Odò SOGÍDÍ jẹ́ odò ìyanu tí ó wà ní ìlú kan lẹ́bà Ọ̀yọ́ Aláàfin, ìlú Áwẹ́ ní ìjọba ìbílẹ̀ Afijíó .
Kòsí ìwádìí kankan tó fi yé wa pé ẹnìkankan ló di odò yìí.
Ìtàn fi yé wa pé àwọn ará ìlú Áwẹ́ sẹ̀ wà láti ìlú Ilé-Ifè tí wọ́n si n wá ibití wọ́n ó tèdó sí. Nibiti wọ́n tí n wá ibití wọ́n o tèdó sí yìí gan-an ní wọ́n tí rí igi kan tí wọ́n n pè ní “Igi àruwẹ́wẹ́” abẹ́ igi yìí ni wón jókòó sí èyí gan-an lómù orúkọ ìlú náà wá ti a mọn sí ÁWẸ́ lónìí. Lára orúkọ igi àruwẹ́wẹ́ yìí ni wọ́n ti padà yọ orúkọ ìlú Áwẹ́ jáde tofi di pé wọ́n n pe ibè ní Áwẹ́ lónìí. Ní gbà ti òùngbẹ ń gbẹ wọ́n tí wọ́n n wá omi kiri ní wọ́n tí rí igi àgbálùmọ̀ kán tí a tún mọn si palábẹ́ ti wọ́n si ba àwọn ọ̀bọ lórí igi yìí. Wọn kọ́kọ́ fẹ́ pa àwọn ọ̀bọ yìí ṣùgbọ́n oun tó duni ní pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni, wọ́n fi àwọn ọ̀bọ náà kalẹ̀. Ni gbà tí wọ́n wo ilẹ̀ ni wọ́n rí odò kán tí wọ́n sì mú omi níbẹ̀. Wọ́n tún já nínú èso yìí tí wọ́n sì muú. Lẹ́yìn tí wọ́n mú èso yìí wọ́n rí pé kòse àwọn ní ìjàmbá kánkán tí wọ́n sì sọ fún ará wọn pé: “ÈSO GIDI” ni . Báyìí ni wọ́n se yọ orúkọ odò tí a mọn sí SOGÍDÍ jáde. “ÈSO GIDI “, “ÈSO GIDI ” ló padà wá di SOGÍDÍ lónìí gẹ́gẹ́ bí “àruwẹ́wẹ́” náà se di Áwẹ́.
Àwọn igi àgbálùmọ̀ yìí sì wà níbẹ̀ títí di òní. Bí èèyàn bá dé ibi tí odò yìí wà èèyàn ó bá àwọn igi àgbálùmọ yìí níbẹ̀ tí àwọn èèyàn sì tún n káa mu títí di àsìkò yìí. Kòsí ohunkóhun tí yóò sẹlẹ̀ sí yàn bí èèyàn bá mun níbẹ̀, tọmọ de tàgbà ni wọ́n n ká nínú àgbálùmọ̀ yìí láti mu. Nígbà tí àwa náà dé ibẹ̀ a mu nínú àwọn àgbálùmọ̀ náà.
Odò SOGÍDÍ jẹ odò ìyanu tó jẹ́pé bí èèyàn bámú ẹja nínú rẹ̀ kòsí bí olúwa rẹ̀ se le sèé tó kòní jiná. Àwọn èèyàn oríṣiríṣi tí gbìyànjú láti se ẹja yìí jẹ nípa dídáná ńlá fún ṣùgbọ́n kàkà kéwé àgbọn ó rọ̀ líle ní n le bí ọrùn akíka. Bí èèyàn bá gbìyànjú dòní dọla láti se ẹja inú odò yìí kò lè jìnnà, àwọn ẹja yìí le kú fún ará wọn bí wọ́n bá gbé ara wọn mì tàbí wọ́n ti dàgbà tí àsìkò ọlọ́jọ́ dé fún wọn,ṣùgbọ́n kí èèyàn sọpé òun fẹ́ ṣe àwọn ẹja yìí lọ́bẹ̀ irọ́ pátá ni. Kòsí bí iná ọun se le pọ̀ tó kòní jiná láíláí. Ara èèmọ̀ Ọlọ́run tó wà nínú odó yìí nun-un. Àìjiná àwọn ẹja inú odò yìí mú kí àwọn ẹja pọ̀ níbẹ̀ tí kòsí sí baba ńlá ẹ nití ó le fi wọ́n se nkan kan. Won kò rí ẹni mú wọn, bóbá jẹ pé àwọn ẹja yìí se é sè lọ́bẹ̀ bóyá gbogbo rẹ̀ ni wọn ò bá ti mú tán. Àìsejẹ yìí fún wọn ni àǹfààní láti seré nínú odó yìí láìsí ìbẹ̀rù kankan. Bi àjòjì bá wọ inú odó yìí wọ́n a jẹ́ kí o mọn pé èèwọ̀ ni láti mú ẹja nínú rẹ̀. Ó seni láànú pé pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ yìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ni wọn a tún mọn tàpá síi òfin yii. Ṣùgbọ́n ẹni a wi fún bó bá fẹ́ kó gbo nítorí pé oun tí ojú ẹni tí ó kọ̀ láti gbọ́ ìkìlọ̀ bárí kí o mọn rán fún ra rẹ̀.
Iṣẹ́ ìwádìí tún fí yé wá pé ọkàn nínú àwọn ọmọ ológun tí n gbé lágbègbè odò yìí sórí kunkun pé òun ó se ẹja náà jiná tí wọ́n sì kìlọ̀ fun ṣùgbọ́n kò gbọ́. Ó gbìyànjú títí láti se ẹja yìí ṣùgbọ́n ẹja kọ̀ kò jiná. Láìpe ọmọ rẹ mẹ́ta gbèkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbora tí òun gan-an alára sì gbé ìgbé ayé ìnira kòtò di pé ó jáde láyé.
Agbegbe tí odò yìí jé àgbègbè tó bání lérú. bí èèyàn bá ń wo odó yìí lọ́kàn kán o seése kí ẹrú máa bání nítorí pé igbó ni ó yíi ká.
Ó jẹ ohun èèwọ̀ láti wọ bàtà wọ inú odò yìí, bákanáà ni èèyàn kò gbọ́dọ̀ ṣẹ òun ẹ̀gbin sínú odò yìí. Kòsí bí èèyàn ṣe lè tó nínú ọlá ó gbọ́dọ̀ bọ́ bàtà sí ẹnu ọ̀nà bí o báfé wo ibẹ̀. Kòsí bí èèyàn ṣe lè tó nínú ọlá kò gbọ́dọ̀ wọ bàtà wọnú odò yìí. Kódà bí Ọba Áwẹ́ bá fẹ́ wọ nú odò wọ́n a máa bọ́ bàtà sílẹ̀ kí wọ́n o tó lè wọ bẹ̀ nítorí ó jéẹ́ oun èèwọ̀ tí gbogbo èèyàn gbọ́dọ̀ pa mọ́n.
Odò SOGÍDÍ tí à ń wí yìí jé odò ìgbà-àdúà tójẹ́pé bí èèyàn bá gbàdúrà níbẹ̀ gbogbo oun tí èèyàn bá tọrọ níbẹ̀ ni yóò wá sí ìmúṣẹ. Wọ́n a máa wá bu omi yìí láti ọ̀nà tó jìn,láti Èkó, Ìbàdàn kódà wọ́n aa máa bèrè fún omi yìí láti ìlú -èbó. Àwọn Àlùfáà àti páítọ̀ lórísìrísí a máa fi omi yìí se ìwòsàn àti ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá gbàdúrà sí tan tí gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ sì máa tèwọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú ògo Elédùà.
Ẹ̀bùn ńlá ni omi náà jẹ fún àwọn ará ìlú Áwẹ́ nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore lóti se fún wọn.
Lára òhun èèmọ̀ tó wà ní Odò yìí ni pé odò kankan kò sàn wo inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ odò yìí náà kò sàn lọ sí ibì kankan . Kòsí ẹni tí ó le sọpé ibití omi yìí ti sàn wá lèyí tàbí orísun rẹ̀ a kàn lè ri pe ojo n rò sí inú rẹ̀ ṣùgbọ́n kòsí ẹnìkankan tó le sọ pàtó ibití SOGÍDÍ ti sàn wá. Omi tó dá dúró ni. Bótilẹ̀jẹ́pé odò yìí kò sàn lọ, omi rẹ dára fún mímu àwọn ará ìlú oríṣiríṣi a sì máa bù omi yìí láti fi se ìwúre. Bí ẹ bá bu omi yìí sẹnu omi tó dára bí omi òjò tàbí omi ẹ̀rọ ni.
Àwọn Obìnrin a máa ṣe ìmòntótó odò ní ojojumo nípa gbigba agbègbè rẹ̀
Wọ́n a máa kìí pé: “SOGÍDÍ, odò tíí sọ àgàn di ọlọ́mọ “.
Ọpọlọpọ àwọn èèyàn ni Elédùà ti dá lóhùn nípasẹ̀ omi yìí . A rí lára àwọn tí odò yìí ti se lóore rí tí wọ́n padà wá dúpẹ́ látàrí oore tí odò yìí se fún wọn.
Omi inú odò yìí kò gbẹ rí, bí a bá ń wòó ni okankan omi náà dúdú lójú ṣùgbọ́n omi tó mọ́ kangá ni. Láti ìgbà tí àwọn ará ìlú Awẹ tí n mu omi yìí wọ́n kò lùgbàdì àrùn onígba-méjì tí àwọn olóyìnbó n pè ní “cholera”.
Àwọn ará ìlú Awe a máa fi ẹran màálù se ètùtù ni àsìkò ọdún Áwẹ́ tí wọ́n ò sì pín ẹran yìí káàkiri ìlú.
Odò SOGÍDÍ a máa gbà àlejò, lásìkò tí odò yìí bá gbà àlejò èèwọ̀ ni láti wọ ibẹ̀ títí tí àlejò náà yóò fi lọ. Wọn a máa tì í pa lásìkò tí ó bá ní àlejò. Odò yìí ti gba àlejò fún odidi ọjọ́ méje rí tí ẹnikẹ́ni kò wọ ibè fún gbogbo ọjọ́ méje yìí.
Lára òun tí iṣẹ́ ìwádìí tún fi hàn wá nipé odò yìí ní Iyemọja. Wọ́n jẹ́ ká mọ̀n pé ní ìgbà kan rí Iyemọja yìí a mọn jáde ni ọ̀sán gangan nígbàti òòrùn bá mú. Àwọn kan tún sọ pé àárín òru ni o máa n jáde, wọ́n sọ eléyìí nítorí àwọn àmì kan tí wọ́n máa n rí ní òwúrò kùtùkùtù. Àwọn àgbààgbà sọpé ni oṣù Ọ̀wàrà ni Iyemọja yìí sáábà máa n jáde lásìkò tí wọ́n bá ń se ọdún Áwẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n jẹ́ kí a mọ̀n pé Iyemọja inú Odò yìí kò jáde mọn nítorí ìwà egbin àwọn èèyàn.
Bótilẹ̀jẹ́pé Iyemọja inú Odò SOGÍDÍ ò jáde síta mọn, pẹ̀lú oríṣiríṣi àwọn àmì, odò yìí a máa fihàn pé Iyemọja náà wà lágbègbè tàbí ó ti gba àlejò kan.
Ẹnití wọ́n bá wí fún pé kò jiná sí òun eewọ tí odò yìí kóríra ṣùgbọ́n to kọ̀ tí kò gbọ́, oun tí ojú rẹ̀ n wá á ,yíò ri.
Àwọn tí wọ́n jẹ́ alamojuto odò yìí fiyè wa pé bí odò yìí se jẹ́ odò ìyanu tó, àwọn ò rí ìkún lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ìjọba. O yẹ kòjẹ̀ ara nkan tóyẹ kí wọn gbé lárugẹ kó jẹ́ òun tí àwọn èèyàn yíò máa wá fi owó wò láti àwọn ìlú ńlá. Ṣùgbọ́n bakanaa ni odò yìí wà láti ọjọ́ tóti pẹ́. Wọ́n ra ọwọ́ sí ìjọba kí o ran àwọn lọ́wọ́ láti jẹ́ kí odò yìí jẹ́ ọkàn lára nkan tí àwọn èèyàn ó wa máa wá wò tí yíò ó sì maa pa owó fún ìjọba àti àwọn ará ìlú Áwẹ́.
Fidio.
Mohammed Ramon Ajani (Àjàní Akéwì)/ Ikọ̀ Àjàní Akéwì