Ìlú ńlá tí ó ní orúkọ, ipò, ẹnu àti ìgbóyà ni ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó jẹ́ láàrín gbogbo àwọn ìjo̩ba ìbílè̩ Àkókó mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Ìlú yìí ní agbára àti ìgbóyà nínú gbogbo ilẹ̀ Àkókó tó wà. Ìdí nìyí tí wọ́n fi í ki ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ní “Kìnnìún Àkókó; a ṣÀkókó rìborìbo.” Oríṣìíríṣìí ìtàn àgbọ́wí, àgbọ́sọ ni ó wà lórí ohun tí ó bí “Ọ̀gbàgì” tí ó jẹ́ orúkọ ìlú yìí. Ọ̀nà mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n gbà ṣàlàyé ohun tí ó bí orúkọ náà. Àwọn kan ní inú “Olúsọngbà” (Olú sọn ọgbà) tí ó jẹ́ orúkọ ọba àkọ́kọ́, tí ó kọ́kọ́ jẹ ni orúkọ náà ti wáyé. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé “Ọlọ́run ṣe oore fún Ọgbà.” Àlàyé mìíràn tí wọ́n tún ṣe ni pé orúkọ yìí wá láti ara “Gbagi” (gba igi) tí ó túmọ̀ sí “kí ènìyàn gba igi eré níbi ìdíje.” Ẹ̀kẹta nínú àlàyé ìjẹyọ orúkọ yìí ni pé, orúkọ náà ṣẹ̀ wá láti ara “Gbani” (gba ẹni) tí ó túmọ̀ sí “gbígba ènìyàn nígbà ìṣòro.” Ẹ̀kẹrin nínú àlàyé ni pé, wọ́n ṣẹ̀dá orúkọ ìlú Ọ̀gbágí láti ara ìhun ìpìlẹ̀ “Ọgbà Igi” tí ó túmọ̀ sí àgbàlá onígi tàbí ààyè tí igi hù sí lóní ìran-àn-ran. Nípasẹ̀ ṣíṣe àmúlò ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè ni ọ̀rọ̀ méjì yìí gbà di Ọ̀gbàgì tí ó ń jẹ́ lónìí.

Ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó wà ní apá Àríwá-Ìwọ̀-Oòrùn. Ìlú náà fi ibùsọ̀ kìlómítà mẹ́jọ jìnnà sí ìlú Ìkàrẹ́-Àkókó. Àwọn ààlà tó wà láàrin àwọn ìlú tí ó yí Ọ̀gbàgì-Àkókó ká kò fi àwọn ohun bíi odò, òkè pa ààlà àyàfi Ìkàrẹ́-Àkókó tí omi Idowò pín wọn ní ààlà. Àwọn ìlú tí ó yí Ọ̀gbàgì-Àkókó ká ni Ìrùn-Àkókó ní apá Ìwọ̀-Oòrùn, Ìkàrẹ́-Àkókó, Arigidi-Àkókó àti Iyé-Àkókó ní apá Ìlà-Oòrùn, Ṣúpárè-Àkókó ní apá Gúsù, nígbà tí Eṣé àti Àfìn wà ní apá Àríwá. Ìlú yìí jẹ́ ilú olókè. Oríṣìí òkè méjì ni ó wà nínú ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Àkọ́kọ́ nínú àwọn òkè náà ni Òkè-Oròkè, èkejì ni Ugòlò.

Ilé-Ifẹ̀ tí í ṣe orírun gbogbo ilẹ̀ Yorùbá lápapọ̀ ni ìlú Ọ̀gbàgì ti ṣẹ̀ wá. Èyí sì hàn gbangba nínú oríkì ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó, pé Ilé-Ifè ni orírun wọn, tí wọ́n ti ṣẹ̀ wá. Nínú oríkì wọn, wọ́n máa ń sọ pé, “Ọmọ Ọwá, Ọmọ Ẹkùn, Ọmọ Oòduà” léyìí tó túmọ̀ sí pé Ẹnuwá nílé-Ifẹ̀ gan-an ni wọ́n ti wá. Ìrìn-àjò tí ó gbé wọn kúrò ní Ilé-Ifẹ̀ ni ó sọ wọ́n di ènìyàn ibi tí wọ́n wà lónìí. Nígbà tí wọ́n ń bọ̀, wọ́n gba ìlú Èkìtì kọjá, ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ìlú Èkìtì, wọ́n sinmi díẹ̀ fún àwọn ọjọ́ díẹ̀, nítorí pé ó ti rẹ̀ wọ́n gidigidi. Èyí ló fà á tí èdè tí wọ́n ń sọ ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó lónìí fi fara pẹ́ ti èdè Èkìtì díẹ̀. Nígbà tí wọ́n sinmi tán, wọ́n tún mú ìrìn-àjò wọn pọ̀n. Ní gẹ́rẹ́ tí wọ́n kúrò ní Èkìtì, wọ́n rí ààyè kan tó tẹ́jú díẹ̀, wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀. Orúkọ ibi tí wọ́n dó sí lọ́jọ́ náà lọ́hùn-un ni wọ́n ń pè ní Ajúpìnmì, ìyẹn ní ọ̀rúndún-kẹtàdínlógún —ibẹ̀ ni wọ́n fi ń dá oko lónìí). Nígbà tí wọ́n ri pé ó tó àkókò kí wọ́n tẹ̀dó síbi tó tẹ́jú dáadáa, wọ́n bá gbéra, wọ́n lọ tẹ̀dó síbi tí wọ́n wà lónìí yìí. Ọgbà tí ó gbààyè ni.

Ọba mẹ́rìndínlógún ni ó ti jẹ ní ìlù Ọ̀gbàgì-Àkókó ní nǹkan bí ọ̀rúndún-kẹtàdínlógún síbi. Àwọn ọba aládé tó ti jẹ náà ni: Ọba Olúsọngbà, Alámọdì, Ọ̀dúndún, Inátu, Àbò, Ikú, Ọ̀dágbàràgàjà I, Ògídílógùn, Adágunmó̩dò, Ọládiméjì, Ẹ̀yíndẹ̀rọ̀, Olórikí I, Ojúkó, Ọmọ Eégún, Olórikí II àti Ọ̀dágbàràgàjà II (tí ó wà lórí àpèrè báyìí). Lóde-òní, àwọn agboolé tí wọ́n ti í jẹ ọba jẹ́ mẹ́fà. Wọ́n ti pa àwọn ìdílé bíi mẹ́rìndínlógún tí wọ́n ti í mú ọmọ oyè pọ̀. Ìdí nìyí tí ó fi jẹ́ pé ìdílé tí wọ́n ti í jẹ ọba fi jẹ́ mẹ́fà. Ọba aládé tí ó wà lórí àpèrè lọ́wọ́-lọ́wọ́ báyìí ni; Ọba Victor O. Adétọ̀nà (Ọ̀dágbàràgàjà II). Orí-adé yìí ṣiṣẹ́ ní àwọn iléeṣẹ́ bíi mélòókan kí àwọn bàbá-ńlá rẹ̀ tó ní kó wá dárí ìlú náà.

Ọba nìkan kọ́ ni ó ń ṣètò ìṣèlú ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó, àwọn ìjòyè wà lára ikọ̀ tí ó ń bá ọba to ìlú. Oríṣìí ọ̀nà mẹ́ta ni wọ́n pín àwọn ìjòyè sí ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Àkọ́kọ́ ni àwọn ìjòyè tí ó jẹ́ pé àwọn ni wọ́n sún mọ́ ọba jùlọ. Nínú àwọn ìjòyè wọ̀nyí ni a ti rí àwọn afọbajẹ. Ìṣọ̀wọ́ ìjòyè wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní Olóyè-gíga. Àwọn ìjòyè náà ni:
1. Olóyè-gíga Arùà ti àdúgbò Òkègbàgbọ́
2. Olóyè-gíga Olúwọ̀rẹ́ ti àdúgbò Ìwọ̀rẹ́
3. Olóyè-gíga Amódò ti àdúgbò Ìwọ̀rẹ́
4. Olóyè-gíga Apajẹ ti àdúgbò Ìwọ̀rẹ́
5. Olóyè-gíga Eléegun ti àdúgbò Eegun
6. Olóyè-gíga Alábìlògbò ti àdúgbò Abìlògbò
7. Olóyè-gíga Olúkọ̀ ti àdúgbò Ùkọ̀
8. Olóyè-gíga Oshòdì ti àdúgbò Ìwù
9. Olóyè-gíga Ọ̀dọgun ti àdúgbò Mọlépè
10. Olóyè-gíga Odù ti àdúgbò Iòṣò
11. Olóyè-gíga Olísà ti àdúgbò Ẹmuta
12. Olóyè-gíga Ẹ̀dẹmọ ti àdúgbò Ẹjọ̀rọ̀
13. Olóyè-gíga Ṣàṣẹ́rẹ́ tí àdúgbò Molepe
14. Olóyè-gíga Ọ̀dọgun ti àdúgbò Ègotò

Àwọn Olóyè-gíga wọ̀nyí ni wọ́n jẹ́ kábàrà fún àdúgbò kọ̀ọ̀kan tí wọ́n wà tàbí tí wọ́n ń darí, wọ́n sì tún jẹ́ olórí fún àwọn olóyè kékeré tí wọ́n jọ wà ní àdúgbò kan náà. Ọ̀wọ́ kejì tí àwọn ìjòyè ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó tún pín sí ni Olóyè. Àwọn ìjòyè wọ̀nyí ni wọ́n tún pọwọ́ lé àwọn Olóyè-gíga ní ìlú yìí. Àwọn ìjòyè wọ̀nyí ni:

1. Olóyè Oshòdì ti àdúgbò Ègikùn
2. Olóyè Ọbaísẹmọ ti àdúgbò Ùkọ̀
3. Olóyè Oshòdì ti àdúgbò Abìlògbò
4. Olóyè Àrẹ̀mọ ti àdúgbò Ẹ̀gakò
5. Olóyè Alárinrin ti àdúgbò Mọlépè
6. Olóyè Ọbáṣùà ti àdúgbò Ìwù
7. Olóyè Asẹ́mọ ti àdúgbò Ẹ̀gakò
8. Olóyè Aṣọjẹ ti àdúgbò Iòṣò
9. Olóyè Oṣùé ti àdúgbò Eegun
10. Olóyè Alájìgbó ti àdúgbò Ègotò
11. Olóyè Sàlajà ti àdúgbò Ẹjọ̀rọ̀
12. Olóyè Ọ́sùnlá ti àdúgbò Ègikùn
13. Olóyè Ọbańlá ti àdúgbò Ẹ̀gakò
14. Olóyè Shábà ti àdúgbò Ẹ̀gakò
15. Olóyè Arẹ̀jẹ ti àdúgbò Eegun
16. Olóyè Sàjọwá ti àdúgbò Ẹ̀gakò
17. Olóyè Ẹlẹ́hà ti àdúgbò Ìwárá
18. Olóyè Olísà ti àdúgbò Ùkọ̀
19. Olóyè Olíkù ti àdúgbò Ègikùn
20. Olóyè Aláwẹ̀ ti àdúgbò Ùkọ̀
21. Olóyè Òṣèré ti àdúgbò Ùkọ̀
22. Olóyè Balógun ti àdúgbò Òfè
23. Olóyè Ògboyè ti àdúgbò Òfè
24. Olóyè Akáyè ti àdúgbò Ẹ̀gakò
25. Olóyè Balógun ti àdúgbò Ẹjọ̀rọ̀

Àwọn olóyè wọ̀nyí ni ó máa ń bójú tó ètò ìdájọ́ ní àdúgbò wọn. Bí ó bá ni ẹjọ́ ti apá wọn ò ká, wọn máa darí rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ àwọn olóyè-gíga, fún àwọn àdúgbò tí ó bá ní. Àdúgbò tí kò bá ní olóyè-gíga, tí wọ́n ò sì ní àǹfààní láti parí aáwọ̀ tí ó bá wà láàrin àwọn ènìyàn àdúgbò, tí ìkùn-sínú wà láàrin wọn, irúfẹ́ ẹjọ́ bẹ́ẹ̀ yóò dé iwájú ọba ìlú. Àdúgbò kọ̀ọ̀kan ni ó ní adarí tirẹ̀. Ọba ni olórí fún gbogbo ìlú pátá. Ọ̀nà kẹta tí ìjòyè ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó pín sí ni àwọn oyè tí wọ́n fi dá àwọn ṣàǹkò-ṣàǹkò ènìyàn lọ́lá láàrin ìlú. Àwọn ọmọ ìlú tí ó bá fi taratara ń gbọ́ tìlú yálà nípa níná owó sí ìlú tàbí jíjà fún ẹ̀tọ́ ìlú ni wọ́n máa ń fún ni irúfẹ́ oyè yìí. Ọkùnrin àti obìnrin ni wọ́n ń fi oyè yìí dá lọ́lá. Àwọn oyè tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí yìí àti orúkọ àwọn ìjòyè náà ni:

1. Olóyè (Dr) J. O. Sanusi – Aṣíwájú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
2. Olóyè Olúbùkún – Ọ̀túnba ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
3. Olóyè Ìyálájé ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
4. Olóyè Adékúajò ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
5. Olóyè Bọ́bajíròrò ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
6. Olóyè Ṣọ́balójú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
7. Olóyè Máyégún ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
8. Olóyè Balógun ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
9. Olóyè Akórewọ̀lú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
10. Olóyè Ìyálóde ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
11. Olóyè Ọ̀tún Ìyálóde ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
12. Olóyè Òsì Ìyálóde ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkók
13. Olóyè Bamòfin ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
14. Olóyè Yeye Aṣíwájú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
15. Olóyè Jémilúà ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
16. Olóyè Gbọ́baníyì ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
17. Olóyè Bọ́baṣèlú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
18. Olóyè Akọgun ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
19. Olóyè Ọ̀tún Bọ́bagúnwà ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
20. Olóyè Yeye Bọ́baṣèlú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
21. Olóyè Erelú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
22. Olóyè Ajagunmólú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
23. Olóyè Atáyéṣe ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
24. Olóyè Yeye Atáyése ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
25. Olóyè Ààrẹ Jagunmólú ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
26. Olóyè Ọ̀tún Ìyálọ́jà ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
27. Olóyè Òsì Ìyálọ́jà ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
28. Olóyè Èyélúà ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó
29. Olóyè Aláàtúnṣe ti ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó

Àwọn ìjòyè wọ̀nyí náà máa ń kópa nínú ètò ìṣèlú láàrin ìlú. Àwọn tí ó jẹ́ obìnrin nínú wọn sáábà máa ń jẹ́ aṣojú fún gbogbo àwọn obìnrin yòókù nínú ìlú. Ẹ̀wẹ̀, àwọn ìjòyè tí ó jẹ́ ọkùnrin náà sáábà máa ń ṣe bí aṣojú fún gbogbo àwọn ọkùnrin. Ohun tí ó fa èyí ni pé, ìgbà mìíràn lè wà tí gbogbo ará ìlú kò ní lè péjọ nínú ìpàdé kan tí ó jẹ́ pé ìjòyè kan tàbí òmíràn ni yóò dúró bí aṣojú. Èyí lè jẹ́ níbi ètò ọrọ̀-ajé, ìtún-ìlú-ṣe tàbí ìjà-fẹ̀hónúhàn láàrin ìlú.

Akínkanjú tí kì í bẹ̀rù ogun ni àwọn ènìyàn ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Ìdí ni wí pé ọ̀pọ̀ ogun ni wọ́n ti jà bó tilẹ̀ jẹ́ pé òmíràn tẹ̀ wọ́n lórí ba ṣùgbọ́n wọ́n padà borí. Oríṣìíríṣìí ogun ni wọ́n jà. Àkọ́kọ́ nínú ogun tí wọ́n jà ni ogun Aje. Ogun yìí wáyé láàrin Ọ̀gbàgì-Àkókó àti Aje tí ń ṣe olórí ogun Ìbàdàn. Aje ja Ọ̀gbàgì-Àkókó lógun, wọ́n sì borí. Fún ìdí èyí, wọ́n gbalẹ̀ (Ọ̀gbàgì) fún odindi ọdún mẹ́wàá gbáko, kí Ọ̀gbàgì-Àkókó tó padà gbara wọn ní ọdún 1960. Ogun kejì tí wọ́n jà ni ogún Tápà, èyí tí ó wọ inú ìlú Àkókó, tí ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó si ti fara káṣá. Wọ́n wá láti kó àwọn ènìyàn Àkókó ní ẹrú pẹ̀lú ipá. Àwọn Tápà ló ni ilẹ̀ Àkókó fún àádọ́jọ ọdún, kí Àkókó tó jàjà bọ́ kúrò lóko e̩rú àwọn Tápà. Yàtọ̀ sí àwọn ogun àtòdewá, ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó tún kojú ogun pẹ̀lú Àfá léyìí tí Òkè-Oròkè bá wọn ṣẹ́gun rẹ̀. Nípa ìwà akin ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ni ó mú kí wọ́n pè Odù fún ìrànwọ́ nígbà ogun Èkìtì Parapọ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún-kọkàndínlógún.

Ní nǹkan ẹgbẹ̀sán ọdún ó lé sẹ́yìn tí wọ́n ti tẹ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó dó ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ àkitiyan lórí ètò ẹ̀kọ́. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí níí kọ́ àwọn ọmọ wọn ní ẹ̀kọ́. Lẹ́yìn àwọn àkókò díẹ̀ sí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo ṣáájú kí ìjọba tó bẹ̀rẹ̀ sí níí kọ́ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo. Àwọn ilé-ẹ̀kọ tí ó wà ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ni:
 Ilé-Ẹ̀kọ́ Alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀:
1. St. John’s Anglican Primary School – 1926
2. Salvation Army Mega Primary School (Salvation Army tẹ́lẹ̀ rí) – 1940
3. Ansar-Ud-Deen Primary School – 1948
4. Our Saviour Primary School (Local Authority tẹ́lẹ̀ rí) – 1955
5. C.A.C Primary School – 1962
6. Community Primary School – 1976
7. Ilè̩-Òwúrò̩ Community Primary School
8. Holy Field Primary School
9. Providence Model Nur/Primary School
10. Home of Christ Nur/Primary School
11. Gain of Honour Nur/Primary School
12. Christ Light Nur/Primary School
13. Start Right International
14. Tolúwani Nur/Primary School
15. Excellent Model Academy

Ilé-Ẹ̀kọ́ Girama:
1. Ahmadiyya Grammar School – 1975
2. Ìrùn/Ò̩gbàgì Anglican Grammar School (Ò̩gbàgì/Ìrùn United School té̩lè̩ tí ó di Ìrùn/Ò̩gbàgì Modern School kí ó tí ó di Secondary) – 1975
3. Ajuta High School (Ansar-Ud-Deen Secondary Modern School tẹ́lẹ̀ rí) – 1980
4. Providence Model Secondary School
5. Holy Field Secondary School.

Ìgbàgbọ́ tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ ni wọ́n ní sí àwọn òrìṣà ìbílẹ̀ ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Ẹ̀sìn Àbáláyé ni wọ́n ń sìn, wọ́n ò sì múkan mọ́kan. Kí ẹ̀sìn Ìsìláámù àti ti Kìrìsìtẹ́nì tó dé ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó ni wọ́n ti mọ̀ pé Olódùmarè tóbi kọjáa bẹ́ẹ̀. Wọn kì í bá Olódùmarè sọ̀rọ̀ tààrà báyẹn ṣùgbọ́n nípasẹ̀ àwọn òrìṣà léyìí tí wọ́n dúró gẹ́gẹ́ bí alárenà láàrin wọn. Àwọn òrìṣà pàtàkì tí wọ́n ń bọ ní ìlú náà ni; òrìṣà Ògún, Eégún, Ọ̀sanyìn àti Imọlẹ̀ léyìí tí Ògún jẹ́ mọ̀-ọ́nká láàrin wọn. Àwọn olùbọ òrìṣà Ògún gbà pé òrìṣà náà kọjá ohun kèrémí, ó jẹ́ jagunjagun, bẹ́ẹ̀ sì ni, ó jẹ́ òrìṣà tí Olódùmarè dá, tí ó sì rán sí òde ayé. Inú oṣù Ọ̀wàrà (oṣù kẹwàá ọdún) ni wọ́n máa ń ṣe ọdún náà léyìí tó máa ń kọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú ọdún Àjàgbó. Ajọrí Ògún ni alàwòrò tí ó máa ń ṣáájú níbi ìbọ òrìṣà Ògún ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó.

Ẹ̀wẹ̀, wọ́n máa ń bọ òrìṣà Eégún nígbà tí wọ́n bá ti í ṣe ọdún tó bá jẹ mọ́ agbo ilé àwọn ọlọ́jẹ̀. Àwọn agbo ilé tó máa ń bọ Ọ̀sanyìn kò wọ́pọ̀, àdúgbò Odèréré ni wọ́n ti ń ṣe èyí. Wọn kì í fi eésan àti igi udí dáná. Fún ti Imọlẹ̀, àwọn obìnrin àti ọkùnrin ni ó máa ń ṣe èyí. Àwọn ni wọ́n máa ń pè láti bomi ẹ̀rọ̀ wọ́n ìlú nígbàkigbà tí àìsàn bá gbòde kan-an. Àwọn yìí náà ni ó máa ń ṣe atọ́nà lọ síbi odò Àwẹ̀yá nígbàkigbà tí wọ́n bá fẹ́ bọ̀ ọ́. Odò náà ní Olú, ó sì máa ń béèrè fún ohun ìtánràn nígbà tí wọ́n bá ti ṣe èyíkéyìí nínú àwọn ohun tí ò fẹ́ sí i. Ọjọ́ ìbọ fún àwọn òrìṣà wọ̀nyí máa ń yàtọ̀ láàrin ìlú. Lẹ́yìn ọdún Àjàgbó tí ó máa ń mú bíbọ òrìṣà Ògún lọ́wọ́, àwọn mìíràn tí wọ́n tún máa ń mú bíbọ àwọn òrìṣà yòókù lọ́wọ́ ni ọdún Ìjẹṣu, ọdún Ọjà-Olorì àti ọdún Ìjùlà Ùrókò. Àdúgbò Ẹ̀gakò ni wọ́n ti sáábà ń ṣe ọdún Ìjùlà Ùrókò. Àwọn géńdé lọ́kùnrin yóò mú pọ̀pá dáni láti máa fi na ara wọn.

Ní ọ̀rúndún-ogún sẹ́yìn ni àwọn ẹ̀sìn àjòjì bẹ̀rẹ̀ sí níí wọnú ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó wá. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ bíbí ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó bẹ̀rẹ̀ sí níí sá tọ àwọn tó ṣe agbátẹrù àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí wá. Ìwọ̀nba péréńte ni ó kù tí ó ń sin ẹ̀sìn Àbáláyé. Bàbá Bákàrè (Séríkí Mùsùlùmí) ni ó mú ẹ̀sìn Ìsìlámù wọ inú ìlù Ọ̀gbàgì-Àkókó. Oun kan yìí náà ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó jẹ oyè Séríkí Mùsùlùmí ní ìlú náà. Ó hàn nínú oríkì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí amẹ́sìn-wọ̀lú:
Ọmọ Ọwá
Ọmọ Ẹkùn
Ọmọ Séríkí Àdínnì
Ọmọ òpó Ìmọ̀le
Ọmọ a-mú-mọ̀le họ̀lú.

Lẹ̀yìn ìgbà tí ẹ̀sìn ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ, oníkálukú ń gbìyànjú kíkọ́ ọmọ rẹ̀ lẹ́sìn. Àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́nì bẹ̀rẹ̀ sí níí kọ́ ilé ìjọsìn kiri inú ìlú. Àwọn Mùsùlùmí tilẹ̀ kọ́ ilé-ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti í kọ́ àwọn ọmọ wọn ní kéú. Àwọn ilée kéú tí wọ́n kọ́ ni;
 Ilée kéú Ẹ̀gakò
 Ilée kéú Òfè/Ùkọ̀
 Ilée kéú Mọlépè
 Ilée kéú Abìlògbò
 Ilée kéú Eegun
 Ilée kéú Alhaja Sanni

Ìjọ Mùsùlùmí ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó pín sí ọ̀nà méjì bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bákan náà ni wọ́n ṣeé pe Ọlọ́run wọn. Wákàtí márùn-ún kan náà ni wọ́n jọ fi í kírun ní ojúmọ́. Ẹ̀wẹ̀, oṣù kan ni wọ́n jọ ń gbààwẹ̀. Àwọn ìjọ náà ni;
 Ansar-Ud-Deen Muslim Society
 Ahmadiyya Muslim Jama’at

Ìjọ ti ọmọlẹ́yìn Jésù ló pọ̀ jù. Ìdí ni wí pé, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ìjọ máa ń dá ìjọ sílẹ̀ tí wọn yóò sì máa ṣe ìdarí rẹ̀. Àwọn ìjọ náà ni;
 St. John’s Anglican Church
 Salvation Army Church
 Christ Apostolic Church
 Cherubim and Seraphim
 Baptist Church
 Roman Catholic Church
 The Apostolic Church
 Jehovah’s Witness
 Redeemed Christian Church of God
 Celestial Church of Christ
 Deeper Life Church
 All Christian Fellowship Ministry

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ọ̀gbàgì-Àkókó ni ó jẹ́ akéú-kéwèé tí wọ́n sì dipò ńlá-ńlà mú láwùjọ. Èrè tí ń bẹ nínú lílọ sí Ilé-ẹ̀kọ́ kò mọ níwọ̀n. Olówó pọ̀ jáǹtíìrẹrẹ nínú àwọn ọmọ ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Díẹ̀ lára wọn ni;
1. Olóyè (Dókítà) J. O S̩ànúsí: Gómìnà báǹkì-àpapọ̀ Orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tẹ́lẹ̀ rí.
2. Olóyè O. Kúmúyì: Adájọ́fẹ̀yìntì ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó.
3. Họnọ́rébù O. Bọ́lárìnwá: Abẹnugan ilé-ìgbìmọ̀ aṣojú-ṣòfin ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó tẹ́lẹ̀ rí, Olùkọ́ni, Olùbádámọ̀ràn-pàtàkì sí gómìnà tẹ́lẹ̀ rí.
4. Olóyè A. Aríbisálà: Oníṣòwò, Adájọ́-àgbà rí nílẹ̀ẹ Nàìjíríà
5. Gbóyèga Awẹ́: Olùdásílẹ̀ ilé-iṣẹ́ ọṣe “DAMATOL” àti ilé-iṣé epo rọ̀bì
6. Fẹ́mi Aládéṣùlú: Olùṣírò-owó ti àjọ-báǹkì-àgbáyé tẹ́lẹ̀ rí (kí Ọlọ́run fọ̀run kẹ́ ẹ).

Oríṣìíríṣìí àwọn ẹgbẹ́ ni ó wà ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí sì ń kó ipa pàtàkì láàrin ìlú. Nípa ṣíṣe ẹgbẹ́ wọ̀nyí, ìrẹ́pọ̀ ń gbilẹ̀ láàrin àwọn ènìyàn ìlú. Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí wà nínú àwọn ọlọ́jà, atóríṣe, mọlémọlé, àwọn àjòjì/àlejò àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ẹgbẹ́ wọ̀nyí máa ń mú ìdàgbàsókè bá ìlú, ọ̀làjú sì máa ń wọ inú ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó. Àwọn ẹgbẹ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó, tí wọ́n sì í kópa ribiribi nínú ètò ìṣèlú ni:
1. Ẹgbẹ́ Ẹlẹ́ran
2. Ẹgbẹ́ Elépo Pupa
3. Ẹgbẹ́ Olóbì Tútù/Gbígbẹ
4. Ẹgbẹ́ Onídìrí
5. Ẹgbẹ́ Onígbàjámọ́
6. Ẹgbẹ́ Ẹlẹ́rọ-Ẹyìn
7. Ẹgbẹ́ Mọlémọlé
8. Ẹgbẹ́ Aláta
9. Ẹgbẹ́ Onírú
10. Ẹgbẹ́ àwọn Ègbìrà
11. Ẹgbẹ́ àwọn Íbò
12. Ẹgbẹ́ àwọn Gárà
13. Ẹgbẹ́ àwọn Haúsá
14. Ẹgbẹ́ àwọn Rẹ́girẹ́gi
15. Ẹgbẹ́ Abániṣe
16. Ẹgbẹ́ àwọn Kanlékanlé
17. Ẹgbẹ́ àwọn ọmọ Èkìtì

Nípa Òǹkọ̀tàn

Bákàrè Wahab Táíwò jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ọ̀gbàgì-Àkókó, ní Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Wabab kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ìmọ̀ Ẹ̀dá-Èdè àti Èdè Yorùbá, ní Fásitì Adékúnlé Ajáṣin, Àkùngbá-Àkókó, Ìpínlẹ̀ Oǹdó. Òǹkọ̀tàn yìí gbégbá orókè ni abala ewì nínú ìdíje ìwé kíkọ tí ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́ gbé kalẹ̀ ní ọdún 2022. Kò ní pẹ́ gbé ìwé méjì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ jáde. Ẹ̀wẹ̀, Mùsùlùmí ni Wahab, kò sì tíì ní ìyàwó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *