Èyí jẹ́ ọ̀rọ̀ tí àwọn olùdásílẹ́ Àtẹ́lẹwọ́, Rasaq Malik àti Ibrahim Ọ̀rẹ́dọlá kà ní ibi ìpèjọ àwọn oníròyìn láti ṣe ayẹyẹ ọdún karùn-ún tí wọ́n dá ẹgbẹ́ ÀTẸ́LẸ́WỌ́ sílẹ̀.

Navigate to English

Ọ̀RỌ̀ IṢÁÁJÚ

Ní ọjọ́ kíní Oṣù òkudù, ni 2017, a bẹrẹ̀ ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́ gẹ́gẹ́ bí èsì sí ògúnlọ́gọ́ ìpèníjà tí ó ń kojú dídáàbò àti àjàyè àṣà àti èdè Yorùbá. Àrídájú tó múlẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti àwọn ọmọ adúláwọ̀ ni kò lè kà tàbí kọ ní èdè abínibí wọn, kò tún sí ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú ètò ẹ̀kọ́ tí kò kàn-án nípá fún àwọn akẹ́ẹ̀kọ́ láti kọ́ èdè abínibí wọn dé ilé ẹ̀kọ́ girama àti ìfàsẹ́yìn ìwé lítírésọ̀ tí ó pegedé. Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ tí ó fẹ́ ìyípadà, a bẹ̀rẹ̀ Àtẹ́lẹwọ́ látí ṣe àtúnṣe sí àwọn ìṣòro yìí nípa ṣíṣe e ní àpèrè tí a fi sọrí títanijí àti àtúntò àṣà Yorùbá pẹ̀lú èròngbà láti pèsè àpèrè fún fífa ojú àwọn ènìyàn mọ́ra àti ṣíṣe ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí ó s’ẹni ní àǹfààní pẹ̀lú ọ̀kanòjọ̀kan àṣà Yorùbá nípa ìdíje, ìdánilẹ́kọ̀, ìfọ̀rọ̀wérọ̀, àti ìpàdé gbogbo ìgbà; láti pèsè àpèrè fún fífipamọ́ àti dídààbò bo ìmọ̀ àbáláyé Yorùbá, àṣà, àti èdè nípa ìbámu pẹlú ìlọsiwájú ìmọ̀

 ẹ̀rọ; àti láti jí ìfẹ́ àwọn ènìyàn nínú lítíréṣọ̀ Yorùbá nípa ṣíṣe ètò ìwé kíkà, ṣíṣe ọ̀nà láti rí lítírésọ̀ Yorùbá àti títẹ̀jáde àwọn ojú tuntun ní èdè Yorùbá.

Láti bí ọdún karùn-ún, a ti dúró ti àwọn àfojúsùn yìí àti pé a ti gbìyànjú láti ri pé a kò kúrò lójú ọ̀nà wọn. Fún ọdún márun, a ti ń gbé àṣà kíkà ìwé Yorùbá lárugẹ nípa àwọn ọ̀kanòjọ̀kan ètò tí ó dálé gbígbé iṣẹ́ Yorùbá jáde ní orí ẹ̀rọ ayélujára, ìṣẹ́ ìwadìí, ìdíje àti gbígbé ìwé Yorùbá lárugẹ. Fún ọdún márun, a ti ṣe ètò kíkọ́ àwọn ènìyàn ní èdè Yorùbá ní ọ̀fẹ́ àti èyí tí àwọn ènìyàn sanwó fún ní orí ẹ̀rọ ayélujára àti kọjúsími kí n kọjúsiọ. Fún ọdún márun, a ti sisẹ́ pẹ̀lú àjọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní òkè òkun láti túnmọ̀ àti kọ ìfiránṣẹ́ tí ó ṣe ìgbélarugẹ àǹfààní ní ẹ̀ka ààbò, ẹ̀kọ́ àti ohun ọ̀gbìn. Fún ọdún márun, a ti ṣiṣẹ́ láti ṣe ìfihàn àti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ògbóntàgi àgbàlagbà òǹkọ̀wé àti onímọ̀ ẹ̀kọ́. Fún ọdún márun, a ti ṣètò ìrànlọ́wọ́ tó péye, àfojúsùn àti ìpolongo fún onírúurú iṣẹ́ àti ètò Yorùbá ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní òkè òkun. Fún ọdún márun, a pèsè àpèrè fún àṣà àti àwọn olólùfẹ́ èdè láti le dásí ìfọ̀rọ̀jomitoròọ̀rọ̀ tó pegedé nípa ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó àti ṣe ìpalára fún àwọn ọmọ Yorùbá.

DIẸ́ LÁRA ÀWỌN IṢẸ́ ÀKÀNṢE ÀTI ÈTÒ TÍ A TI ṢE NÍ ỌDÚN MÁRUN SẸ́YÌN

 • Ní ọdún 2018, a gbé jáde ìwé àkójọpọ̀ lítírésọ̀ Yorùbá tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́ “Àtẹ́lẹwọ́ Pélébé” tí ọ̀rọ̀ ìsájú àti àfihàn rẹ̀ jẹ́ kíkọ láti ọwọ́ ọ̀jọ̀gbọ́n Moyọ̀ Òkédìjí àti Ọ̀gbẹ́ni Kọla Tubosun. Ìwé náà ní kọjá ogójì òǹkọ̀we ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti ní ìlú bí i Sáúdí Arabia, United States àti United Kingdom.
 • Ní ọdún 2018, a ṣe ètò àkọ́kọ́ ìpenijọ ní ọgbà fáfitì Ìbàdàn níbi tí àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè Nàìjíríà àti òkè òkun péjú sí.
 •  Ní ọdún 2018, Àtẹ́lẹwọ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹka kíka lítírésọ̀ Yorùbá ti orí afẹ́fẹ́ tí ó wà ni www.atelewo.org.
 • Ní ọdún 2019, a ṣe ìfilọ́lẹ̀ ètò ìwé rírà láti lè fún àwọn èèyàn tí ó wà ní òkè òkun ní ànfààní láti rí ìwé lítírésò Yorùbá kà.
 • Ní ọdún 2019, a ṣiṣẹ́ pẹ̀lú The Artivists NG, ẹka aláwàdà, ní orí iṣẹ́ kan tó jẹmọ́ álífábẹ̀ẹ̀tì Yorùbá.
 • Ní ọdún 2019, a bẹ̀rẹ̀ Jomitoro, èyí tó jẹ́ ìfọ̀rọ̀jomitoro olóṣooṣù níbi tí àwọn ọ̀dọ́ tí má ń pàdé láti yànnàná ọ̀rọ̀ tóńlọ láti ojú ìwòye àṣà Yorùbá tó pegedé. A lo ànfààní àpèrè yìí láti dá àwọn ènìyàn lẹ́kọ nípa ìtàn àti àṣà àwọn Yorùbá àti láti kọ àwọn ọ̀dọ́ nípa orísun wọn.
 • Ní ọdún 2020, pẹ̀lú ìṣẹ̀lẹ̀ àjàkálẹ̀ àrùn Covid-19, a bẹ̀rẹ̀ ìwé kíkà ojoojúmọ́ ní orí Zoom láti tẹ̀síwájú nípa kíkó àwọn ènìyàn jọ. Eléyìí padà di ìwé kíkà òpin ọ̀sẹ̀.
 • Ní ọdún 2020, a ṣe ìfilọ́lẹ̀ Ògbóntarìgì, iṣẹ́ àkànṣe ọdọọdún láti ṣe àyẹ́sí àwọn àgbàlagbà àti àwọn tó wà láyé nínú àwọn òǹkọ̀tàn Yorùbá pẹ̀lú ẹ̀bùn àti ìfihàn ní orí afẹ́fẹ́. Ẹni àkọ́kọ́ tó jẹ àǹfààní eléyìí ni Bàbá Láwuyì Ògúnníran, gbájugbajà ọ̀ǹkọ̀tàn Éégún Aláré.
 • Ní osù ọ̀wàrà ní ọdún 2021, a ṣe ìfilọ́lẹ̀ ibùgbé ìkàwé orí afẹ́fẹ́ láti ṣe ìwé Yorùbá ní kíkà àti láti mú kóríya àwọn ìwé tuntun.
 • Ní ọdún 2021, a ṣe ìdíje-rà ìwé ákọ́kọ́ ní orí ẹ̀rọ Twitter láti pe àkíyèsí àwọn èèyàn sí àwọn ọ̀rọ̀ tó ń lọ ní agbede ìwé lítírésọ̀ Yorùbá àti títẹ ìwé Yorùbá jáde.
 • Ní ọdún 2021, a jọ ṣe àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn Yorùbá Wikimedians User Group ti àjọ Wikipedia Nigeria láti ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lóri Wikidata àti títẹ iṣẹ́ sórí Wikipedia fún àwọn ọ̀dọ́ tó lé ni àádọ́ta tí wọ́n sì alákọ̀wé òhun olólùfẹ́ àṣà ní ọgbà fásitì Ibàdàn.
 • Ní ọdún 2022, a ṣe ìfilọ́lẹ̀ #Òṣùmàrè, èyí tí í ṣe iṣẹ́ NFT láti polongo iṣẹ́ ọ̀nà Nft ní ààrin àwọn Yorùbá àti láti polongo àṣà Yorùbá nípa iṣẹ́ ọ̀nà NFT.

ÌDÍJE Ẹ̀BÙN ÀTẸ́LẸWỌ́ FÚN LÍTÍRÉSÒ YORÙBÁ 2023

Ní ìlànà àfojúsùn wa, Àtẹ́lẹwọ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ “ÌDÍJE ÀTẸ́LẸWỌ́ FÚN LÍTÍRÉSỌ̀ YORÙBÁ” ní 2020. Ìdíje yií wà fún àwọn òǹkọ̀wé tí wọn kò tí ì tẹ ìwé jáde rí ní èdè Yorùbá. ÌDÍJE ÀTẸ́LẸWỌ́ FÚN LÍTÍRÉSỌ̀ YORÙBÁ” jẹ́ fífilọ́lẹ̀ láti mójútó àwọn ìṣòro tí ó jẹmọ́ àwọn òǹtẹ̀wè, pínpín ìwé, ṣiṣe ìgbìyànjú nípa òǹkàwé, ati bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ.– tí kíkọ ìwé ní Yorùbá ń kojú. Ìdíje Àtẹ́lẹwọ́ fún litiréṣọ̀ Yorùbá ní èróńgbà láti ṣe ìtanijí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ǹǹkan ìwúrí tí ó jẹ́ ti Yorùbá.

Fún ìgbà àkọ́kọ́ ìdíje náà, ìgbàláyè wà fún àwọn òǹkọ̀wé láti ṣe ìfirańṣẹ́ ewì, ìtàn, àti eré oníṣe. Lẹ́yìn ìdíje tí ó lààmìlaaka náà, a rí àwọn tó gbégbá orókè márùn. Mustapha Sherif jẹ́ gbogbogbo olúborí fún ìwé ìtàn rẹ̀ tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Orin Ewì Akọdan”. Àwọn tó tún gbégbá orókè tún ni Ṣeun Adéjàre (T’ẹníkú Ló gbé), Amos Ọlátúnjí Pópóọlá (Akínkanjú Ọdẹ Nínú Igbó Àmọ̀tẹ́kùn), Sodiq Lawal (Aròjinlẹ̀ Àròfọ̀), Agboọlá Àyándìran (Ó Já Sọ́pẹ́). Ẹni tó gbégbá orókè gbogbogbo gba ẹ̀bùn owó àádọ́ta Naira nígbà tí àwọn tó gbégbá orókè yókùn gba ẹ̀bùn ìwé àti àmì ẹ̀yẹ.

Fún ìgbà ẹ̀kejì ìdíje náà, a ṣe àfikún ẹka kan tí à ń pè ní “aáyan ògbufọ̀” fún àwọn ìwé ìfiránsẹ́ tí ó ṣe aáyan ògbufọ̀ ìwé ní èdè míràn sí èdè Yorùbá. Lẹ́yìn àwọn ìlànà yìí, a ní àwọn márun tí ó gbégbá orókè. Waliyullah Tunde Abímbọ́lá jẹ́ olùborí gbogbogbo fún ìwé rẹ̀, Oko Ẹranko, aáyan ògbufọ̀ ìwé George Orwell tí orukọ rẹ̀ ń jẹ́ “Animal Farm” sí Yorùbá ìwé. Àwọn olùborí yóò kù ni Kafilah Ayọ̀bámi Fashola (Àbẹ̀ní), Bakare Wahab Táíwò (Àtẹ́wọlará Akéwì Akowe), Anífowóṣe Zainab Olúwafúnmilọ́lá (Ìgbẹ̀yìn Òwúrò) àti Abdulkareem Jeleel Ọlásúnkànmí (Ewí Kòbọmọjẹ́). Ẹni tó jáwé olúborí gbogbogbo gba ẹ̀bùn owó ẹgbẹ̀rún náírà nígbà tí àwọn tó gbégbá orókè yókùn gba àmì ẹ̀yẹ àti àádọ́ta lẹ́yọ kọ̀ọ̀kan.

Ní òní, inú wa dùn láti kéde ìfilọ́lẹ̀ ìdíje náà ní ìgbà ẹ̀kẹta. À á sì ń pe àwọn òǹkọ̀wé tí wọ́n kò tí ì tẹ̀wé jáde rí ní èdè Yorùbá láti fi ìwé wọn ránṣẹ́ sí wa. A ó ma gba àgbàwọlé láti oṣù kínní June di ọgbọ̀n ọjọ́ ní oṣù ọ̀wàrà. Ìlànà dídájọ́ ìdíje náà yóò bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kíní ní oṣù Bélú di ọgbọ̀n ọjọ́ ní oṣù Ṣẹ́ẹ́rẹ́ nígbà tí ayẹyẹ ẹ̀bùn gbígba yóò wáyé ní Ìbàdàn ni ọjọ́kọkànlélógún ní ọ̀dún 2023 ní ìrántí ọjọ́ àṣeyẹ èdè abínibí. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn alátìlẹ́yìn wa, inú wá dùn láti kéde pé ẹ̀bùn náà ti gbèèrù si àtipé olùgbégbá orókè gbogbogbò yóò lọ ilé pẹ̀lú ẹ̀bùn owó 250, 000 Naira àtipé ìwé rẹ̀ yóò jẹ́ títẹ̀ jáde, nígbàtí àwọn olùborí mẹ́ta yóòkù yóò lọ ilé pẹ̀lú ẹgbẹ̀run lọ́nà ọgọ́rùn-ún Naira ní ẹni kọ̀ọ̀kan. Ẹ kà á síwájú sí ní www.atelewo.org/idije-iwe.

ÌDÚPẸ́

Fún ọdún márun, a ní ànfààní ńlá láti rí àtìlẹyìn àwọn èèyàn pàtàkì tí wọ́n tún jẹ́ olólùfẹ́ àṣà àti èdè Yorùbá. Láìṣeyèméjì, a ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní ààyè yìí ṣùgbọ́n púpọ̀ nínú ohun tí a ṣe kò bá má ti jẹ́ ṣíṣe láì sí àtìlẹyìn wọn. Ní ákọ́kọ́, a fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Adélékè Adéẹ̀kọ́, ọ̀jọ̀gbọ́n pàtàkì jùlọ ní ẹ̀ka ọ̀rọ̀ àgbáyé àti alága fìdíẹẹ́ ni fáfitì Ohio. Ọ̀jọ̀gbọ́n Adéẹ̀kọ́ jẹ́ alátìlẹ́yìn wa àtipé wọ́n ti ṣe ǹǹkan lọ́pọ̀lọpọ̀ láti pèsè ìtọ́sọ́nà, mímọ ènìyàn àti gbígbárùkù ti àwọn ọ̀kanòjọ̀kan ìṣe tí a ti ṣe ní bí ọdún mẹ́ta sẹ́yìn. A tún fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọ̀gbẹ́ni Ọládélé Onílé-Eré fún gbígbárùkù ti ẹgbẹ́ náà, pàápàájùlọ níbi dídàgbàsókè àti ṣíṣe ìlọsíwájú fún ìdíje ọdọọdún ti litiréṣọ̀ Yorùbá. Àwọ́n tí a tún fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ wọ́n ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Moyọ̀ Òkédìjí, ọ̀jọ̀gbọ́n Àrìnpé Adéjùmọ̀, ọ̀jọ̀gbọ́n Saheed Adérìntọ́, Màmá Molara Wood, Ọ̀mọ̀wé Akin Adésọ̀kàn, Ọ̀mọ̀wé Tósìn Gbógí, Ọ̀mọ̀wé James Yeku, Ọ̀mọ̀wé Gabriel Bamgbose, Bàbá Odòlayé Àrẹ̀mú, Bàbá Musiliu Dàsọfúnjó, Jumoke Verissimo, Kọ́lá Túbọ̀sún, Dámilọ́lá Adébọ́nọ́jọ́, Fatoba Onala, ‘Gbenga Adeoba, Ayo Adams, Deji Komolafe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí ààyè kò sí láti dárúkọ.

Bákannáà, a fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ẹgbẹ́ bí Goethe-Institut, The Artivists, Oyo Insights, Yoruba Name, Distrifoods, Building Nations Initiative, HueNation Agency, Petspoint Recycling àti àwọn ìyókùn.

A dúpẹ́ pé ẹ fi ọkàn tán wa, a sì dúpẹ́ tí ẹ kò da dá’wa nìkan.

ÀFOJÚSÙN ỌJỌ́ IWÁJÚ

Fún ọdún márun tó ń bọ̀, ní àfikún ti ríri pe àwọn iṣẹ́ ti à ń ṣe ń gbèrù si, à ń wo kíkọ́ ibùgbé àṣà ńlá kan fún ìlọsíwájú àṣà adúláwọ̀ nígbà ti a ó tún ma lo ọgbọ́n àtinúdá àti ìmọ sáyẹ́nsì. Ibùgbé àṣà náà yóò jẹ́ ibìkan fún àwọn ọ̀dọ́ láti fọwọ́sowópọ̀ ní ojúkorojú àti ní orí afẹ́fẹ́ láti gbékalẹ̀ ǹǹkan ọ̀tun, ìròrí, iṣẹ́ àti ètò tí yóò mú ìlọsíwájú bá àṣà àti ìṣe adúláwọ̀. Ní ÀTẸ́LẸWỌ́, a gbàgbọ́ pé ọjọ́ iwájú àgbáyé jẹ́ ìmọ̀ tẹ́ẹ́kìì àti ọ̀dọ̀, àti pé tí a bá fẹ́ dáàbò àti ṣíṣe ìgbé l’árugẹ àwọn àṣà àti èdè adúláwọ̀, a ní láti ṣe àgbékalẹ̀ àwùjọ tí ó dára fún àwọn ọ̀dọ̀ láti lè ṣe ǹǹkan tí yóò wúlò tí èyí yóò sì fún wọ́n ní àǹfààní láti mójútó ǹǹkan tí yóò jẹ́ kí wọ́n ní ojúṣe tí ó wà lára gbígbé àṣà l’árugẹ.

ÌRÀNLỌ́WỌ́

Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́, a tí máa ń ṣe àwọn ètò wa pẹ̀lú àtìlẹ́yìn àwùjọ àti pé a dé ibi tí a dé pẹ̀lú àtìlẹ́yìn tí à ń rí gbà. À ń fi àsìkò yìí pe àwọn èèyàn láwùjọ fún ìrànlọ́wọ́ àti ṣíṣe agbátẹrú kí á ba lè tẹ̀síwájú nínú àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe fún ìgbélárugẹ èdè àti àṣà. Ẹ lè kàn sí wa ní egbeatelewo@gmail.com tàbí 07061282516.

Irọ́ ni wọ́n ń pa, Yorùbá ò le è parun
Èké ni wọ́n ń șe, Yorùbá ò le è parun
Àtẹ́lẹwọ́ la bá'là, șè b'ádẹ́dàá ló kọ ọ́
Irọ́ ni wọ́n ń pa, Yorùbá ò le è parun

Being an address delivered by the cofounders of Atelewo, Rasaq Malik and Ibrahim Ọ̀rẹ́dọlá at the Press Conference organised to mark the 5th year anniversary of ATELEWO.

Lọ sí Yorùbá

INTRODUCTION

On the 1st of June, 2017, we started ÀTẸ́LẸWỌ́ Cultural Initiative as a response to the myriads of challenges and threats facing the preservation and survival of the Yorùbá culture and language. It is a well-known fact that a majority of Nigerians and Africans at large are unable to read or write in their indigenous African languages, this is not helped by education policies that do not mandate students to learn an African language up to secondary school level and the waning presence of quality literature materials in these languages. As a course changing initiative, we started ÀTẸLẸWỌ́ ́to solve some of these problems by making it a platform dedicated to the reviving and repositioning of the Yorùbá culture with the mission to provide a platform for stoking interest and generating fulfilling engagements with the dynamics of the Yorùba ́culture through competitions, lectures, dialogues, and regular meetups; to provide a platform for the documentation and preservation of Yorùba ́ancient knowledge, culture, and language in keeping pace with technological advancement; and to rekindle people’s interest in Yorùbá literature by organising readings, making Yorùba ́literature accessible and publishing new voices in the Yorùba ́Language.

For the past five years, we have been committed to these ideals and mission and we have strived to ensure we don’t depart from them. For five years, we have been at the forefront of promoting Yorùbá literary culture through a series of projects involving online publishing, research, competitions and Yorùbá books promotion. For five years, we have organised both free and paid Yorùbá literacy training events online and offline. For five years, we have worked with national and international organisations to translate and create messages promoting values in the health, education and agriculture sectors. For five years, we have committed to works documenting the lives of the old veteran Yorùbá authors and academics. For five years, we have consulted and provided valuable support, insights and advocacies for various Yorùbá projects and initiatives nationally and internationally. For five years, we have provided a platform for culture and language enthusiasts to engage in rich dialogues about issues relating to and affecting the Yorùbá people.

SOME OF OUR PROJECTS AND ACTIVITIES IN THE LAST FIVE YEARS

 • In 2018, we published a Yorùbá Literary anthology titled “ÀTẸ́LẸWỌ́ PÉLÉBÉ” forwarded and introduced by Prof. Moyo Okediji and Mr. Kola Tubosun respectively. The anthology had over 40 contributors within and outside Nigeria from places like Saudi Arabia, the United States and the United Kingdom.
 • In 2018, we organised our first Yoruba Literary and Cultural Conference at the University of Ibadan where we recorded the attendance from within and outside Nigeria.
 • In 2018, ÀTẸ́LẸWỌ́ launched the very first online Yoruba literary magazine located at www.atelewo.org.
 • In 2019, we launched Atelewo Bookshop to make access to Yorùbá literature easier for the diaspora Nigerians.
 • In 2019, we worked with The Artivists NG, a comic brand, on a comic project around the Yorùbá Alphabets.
 •  In 2019, we started the Jomitoro monthly conversation series where young people come together to analyse trending issues from the lens of rich Yorùbá traditions and practices. We take advantage of this platform to educate people about the history and practices of the Yorùbá people as a way of engaging the younger generation about their cultural heritage.
 • In 2020, with the coming of the pandemic, we started a Daily Yorùbá Book Reading on Zoom online to continue to reach people virtually. It later metamorphosed into a weekend Yoruba book reading programme.
 • In 2020, we launched Atelewo Prize for Yoruba Literature as an annual competition open to previously unpublished writers of the Yoruba language. The Prize is instituted to address some of the problems–committed publishers, distribution, cultivating invested readerships, etc.–that creative writing in Yorùbáfaces.
 • In 2020, we launched Ògbóntarìgì, an annual project to honour old and living Yorùbá Authors with Awards and Mini-Documentaries. The first beneficiary of this project was Láwuyì Ògúnníran, famous author of Eégún Aláré.
 • In October 2021, we launched our Yorùbá Digital Bookshop in line with our mission of making Yorùbá books accesible and inspire newer works.
 • In 2021, we organised the first Yorùbá book auction on Twitter as a way to call people’s attention to the issues around Yorùbá books publishing.
 • In 2021, we partnered The Yorùbá Wikimedians User Group of Wikipedia Nigeria to organise a 2-day intensive training on Wikidata and Yorùbá Wikipedia editing for over 50 young Yorùbá language experts, enthusiasts and scholars at the University of Ibadan.
 • In 2022, we launched #Osumare, an NFT project designed to promote NFT awareness amongst Yorùbá people and also to promote Yorùbá culture through NFT arts.

ÀTẸ́LẸWỌ́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE 2023

In line with our goals and objectives, ÀTẸLẸWỌ́́ launched the annual “ÀTẸLẸWỌ́́ PRIZE FOR YORÙBÁ LITERATURE” in 2020. The competition is open to previously unpublished writers working in Yorùba ́language. The ÀTEĹẸẈ́Ó PRIZẸ FOR YORÙBÁ LITERATURE is instituted to address some of the problems–committed publishers, distribution, cultivating invested readerships, etc.–that creative writing in Yorùbá faces. The ÀTEĹẸẈ́Ó PRIZẸ FOR YORÙBÁ LITERATURE intends to rejuvenate the more than the century-old, vibrant, universally praised, and unquestionably rich Yorùbá literary culture.

For the first edition, entries were opened for writers to submit to poetry, prose and drama categories. After the keenly contested competition, we had a total of five winners. Mustapha Sherif emerged as the overall winner for his manuscript “Orin Ewì Akọdan”. Other winners are Ṣeun Adéjàre (T’ẹníkú Ló gbé), Amos Ọlátúnjí Pópóọlá (Akínkanjú Ọdẹ Nínú Igbó Àmọ̀tẹ́kùn), Sodiq Lawal (Koówè Ń kéé), Agboọlá Àyándìran (Ó Já Sọ́pẹ́). The overall winner received a cash prize of 50,000 Naira while the rest of the winners received plaques and book prizes.

For the second edition, we added a new category called “Translation” for entries that translated works in other languages to the Yorùbá language. And at the end of the process, we equally had five winners. Waliyullah Tunde Abiimbola emerged as the overall winner for his manuscript, Oko Ẹranko, a Yorùbá translation of George Orwell’s “Animal Farm”. Other winners are Kafilah Ayọ̀bámi Fashola (Àbẹ̀ní), Bákárè Wahab Táíwò (Atewolara Akewi-Akowe), Anífowóṣe Zainab Olúwafúnmilọ́lá (Igbeyin Owuro) and Abdulkareem Jeleel Ọlasunkanmi (Ewì Kòbọmọjẹ́). The overall winner received a cash prize of 100,000 Naira while the rest of the winners received a plaque and 50,000 Naira each.

Today, we are happy to announce the launch of the 3rd edition. And we’re calling on previously unpublished writers working in the Yorùbá language to put in their works. We’ll be accepting submissions from the 1st of June to the 30th of October. The judging process will commence on the 1st of November to the 30th of January while the award ceremony will happen in Ibadan on the 21st of February, 2023 in commemoration of International Mother Language Day. With the support of our stakeholders, we are also happy to announce that the prize has increased and the overall winner will be going home with 250,000 Naira and his book will be published in hard copies, while three other winners will go home with 100,000 Naira each. More information can be found at www.atelewo.org/idije-iwe.

APPRECIATION

For the past five years, we have been very fortunate to have the support of wonderful people who are equally lovers of the Yorùbá language and culture. No doubt, we have done quite a lot in this space but much of what we have done would not have been possible without their support. First of all, we will like to appreciate Professor Adeleke Adeeko, Humanities Distinguished Professor & Department Interim Chair at the Ohio State University. Professor Adéẹ̀kọ́ is our patron and he has done a lot to provide us with guidance, network and support for our various activities in the last three years. We will also like to appreciate Mr Ọládélé Onílé-Ere for his support for the organisation, most especially in the development and sustenance of our annual prize for Yorùbá literature. Others we will like to appreciate are Professor Àrìnpé Adéjùmọ̀, Dr Tosin Gbogi, Dr James Yeku, Dr Gbenga Bamgbose, Jumoke Verissimo, Molara Wood, Kola Tubosun, Akin Adesokan, Damilọ́lá Adébọ́nọ̀jọ, Professor Moyọ̀ Òkédìjí, Fatoba Onala, Gbenga Adeoba, Ayo Adams, Deji Akomolafe, Professor Saheed Aderinto, Odolaye Aremu, Musiliu Dasofunjo and many others too numerous to mention.

Similarly, we will like to appreciate organisations like Goethe-Institut, The Artivists, Oyo Inisghts, Yoruba Name, Distrifoods, Building Nations Initiative, HueNation Agency, Petspoint Recycling and others.

Thank you for the trust and thank you for not leaving us to do it alone.

LOOKING TO THE FUTURE

For the next five years, in addition to making our existing works sustainable, we are also looking at building a state of the art Cultural Innovation hub dedicated to advancing the course of African cultures while leveraging innovation and technology. The Cultural Innovation Hub will be a place for young people to collaborate physically and virtually to develop the next startup, idea, project and initiative that promotes African cultures and languages. At ATELEWO, we believe that the future of the world is both Tech and Youth, and if we want to preserve and promote African culture and languages, we need to create the right environments for young people to develop assets so they can take up the agency for the responsibilities around building for culture.      

SUPPORT 

As an organisation, we have always thrived on public support and we are only able to get here because of the support we’ve been receiving. We are hereby calling on the public for support and partnership so we can continue to do the works we are doing for the promotion of language and culture. We can be reached at egbeatelewo@gmail.com or 07061282516.

Irọ́ ni wọ́n ń pa, Yorùbá ò le è parun
Èké ni wọ́n ń șe, Yorùbá ò le è parun
Àtẹ́lẹwọ́ la bá'là, șè b'ádẹ́dàá ló kọ ọ́
Irọ́ ni wọ́n ń pa, Yorùbá ò le è parun

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *