Ọ̀rọ̀ kan tí ń dùn mi lọ́kàn ọjọ́ pẹ́.
Àsìkò tí tó wàyí tí n ó rò fáráalé.
Ọ̀rọ̀ kan tí ń ṣe mí ní kàyéfì ọ̀nà jìn.
Àsìkò tí to tí n ó kà férò ọ̀nà.
Bóyá ọ̀rọ̀ a jẹ́ níyanjú bí n bá wí i?
Lọ́jọ́ t'Ólú ti dábo ló tí ṣe wọn lẹ́yin.
À lọ́jọ́ Olú tí ṣẹ̀ wọ́n sí dúníyàn
N ló ti ṣe wọ́n ní wúrà.
Lọ́jọ́ t'Ólú ti dábo ló ti ṣọ́ wọn ní Kíkẹ́lọmọ.
Ẹni ìkẹ́ òun ìgẹ̀ ni wọ́n jẹ́.
Bí ń bá ṣì wí, ẹ wí ń mi?
Bí mo bá wohun tójú abo ń rí
Ominú a kọ mí.
Bí mo bá wàrà tákọ ń fabo dá
Àyà mi a sì là gààràgà.
Ìyà tó ń jẹ obìnrin kò kéré.
Ṣe tìgbà ìwáṣẹ̀ ni ka sọ ní?
Tí wọn kìí fẹ́ rímí abo láàtàn.
Ṣé tinú ẹbí ni ká rò àbí èyí tí wọn ń bá fínra láwùjọ?
Ọ̀kẹ́ àìmọye fìtínà yìí ò lóǹkà.
Ṣe ó yẹ kí èfọ̀ ó lè ẹ̀fọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀ láwo?
Ìbí kò kúkú jùbí
Mo ṣe bí a ti bí ẹrú ń lá bọ́mọ?
Kí lọ̀bọ fi ṣorí tí ìnàkí ò ṣe?
Ẹ sobìnrin digbá ìkolẹ̀.
Àwọn t'Ólúwa ń bù ú kún
N làwọn akọ kan ń bù ú kù.
Àwọn tọ́ba mi òkè ń pọ́nlé
N làwọn aláìláání sọ di gbàtúẹ̀yọ̀
Tí ò ju ọmọnáagún lójú ú wọn.
Ta lẹni tó wà láyé,
Tí kì í ṣobìnrin lọlọ́kọ̀ rẹ̀ wá sáyé?
Ta lẹni to wà lókè èepẹ̀
Tí kìí ṣobìnrin lo ní sábàbí ẹ̀
Tí wọ́n fi ń pè é léèyàn?
Ipò tí Wáídù to abo sì yàtọ̀ gédégédé.
Ọ̀gá ni kánhún wọn láàárín òkúta.
Ọ̀gá ni ilá pẹ̀lú ìlasa.
Ọ̀gá nìyáa Múdà wọn.
Ọ̀gá ni wọ́n nínú ohun gbogbo.
Akọ tó bá ń lu ìyàwó ẹ̀
Tọ́ lẹní tí à ń lọ yẹ ọpọlọ rẹ̀ wò l'Árò.
Torí lílù kọ́ lẹ fi pínlẹ̀ ìfẹ́.
Akọ tó bá ń da bùkátà sáyà lágbada
Ó yẹ kí wọn ó lọ kí wọn ní Yábàá apá òsì.
Ìfipá bánilò yìí tó gẹ́!
Ṣé torí ìgbádùn ìṣẹ́jú bínńtín
Lè ṣe ń bọmọlọ́mọ láyé jẹ?
Ṣé nítorí ìgbádùn ìṣẹ́jú akàn
N lẹ ṣe ń ràn abo lọ sọ́run lójijì?
Kùkù àgbàdo tí ń bẹ nísàlẹ̀
Ni ó jẹ ki ẹlòmíràn ó gbọ́n.
Àtiláawi ló sọ ẹlòmíràn di ajá.
Bí jagunlabí ba ti fojú rí abo
Ara òbúkọ rẹ̀ ó ní lélẹ̀ mọ́.
Wọn a fì iyán sílé
Wọ́n a máa dá ọkà láàmú níta.
Èyí tí wọ́n ní nílé ò wù wọ́n mọ́
Èyí tó o sọ dààyò níta
Kí ló fi yàtọ̀ sí tilé?
Kó kúkú sobìnrin tí kò rẹwà.
Bó bá rówó túnra ṣe.
Bí èpo ẹyin lara màdáámú yó ṣe máa dán.
Wọn a máa dàbí ìyàwó àṣẹ̀sẹ̀ gbé lójoojúmọ́
Bi mo bá parọ́ ẹ ja mí.
Kí wá ni wọ́n ṣe?
Tí ẹ fi ní kí wọ́n fò, kí wọ́n nìṣó.
Ayé tí dorí kodò obìnrin ó nìyí mọ́
Àwọn ni wọ́n tún ń ṣojúṣe nínú ilé.
Ojoojúmọ́ ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ bí aago.
Bàbá, ọjọ́ wo ni ẹ̀yin tí sanwó ilé ẹ̀kọ́
Àwọn ọmọ yín gbẹ̀yìn?
Bó bá wa dọ́jọ́ iwájú ẹ̀ ó ma yanbọ:
Èmi náà níọmọ tọ́ wà nílùú ọba.
Ẹ kò ṣe nídìí pẹpẹ, ẹ sì ń fẹ́ jẹ níbẹ̀.
N ó sọ táwọn tí sànmọ́nì lọ tín-ín-rín fún
Tí wọn tí ń rọ́wọ́ yọ tẹ́lẹ̀.
Àwọn obìnrin tí kìí ṣe ọ̀dájú ń bẹ
Wọ́n mọ baálé tí kìí ṣe bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.
K'Ọ́ba ó tètè dágbà padà fún irú ú wọn.
Obìnrin kì í ṣẹni ẹ̀tẹ́ òun àbùkù.
Obìnrin kì í ṣeni àrífín sẹ́.
Àwọn niyọ̀ ayé.
Ibi a bá ti ṣàfẹ́kù wọn ibẹ̀ kì í lárinrin.
Nípa Òǹkọ̀wé
Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Baptist Primary School, Bódè Ìjàyè,Abẹ́òkúta.Lẹ́yìn náà ni ó tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Líṣàbí Grammar School, Ìdí Aba. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Èdè Yorùbá àti Haúsá ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà Federal College of Education,Òṣíẹ̀lẹ̀,Abẹ́òkúta. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín,Ìjagun,Ìjẹ̀bú Òde .Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ilé ẹ̀kọ́ girama ni. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti ìtan àròkọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ìfẹ́ rẹ̀ sí àṣà àti ìṣe Yorùbá kí ó má lè dìmẹ́ẹ́rí kò láfiwé
Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti MsAfropolitan