Àṣẹ Àwòrán yìí jẹ ti JerryPencil

Ìlú yìí kan gógó ó sì
kún fún àwọn àṣá
tí wón sọ pé àwọn nì ìyá
àwọn òròmodìyẹ.

Egbìrìn ọ̀tẹ̀ bí à ń ṣé pa ìkan
ni ọ̀kan rú ní ìlú mi.
Ní àgbàlá òdòdó yìí
ẹ̀gún ń wù lára ènìyàn,
Ìlú yìí ò lóun ò fa awọ àra mi ya
àwọn ẹ̀gún ibí yìí
ò làwọn ò dá ọgbẹ́ sí ọkàn mi.
Afẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ ní ìhà yín
kò ní oun ò ba igi oko jẹ́
ìjì tó ń jà ò sì ní oun kò
tú gbòngbòn rẹ dàànù.

Ìlú yìí kan gógó ó sì
kún fún àwọn àṣá
tí wón sọ pé àwọn nì ìyá
àwọn òròmodìyẹ.
Ìlú mi kò ní ká má mà jó
tí a bá tilè gbe orin arò.
Ìjàmbá sì di odò láìní afárá
tó sàn káàkiri ara waa.
À ń wò òkè, ṣùgbọ́n a ò mo ibi tí
àwọn òrìṣà òkè dojú kọ.

Nípa Akéwì

Salawu Olajide ń gbé Ilé-Ifè. A lè kà nípa àwọn iṣẹ́ rẹ̀ míràn lórí Salt Hill, Glass, Rattle, New Orleans Review, Soul-Lit, Saraba, Praxis Magazine, Transition, The Mantle àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *