Kínní ọ̀rọ̀ se kàn mí? Kò le rárá. Ní ìjẹ́tá, olè oníkẹ̀kẹ́ kan jí táyà iwájú kẹ̀kẹ́ tèmi níbi tí mo só mọ́.
Ẹ forí jìn mí o, ẹ̀yin tí è ń gbé inú ilé yí. Ẹ̀rù ajá yín tí ó ń bà mí ni mo ṣe kọ lẹ́tà. Kí n má gbà yín ní àkókò, ọ̀rọ̀ kẹ̀kẹ́ ni mo fẹ́ bá yín sọ. Ọ̀rọ̀ kẹ̀kẹ́. Kẹ̀kẹ́ tí àwọn olè jí ìdá méjì nínú mẹ́ta rẹ̀. Mo ṣe àkíyèsí wípé táyà iwájú nìkan ni ó ń bẹ lórí ìso. Mo sì mọ wípé iṣẹ́ ọwọ́ àwọn olè oníkẹ̀kẹ́ ni.
Ẹni tí ó jí kẹ̀kẹ́ yín jí idà méjì nítorí wípé idà kan, ìyẹn táyà iwájú, nìkan ni ẹ so mọ́lẹ̀. Táyà iwájú ọ̀hún nìkan ni ó sì ń bẹ lórí ìsò báyìí.
Kínní ọ̀rọ̀ se kàn mí? Kò le rárá. Ní ìjẹ́tá, olè oníkẹ̀kẹ́ kan jí táyà iwájú kẹ̀kẹ́ tèmi níbi tí mo só mọ́. Bí mo ṣe ń kọjá ní ọ̀sán yìí, tí mo rí idà kan tó kú nínú kẹ̀kẹ́ yín, ní mo ronú wípé olè tí ó jí kẹ̀kẹ́ yín ní o jí táyà iwájú kẹ̀kẹ́ tèmi.
Ọwọ́ tèmi dí díẹ̀ báyìí, n kò lè wá olè oní kẹ̀kẹ́ yìí. Ṣùgbọ́n mo mọ̀ wípé ẹ ó ti máa wà kẹ̀kẹ́ yín. Ẹ dákun, bí ẹ bá rí kẹ̀kẹ́ yín, èmi ni mo ní táyà iwájú rẹ. Ẹ bámi ṣowọ́ rẹ̀ sí àdírẹ́sì yìí: yàrá kẹrìnlá, ilé Máàkù, àdúgbò yín.
Tiyín ó ní baje ó.
Tọ̀wọ̀ tọ̀wọ̀,
Tàfá