Jòjòló akéwì tún dé 
Mo fẹ́ kọrin ewì sétí aráyé
Ẹ yá mi létí yín.
Ọ̀rọ̀ fẹ́ máa jábọ́ bí odi ẹyìn.
Kí ẹ sáré tete wá gbọ́ nàsíà.

Ẹni kò bá mọbi ẹgbẹ́ ẹ̀ ti là
Eré à-sá-bólórúnkún ni wọn ó máa sá.
Ó gbọ́ pé wọ́n ń là nílùú òyìnbó
Ǹ jẹ́ ò béèrè ìtọ́sọ́nà lọ́wọ́ Olú?
Ṣe gbogbo ènìyàn làyànmọ́ rẹ̀ gbébẹ̀ ni?

Ìwọ náà gbẹ́wù kọ́rùn ó dìlú ọba
Òótọ́ ni páwọn kán tí kórè oko wálé
Látìlú òyìnbó kì í kúkú ṣe irọ́.
Iṣẹ́ tí wọn ń ṣe kó ṣe é wí fáráalé
Awo mọ̀ sínú ni gbogbo wọn fi ń ṣe.

Èyí tó bá ń náwó yàfùyàfù
Lè ti rí kọ̀ráà lù ní jìbìtì.
Ọ̀pọ̀ tó ń ṣiṣẹ́ àṣelàágùn kúkú ń bẹ.
Tó jẹ́ pé iṣẹ́ gidi ni wọn fi là
Tó jẹ́ pé iṣẹ́ to ní láárí ni wọ́n fi lu.

Iṣẹ́ naní lòmíràn fi ń máta sẹ́nu.
Ká ṣiṣẹ́ dẹ́rẹ́bà ká fọ mọ́tò
Ni wọn fi ń dolówó.
Mo ṣe bólè ló bọmọ jẹ́.
Orúkọ tó bá wuni làá jẹ́ lẹ́yìn odi.

Bí ẹ bá rẹ́ni tí kò wálé bọ̀rọ̀
láti ìlú òyìnbó, ó lè jẹ wípé
Awọ ni kòì kájú ìlù fún un.
Eré é kí n kan ṣẹ́nuure ni wọn ń sá.
Bí ago ni wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́.

Inú òtútù lọ́pọ̀ tí ń jáṣẹ́ mọ́ra.
Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí nígbàkúùgbà
Ọ̀nà kí wọn ó lè róhun tọ́ka sí
Tí wọ́n bá wá sílé ni wọn ń tọ̀.
Torí ilé báyìí làbọ̀ ìsinmi oko.

Ẹbí kò kúkú mohun àwé ń fojú wíná
Mú un wá lapá ẹyẹlé wọn ń ké
Bárá ìlú òyìnbó bá tún jàjà fowó ránṣẹ́
Wọn a ní ṣówó lèyí àbí kí n la?
Wọn a fẹnu tẹ́ńbẹ́lú owó ẹni ẹlẹ́ni.

Oògùn olóró ni ẹlòmíràn gbé
Tó dẹni ń jẹ̀wà ní túbú
Nítorí pé wọ́n fẹ́ dolówó ọ̀sán gangan
Wọ́n dẹni ò náání orúkọ baba
Wọ́n dẹni ò bìkítà orúkọ yeye.

Bọ́wọ́ pálábá wọn ò bá ségi
Irú wọn ní ń náwó bí ẹlẹ́dá
Bí wọ́n bá fojú kanlé.
Wọn a máa jayé bí ọba.
Gbogbo àdúgbò ni kò ní rímú mí.

Àwọn lọ̀pọ̀ ń wò gẹ́gẹ́ bí i dígí
Ni wọ́n fi ń sáré àsápajú dé
Nítorí kóyìnbó lè lu físà rẹ̀ lóǹtẹ̀.
Níjọ́ tó bá dé ẹ́ńbásì lọ ṣèdánwò
Ẹlòmíràn á di aládúrà òun ẹ̀gbẹ̀jí.

Lóòótọ́ ìlú tó rẹwà nìlú ọba
Létòletò lohun gbogbo ń lókè òkun
Ẹni àyànmọ́ rẹ̀ bá rọ̀ mọ́bẹ̀ ni.
Ọmọ adáríhunrun ti yànpín látọ̀run
Kí ló wá dé tójú ń kán wa láyé?

Ará ìlú òyìnbó ṣe pẹ̀lẹ́ ilé ń yọ̀.
Bíṣu ẹni bá ta ṣe làá dọwọ́ bò ó.
Ẹ rántí pé ọ̀pọ̀ aláàmù ló dakùn délẹ̀
A ó mọ̀ èyí tínú ń run nínú wọn
Ará ìlú òyìnbó ẹyẹ ìbẹ̀rù ní tọ̀jọ́.

Ẹ má borúkọ ìlú yín jẹ́
Ẹ sọ ilẹ̀ adúláwọ̀ lórúkọ tó rẹwà
Tí ẹ kò bá hùwà tó ṣe é tọ́ka sí
Ẹ ti bọ̀nà jẹ́ férò ẹ̀yìn nìyẹn.
Ara ìlú òyìnbó ẹ ṣe mẹ̀dọ̀.

Nípa Òǹkọ̀wé

Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn. Ó jáde nílé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Baptist Primary School, Bódè Ìjàyè,Abẹ́òkúta.Lẹ́yìn náà ni ó tún tẹ̀síwájú ní ilé ẹ̀kọ́ Líṣàbí Grammar School,Ìdí Aba. Ó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Èdè Yorùbá àti Haúsá ní ilé ẹ̀kọ́ Olùkọ́ni Àgbà Federal College of Education,Òṣíẹ̀lẹ̀,Abẹ́òkúta. Ó tún kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín,Ìjagun,Ìjẹ̀bú Òde .Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ilé ẹ̀kọ́ girama ni. Ó fẹ́ràn láti máa kọ ewì àti ìtan àròkọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Ìfẹ́ rẹ̀ sí àṣà àti ìṣe Yorùbá kí ó má lè dìmẹ́ẹ́rí kò láfiwé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *