Eerin wó, Àjànàkú sùn bí òkè!

O ṣe ni láàánú gidigidi láti gbọ́ pé Bàbá Láwuyì Ògúnníran, ọ̀kan gbòógí nínú àwọn òǹkọ̀we Yorùbá pa ‘po da ni ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù kẹ́sàn-án, ọdun yìí. Ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀, Bàbá Láwuyì Ògúnníran jẹ́ ògbóǹtarìgì àgbà òǹkọ̀wé tí wọn ti ṣe àwọn iṣẹ́ ribiribi fún ìtànkálẹ̀ ìṣe àti àṣà wa.

Bàbá Láwuyì Ògúnníran kọ púpọ̀ nínú ìwé lítíresọ̀ Yorùbá, eléyìí tó mú wọn dá yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òǹkọ̀wé ẹgbẹ́ rẹ̀.Yàtọ̀ sí gbajúgbajà Eégún Aláré, ọkan lára àwọn ìwé ti Baba Lawúyì kọ, wọn tún kọ àwọn ìwé bíi: Ọlọ́run ò màwàdà, 1991, Ìbàdàn Mẹ̀siọ̀gọ̀, 2000, Igi wọ́rọ́kọ́, 1998, Ààrẹ Àgò Aríkúyẹrí, 1977, Eégún Aláré, Ọmọ Alátẹ ìlèkè, Abínú ẹni, 1997, Ẹrù ìfẹ́, Ọ̀nà kan ò wọjà, 1991, Níbo láye doríkọ, 1980, Ogún ọ̀kẹ́ mẹ́fà, Àtàrí Àjànàkú, 1987, Aaro mẹ́ta àtọ̀runwá, 1993, Bó o láyà o sẹ̀kà, Adédẹ̀wá àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Àwọn ìwé yìí kamọmọ bẹ́ẹ́ni wọ́n kọ́ ni l’ọ́gbọ́n nípa oríṣiríṣi ìgbé ayé ọmọ’nìyàn. Gẹgẹ bi àwọn tán jọ jẹ́ sàwáwù, Bàbá Láwuyi fi òye oun ìmọ̀ wọn nípa àṣà Yorùbá han ninu ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tó ti ka ìwé wọn, Eégún Aláré ló le jẹ́rìí si iṣẹ ọpọlọ tó wà níbẹ̀. Yàtọ̀ sí jíjẹ́ òǹkọ̀wé, Bàbá Láwuyì Ògúnníran tún jẹ́ ẹni tó ṣe iṣẹ́ ribiribi fún Ìjọba Gúsù-ìwọ̀-oòrùn Nàìjíríyà gẹ́gẹ́ bi olùpìtàn, òlùṣèwádìí àti oníròyìn.

Àwọn Olóòtú Ẹgbé Àtẹ́lẹwọ́ Pèlú Baba Láwuyì Ògúnníran ni ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹ́sàn-án, ọdun 2020

Ni ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí (ọjọ́ karùn-ún, oṣù kẹ́sàn-án, ọdun yìí), ÀTẸ́LẸWỌ́, ẹgbẹ́ ti a gbé kalẹ̀ fún ìdàgbàsókè àtí ìgbélárugẹ èdè àti àṣà Yorùbá, ṣe àbẹ̀wò sí Bàbá Láwuyì Ògúnníran ní ilé wọn ní Baṣọ̀run ní ìlú Ìbàdàn. Eléyìí jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ tí à ń ṣe lọ́wọ́ láti fi ṣe àmì ẹ̀yẹ àti láti fi gb’óríyìn fún àwọn àgbà òǹkọ̀wé lítírésọ̀ Yorùbá tí wọ́n wà láàyè. Nínú èyí ni a ti ṣe fíímù ráńpẹ́ lórí ìgbésí ayé wọn ti à sì tún fún wọn ni àmì ẹ̀yẹ “fun ìgbélárugẹ èdè àti àṣà Yorùbá nípa ìwé kíkọ”.

Ni púpọ̀ nínú ìgbésí ayé Bàbá, wọn ṣe iṣẹ́ takun takun fún kí àṣà má parun nípa àwọn ìwé lítírésọ̀ ti wọn kọ. Bàbá Láwuyì Ògúnníran—gẹ́gẹ́ bí àwọn òlùjagun àṣà bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Akínwùnmí Ìshọ̀lá, Baba Adébáyò Fálétí, Baba Ọládẹ̀jọ Òkédìjí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—yóò lọ nínú ìwé ìtàn gẹ́gẹ́ bí ọmọ Yorùbá àtàtà to ní’fẹ́ ìran rẹ dé góngó. Èróngbà wa ni pé, irú ẹni báyìí a jẹ ẹni ti yóò ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ àti kóríyá, ṣùgbọ́n o ṣe ni láànú pé kò rí bẹ́ẹ̀. Nígbà ti a lọ ṣe ìfọ̀rọ̀wanilẹnú wò pẹ̀lú Bàbá àti ọmọ wọn, Túndé Ògúnníran, ọmọ wọn sọ fún wa pé pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ribiribi tí Baba ṣe, kò sí ẹni to fún Baba ni àmì ẹ̀yẹ kankan àti pé àmì ẹ̀yẹ tí a ṣe fún Baba ni yóò jẹ́ àkọ́kọ́ irú ẹ.

À ń fi àsìkò yìí ké sí ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lábẹ́ Ọlọ́lájùlọ Onimọ̀-Ẹ̀rọ Sèyí Mákindé láti ṣe gbogbo ohun tí ó bá tọ láti ri pe orúkọ Bàbá Láwuyì Ògúnníran kò parun ni’lẹ̀ káàárọ̀-Oòjíire. Kò sí ǹkan tí ìjọba bá ṣe fún Bàbá Láwuyì Ògúnníran tó pọ̀ jù. Èyí tún rán wa létí pé kí a ma gb’oṣùbà oun oríyìn fún àwọn ònkọ̀we èdè Yorùba.

Kí Ọlọ́run dẹlẹ̀ fún Bàbá.

Àmín Àṣẹ Èdùmàrè.

 Láwuyì Ògúnniran
Àgbà ọ̀jẹ̀ ọmọ Ejíwándé Ìlágbẹ̀dẹ
Ìrèmògún ọmọ Àyóyọ̀ tí í j'Éjigbọjọ̀
Ejiwẹ́rẹ́ ni 'ò jẹ́ n ná'jà ní Sànbe,
Tòtòwẹ̀lì ni 'ò jẹ́ n ná'jà t'Ìrè;
Kò-ṣ'eji-kò-ṣ'òjò l'ó jẹ́ n ná'jà Mògún kalẹ́.
Ejíwándé ará À-wújà-irin;
Ọmọ Olúgbọ́n ń ké n'ílé baba wọn,
Gbogbo wọn l'ó ń pé Wándé ti mú 'rin jẹ;
Àgbẹ̀ roko kí o tọ́ orí òkítí wò
Yóó mọ̀ p'éyín alágbẹ̀dẹ 'ò ran 'rin.
Ará Ìrèmògún ọmọ Àyóyọ̀
Ó di gbéré, ó di kéṣe o!
Ẹ ẹ̀ ní r'ójú olórò mọ́ nù-ún
Láwuyi dágbére fún 'lẹ̀ láìní w'áyé mọ́!

Erin wó. Àjànàkú sùn bí òkè.
Sùn un re o!

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *