ẸFÚNṢETÁN

Ọya ṣe tán ó rà sílé 'rá
Ṣàngó ṣe tán ó wọlẹ̀ní Kòso 
Ẹfún ṣe tán ó lójú orógbó
Ẹfun ṣe tán ó wẹwù ìjà sọrùn
Ohun ojú òkú ri ní popo
Ẹ bere lọwọ ikú wò
Ohun ṣàngó rí ní Kòso
Ẹ bere lọwọ adóṣù wo
Ohun ẹfún rí kó tó ṣèyí tán 
Ló mú ẹfun gẹgún ọ̀ràn
Ẹfún tuná lójú bi ọká
Ẹfún toró lẹnu bí eré
Ẹfun ò déédé bínú
Bí kò bá nídìí ìṣẹ kìí déédé ṣẹ
Ẹfun ò déédé pajúdà o jàre
Ẹfúnṣetán aníwúrà
Ìyálóde ilẹ Ìbàdàn
Abìwàpẹlẹ n dẹtù
A -dú-máa-dán bíi kóró iṣin
A-bẹ̀-rín pònyẹ̀kẹ̀ lórí ojú tó lé tìróò
A-bo-rí-já-ko akọbìnrin
Alówóńlé aníṣulóko
Alẹrúlọgbà alówólódù
Olówò ẹtù tí kìí jagun
Ọ-pàṣẹ ogun fìdí mọlé
Kí lèrè ẹní lókìkí tí ò lọmọ
Tààgàn kọ ti ìgbéraga kọ́
Ojú ẹ fi ń wo ẹfúnṣetán ò ríbẹ o jàre
Ẹní lówó lọwọ, tí ò lọmọ, ò lẹyìn
Lójú ayé rẹ nìran rẹ̀ dópin
Ẹrú wá ń bimọ, ẹní ó máà bínú
Ọmọ tirẹ kú tòun tọlẹ̀ nínú
Ojú pọn ẹfun ó lójú orógbó
Ojú pọn ẹfun ó wẹwu ìjà sọrùn
Ẹfún ṣe eléyìí tan
Ó ń ṣojú koko sọmọlọmọ níkòó
Ó ń wò hàùn pa tọmọ tiye
Bóo bá ń gbọtàn tán
Tóò tíì gbọ àrọbá tán
Ìtàn ń tàn ọ lọwọ ni
Nítorí àrọbá gan baba ìtàn kítàn
Bóo bá wá ń kàtàn
Lọ ka tẹfúnṣetán
Kóo le mọ kókó ìdí ìtàn.

ÈKÓ AKÉTE

 Orin;
Èkó ooooo, Èkó ooo eee
Èkó ooooo, Èkó ooo eee
Èkó akéte ìlú ọgbọn 
Èkó akéte ìlú ìmọ̀
Èkó ooooo...

Gbogbo igi ní ń bẹ nígbó
Gbogbo rẹ kííṣe gbẹ gbẹdu
Gbogbo ìlú ní ń bẹ ní Nàìjá
Gbogbo wọn kííṣe mú yangàn bí Èkó 
Ọjọ ajé lòní Èkó ò gba gbẹrẹ rárá
Ṣùgbọn síbẹ ó gbolè ó tún gbọlẹ
Ló fi dirúwa ògìrì wá
Tájèjì fi fẹ máa fọwọ lalẹ níbẹ̀
Èkó akéte a rọ ṣẹṣẹ mọmọ já lèkó
Èkó a rómi sá lẹgbẹ-lẹgbẹ
Alagbalúgbú omi ń bẹ nípìnlẹ Èkó
Níbi táfárá ti ń gorí afárá kọjá
Níbi tí márosẹ̀ ti ń lé tìróò
Èkó takété sáàrin omi ni
Ni wọn fi ń pèé lékòó akéte
Lórígun mẹrin Èkó
Tútù làá rọdẹ tútù làá rọ bàbà níbẹ̀
Gbogbo nǹkan ìgùn ló pé sílùú Èkó
Ẹ jọwọ ẹ fún mi níwèé ìrìnnà
Bó ṣọkọ akérò bó ṣọkadà
Bó ṣe rélùweè bó ṣọkọ ojú omi
Tàbí bàlúù
Mo fẹ lọ gbélu Èkó sẹ́
Mo fẹ dówòrò kín n ṣòwò tó pé
Mo fẹ gbàdúmọtà kín n tàtà jèrè náà o
Ìlú táa ti ń kọgbọn ta máa lá ò gbọn rárá
Ìlú táa ti ń lówó lọwọ ta máa lá ò ní ṣéńjì lápò
Bóo bá gbóko tóò bá gbọn
Tóo wá dékòó tóo tún gọ o jàre
Óò leè gbọn mọ láyéè rẹ
Nítorí Èkó a kóni mọra ni
 Èkó ilé ọgbọn, ilé ẹkọ , ilé ìmọ̀
Mo fe rìn rìn àjò lọ sílùú Èkó
Èrò yà ẹ máa bá mi kálọ
Ibí ni wọn pè lékòó
Èkó ni wọn pè níbí
Ère mẹta tí ń bẹ nípìnlẹ̀ Èkó
Ọkan lóò gbọdọ rìndìnjù
Ọkan lóò gbọdọ sùẹgbẹ̀
Ọkan lóò gbọdọ ya múgùn léèyàn
Mo ti rókun tó já sókè òkun 
Mo ti rọsà tó já sókè ọya 
Bóo bá wọnú Èkó tán
O le sọnù sórí ìrìn
Níbi tílé ti ń jọra wọn
Ilé aláwò ṣí fìlà ńlá-ńlá
Mélòó la fẹ kà nínú eyín adípèlé 
Tinú ọrún tòde ọjọ 
Bójú ò bá tẹ̀yìn ìgbẹ̀tì
Ojú ò le tèkó láyé
Jẹjẹ lọmọ Èkó ń lọ
Ọmọ onílùu a tẹẹ jẹjẹ 
Àjòjì ní ń tẹlẹ yí gànràn-gànràn.

ÈKÌTÌ KETE

A kìí wà láyé ká mọ lárùn kankan
Ìjà gboro n tìbàdàn
Owó òde ni tọyọ ile
Máṣu mátọ̀ ni tèkó ile
Agídí wọn pọ lékìtì kete
Ìlú tó lé téńté sórí àpáta ni
Àpáta lodi ràbàtà tó yékìtì ká ò eee.
Kete rian nílu Ẹkìtì
Kẹ bámí gúnyán tó fẹlẹ́
Mo fẹ wá ṣọdún ewì níbẹun
Léyìn ìkọlé ayé àti ìkọlé ọrun
Ìkọlé Èkìtì ló tún kàn
Ẹ jẹ ká rèkọlé Èkìtì
Kẹẹ wá wàpáta paara
Kẹẹ wá wòke ìgbemì
Àfonífojì tí ń móyì kọ́ ni
Kẹẹ wá wo koto gìrìwò náà 
Lẹyìn Èkó akéte
Èkìtì kete náà ló kàn
Ìran Èkìtì ló lòkè gbemì
Òkè pàràbàtà dúró gó gò gó
Òkè yìí máa wó lónìí
Òkè yìí máa wó lọ́la
Òkè yìí ò ní wó mọ́
Ó kàn ń jọ bẹẹ náà ni
Ọmọ alápata sàpátadowo
            Ọmọ ẹkùn ọmọ ọwá ọmọ lókè méjì 
Tètè bán gúnyán
Bámi wálà ìkàsì pẹlé ẹja yinyan
Mo fẹ gòkè ìmèsì
Mo fẹ gòkè àtà
Mo fẹ dòkè àpáta
Kin tó pa dà sí ìgárá òkè
Èrò jẹ á rèkogòsì
Níbi omiígbóná àtomitútù 
Ti gbé ṣọrẹ ara wọn 
Lẹyìn ìkọlé ayé àti ìkọlé ọrun
Ìkọlé Èkìtì ló tún kàn an

ẸDÚNJỌBÍ

Èjígbèmí ni wọ́n pè léjìogbè
Awo méjì méjì rè mò ń bá wọn dá o
Ọ̀kan ǹ bá bí, èjì ló wọlé tọ̀ mí wá
Búmi kí n bá ọ relé
Kìmí kí n padà lẹ́yìn rẹ
Èjíwùmí fò kìṣì bí ẹlẹ́gà òkè
Èjíwùmí ará òde ìlẹ́gà
Ẹdun ò gbọdọ̀ jẹran ẹ̀gà
Ẹdúnjọbí ọmọ kúlegun
Èjíwùmí a gbórí igi réte
Táyélolú èjìrẹ ará ìṣokùn
Ọmọ kẹhìndé gbẹ̀gbọn
Wíní-wíní lójú orogún
Èjìwọ̀rọ̀ lójú ìyá ẹ̀
Àìtètè jí onílé gbalé
Èjìrẹ̀ mọlé olówó kò lọ
Èjìrẹ̀ mọlé ọlọlá kò lọ
Ò bẹ kìṣì, bẹ kẹṣẹ́
Ó bẹ sílé alákìsà
Ó salákisà donígba aṣọ
Níjọ téjìrẹ ti dáyé, èjìrẹ ò jalè rí
Lójú olóko ni wọn tii mú tiwọn jẹ
Èjìrẹ òrílà máa bọ lọdọ̀ mi
Mo lépo nile, mo lẹwà lọdẹ̀
Ìyàwó mí lè jó jó jó
Èmi náà mo le sọ̀dí wùkẹ̀
Èjìrẹ tí mo bí, tí mo jó jó jó
Èjìrẹ tí mo bí, tí mo máyọ̀ọ yọ̀
Ẹni èjìrẹ wù, kó yáa níwà tútù
Òṣónú ilé àwa ò bíbejì
Onínúure ní ń bẹdun 
Ẹdúnjọbí, èjíwùmi
Èjíwùmí èjìwánwálé
Èjìrẹ ọ̀kín ará ìṣokùn
Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi
Ẹ sọ fáráayé kí wọn ó gbọ́
Ẹdúnjọbí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà
Tí wọn ta pákúnṣirín epo lé lórí
Èjíwùmí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà
Tí wọn da jiwin-ni-jìn àkísà bọ̀ lọ́rùn
Ẹdúnjọbí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà
Tí wọn ń fìlù kójó kó jáde
Taló fẹ bíbejì kó nawọ́ ọọọ.

ỌNÀ ÌLU WA

Ojú òpó kìí di
Ẹnu isà kìí ṣẹ̀jẹ̀
Bígba ojúlé tií wọlé ikan
Bígba ọ̀nà tií wọlé àwúrèbe
Bẹ̀ lojú ọ̀run ń dán gbin rin
Ọ̀nà ọ̀run ń yọ̀ kù làlà
Ọ̀nà tóóró yọ̀ wá látọ̀run
Tí kò ní gbòǹgbò
Tí kò ní ìtàkùn
Tí kò ní ìdágbẹ́
Inú aláboyún ni wọn pè bẹẹ
Ọ̀nà tóóró ló yẹgbó
Ọ̀nà tààrà ló yẹ̀gboro
Gbogbo ọ̀nà wa bíi abúlé onígò ló rí
Gbogbo ọkọ̀ ń rìn jẹjẹ́
Gbogbo ọkọ̀ tó bá rìn jàùjàù
Olúwa rẹ̀ á kòyọnu ni
Nítorí ọ̀nà ìlú wa tí kò dán kòòrò 
Ihò ń bẹ lọnà kó kò kó
Kòtò ń bẹ ní márosẹ̀ gìrìwò
Òpópó ilé ò ṣeé dúró sí
Ọ̀nà tààrà ò ṣeé gbà dọjà
Àyàfi ká máa pẹkọrọ
Bíi aláàmù lébàá ògiri
Omi ń yalé
Ọ̀gbàrá ń yàgboro
Kọ̀ǹkọ̀ àtàkèré ń fọhùn lọọ̀dẹ̀
Ilé ayé ni Mẹkà ń gbé
Òpópó Mekà mọ roro
Bíi díígí aláwòtúnwò
Lọjọ wo nìjẹ̀bú Igbo fẹ dìjẹ̀bú òde
Lọjọ wo nigbó gan án fẹ dìgboro
Lọjó wo lọ̀nà tóóró fẹ di márosẹ̀
Àtolóṣèlú àtẹni wọn ṣèlú lé l'órí
Àláà mi ò gbọdọ̀ kú
Àláà mi ò gbọdọ̀ kútà
Mo fẹ jí kí gbogbo ọ̀nà ti lé tìróò
Mo fẹ jí kéku ó máa ké bíi eku
Mo fẹ jí kẹyẹ ó máa ké bíi ẹyẹ
Mo fẹ jí kọmọnìyàn ó máa fọhùn bíi ènìyàn.

ỌMỌ YORÙBÁ

Lámi lámi ní ń ṣeré agbami
Àfòpiná ní ń ṣeré ògunná
Ọ̀gá ni káún láwùjọ òkúta
Egungun bíi eyín ò sí lágbárí
Nínú ayé yìí sẹ́
Ògbóǹtàrigì nilẹ̀ adúláwọ̀
Àràbà niwá nílẹ̀ẹ Nàìjá
Láàrin gbogbo adúláwọ̀ to ku
Ìran kan ń bẹ nílẹ̀ẹ Nàìjá
Tí wọ́n tún gba sàdáńkátà
Ọ̀kan ṣoṣo àràbà tí ń migbó kìji kìji
Nìran Yorùbá jẹ nígboro Nàìjá
Ọ̀gá niwá, aṣewẹrẹ jayé
Alágẹmọ ni wá, 
Gbogbo aṣọ ìgbà ló bá wá lára mu
Ilẹ̀kílẹ̀ tí Yorùbá bá jásí
A gbóúnjẹ fẹ gbẹ a tún gbàwo bọ̀
A gbayì ní tìbú tòòró ayé ni
Nínú ìmọ̀ wọn mọ̀ wá
Nínú ọgbọn wọn gbọwá
Nínú ìfaradà a rọkú
Nínú ìbáṣepọ̀ a gbayì
Àkìtàn niwá, ara wá gbẹ̀gbin
Abẹrẹ niwá a ò lókùn nídìí
Òkìtì ọ̀gán niwá, gbogbo ọ̀nà ló wọ̀lú wa
Ọmọ oníyọ̀ tí ń jàtẹ́
Ọmọ ẹlẹran tí ń jeegun
Òkèlè ń bẹ nílẹ̀, a ò rọbẹ̀ fi kàn
Amúkùn-ún niwá, 
Ẹrù ti wọ láti ọwọ àwọn àgbààgbà
Ọmọdé ilé là ń dẹ̀bi ọ̀rọ̀ rú o jàre
Àbí kí la tún fàgbà ṣe tó ju káà fi rẹmọdé jẹ lọ
Atẹgùn tín gbanú akéwì
Ni mo ní kí n fẹ síta
Ò lè ṣọyẹ, ó lè ṣooru
Ṣé òtútù rẹ̀ ò mùu yin jù
Ṣé oru rẹ̀ náà o máa pọ̀ lápọ̀ju

TÌRÓÒ Ọ̀BẸ̀

 Ìgbàgbé ṣemí mi n ò lé tìróò  
             Mo jáde tán, ojú wá rí gbaguẹ
             Ojú mi ò dára lágbárí
             Kò tún dára lára ẹlòmíràn
             Gbogbo ọwọ tí ń ròde ọ̀fún ẹ farabalẹ̀ 
             Mo fẹ gbàdúrà ìdákẹjẹ́
             Ẹní bá ń wíjọ á wúkọ́
             Ẹní bá ń ṣàròyé á sín
             Ẹní bá ń pariwo á gbèsúkè
             Ìrìnàjò tí a fẹrìn a dọfun tòló. 
             Kí a tó sebẹ̀, kó tó ta sánsán
             Ojú ní láti rí nǹkan
             Bó bá ṣerọ ni mo pá
             Ẹ bèrè lọwọ àlùbọsà
             Ẹ wojú ọbẹ̀ kẹẹ múyán 
             Èsì ń bẹ lọwọ alásè
             Ẹmí tí ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ
             Ojú la ó ti mọbẹ̀ tí ò lépo
             Epo ọbẹ̀ gangan ni tìróò
             Bí ẹ bá sewébẹ̀ tí ò gbé ẹ̀gúsí. 
             Ojú ọbẹ̀ ọ̀hún fọ́
              Bí ẹ bá sewébẹ̀ tí ò lépo
              Ojú ọbẹ yẹn ò ní tìírò
              Bí ẹ bá fẹ káta ó rojọ́
              Ẹ lọ ata ní ọlọ 
              Kí ẹ gbáa sínú u pákúnṣirín epo
              N ò wá polówó magí níbí
              Ẹ kórú dà sọ bẹ̀
              Bẹ ò rírú, ẹ wógìrì lọ
              Adití á gbóhùn ata. 
              Afọjú á mọ̀ pérú wà lọbẹ̀
               Ẹ̀ fàlùbọsà sọbẹ̀
                Kóúnjẹ ó ma jóògùn
                Kóògùn ó ma jóúnjẹ
                Bí ẹ bá ń ròde ọ̀fun. 
                Ẹ dákun ẹ má jàtẹ́
                Ẹni ń jẹun tí ò lọsà
                Àtẹ ní ń jẹ
                Ọ̀lásúnkànmí ń se yátì lọbẹ̀
                Ẹ wojú ọbẹ̀, ẹ tọbẹ̀ wòòòò 

Ọ̀BẸ TÓDÙN

 Àìdùn ọsàn ni n lè mu méjọ̀lá
             Bọsàn bá dùn n ó pada mugba
             Àìlówó lọwọ́
             Lọbẹ̀ yí dùn kò wẹran
             Àìlówó lápò. 
             Lọbẹ̀ yí dún kò wẹja
             Bówó bá ń bẹ lọwọ́
            Tí kúnkúṣì bá ń bẹ lápò
            Ká sebẹ̀ tó pójú owó
            Bẹja ti ń jùrù lọbẹ̀. 
            Kẹran ó máa tinú ẹran jáde
            Bí ẹ bá ń wọbẹ̀ tó dùn
            Pẹ̀lú òórùn tó le jí òkú ní pópó
            Pẹ̀lú adùn tó le mú ni járun
            Nílẹ̀ káàárọ̀ o ò jíire 
             Níbi tí a ti ń fitan erin jẹyán
             Níbi ti a ti ń fitan ẹfọ̀n jọkà
             Pẹ̀lú ọbẹ̀ tí kò ṣe é fọwọ rọtì
             Ẹ pe ééyọ wá kó wá dási
             Ẹ pẹ̀fọ wá kó wá dárà 
             Ṣe ẹ ti jewé ròkó 
             Àbí ẹ ti jọ̀mùnú kókò
            Bẹ ò bá mọ̀gbó
             Ṣebí ẹ màbáláyé
             Ó yẹ kí ẹ le mọ ṣọkọ 
             Ẹ mọ ṣaláì mọṣápá
            Nìtorí a máa toro mọyán
            Ẹfọ ni márúgbó ṣányán
            Ọ̀mọ ìyá efinrin
             Ewúro ọbẹ̀ 
             Gbẹ̀gìrì ń bẹ lápá kan ọ̀tún
             Gbúre ń bẹ lápá àlàfíà mi
             Tẹ̀tẹ̀ kìí tẹ láwùjọ ẹ̀fọ́
             Méjì lamúnútutù
             Bí a ti ń rí funfun 
             Bẹẹ la ń rí pupa
         Níbo ni eéyọ wà ná
             Eéyọ́ nilá
             Eéyọ́ lọ̀runlá
             Eéyọ́ nìlasa. 
             Ewédú òun ẹkù
             Ṣebí ẹ ti lá lúrú rí
         Ṣé ẹ ti jàpọ̀n náà rí
             Ọlásúnkànmí ń se yátì ẹ ò mọ̀
             Òkèlè ń bẹ nílé. 
             Ọ̀bẹ̀ ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá
             Gbogbo wa la mọ̀ bẹ́ẹ̀.

Nípa Oǹkọ̀wé

Abdulkareem Ajimatanraẹjẹ jẹ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Èkó. O lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ Èkó ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ (B.a Yorùbà) ní Ifáfitì Ọlábísí Ọnàbánjọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Oǹkọ̀wé, Olùkọ́, Oníṣẹ́ ọwọ́, Alátinúdá, atọ́kùn ètò lóríi rédíò àti tẹlifísàn ni Ọ̀gbẹ́ni AbdulKareem.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *