Mi ò rántí ìgbà tí mo kọ́kọ́ gbọ́ gbólóhùn “Ọlọ́jọ́” nínú ọ̀rọ̀, àmọ́ mo rántí wípé nígbà èwe mi, tí àwọn èèyàn bá sọ wípé, “Ọlọ́jọ́ ti dé”, mo máa ń rò ó lọ́kàn mi, ìtumọ̀ gbólóhùn náà. Mo tilẹ̀ kọ́kọ́ rò wípé Ọlọ́jọ́ dà bíi Alájọ tí máa ń káàkiri lọ gba àjọ lọ́wọ́ àwọn èèyàn ní. Tàbí kẹ̀, bóyá Ọlọ́jọ́ jẹ́ ayánilówó, sugbon dípò owó, ọjọ́ ni máa ń yá èèyàn. Bóyá nígbà tí àkókò tí Ọlọ́jọ́ bá dá fún àwọn onígbèsè rẹ̀ bá pé ló máa ń yọjú láti mú wọn lọ. Àbí, yóò ṣáà ní ìdí tí ẹni tó lọjọ́ yóò ṣe wá yọjú sí èèyàn? Ọkàn ọmọdé ṣá! Nígbà tí mo dàgbà díẹ̀ sì ni mo tó ṣàkíyèsí wípé tí àwọn àgbàlagbà bá sọ nípa èèyàn wípé, “Ọlọ́jọ́ rẹ ti dé”, ó tún mọ̀ sí wípé onítọ̀hún tí ṣe aláìsí nìyẹn. Nígbà náà ni mo wá tún gbólóhùn náà yẹ̀wò, mo sí sọ lọ́kàn ara mi wípé Ọlọ́jọ́ ni ẹni tí ó lọjọ́, tí ó sì fi oye ọjọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ jíǹkí kálukù ohun abẹ̀mí. Nígbà tí òye ọjọ́ oníkálukú bá pé ní Ọlọ́jọ́ yóò padà wá gba ọjọ́ rẹ padà.
Ká pa àwàdà tì sí ẹ̀gbẹ́ kan, ààyè iṣẹ́ yìí ló mú mi lọ ṣe ìwádìí fínnífínní àkọ́kọ́ mi lórí ọdún Ọlọ́jọ́ àti ìṣẹ̀dálẹ̀ rẹ. Torí, ká má parọ́, ká má sì jalè, àwọn ooṣà tí ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá kìí ṣe díẹ̀, ó sì lè nira díẹ̀ fún èèyàn kan láti mọ gbogbo wọn sórí. Ní Ilé Ifẹ̀ nìkan, ọdún ooṣà tí wọ́n máa ṣe lé ní ọgọ́rùn-ún. Mélòó l’èèyàn fẹ́ rántí, láì bá ṣe wípé Olúwa rẹ jẹ abọ̀rìṣà tí ń fi gbogbo ìgbà gbé ní Ilé Ifẹ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ka ara mi mọ àwọn olólùfẹ́ àṣà, mo gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ wípé ìmọ̀ péréte ni mo ní nípa àwọn ọdún ooṣà lápapọ̀. Pẹ̀lú gbogbo ọdún ooṣà tí ń bẹ ní ilẹ̀ Ìjẹ̀bú tí mo ti wá, bíi ọdún Agẹmọ, orò, Ogún, Sango, tí a bá tún wá ka gbogbo ọdún tí wọ́n ń ṣe ní Ìlè-Ifẹ̀, ó rọrùn fún èèyàn láti gbàgbé nípa àwọn ọdún kàn-àn kan.
Láì fa ìtàn yìí gùn jù, ààyè iṣẹ́ yìí mú mi ṣe ìwádìí nípa Ọdún Ọlọ́jọ́. Mo lọ sí orí ẹ̀rọ ayélujára, mo sì bi àwọn ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ mo tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Ilé-Ifẹ̀ nípa ọdún naa. Ìwádìí yìí ṣí mi lójú gidi gan, nítorí nípasẹ̀ rẹ ni mo ti ṣe àwárí ipa pàtàkì tí ọdún Ọlọ́jọ́ kó ní ìran àwa Yorùbá. Mo kọ́ pé odún Ọlọ́jọ́ ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, Ọọ̀ni, Ọba Adéyẹyè Ẹniìtàn Ògúnwùsì júwèé ọdún náà gẹ́gẹ́ bíi ayẹyẹ àjọyọ ìran adúláwọ̀ lápapọ̀.
Ìwádìí fi hàn pé Ọlọ́jọ́ jẹ́ ọba nígbà kàn rí ní Ilé-Ifẹ̀. Ohùn ni Ọọ̀ni kọkànlélọ́gbọ̀n tó jẹ́ ní Ilé-Ifẹ̀, ohùn ló sì wà ní ìgbọ́nu Adé-Aàrè. Nígbà náà lọ́hùn-ún, tí Oṣògún bá fẹ́ lọ b’ọ̀gún, ó gbọ́dọ̀ wá gba àṣẹ lọ́wọ́ Ọọ̀ni. Ọọ̀ni gbọ́dọ̀ fi Adé-Aàrè súre fún Oṣògún, kí ó tó lè lọ l’agùn-ún. Láì sí ìwúre yìí, Oṣògún ò leè l’agùn-ún. Àmọ́ bákan náà, láìsí ìlagùn-ún, ọdún Ọlọ́jọ́ ò leè wáyé. Èyí ni ìpìlẹ̀ ọjọ́ Ìlagùn tí ọdún Ọlọ́jọ́ máa ń bẹ̀rẹ̀.
Ṣíwájú ọjọ́ Ìlagùn yìí, Ọọ̀ni yóò ti wà ní ìyàsọ́tọ̀ fún ọjọ́ márùn-ún láti bá àwọn ooṣà mọ́kànlénírinwó dámọ̀ràn, yóò sì ṣe àwọn àdúrà pàtàkì àti ètùtù pẹ̀lú àwọn abọrẹ̀ méje. Ní àsìkò yìí, Ọọ̀ni kò ní jẹ oúnjẹ ayé, oúnjẹ èmi ni yóò máa jẹ, pẹ̀lú atare àti obì. Lẹ́yìn àwọn ọjọ́ márùn-ún yìí ni Ọọ̀ni yóò jáde pẹ̀lú Adé-Aàrè lórí, tí àwọn èèyàn nígbàgbọ́ wípé àwọn ooṣà ti ró ní agbára. Ọọ̀ni, pẹlu Oṣògún, àti àwọn abọrẹ̀ mìíràn yóò lọ sí Okemogun, níbi tí Oṣògún yóò ti fi ajá rúbọ lẹ́yìn tí wọn bá ti ṣe àdúrà fún ọrọ̀, ìlera àti àlàáfíà àwọn ará ìlú. Lẹ́yìn ètùtù yìí ni àwẹ̀jẹ wẹ̀mu yóò wá bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu.
Ìwádìí tí mo ṣe nípa ọdún Ọlọ́jọ́ mú inú mi dùn, nítorí wípé, ìmọ̀ mi nípa àṣà àti ìṣe Yorùbá tún gbòòrò síi. Lẹ́yìn tí mo ka gbogbo àkọsílẹ̀ tí mo rí lórí ẹ̀rọ ayélujára, tí mo sì tẹ́tí sí àwọn ìtàn tí àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ fún mi, mo sọ lọ́kàn mi wípé Ọlọ́jọ́ ti dé fún ìgbà aimo mi.
Nípa Ònkọ̀wé
Dunni Adénúgà ń gbé ní ìlú Ìbàdàn.