Tata Àti Ìrẹ̀: Ẹranko Olóhùn Tó Bá Ìgbà Mu / On The Grasshopper And Cricket
Ewì inú Ayé ò kú rí: Nígbà tí gbogbo ẹyẹ ò bá lókun mọ́ látàrí oòrùn gbígbóná, Tí wọ́n sì f'ara pamọ́ sínú igi tútù, ohùn kán yóò dé Igun sí igun nípa koríko titun tí a gé kalẹ̀; Bi Tata ti rí nìyí, ohùn rẹ yìí a máa játóò Ní àkókò ìgbádùn tí ń bẹ nígbà oru, ko fi ìgbàkan ṣe tán Àti má dunnú mọ́; bí ó ba ṣeré tí ó rẹ̀ẹ́ A máa sinmi nínú ìrọ̀rùn ní abẹ́ koríko tí ó dára. Ewì inú Ayé kò le è dúró láiláí: Àṣálẹ́ kan nígbà òtútù, tí òtútù nini Mú kí ìpalọ́lọ́ kó wà, láti inú ilé gbígbóná ni a gbọ́ íhan, Ìrẹ̀ tí ń kọrin, tí ó mú àlékún bá oru l'áàkókò òtútù. Orin náà dàbí ẹ pé kò tilẹ̀ yàtò létí ẹni tó ń sùn, Bíi ti Tata tó wà láàárín àwọn koríko orí òkè.
On The Grasshopper and Cricket
The poetry of earth is never dead: When all the birds are faint with the hot sun, And hide in cooling trees, a voice will run From hedge to hedge about the new-mown mead; That is the Grasshopper’s- he takes the lead In summer luxury,- he has never done With his delights; for when tired out with fun He rests at ease beneath some pleasant weed. The poetry of earth is ceasing never: On a lone winter evening, when the frost Has wrought a silence, from the stove there shrills The Cricket’s song, in warmth increasing ever, And seems to one in drowsiness half lost, The Grasshopper’s among some grassy hills.
~John Keats (short poem)
Ọ̀rọ̀ Nípa Olùtúmọ̀:
Olúwáfẹ́mi Kẹ́hìndé jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, tí a bí ní ìlú Ìbàdàn. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.
Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria culture image on wheather https://www.google.com/search?client=ms-opera-mini-android&channel=new&biw=412&bih=658&tbm=isch&sxsrf=ALiCzsZX3mE4al1Mv_zfGqYuA6A-sGpUgw%3A1671818955739&sa=1&q=nigerian+art+images+on+wheather+and+season