Ìbínú kò mọ̀ pé olówó òun ò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. 
Ọ̀rẹ́ wa kan ló fi àṣejù kó bá ara rẹ̀ lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí.
Ó ń wa mọ́tò rẹ̀ lọ lójú títì, ni mọ́tò tó tóbi ju tiẹ̀ lọ bá kọlu mọ́tò rẹ̀. Gbàùù!
Ọ̀rẹ́ wa sáré dá mọ́tò dúró. Ó bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní fi ohùn sílẹ̀.
Dẹ́rẹ́bà mọ́tò kejì bẹ̀ ẹ́. Gbogbo àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́, ṣùgbọ́n kò gbọ́. Ń ṣe ló tún ń lé fùrùkọkọ, ló ń da òyìnbó sílẹ̀ bíi ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀.
Títí tí dẹ́rẹ́bà mọ́tò kejì fi sọ pé, "Ẹ̀yin oní mọ́tò kéékèèké yìí gan, tiyín pọ̀."
Kí ni ọ̀rẹ́ wa gbó èyí sí, ó tutọ́ sókè, ó fojú gbà á. Ó yarí. Ó bínú gan. Ó lérí. Ó ń tu bíi sèbé tí inu ń bí.
Dẹ́rẹ́bà mọ́tò kejì tún sọ pé, "Kí lo fẹ́ ṣe gan?"
Ọ̀rọ̀ yí túnbọ̀ bí ọ̀rẹ́ wa nínú. Ó wò yán-yàn-yán káàkiri,ó sì rí àpólà igi kan. Ọlọ́run ló mọ èṣù tó gbé igi náà síbè. Gbogbo àwọn tó ń rọ̀ ọ́ pé kó ní sùúrù gan sún mọ́ ẹ̀yìn.

Ni ọ̀rẹ́ wa bá pariwo pé, "Mọ́tò tí o ń pọ́nlé yìí, màá bayé ẹ̀ jẹ́."
Ó ń fi àpólà igi náà bí ẹni ń fi ìgbẹ́ inú ọ̀rá.
A kò mọ̀ bóyá ó fi ń dẹ́rù ba dẹ́rẹ́bà kejì ni, bóyá ó sì fẹ́ jù ú ni. Nǹkan tó ṣáà ṣẹlẹ̀ ni pé àpólà igi bọ́ lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ wa, ó sì ba gíláàsì mọ́tò ńlá náà. Gbogbo èèyàn kọ háà!
Gbogbo gíláàsì mọ́tò náà rọ̀ wálẹ̀ bíi eji òwúrọ̀.
Gbogbo bí àwọn èèyàn ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí gíláàsì náà, tí wọ́n sì ń yẹ̀ ẹ́ wò ni dérébà ọkọ̀ ńlá náà ti pé olówó rẹ̀ tí ó sì ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fun.

Láìpẹ́, bàbá olówó de pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá. Gbogbo àwọn olùwòran fọ́n ká. Àwọn ọlọ́pàá ré ọ̀rẹ́ wa ní ìfáṣẹ̀ sínú mọ́tò. Wọ́n sì gbé e lọ.
Lẹ́yìn tí a ti bẹ bàbá olówó tán, a lọ sanwó ìtanràn ọ̀rẹ́ wa.
Ní tésàn, a rí i níbi tí wọ́n dá a gúnlẹ̀ sí. Ńṣe ni ọ̀rẹ́ wa ń wò pàkò-pàkò bíi ọ̀daràn ẹyẹ tí musàn.
Àwọn bàbá wa ní; Ẹni tí ò bá gba kádàrá, á gba kodoro.
Àti kodoro, ati kóńdó ọlọ́pàá, gbogbo ẹ ni ọ̀rẹ́ wá jẹ kí wọ́n tó fi sílẹ̀.

Torí ijọ́ mìíràn, tí inú bá ti ń bí ẹ, bóyá èèyàn kan ṣẹ̀ ọ́, kí ó tó fi ìbínú ṣe nǹkan kan, wo ara rẹ nínú aṣọ ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ṣé ó yé ẹ́?

Ire o.

Nípa Òǹkọ̀wé

Waliyullah Túndé Abímbọ́lá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀. Ó fẹ́ràn gbogbo nǹkan tó bá jọ mọ́ kíkọ àti kíkà ní èdè Yorùbá. Àti èdè Gẹ̀ẹ́sì náà. Ọmọ Ìloòbú ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ni. Ẹ lè wá a sí Ilé-Ifẹ̀, Òṣogbo tàbí Ìloòbú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *