yẹ ọ — àmọ́ bóyá kó rí bẹ níbí yìí nítorí èdè Korean jẹ́ èdè tí ó ti gbinlẹ̀ gidigidi tí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ṣí n sọ — àmọ́ ní Nàìjíríà, oun gbogbo lórí aféfé ni èdè gèésì. Gbogbo ibi tí o bá wo, ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán, CNN àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Èyí sì ni pé, èdè gèésì ti gba gbogbo ibi. Èyí tún ni wípé, kò sí wàhálà fún èdè gèésì nítorí wípé kò ní ṣe aláìsí. Àmọ́ àwọn èdè mìíràn níbi tí àwọn ẹ̀rọ ayárabíàṣá yìí bá wà yíò jìyà àìlèso ati àìlèkà. Àpẹẹrẹ ni Bàbá Àgbà mi tí mo sọ̀rọ̀ rẹẹ̀ ní ìṣájú, ó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàlélọ́gọ̀rún, ó sì lè kọ àti mọ̀ọ́ kà ní èdè Yorùbá nítorí èdè yìí ní a fi ko nígbà tí o sì wá ní ọmọdé. Yorùbá jẹ èdè tí a n kọ ní àmì, o sì lè kọ Yorùbá rẹ pẹ̀lú àmì. Bí ọ bá kọ ounkóun síi ní èdè Yorùbá, yóò dá ọ lóhùn yíò sì tún kó padà sí ọ ní èdè Yòrùbá. Àmọ́ kò lè kọ, kò sí lè mọ̀ọ́kà ní èdè gèésì. Bàbá àgbà mi yìí sì ni èro alágbèéká èyí tí a ko ní èdè gèésì. Nínú àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí, a lè mú oríṣiríṣi èdè tí ó bá wù wá gẹ́gẹ́bí French, German, abbl. àmọ́ o kò lè yìí ẹ̀rọ rẹ sí èdè Yorùbá nítorí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ilé iṣẹ́ nlánlá ni kò tíì ṣe ohun èlò tí yíò ní Yorùbá lédè.

Àwọn ènìyàn bí ọgbọ́n mílíọ̀nù níí sọ èdè Yorùbá ní ilé Nàìjíríà àti l’ókè òkun. Mo ti ṣàkíyèsí láti ìgbà ilé ẹkọ́ mi ní fáfitì wípé ẹ̀rọ Microsoft word máa n fàlà sí ìdí orúkọ mi ní àwọ̀ pupa láti fi hàn mí wípé orúkọ yìí kò lo ní ìbámu. Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn ẹ̀rọ ni a kò ṣẹ̀dá ní èdè áfríkà àmọ́ ní àwọn èdè míràn. Tẹ́lẹ̀ mo máa nso wípé bóyá nítorí pé kìí ṣe gbogbo ènìyàn ní máa lo àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyí, àmọ́ ọmọ Yorùbá tó ọgbọ́n mílíọ̀nù. Ní ọjó kan, mọ mú ẹ̀rọ alágbèéká mi, mo sì rí sírí, ohùn tí a dá sínú ẹ̀rọ láti máa dáni lóhùn ní èdè gèésì tàbí ní èdè Korea, nkò mọ̀. Mo tún wọ àwọn èdè tí atúnlè ti gbọ́ sírí, mo rí swedish. Mo lo sí orí Google láti wá iye àwọn ènìyàn tí n sọ Swedish, àbájáde je láàrin mílíọ̀nù mẹ́sàn-an sí méwàá. Èdè Norwegian jẹ́ mílíọ̀nù márún sí mewa, Danish je mílíọ̀nù mẹ́rin sí márùn. Lápapò, iye àwọn tí n sọ èdè métèèta jẹ mílíọ̀nù márúndilógun sí ogún. Nígbàtí àwọn tí wọ́n nṣọ èdè Yòrùbá jẹ́ ọgbọ̀n mílíọ̀nù kò dẹ̀ sí ẹnìkẹ́ni tí ó lérò wípé kí èdè yìí ni àsàyàn tire.

Èyí jẹ́ kí n mọ̀ pé ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìyapa ló ti n ṣẹlẹ̀, nítorínà ní àwọn iṣẹ́ mi ṣe n sọ̀rọ̀ lórí àwọn oun náà. L’ákọkọ́ ná, mo gbìyànjú láti kọ́ ní èdè Yorùbá. Èyí le nítorí wípé wọn kò tó wa láti mọ Yorùbá dáradára bí ede gèésì, n ó tùn máá sọ̀rọ̀ lórí èyí. Àmọ́ nítorí pé ó ti jẹ́ dandan láti dá àwọn oun èlò akọ́mọlédè ní òde òní sílẹ̀, a ní láti bẹ̀rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ nítorí kò sí ẹnìkan tí ó ti ṣe èyí rí. Olùmò nípa èdè nimí—mo kẹ́kọ̀ọ́ láti mọ nípa èdè—n o sì lo iṣẹ mi lati ṣ’èdá ààyè fún Yorùbá kí ó lè l’òkìkí lórí ẹ̀rọ ayélujára. Ní ṣíṣe èyí, mọ lérò láti jẹ́ kí àwọn tí n sọ èdè abínibí wọn àmọ́ tó dàbí ẹni pé ó ti n fà sẹ́yìn lè tètè wá ọ̀nà láti ṣ’èdá bi èdè wọn kò se ní parun. Gbogbo èrò àti oun èlò tí a n lò ni a ti ṣe kí o le wà fún gbogbo ènìyàn. Gbogbo kóódù tí a lọ̀ ló nbe lórí ìtàkùn àgbáyé GitHub nítorí kí àwọn ènìyàn lè lọ ibẹ̀ nígbàkúgbà fún lílò fún èdè wọn.

Moti sọ tẹ́lẹ̀ pé n o sọ̀rọ̀ nípa bí mo se dàgbà ní Ibàdàn. Ìbàdàn jẹ́ ileto kekere sí Èkó. Àwọn òbí mi, èyí tí ó yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ àwọn òbí ìgbàlódé mọ ipa tí Yorùbá nkó ní sísọ ní ilé. Bó tilẹ jẹ pé wọ́n mọ̀ wípé àwọn ẹgbẹ́ wa ìyókù nsọ̀rọ̀ ní èdè gèésì. Nítorínà ó le láti ṣọ́ ọmọ bí ó bá nsọ èdè abínibí rẹ̀ n’íta. Àwọn ilé ìwé aládàáni tí a sì nlo náà, èdè gèésì nìkan ni wọ́n fi n kọ́ni. Nígbà míràn, wọ́n lè fi ìyà jẹ ni bí o bá sọ̀rọ̀ ní èdè re, èyí nsẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nsọ èdè náà. Èyí dàbí ẹni pé gẹ́gẹ́bí o tí wà ní Korea yìí, tí o sì n so èdè Korean, o lo sí ilè ẹ̀kọ́ wọ́n sì n sọ èdè gèésì, àwọn olùkọ rẹ tún wá so wípé wọn kò gbọ́dọ̀ gbọ́ èdè Korean mọ́ nínú ilé-ìwé, àìjẹ́bẹ̀ ìyà ni olúwa rẹ̀ yóò jẹ.

Àwọn oún ti a ka kọja niyi, àwọn òbí wa tilẹ̀ tún rò wípé oun dáradára ni nítorípé èdè gèésì jẹ́ èdè ẹ̀kọ́ àti èdè ìṣúná nítorí náà láti lè kọ́ èdè gèésì o ní láti yé máa so èdè abínibí rẹ. Ìwádìí àwọn onímọ̀ nípa èdè tí jékí o yé wa pé, Irọ́ ni o wà nídìí ọ̀rọ̀ náà. Wípé kí ènìyàn dángájíyá ní èdè elédè kò ní ènìyàn má mọ èdè abínibí rẹ. Àmọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ ṣí ní irú ìmọ yìí. Nítorí náà a lè rí ọ̀pọ̀ ènìyàn láti ìdílè tí kò sì fún lópòlopò tí n rọ̀ wípé mímọ èdè gèésì yíò ṣilẹkun àtiríṣe láti bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́. Nkọ̀ tí lẹ̀ sọ wípé òun búburú ni. Nkó lòdì sí kíkọ́ èdè gèésì, àmọ́ òye pé kíkọ́ èdè gèésì nìkan ni ng o ṣe, nkọ̀ ní kó nípa èdè abínibí nítorí yíò d’èmí lọ́nà láti kó èdè mìíràn jẹ́ ọ̀rọ̀ aláìgbọ́n nítorí èyí kìí n ṣe òtítọ́ àti pé, o n gbìyànjú láti tẹ́nbẹ́lú èdè àbínibí rẹ lójú èdè míràn. Èyí sì jẹ ara àwọn òkùnfà ìmúnisìn.

Ní ọjọ́ kan lórí ẹ̀rọ ayélujára Twitter, ìròyìn kàn n já wípé wọ́n fẹ́ ṣẹ̀dà Twitter ní èdè míràn, lógán tí mo gbọ́, èmi àti ọ̀rẹ́ mi se yẹ̀yẹ́ wípé nínú gbogbo èdè tí wọ́n fẹ́ fi ṣẹ̀dá Twitter, kò ní sí èdè Áfríkà kankan. A sì yèẹ́ wò, àmọ́ nkó lè rántí òun tí a bá. Èyí sì mú mi rò wípé, kílódé tí kò fí sí Twitter ni èdè Yorùbá, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ Nàìjíríà níí lo Yorùbá, tí wọ́n bá sì ráyè, wọ́n yíò fé láti fi ọ̀rọ̀ wọ́n náà sórí Twitter. Twitter yìí jé ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀dọ́ nlọ̀ ti ṣiṣẹ́, slṣeré àti lọ gbogbo ọjọ́ wọn, njẹ́ bí a bá ṣẹ̀dá rẹ̀ ní èdè àbínibí wọn, àwọn ọ̀dọ́ wọ̀nyí yíò fe láti lo Twitter ju titẹ́lẹ̀ lo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn kò fẹ́ lati kọ́ nípa èdè wọn, àmọ́ tí gbogbo oun tí wọ́n bá nlọ̀ bá wà ní èdè Yorùbá gẹ́gẹ́bí ilé ẹ̀kọ́, ìjọba, ẹ̀rọ ayélujára àti tí ìgbàlódé ọkàn wọn yíò yí sí èdè náà. Èyí ló jẹ́ kí n máa wá orísìírísìí ọ̀nà láti jẹ́kí èdè abínibí wà máa ṣeyo nínú òun gbogbo ìgbàlódé.

Èyí wá mú wa pinnu wípé aóọ̀ bẹ̀rẹ̀ àyájọ́ Tweet Yorùbá ìyen ní ọdún 2012. Oun tí àá sì máa ṣe nipé, àó wá gbogbo àwọn tí n bá so Yorùbá tí wọn sì n lọ Twitter láti fí Yorùbá tẹ gbogbo àtẹ̀jíṣẹ́ wọn kò sì pọn dandan wípé wọ́n dángájíyá nínú èdè náà, àtipé ki wọn dárúkọ Twitter ní gbogbo àtẹ̀jíṣẹ́ wọn kí Twitter leè mọ̀ wípé, a ní èdè kan tí n jẹ́ Yorùbá. Òpò ènìyàn ló darapọ̀ mọ́ wa, àti àwọn tí wọ́n mọ̀ nípa Yorùbá, àti àwọn tí wọn kọ̀ fi béè mọ̀ọ́. Mo sì ti kọ àròsọ ránpẹ́ lórí ìdí tí a fí n ṣe èyí. Ní ìparí ọjọ́ náà, ẹnikẹ́ni ní ilé iṣẹ́ Twitter ní láti ríi pé àwọn kan n sọ̀rọ̀ ní èdè kan tí wọn kò tíì gbọ́ rí. Wọn pè mí, wọ́n sì sọ wípé wọn yíò se oun kan lórí rẹ̀. Ìyẹn ní ọdún 2012. Ní ọdún 2014, ní ọjọ́ kínní oṣù Ẹrẹ́nà, ní déédé ìgbà tó je ní ọdún tó kọjá, wọn kòó ti padà pè mí. A sì sọ ọjọ́ náà, ọjọ́ kínní, Oṣù Ẹrẹ́nà, ní àyájọ́ ọjọ́ Tweet Yorùbá, a sì ṣe bí a tí ṣe l’ákọkọ́. Twitter kò sì sọ oun kan.

Ní 2014, a tún ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà náà ọ̀pọ́lọ́pọ̀ àwọn ènìyàn ló ti gbọ́ èyí, nígbà tí o fi máa di Oṣù Ogun, ẹnìkan tí n ṣiṣẹ́ ní Twitter fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí mi, mo sì ríi, èyí sì jẹ́ ẹ̀dà Twitter ní èdè Yorùbá àti ti Espetanto. Wọ́n sì ààyè náà láti jẹ́ kí àwọn ọ̀nkọ̀wẹ́ àti àwọn tí n sọ èdè Yorùbá láti wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti túmọ Twitter ni èdè Yorùbá, a sì se bẹ. Bó tilẹ jẹ pé wọn kòó tíì ṣe ìfilọ́lẹ̀ Twitter ní èdè Yorùbá, àmọ́ wọ́n tí gbìyànjú láti ṣi ààyè náà sile a sì ti túmọ náà, èyí fún ni ìrètí wípé bí a bá fé ounkóun a kọ́kọ́ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ fún. Ọ̀nà mí sì po nípa ìjà fún èdè, Yorùbá sí jẹ́ ọ̀kan lára rè. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ mí nípa èdè mímọ̀ àti kíkọ́, mo ní ààyò láti jékí àwọn èdè míràn tí wọ́n tí n lọ sí ìparun wà láàyè. Èyí jẹ́ ìlépa mi gidigidi, nígbà míràn ọ sì lè rí bí ẹnipé kò lè wá sí ìmúṣẹ nítorí pé ọpọlọpọ èdè ló wà. Òmíràn máa ku, kò kan bí a bá ṣe làkàkà tó. Àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn mi nípé gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀rọ, mọ fẹ́ ṣẹ̀dá ààyè fún àwọn èdè yìí, pàápàá fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọny nfẹ́ láti lo èdè yìí. Bí a kò bá sì lè ṣe èyí, èdè wa yíò sọnù níkẹyìn.

Lórí lítírésò, mo ti gbìyànjú láti kọ̀wé pẹ̀lú Yorùbá. Ó le. Gégébí onkọ̀wé, mo bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ̀wé pẹ̀lú èdè gèésì lọ́kàn mí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi náà jẹ́ onkọ̀wé, ó ti n kọ̀wé ní èdè Yorùbá. Ìdí èyí ni pé o dàgbà ní agbègbè tí èdè gèésì kò jé gbóògì. Ó kàn wà fún àyálò, Yorùbá sì ní oun gbogbo tí wọ́n nlo. Mọ ngbìyànjú láti kọ̀wé dáradára ní èdè Yorùbá. Mo tiraka lórí èyí. Ọ̀kàn lára àwọn iṣẹ́ mi dá lórí ipa tí èdè fi n sọnù àti ọ̀nà ànfààní tí n bẹ nínú Lítíréṣọ̀ àti ìṣèjọba. Mọ ti dábàá pé kí àwọn adarí wàá máa sọ èdè abínibí w nígbàkúgbà ti won ba lo sí àwọn ìlú ẹyìn odi nítorí ọpọ igba ni aáyán ogbufọ nbe lati túmọ èdè tí o ba nso. Nipasẹ eyi, won n je ki àwọn ènìyàn mò pé wọn nso èdè kan, tí o dára. Àwọn tí o sì mọ̀ nípa èdè yìí, tí wọ́n ngbé lẹ́yìn odi, yíò ní ìdùnú láti ṣọ ede naa.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló ti pe àlàyé yí níjà nítorí èdè pọ́ọ̀ ni orílẹ̀-èdè mí, èdè wo ni kí olórí orílẹ̀-èdè sọ? Bí adarí kan bá sì sọ èdè àbínibí tirè, á jẹ́ wípé, kí yíò sọ èdè  míràn. Ìdáhùn mi ní wípé, olórí orílẹ̀-èdè wá, wọn sì n lo. Adarí kan lè sọ Hausa, kí òmíràn dé orí àlééfà kí ó sọ̀o Yorùbá tàbí Igbo. Èyí yíò jékí a wọnú ara wọn, àwọn tí wọn n wo orílẹ-èdè wa yíò rí oríṣiríṣi èdè tí a ní. Yíò jé kí èdè wa túbọ̀ máa dàgbà síi.

ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú yín lọ́ mọ àwọn onkọ̀wé Nàìjíríà bíi: Tẹ́jú Cole, Chimamanda Ngozi Adichie, Chinua Achebe, Wọlé Ṣóyínká abbl. Gẹ́gẹ́bí mọ tí nsọ, wọ́n wà láti iran orisirisii awọn onkọwe ti n kowe ni ede gèésì. Àmọ́ wọn jòwó ara won láti le kọ ní èdè gèésì ti Brítánì tàbí ti àwọn ìwọ̀ oòrùn. Mọ n ṣe àpẹẹrẹ kiko ní Yorùbá. Àmì ní yoruba. Yorùbá jẹ èdè tí o dàbí Chinese. Ọ̀rọ̀ kan lè jẹ́ orísirísi nkán èyí sì dà lórí irú àmì ohùn tí o bá lò. Ọwọ́ gẹgẹ bí àpẹẹrẹ tún lè jẹ́ Owó, tàbí Ọ̀wọ̀ tabi ọwọ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ wọ́nyí ní ẹyọ álífábẹ́tì mẹ́ta o-w-o. Àmì ti o bá lo sí ọ̀rọ̀ yìí yíò tọ́pa rẹ sí ìtumò tí o máa rí. O lẹ̀ sọ àwọn tí n gbọ nú tí o kò bá lo àwọn àmì ohùn yìí dáradára. AÀwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nínú èdè Yorùbá ti ṣiṣẹ́ lórí bí a ṣe lè lo Yorùbá nínú ọ̀rọ̀ kíkọ. Ìdí tí mo fí n kọ́ èdè Korea ni wípé mọ fẹ́ láti mọ orísirísi ànfàní tí n bẹ láti ṣ’èdá ọ̀nà àti kọ̀wé tuntun tí àwọn ènìyàn lè rí sí. Nísìsiyìí, ọ̀nà kan ni èdè Yorùbá tí a ní ní fífi àmì ohùn sí èdè Yorùbá. Pẹ̀lú àwọn àmì ohùn wọ̀nyí, o ṣeéṣe kí o fẹ́ so oun kan àmọ́ ki o máa sọ̀rọ̀ nípa nkán míràn. Ọ̀rọ̀ kan wà nínú Yorùbá ti a le túmọ sí Ọkọ, tàbí Ọkọ̀, tàbí Ọkọ́, tàbí Okó. Bí o kò bá sì lo àmì ohùn rẹ dáradára lọ́dọ̀ ẹni tí o bá mo èdè náà, o lè máa bù wọn láìmọ̀..

Nígbàtí àwọn ènìyàn bi Chinua Achebe, Wọlé Ṣóyínká nkòwé. Wọn n kọ̀wé pẹ̀lú èdè gèésì ní ọkàn wọn, nígbàtí wọn sì máa kowe débi tí lílọ Yorùbá ti pon dandan, wọn kò fi àmì ohùn sí. Bí e bá wo ìwé mí yìí, e o ri bí mo ṣe kọ orúkọ mi. Àwọn àmì ti e ri ni mo n sọ̀rọ̀ lé lórí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Nàìjíríà tí n sọ Yorùbá lóde òní ni kò kọ́ nípa àmì ohùn. Wọ́n dàgbà ní ìran tí àwọn òbí wọn kò bìkítà láti kọ́ wọn. Èyí sì ni ìran tí Wọlé Ṣóyínká, Tẹjú Cole àti àwọn ìyókù ti jáde. Ìtìjú ni èyí jẹ́. Èrèdí àti ní lítírésò fún orílè-èdè kan ni láti kó nípa àṣà àti oun gbogbo tí ó wà nínú agbègbè náà. Mọ sì lérò pé bí a bá tilẹ̀ nkó ní èdè gèésì, bí a bá dé’bi àti kó ní èdè Yorùbá, o yẹ kí a fi ọkàn sí lílo èdè náà dáradára.

Oun ìbànújẹ ni fún mi tí àwọn onkọ̀wé yìí bá dé’bi tí wọn yíò tí ko èdè míràn, gẹ́gẹ́ bí French, wọn yíò kọ́ pẹ̀lú àmì tó tọ́. Bí wọ́n bá sì n ko ní èdè Swedish, bákan náà ni. Nínú ìkan lára àwọn àròkọ mi lórí Tẹ́jú Cole, ẹni tí o jẹ ọlọgbọ́n onkọ̀wé gidigidi ní bí ọdún kan sẹ́yìn, mo ko nípa àwọn àròkọ rẹ̀ tí n jẹ Known and Strange Things. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orúkọ tí ó dá jẹ́ èdè Swedish àti ti German pẹ̀lú àwọn àmì wọn. Àmọ́ tí o bá jẹ́ ní èdè Yorùbá, kò ní kọ wọ́n pẹ̀lú àwọn àmì wọn èyí sì jẹ oun tí kò dùn mọ́ọ́ mí nínú.

Mọ ti sọ nínú àwọn ìwé mí wípé, oun kan pàtàkì tí a ní láti ṣe gégébí ọmọ Áfríkà kí a lè sọ èdè wa dáradára ní kí a kọ́kọ́ mọ irú ẹni tí a jẹ́, kí a sì jíròrò nípa bí a ṣe fé kí àwọn ènìyàn mò wá sí. Àti pé kí a yípadà kúrò nínú gbogbo èrò wípé èdè àwọn Brítánì ni ó dára jù, nípa ṣíṣe èyí, bóyá a ọ lẹ̀ dé ògangan ibi tí a o pe ni lítírésò áfríkà. Nkọ̀ yni ìṣòro pẹlú lítírésò áfríkà ní èdè gèésì, oun tí mọ fẹ́ ni pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn lítírésò áfríkà tó wà ní èdè gèésì tabi French tabi Portuguese èyí ni àwọn èdè àt’ọ̀húnrìnwá. Kí àwọn amúnisìn yìí sì to dé, a tí n sọ ìtàn, a sì tin n bá ara wa sọ̀rọ̀ lórí oun oríṣiríṣi. Ó sì ye kí a máa ṣe bẹ́ẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé a óò túmọ rẹ sí èdè Yorùbá, èyí tí kí n ṣe ìṣòro. Orílè-èdè bí Korea ti kọ́ wa bí ó ṣẹ lè ṣeéṣe. Iṣẹ́ mí sì ní láti kó, láti àwọn ilu bíi Wales, Kenya, South Africa àti àwọn ìlú mìíran tí wọ́n tí kọ nípa lílo èdè abínibí wọn ní lítírésò, ẹ̀kọ́, ìjọba, ati pàápàá ìmọ̀ ẹ̀rọ.

Nísìsiyìí n o fi ààyè sílẹ fún ìbéèrè. Mo lérò pé é o ka àròkọ yìí, ẹ o sì jẹ kí n mo oun tí e n rò. Àmọ́ àkópọ̀ àfáàrá àwọn oun tí mọ n ṣé níyì, ìdí tí mọ fí n ṣe wọ́n àtí àwọn ìṣòro tí mọ n fojúsọ́nà láti kojú.

Eṣeun.

Nípa Kola Tubosun

Kọ́lá Túbọ̀sún je Onkowe ati onimo ede, oun ló sì dá YorubaName.com sile. Ní odun 2016, ó gba amì eye Ostana Prize fún litereso, ni Cuneo, Italy, fun ise re lori ilosiwaju ede abinibi.

Nípa Olùtúmò

Olúwábùkúnmi Abraham Awóṣùsì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ìbàdàn ní èka ìtàn. Ó mú èka ìtàn Áfríkà àsìkò yìí ni ọ̀kúnkúndùn. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ lóríṣiríṣi ti jáde lórí ìtàkùn àgbáyé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *