Wón ní,

Ikú ogun ló ń pa akíkanjú

Ikú odò lo ń p’òmùwẹ̀

Ikú ẹwà ni wón ní ó ń pa egbin

Ikú abo ló pa Bùròdá Àjàyí o

Nígbà ayé Bùròdá Àjàyí,

Kò sí abo tí wọn kìí gbé,

Bó ṣe kúkúrú, bo ṣe èyí tó gùn bí ọ̀pá ìbon

Bó ṣe èyí tó ki bí ọ̀pọ̀lọ́

Bó sì jẹ ọmọ pẹlẹbẹ bí bébà,

Gbogbo ejò fún Bùròdá Àjàyí, jíjẹ ni

‘Kinní’ wọn kò mo moyó bó bá ti jẹ́ t’alábo dé yìí

Bó ṣe omidan àbí adélébọ̀.


Ọjọ́kìíní àná tí Bùròdá Àjàyí lọ ká Àǹtí Sílífià—

ìyàwó àfẹsona Bùròdá Súkúdì mó’lé,

Ṣèbí gbogbo èèyàn ló mò pé ajá ilé ni Àǹtí Sílífià

Gbogbo ọkùnrin àdúgbò a sì má yèbá fún wọn

Nítorí Bùròdá Súkúdì è fi ìyàwó wọn ṣeré

Wọn sì ti pẹ́ ni oríṣiríṣi ẹ̀wọ̀n bí ọ̀bọ—

kí wọn tó wá máa tá bàtà, tá báàgi, tá jinsii,

Àmọ́, ìwà bo ba o pá, bó o ba, o bùú l’ẹsẹ̀ ti mọ́ wón lára.


Ọjọ́ tí à ń wí yìí,

Ọjọ́ burúkú, Èṣù gba píọ́ wọtà mu.

Bùròdá Súkúdì ti gbé báàgi àti àwọn wóróbo wọn lọ sójà

Àǹtí Sílífià a sì máà tẹ̀lé wọn lọọjà

Àmọ́ lọ́jọ́ ọ̀ún, ó sọ fún Bùròdá Súkúdì pé ó fẹ́ rẹ òun díè,

Ní Bùròdá Súkúdì bá dá lọ sọjà.


Ṣùgbọ́n kò pé wákàtí méjì ni ara Bùròdá Súkúdì ò balẹ̀ mọ́,

Lóòótọ́, Bùròdá Súkúdì fẹ́ràn kí wọ́n ma tajà ju, lẹ́yìn kí wọ́n ó pa èèyàn lọ,

Àmọ́, wọn sọ fún Bùròdá Ifeanyi ọ̀rẹ́ wọn tí ó wà ní ẹ̀gbẹ ìsọ̀ wọn

Pé kí ó ma bá wọn fojú wo igbá.

Ifeanyi bẹ Bùròdá Súkúdì pé kán jẹ́ kó ṣe díè sii.

A ò wá mò bóyá àwọn ará ilé Àǹtí Sílífìà ló fàbò sórí wọn lọ́jọ́ náà.


Fẹ̀rẹ̀, Bùròdá Súkúdì ti sọdá s’apá kejì,

Wọn wọ mọ́tò ilé.

Ilé tí wọ́n ó wọ̀ bayìí,

Bùròdá Àjàyí àti Àǹtí Sílífìà—

ìyàwó àfẹ́sọ́nà—wọn ni wón bá lórí bẹ́ẹ́dì wọn,

Ojú Bùròdá Súkúdì sáná.

Yàrá kan náà ni wọ́n kú ń lò.

Wọ́n gbé bẹ́ẹ́dì sẹ̀gbẹ́ kan,

Wọ́n sì gbé tẹlifísàn, àga àti tábìlì sí ẹgbẹ́ kejì

Bùròdá Súkúdì e kúkú rìn, kí èèyàn gbùró ẹsẹ̀ wọn,

Kọ́kọ́rọ́ ọwọ́ Bùròdá Súkúdì ni wọ́n fi ṣílẹ̀kùn.


Háà! Abiyamo o!

Ìkúnlẹ̀ abiyamo o!

Bùròdá Súkúdì na Bùròdá Àjàyí—

àfi bíi bẹ̀m̀bẹ́ òòru ọjọ́ Mọ́lúdì

Èèyàn lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́ kú ni Bùròdá Àjàyí tẹ́lẹ̀,

Gbogbo èèyàn ló jáde bẹẹ Bùròdá Súkúdì

Àmọ́, wọn ò gbọ́ ẹ̀bẹ̀

Gbogbo géńdé ilé tí ò bà bá wọn mú Bùròdá Súkúdì

—ti re ibi iṣẹ́—

Kódà bí Bùròdá Àjàyí ò ṣe sí níbi iṣẹ́ asobàtà tí wọ́n ń ṣe gan, kò yé wa

Àmọ́ kò jọ wá lójú, wọn ò kí ń ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀.


Bùròdá Súkúdì na Bùròdá Àjàyí bí kúkú, bí yíyè—ọsibítù kọ̀ wọn lọ́jọ́ náà,

Agbada bàsíà ni wọn fi wọn ìyà fún Bùròdá Àjàyí.

Àmọ́, ọjọ́ ọ̀ún kọ́ ni ọjọ́ tí Bùròdá Àjàyí kọjá lọ sí ọ̀dọ̀ Baba lókè,

Bùròdá Àjàyí kúkú kí ọwọ́ àgbèrè wọn bọ aṣọ.


Àfi ìgbà tí Wòlíì ìjọ tuntun àdúgbò wa kódé,

Wòlíì náà níwà tútù, àfi bí àdàbà

Ìyàwó Wòlíì náà kìí ṣe oníjògbòn, jéjé ni wọ́n máa ń lọ,

Àṣé ìyá Wòlíì d’aṣọ b’ojú éégún ni,

Àwa ò kúkú mo nkankan.


Àfi ọjọ́ tí Bùròdá Àjàyí sáré láti ilé lọ s’áàrín ọjà

Ní wọn ń fi igbe b’ọnu,

Ní wọn ń k’ígbe ‘ẹ má na mí mó, máa jẹ́wọ́’

Enikankan ó lè sún mọ́ wọn

Nígbà tí a ó kúkú rí ẹni tí òun na wọn

Afi ìgbà tí Bùròdá Àjàyí kẹ́nu bọ ọ̀rọ̀,

Àṣẹ Bùròdá Àjàyí ń ṣe wọlé wòde pelu ìyàwó Wòlíì tuntun

Bóyá Wòlíì náà sì fura ni o, àwa ò mò

Wọn tí na kinní burúkú tí wọn ń pè ní mágùn sílẹ̀ fún ìyàwó wọn

—tí’yìun sì dá kọjá lai mo

Mágùn ologede ni.. Ojo burúkú lọ́jọ́ naa.


Kìí ṣe àsìkò ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀ún náà ṣẹlẹ̀

Ńṣe ni Bùròdá Àjàyí ń kígbe ọ̀gẹ̀dẹ̀ là í ṣe ọ̀bọ,

Gbogbo ọ̀gẹ̀dẹ̀ tí ń bẹ létídò ni wọn jẹ,

Wọ́n jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ àgbáàgbá, wọn jẹ ọ̀mìnì

Bí wọ́n ṣe ń jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ páráǹtà ni wọn ń jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ jóòkóso

Síbè igbe ọ̀gẹ̀dẹ̀ ni wọn ń pariwo,

Ká má paaro, igbe ọ̀gẹ̀dẹ̀ yìí ni wón ké lọ bá Baba lókè.


‘Ó mà ṣe o!’ ní ó tẹnu àwọn èèyàn bọ́ s’óde

Àmọ́, omi ti tán ní ẹ́yìn ẹja wọn

Àgbèrè ti rán Bùròdá Àjàyí lọ s’ókè,

Ikú odò ti pa òmùwẹ̀ wọn, láasí lasì.


Kàfí Fáshọlá jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ́ gbòye ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fáfitì ìlú Ìbàdàn.

Comments

  1. Ewo, e e ni binu ni. Kosi ami ohun ni ori fone yi, nitori na, e gba mi laye, ki n ko ede geesi.

    It’s very good for brother Ajayi. Makes me remember that old movie, Thunderbolt, back in the days. But this story is incomplete fa; what happened to Aunty Silifia and iyawo woli?

    1. Ìtàn náà dá lé orí Bùròdá Àjàyí ni. Àǹtí Sílífìà àti Ìyá Wòlíì kàn ń ré kọjá ní.

  2. Mo kọ́kọ́ kan sáárá si ònkọ̀tàn yi fun itan ti o kọ yi. O gbinyanju. Ẹ̀gàn ni hẹ̀. Sugbọn ìgbékalẹ̀ itan naa ko múná d’óko. Fun apẹẹrẹ: obinrin ti a ba pe ni àfẹ́sọ́nà kò tí le ma ba ọkọ gbe papọ. Ṣugbọn ninu àròkọ yi, Sukudi ati Silifa ti n ba ara wọn gbe.

    1. Ẹṣé.. Ẹ kú àkíyèsí. Àṣà ló kú dé,ni orin dì òwe… Lóòótọ́, kò sí nínú ìṣe ilẹ̀ wá àmọ́ bí àwọn ọmọ ayé ìsín ṣe ń ṣe nìyẹn.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *