Àwọn ará Ẹ̀gbá tí ó tèdó sí ìpínlẹ̀ Ògùn lónìí jẹ́ ọ̀kan nínú ojúlówó ọmọ Yorùbá. A lè pín Ẹ̀gbá sí ònà mẹ́rin Aké , Òkè-Ọnà, Gbágùrá àti Òwu. Lóòótọ́ , àwọn  mẹ́ta  àkọ́kọ́ ni ó  jẹ́ ojúlówó Ẹ̀gbá. Ṣùgbọ́n, bí  ìgbà ṣe ń lọ ni a fẹ àwọn tí a lè pè ní Ẹ̀gbá lójú .

Àwọn ọmọ  Ẹ̀gbá ti ṣe gudugudu méje ní ilẹ̀ Yorùbá àti ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. A kò lè gbàgbé iṣẹ́ takuntakun wọn. Ẹni-ọ̀wọ̀ Olúdọ̀tun  Ransome Kútì , Fẹlá Kútì , Arábìnrin Fúnmilayọ̀ Ransome Kútì , MKO Abíọlá , Olóyè Olúṣẹ́gun  Ọbásanjọ́ , Ọlóyè Ernest Shónẹ̀kàn, Olóyè Akin Olúgbadé, Bẹ́ẹ̀kọ́  Ransome Kútì , Ọ̀mọ̀wé  Olíkóyè Ransome Kútì, Ọ̀mọ̀wé Saburi Bíòbákú, Ọ̀mọ̀wé  Thomas Adéoyè Lambo, J.F Ọdúnjọ, Chief Commander Ebenezer Obey, and Àyìnlá   Ọmọwúrà, Abdul lateef Adégbìtẹ́ , Sẹ́nátọ̀ Ìbíkúnlé Amósùn , Olúsẹ́gun Ọ̀sọbà , àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Gbogbo ẹ̀yà àti ọmọ Yorùbá ni ó rí Ilé-Ifẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orírun wọn, ṣùgbọ́n  ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ẹ̀yà Yorùbá ni àwọn ará Ègbá jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ojúlówó Yorùbá àti Yorùbá tó gbé ìwọ̀n ń jẹyọ lára Yorùbá Ọ̀yọ́ àti ti Ẹ̀gbá gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Samuel Johnson ṣe sọ nínú ìwé rẹ̀ lórí ìtàn Yorùbá. Pẹ̀lú pẹ̀lú , olóògbé Bíṣọ́ọ̀bu Àjàyí Crowther náà jẹ́rìí sí i nígbà tí wọ́n n po ojúlówó Yorùbá pọ̀.


Àwọn ará Ẹ̀gbá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Odùduwà , wón sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba méje tí ó ní adé ojúlówó tí ó ṣẹ̀dá láti ọwọ́ bàbá ńlá wa, Odùduwà. Àwọn ará Ègbá ń gbé ni oko Ègbá. A mọ àwọn ará Ẹ̀gbá gẹ́gẹ́ bí àgbẹ̀ àti jagunjagun. Àwọn ará Ẹ̀gbá l’ákọ̀ọ́kọ́ tẹ̀dó sí igbó Ẹ̀gbá, eléyìí wà ní  Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lónìí . Wọ́n wà lábẹ́ Ìjọba Ọ̀yọ́ kí wọ́n  tó gba òmìnira pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Lísàbí, èyí ni a ṣe ń pè wọ́n ní ọmọ Líṣàbí Agbòǹgbò Àkàlà . Pàtàkì nínú ìtàn àwọn ará Ẹ̀gbá ni ìgbà tí àwọn jagunjagun Ìbàdàn lé wọn kúrò ní agbègbè àti ilẹ̀ wọn . Nínú rògbòdìyàn yìí, Lámọdi, Balógun àwọn ará Ẹ̀gbá bá a lọ . Èyí ló mú kí àwọn ọmọ Ẹ̀gbá farasin láti dáàbò bo ara wọn ní Olúmọ ní Abẹ́òkuta ní 1830. Abẹ́òkuta lónìí jẹ́ oko Adagba , tí ó jẹ́ àgbẹ̀ láti ìlú Ìtokò .

Ìlú titun, Abẹ́òkúta yìí gba àwọn ará Ẹ̀gbá dáadáa . Abẹ́òkúta jẹ́ ibi ààbò fún wọn , wọ́n sì ń gbé ní àlàáfíà . Èyí jẹ́ kí wọ́n  fa àwọn ará tí ó kù tí wọ́n sá fún wàhálà àwọn ará Ìbàdàn sí Abẹ́òkúta tako sísálọ wọn ìlú Ẹ̀gbádò tàbí Bàdágìrì. Láì pẹ́ ọjọ́ , àwọn ọmọ Ẹ̀gbá tẹrí àwọn ará Ẹ̀gbádò tí ó súnmọ́ wọn ba. Àwọn ará Ẹ̀gbádó pàdí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn Dahomey láti kọjú ìjà sí àwọn ará Ẹ̀gbá , àti láti  ṣí wọn ní ìdí kúrò ní Abẹ́òkúta . Ṣùgbọ́n ní gbogbo ìgbà tí àwọn atiláàwíí yìí dìde ogun sí wọn , àwọn ará Ẹ̀gbá máa ń borí wọn . Ogun àti ọ̀tẹ̀ lọ́tùn-ún àti lósì ni àwọn ará Ẹ̀gbá dojú kọ ní ìlú titun yìí . Ìgbìmọ̀pọ̀ àwọn Ìjẹ̀bú , Ọ̀yọ́ àti Ìbàdàn kò sì borí wọn ní Abẹ́òkúta .

 Ní àárín ìgbà yìí ni àwọn ọmọ Ẹ̀gbá padà sí ilé láti òkè òkun lọ́pọ̀ ìgbà láti oko ẹrú ìmúnisìn Òyìnbó . Wọ́n wá pẹ̀lú ọgbọ́n oríṣiríṣi àti ìmọ̀ nípa gbogbo ọgbọ́n tí ó lè mú àwùjọ gòkè àgbà . Paríparí rẹ̀, kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ wọ ìlú Abẹ́òkúta ní ọdún 1842. Ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ sì wá kópa pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ìlú Ẹ̀gbá . Ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́ mú ètò ẹ̀kọ́ ìgbàlódé wá sí ilẹ̀ Abẹ́òkúta . Èyí sì gbé àwọn ará Ẹ̀gbá sókè ju àwọn ẹ̀yà Yorùbá tí ó kù .

A gbọ́ wí pé àwọn ará Ẹ̀gbá fi òpin sí ìjọba kéréje kéréje láàárín wọn , wọ́n sì wá dá  ìjọba kan ṣoṣo sílẹ̀ lábẹ́ olórí wọn , Sẹ́ríkí Ṣódẹkẹ́ . Eléyìí dùn mọ́ àwọn Òyìnbó amúnisìn, wọ́n sì fi àwọn ará Ẹ̀gbá sílẹ̀ láti máa ṣe ìjọba wọn lọ nígbà tí wọn kó àwọn ará ìlú Nàìjíríà tí ó kù sí abẹ́ ìsìnrú àwọn Òyìnbó láti ìlú Ọba . Ní ọdún 1893, àwọn Òyìnbó yìí ṣe ìpinnu pẹ̀lú àwọn ará Ẹ̀gbá láti fi wọ́n sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀ èdè Olómìnira . Nínú ìjọba ìlú Ẹ̀gbá yìí , Aláké jẹ́ gẹ́gẹ́ bí i Ààrẹ àti olórí ìgbìmò ti àwọn ọba , Ọ̀ṣilẹ̀ ti Òkè -Ọnà, Àgùrá ti Gbágùrá , Olówu ti Ìlú Òwu . Àwọn Olórí ẹ̀sìn Àbáláyé , Ìgbàgbọ́ àti Mùsùlùmí sì jẹ́ mínísítà nínú ìjọba náà . Ilé Ògbóni tí ó wà ní Ìtokò ṣíṣẹ Ìgbìmọ̀ aṣòfin àti ẹ̀ka ìdájọ́ nílùú Ẹ̀gbá . Àwọn ẹ̀sùn kéékèèké sì ń gba ìdájọ́ ní Ìdí ère nínú ààfin Aláké . Ṣùgbọ́n gbogbo ìdájọ́ ní láti gba àṣẹ àti òǹtẹ̀ Aláké kí ó tó di àṣẹ , èyí ló mú ọ̀rọ̀ tí ó di gbajúmọ̀ ní ìlú Abẹ́òkuta pé , “Ẹjọ́ kù s’ Áké ”.

Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní Abẹ́òkuta nígbà náà jẹ ogóje-ó-lè-mẹ́ta (143), wọ́n sì ń ṣe ìjọba wọn fúnra wọn nípasẹ̀ àṣẹ àdáwà ránpẹ́ láti ọ̀dọ̀ Aláké , tí ó jẹ́ olórí wọn . Àwọn Ọba ìlú Ẹ̀gbá /Abẹ́òkúta tí ó kù sin ìjọba lórí agbègbè wọn, lábẹ́ ìdarí Aláké . Èyí mú kí àlàáfíà àti ìdàgbàsókè bá ìjọba nílùú Ẹ̀gbá . Ẹ̀gbá àti Ìlú Ọba sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oríṣiríṣi ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú wọn ní ètò ọrọ̀ ajé àti ìdájọ́ . Ọba Gbádébọ̀ I lọ sí ìlú Ọba ní ọdún 1942 láti lọ kí Ọba obìnrin Victoria.

Ṣùgbọ́n ní àìpé ọjọ́ , aṣoojú ìlú ọba ní Èkó gbìmọ̀ láti fi Ìlú Ẹ̀gbá sí abẹ́ ìjọba amúnisìn Ìlú Ọba . Èyí sì ṣe é ṣe nígbà tí rògbòdìyàn wáyé ní ìlú Ẹ̀gbá /Abẹ́òkúta látàrí ogun Ìjèmọ . Aṣoojú yìí lo àǹfààní  èyí láti kọlu Abẹ́òkúta . Ní ọdún 1918 sì ni òpin dé bá òmìnira ìlú Ẹ̀gbá tí ó si jẹ́ ara ìlú Nàìjíríà ní abẹ ìsìnrú  Ìlú Ọba . Àwọn Ọba ìlú Ẹ̀gbá lónìí ni: Ọba Adédọ̀tun Àrẹ̀mú Gbádébọ̀ III- Aláké ti ìlú Ẹ̀gbá , Ọba Adédàpọ̀ Tẹ́júoṣó  (Kárúnwí III) – Ọ̀silẹ̀ Òkè-Ọnà Ẹ̀gbá , Ọba Saburee Babájídé Bakre (Jáwọ̀lú II)- Àgùrá ti Gbágùrá , Ọba Saka Mátẹ̀milọ́lá (Olúyalo-Otileta VII).

Àwọn ọmọ Ẹ̀gbá jẹ́ akíkanjú , wọn kò ya ọ̀lẹ , wọ́n gbé ìlú wọn ga níbikíbi tí wọ́n bá ti bá ara wọn lórílẹ̀ èdè ayé .

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *