Ìlẹ̀kẹ̀ má jà á sílé má jà á síta ibì kan ni yóò já sí lọ́jọ́ kan. Dùnúnkẹ́ rẹwà lọmọ. Ó pupa bí àsáró elépo. Ṣàṣà ọkùnrin ní yóò fojú kàn án tí kò ní wò ó ní àwòtúnwò.O dára bí egbin.Kò sí aṣọ tí ó wọ̀ tí kò ṣe rẹ́gí bí ìdodo ẹ̀fọn lára rẹ̀. Ká má parọ́ Dùnúnkẹ́ yááyì l’ọ́mọge. A kìí bímọ nísọ̀ ewúrẹ́ kó lọ ìsọ̀ àgùntàn lọ jẹ. Ìyáàyá a rẹ̀ ló jọ bí ìmumu. Ká má parọ́ Ọlọ́run parí ẹwà sí i lára.
Kò sí ọkùnrin tí kìí fẹ́ kọ ẹnu ìfẹ́ sí i. Irú ẹwà tí Olódùmarè fi jínǹkí i rẹ̀ kò tàsé e ti Ọ̀kín ọba ẹyẹ. Ilé e wọn kò dá rí àfi bí ìgbà tí kò sí ọmọbìnrin mìíràn mọ́ ní àdúgbò wọn. Àwọn mìíràn kúkú wà àmọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ọkùnrin tótó fún ùn! Ká fi sẹ́nu ká dákẹ́ ni. Òun ga-an pàápàá kò mọ ẹni tí ó lè ṣe hòo fún nítorí pé bí ọkùnrin bá ń dọdẹ abo kò sí àrà tí kò sí lọ́wọ́ ọ wọn. Kò mọ ti ẹni tí ó lè ṣe é nínú àwọn Ò-róbìnrin-dòòyì wọ̀nyí nítorí pé gbogbo wọn ní ń fẹ́ kí iyọ̀ ọ́ dun tiwọn.
Ṣe bí tí ẹni méjì bá ń tayò, ẹnìkan ni yóò borí. Ìfẹ́ ẹ rẹ̀ sí Sanjọ́ pọ̀ àmọ́ kọ́kọ́rọ́ kan tó beyín ajá a rẹ̀ jẹ́ ni pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde nílé ẹ̀kọ́ Yunifáfitì ìmọ̀ ẹ̀rọ kan ni, ó ṣì ń wáṣẹ́. Dèjì ní tirẹ̀ ti ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn ìjọba àpapọ̀ kan ní Èkó gẹ́gẹ́ bí olùṣírò owó, ó sì ti rí nǹkan jájẹ. Àwọn àgbà sì máa ń sọ pé owó l’obìnrin mọ̀. Owó yìí ló ranjú mọ́ Dùnúnkẹ́ tí ó fi jọwọ́ sílẹ̀ fún Dèjì. Kì í ṣe pé kò yó ìfẹ́ Dèjì náà o! Ọjọ́ tí ó jẹ́ hoo fún Dèjì pẹ́pẹ́yẹ pọnmọ lọ́jọ́ náà. Ilé oúnjẹ tí ó dára jù lọ ni ó gbé Dùnúnkẹ́ lọ jẹun lọ́jọ́ náà. Ọ̀pọ̀lọ́ ríbi tútù bà sí. Òrékelẹ́wà náà fẹ̀ síwájú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Dèjì àfi bíi ayaba. Ọyẹ́ ń kù rìrì sí àtùpà pálọ̀ lórí.
Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, tí oṣù ń gorí oṣù, ìfẹ́ àwọn méjèèjì ti rí ẹsẹ̀ walẹ̀ dáadáa. Àwọn òbí àwọn méjèèjì tí mọ̀ wọ́n gẹ́gẹ́ bí àfẹ́sọ́nà ara wọn. Kódà wọ́n ti ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ ìgbéyàwó. Iṣẹ́ tí Dèjì ń ṣe kò jẹ́ kí ó fi bẹ́ẹ̀ ráyè. Òru ni ó máa ń dé. Òpin ọ̀sẹ̀ tí ó yẹ kí o tún máa fi gbọ́ tí ara rẹ̀ nígbà mìíràn,ó tún máa ń lọ síbi iṣẹ́. Nítorí náà,wọn kì í sáábà ríra déédé. Àmọ́ kò sí ohun tí Dùnúnkẹ́ bèèrè tí Dèjì kì í ṣe fún un.
Àwọn ẹbí dájọ́ ìgbéyàwó, ọjọ́ kò láyọ̀, wọ́n ṣe é ayé gbọ́ ọ̀rún mọ̀.Oríṣìíríṣìí ọ̀bẹ làá rí lọ́jọ́ ikú erin. Àwọn èèyàn tó lórúkọ nílùú àti nínú iṣẹ́ ìjọba ló péjúpésẹ̀ lọ́jọ́ náà. Olóyè ìlú ni bàbá Dùnúnkẹ́, àwọn orí adé àti ọrùn ilẹ̀kẹ̀ ló péjú pésẹ̀ .Gbajúmọ̀ olórin jùjú kan ló wá f’orin dá ìjókòó lára yá lọ́jọ́ ìgbéyàwó yìí.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti fa tọkọtaya fún ara wọn. Ọ̀rọ̀ wá kù sí àwọn méjèèjì lọ́wọ́.Ṣe wọn kò kúkú ní bá wọn gbé. Ṣùgbọ́n alága ìgbéyàwó tí gbà wọ́n ní ìmọ̀ràn pé kí wọn má gba ẹnìkẹ́ta láyé láàárín wọn. Nǹkan ń lọ déédé lọ́dún mẹ́rin àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe ìgbéyàwó. Bìrí ni nǹkan yí padà! Èyí kò ṣẹ̀yìn àìgbélé ọkọ rẹ̀ dáadáa. Àsìkò àtisun oorun ọmọ kò sí. Isó inú ẹ̀kú ni ọ̀rọ̀ náà. Ojoojúmọ́ ni ó fi ń ronú pé ọjọ́ wo ni ayé yóò kí òun náà kú ewu ọmọ. Èrèdí ìgbéyàwó sì ni ọmọ ni ilẹ̀ Yorùbá.Ó ti pe ọkọ rẹ̀ sí àkíyèsí lọ́pọ̀ ìgbà pàbó ni ó ń já sí.
Ṣé kí a wá sọ pé ẹni tó ń wá ìfà ń wófò ni ọ̀rọ̀ Dùnúnkẹ́? Sanjọ́ tí ó fi sílẹ̀ nítorí pé kò rí jájẹ náà tí rí iṣẹ́ sí iléeṣẹ́ aládáni kan ní Ìbàdàn. Nǹkan tí ń ṣẹnuure díẹ̀díẹ̀ fún àwé náà.Ní ọjọ́ kan, Dùnúnkẹ́ pàdé Sanjọ́ ní ilé epo.Dùnúnkẹ́ gan án ní ó kọ́kọ́ rí i. Ariwo orúkọ Sanjọ́ tí ó pa ni ó jẹ́ kí ó mọ̀ pé òun náà wà nílé epo. Àwọn méjèèjì dìjọ sọ̀rọ̀, wọ́n gba nọ́ńbà ẹ̀rọ alágbéká ara wọn. Kò sí àyè láti sọ̀rọ̀ nítorí Sanjọ́ ń kánjú.
Ìṣòro àìrójú Dèjì nílẹ̀ kò jẹ́ kí ó mọ ìgbésẹ̀ tí ó lè gbé. Ẹ̀ẹ̀kàn lọ́gbọ̀n tí wọn dìjọ ń ṣe lọ́kọláya kò ì so èso rere. Ọjọ́ kan ni ó ronú kan Sanjọ́ pé ọjọ́ tí àwọn dìjọ pàdé kẹ́yìn òun bèèrè ìyàwó rẹ̀, ó sì sọ pé Dòdó-ń-dáwà ṣì lòun. Ó rántí ìdààmú rẹ̀ nílé wọn kí ó tó di pé Dèjì lòun padà gbà fún. Ọkàn rẹ̀ a máa lọ sọ́dọ̀ Sanjọ́ bóyá yóò sanjọ́ gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ̀.
Àwọn àgbà bọ̀ wọn ní bí ó bá kọjú sí ọ kí ó tá, bí ó bá kẹ̀yìn sì ọ, kí ó tá, bi o bá ku ìwọ nìkan kí o tún èrò ara rẹ pa.Wọ́n ní ilẹ̀ obìnrin kì í pẹ́ ṣú. Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò. Ṣé kí Dùnúnkẹ́ pọ̀ sókè rajà ni àbí kí ó sì máa forí tì í? Ṣé kí ó máa yan Sanjọ́ ní ọ̀rẹ́ ìkọ̀kọ̀ ni àbí báwo? Tí àkàrà bá tú sépo ń kọ́? Ìkòríta tí ń dààmú àlejò rèé!
Nípa Òǹkòwé
Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.
Àwòrán tó wà ní ojú ìwé yìí jẹ́ ti MelanMag
Eléyìí gba yì