Ta Ni Kí Ń Bi?

Mo wò òréré ayé yíká 
Ayé ò yé mí rárá
Mo wò sánmọ̀ lọ súà
Kò yé mi bó ṣe rí.
Ìrònú sórí mi kodò.

Ọ̀rọ̀ hùn hùn nínú ẹlẹ́dẹ̀
Mọ̀ sínú ni mo fawo dá
Ọ̀rọ̀ gbénú rà bí ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀
Mọ̀ síkùn ni mo fawo ṣe
Ọ̀rọ̀ lọ́dìí òkòtó kò yé mi.

Isó inú ẹ̀kú lọ̀rọ̀ tí mò ń rò.
N ò mẹni àá fọ̀rọ̀ lọ̀?
Tí ó ní pàfín lóyìnbó fún ni.
N ò mẹni àá bèèrè lọ́wọ́ ẹ̀?
Tí ò ní pajá lọ́bọ fún ni.

Ẹni a ń ronú rẹ̀ pamọ́
Òun gan-an ni n ò bá bí
Ẹni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń ṣeni ní kàyéfì
N ló yẹ kí n pè kó fèsì
Àmọ́ ń ò rẹ́lẹ́jọ́ bá ṣú rárá.

Ìdí tó fi pamọ́ kò sẹ́ni tó yé
Èrèdí tó fi farasin ò yẹ́nìkan.
Òhun ni sábàbí tó fi pamọ́ yé
Tó fi ń dára láì jẹ́ ká fojú rinjú.

Làá hàn mí ní bàtá ń ké lótù Ifẹ̀.
Kí ló wá dé tọ́rọ̀ ò já gbàgede?
Èmi ló ṣẹlẹ̀ tójú amọ̀kòkò mi ò tólẹ̀?
Èmi ló dé tọ́rọ̀ dọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀?
Tí gbogbo nǹkan lọ́dìí òkòtó.

Kò sẹ́ni tó lè dára tí ń dá
Òun sì ń rí gbogbo ojú
Bójú sí pégba kò le è ri.
Àfẹni tó bá kà á kún láyé
Ló le gán-án-ní rẹ lálùkìyáomọ̀.

Ọ̀kan ṣoṣo dondo kúkú ni
Méjìméjì ló ṣẹ̀dá ohun gbogbo
Kò sẹ́ni tó mọye ẹ̀dá tó dá
Kò sẹ́ni tó le fọwọ́ sọ̀yà èyí
Bó bá wà ẹ ní kó wá wí?

Igi tó dá sínú igbó kọjá ogún.
Ẹyẹ tó dá síjù kọjá ọgbọ̀n.
Ẹranko tó ń bẹ láginjù ò lóǹkà.
Ẹja tí ń bẹ níbú ò ṣe é fẹnu ròyìn
Èyí tó fi hàn wá ó tó nǹkan.

Ìrònú Ò Papọ̀

Ohun tó ń dunni,a pọ̀ lọ́rọ̀ ẹni 
Ológún ẹrú kú aṣọ rẹ jẹ́ ọ̀kan.
Ohun tí ń ṣepo kọ́ ló ń ṣọ̀rá.
Ohun tí n sọmọ kọ́ ló ń ṣèyá
Ọmọ ń ronú, ìyá ń rokà.

Ohun tí ń ṣabiyamọ yàtọ̀ ságàn.
Ohun tí ń ṣe oníbàtá yàtọ̀ sóní ìyáàlù.
Ebi a máa ń pani pọ̀
Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ̀rọ̀ ń dùnnìyàn.
Ẹsẹ̀ ijó ó papọ̀ rí lójú agbo
Ìkúùkù làá dì jó èyí tó bá dunni.

Ìrònú ò lè papọ̀ láéláé.
Ìkanra là á fi sọ̀rọ̀ tó bá dunni
Ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ lejò fi ń gun àgbọn
Àmọ́ wàràwàrà ni ti àlégbà.
Bómi ó gbóná ẹ̀bà ò tẹ̀.

Iṣẹ́ aláǹtakùn ni kó ta òwú
Iṣẹ́ agbe ó fara jọ tàlùkò
Iṣẹ́ lékeléké kò papọ̀ mọ́ tí ẹ̀lúlùú
Agbe ló laró àlùkò ló losùn
Lékeléké ló lẹfun tẹ̀lúlùú ni kó fàjò.

Ìrònú ò papọ̀ rárá
Iṣẹ́ ojú gbà ni kó ríran kedere
Iṣẹ́ ẹsẹ̀ yàn ni kó tẹ̀nà ṣà ṣà ṣà
Tòṣípàtà ni kó lé téńté sójú omi
Tàkèré ni kó jẹ̀ lálẹ̀ odò.

Ohun tó ń ṣeni ò jọra wọn
Ọ̀rọ̀ tí ń dun ni ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀
Ìrònú ò papọ̀ rárá.

Wèrè Aláṣọ

Ayé dórí kodò bí àdán 
Ayé kọ̀ kò gún mọ́.
Ayé tí polúkúrúmuṣu.
Òjòjò ọlọ́jọ́ pípẹ́ ń ṣayé
Kí la ó ti ṣèyí sí?

Ọ̀gẹ̀dẹ̀ ń bàjẹ́, a ló ń pọ́n
Ojú egbò lọmọ aráyé fi ń tẹlẹ̀
Ojú ń rà, a ní ṣe ló ń là.
Nǹkan ń bàjẹ́, a ló ń dára
Mo rímú he, ète sọnù!

Ohun Olú fi pamọ́ síbi ọ̀wọ̀
Di mẹ́ta tọ́rọ́ nígboro
Ààyè ọ̀wọ̀ tó yẹ káṣọ ó bò
Dàdánwò sákọ lọ́rùn nígboro
Àrà meèrírí kí là ó ti ṣèyí?

Ìbíǹbí labo ń rìn wàyí!
Wọn ó náání ààyè ọ̀wọ̀ yí mọ́
Wèrè aláṣọ wá pọ̀ nígboro
Asíwín aláṣọ lùgboro pa
Ojúlówó aláńgànná wá ṣòro dá mọ̀.

Ọlọ́dẹ orí gidi ṣòro dá mọ̀
Òmíràn a wọṣọ a dàbí i jáwéjura
Òmíràn a dàbí igún tíyà ń bá fínra.
Wọn a máa rìn bí àgéré
Wọn a máa ṣẹ́jú bí iná ọba tí ò gbádùn.

Ìhòòhò ni wọn ń rìn ká
Ìtìjú ò sí fábo mọ́ rárá
Wọ́n sọra wọn di bàbàrà
Ohun tó yẹ kí wọn ó fi pamọ́
Ìpolówó ọjà ni wọ́n fi ń ṣe.

Iyì òun àpọ́nlé ò sí fábo mọ́
Wọn ó yá ajá jẹ́ rárá
Bí òmíràn bá jókòó tí èèyàn
Bí òkú ẹran ni yóò máa rùn
Ìpara àdàmọ̀dì tí sọ wọ́n di bámíì

Ilẹ̀ tí ò lọ́ràá ṣe lè mú irúgbìn re jáde?
À-bí-ǹ-pabẹ́ abo wá pọ̀ bíi bèbèsùá
Ọmọ kìí bá ìpele ìyá ẹ̀
Kò sí aṣọ dá láéláé.
Ohùn a bá fọn sí fèrè ni mú jáde.

Wọ́n baye jẹ́ tán poo!
Wọn ń pè é lọ́lájù
Ṣé ọ̀làjú lèyí àbí ìpìlẹ̀ wèrè?
Ṣé ojú ń là lèyí ẹ̀yin òbí?
Ẹ sì ń wò láìbìkítà rárá

Orin ìgbà lonígbà ń lò lẹ̀ ń kọ.
Ká wọṣọ ká jọmọ Yòòbá àtàtà
Tí dàfìsẹ́yìn téégún ń fiṣọ
Àwọ̀tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ń polówó
A tilẹ̀ jẹ́ èyí tó mọ́ tónítóní.

Bí i kúrúna, ẹ̀yi ti ba ara jẹ́
Gbẹ̀rẹ̀bí tí dá bátànì sí wọn lára
Kẹ́míkà ti sọ ara wọn di bá míì.
Wọn a funfun bí ọbẹ̀ tí ó lépo
Wọn a máa rùn bí òkú ẹran.

Ọ̀rọ̀ yìí ń fẹ́ àtúnṣe pàjáwìrì
Ká pé ìpàdé àwọn àgbààgbà
Kí Ọmọ́yẹ ó tó rin ìhòòhò wọjà.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *