Dèbórà, Obìnrin Ogun
Ìmísí: Ìwé nípa ìgbésí ayé Àyìnlá Ọmọ Wúrà
Ìwé tó kọ nípa a rẹ̀ kìí ṣé mímọ́
Bíkòṣe ti mímọ̀—
Ìmọ̀ ogun.
Ìmọ̀ ogun:
Bí a tí ń gbá géńdé ọkùnrin mú bíi jíà mọ́tò…
Kí a sì fi wa ara ẹni lọ sí’lẹ̀ ìlérí.
Bí a tí ń gbá ọlọ́lá okùnrin mú bíi ìbọn ṣakabùlà
Kí a sì yin ògo rẹ̀ jáde bíi ọta—kó paná gẹ́gẹ́ bó bá ṣe tan’ná.
Bí a tí ń ju àdó olóró sí àárín ọ̀rẹ́
Kò sí dàbí ẹni pé wọ́n tari ara wọn sí ogun àrèmabọ̀.
Ìp’òǹgbẹ Ilẹ̀
ọkàn mi ń já túẹ́ bíi òwú
gbogbo omi ara mi re jọ sí ojú ù mi: agbami omijé
Wọ́n ń hó bíi omi táa gbàgbé sórí iná
afẹ́fẹ́ ìrántí sì ń fẹ́ wọn dànù
Ìka ọwọ́ mi kún fún àpá eyín
tó bẹ ́ẹ̀ tí àbámọ̀ fi kọ̀ wọ́n sílẹ̀ fún ètè mi
Gbogbo omi ara à mi wá gbẹ,
Ó sì ń p'òǹgbẹ omi ilẹ̀
ṣùgbọ́n ìka ọwọ́ ọ̀ mi kún fún egbò àbámọ̀
a ò dẹ̀ kìí bá ẹni tó fẹ́ di ara à kan
pẹ̀lú ilẹ̀ wú ilẹ̀
Nípa Òǹkọ̀wé
Ìbùkúnolúwa Dàda jẹ́ akéwì àti akẹ́kọ̀ọ́-oníròyìn. Ó ń ka nípa ìkéde iṣẹ́ àgbẹ̀ àti ìdàgbàsókè ìgbèríko ni Yunifasiti ìlú Ìbàdàn; ó ì wà ní ipele tó ga jùlọ. Iṣẹ́ rẹ dá lórí àṣà, ìfẹ́, ẹ̀sìn, ìgbésí ayé ati àlàáfíà ọkàn. Nígbà tí kò bá ń kàwé, ẹ ma ba ní’dì i orin tàbí àwọn àwòrán tí a lè fi ẹrọ bíi Canva tàbi Photoshop yà.
Àṣẹ lórí àwòrán iṣẹ́ yìí jẹ́ ti Ọmọ́wùnmí Dàda.