Orin: Ẹnikẹ́ni tí ìwọ
bá nípa láti se ìrànlọ́wọ́ fún
Òun náà lẹni kejì rẹ, tọ́jú rẹ.
Ẹnikẹ́ni tó bá nípa láti ṣe ìrànwọ́ fún
Dákun má ṣe fi jára
Ohunkóhun to bá ní láti fi dùnyàn nínú
Jọ̀wọ́ máa ṣe sahun rẹ̀
Ọ̀dájú, ìkà àbòsí kò pé
Gbígbé ayé ṣe rere ló yẹ
Nítorí bí a bá sọ̀kò lọ́jà nígbà mìíràn
Ará ilé ẹni ni ń bá
Bí ó ṣe bá Dókítà ilé ìwòsàn ọ̀hún náà lọ́jọ́ náà
Sèbí bó ti wu Olúwa ló ń sehun
Kabíyèsí ohun tó wù ú ló ń fi ń dárà
Ìjàmbá ọkọ̀ ló kọlu ìyá àgbà kan lópòpónà
Ojú ló kú rójú ṣàánu---àwọn ẹni rere ti tara dìde
Kátó sẹ́jú wàì ìyá ti dé họsibíítù
Nọ́ọ̀sì lọ pe Dókítà wá ni wọ́n fi bọnu
Mò ń sinmi lọ́wọ́ lọ̀gá Dókítà fi fèsì
Wọ́n ní ìrora yìí pọ̀ kó ṣàánú ìkúnlẹ̀
Ó fi gbígbọ́ sàìgbọ́ ni fàájì rẹ̀ ń lọ
Nígbà tó bùse gàdá tó bùse gèdé
Wọ́n mú ìròyìn lọ ba pe ìyá ti kú
Lóní òkú náà dà káwo bá ò ti sín
Ó káwọ́ mórí ló ń sunkún àsunyara
Mo ti fọwọ́ ara mi sera mi ló gbẹnu rẹ̀ gbogbo
Ìyá tó bí mi lọ́mọ ló jẹkú ìrora lọ
Ariwo kíkan wá gbẹnu rẹ̀ kankan
Moní sèbí ká máa ṣe rere ló yẹ
Ire ló pé, ìkà kọ́
Dáadáa ṣíṣe la fi ń gbáyé ìrọ̀rùn
Ìfẹ́ràn làkejì layé fí ń tòrò nini bí i omi afòwúrọ̀ pọn
Nípa Òǹkọ̀wé
Malik Adéníyì kọ ewì yìí ránṣé láti ìlú Ìbàdàn.