Ẹni tí yóò bá pẹ̀gàn àjànàkú ni yóò sọ pé òun rí nǹkan fìrí. Igi pọ̀ nígbó àmọ́ ọ̀tọ̀ ni igi ọ̀mọ̀. Kòkòrò pégba nígbó ṣùgbọ́n èyí tí yóò rùn bí ìkaǹdù wọ́n bí ojú. Iṣẹ́ oríṣiríṣi pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, gédégédé ní iṣẹ́ olùkọ́ yàtọ̀ sí àwọn yòókù. Àwọn olùkọ́ lórí tó dúró fún àgbọ̀n mumi. Iṣẹ́ olùkọ́ ni ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ gbogbo iṣẹ́. Ẹ gbọ́ ta ló le di ohunkóhun láyé tí kò bá fi tí tíṣà ṣe?

Ọdẹ́wálé kìí ṣe òpè nínú iṣẹ́ olùkọ́. Ọjọ́ rẹ̀ tí pẹ́ nínú iṣẹ́ yìí, kò sí ẹnì tí ó lè kọyán rẹ̀ kéré tí ó bá dibi kí a fi ẹfun tún orí ọmọ ṣe. Náání-náání-náání ohun a ní làá náání ọmọ aṣẹ́gítà a máa náání èpo igi bí ọdẹ ṣe ń náání apó. Láti pínníṣín ni Ọdẹ́wálé tí máa ń bá bàbá rẹ̀ lọ síbi iṣẹ́. Nítorí náà, láti ìgbà náà ni ó ti pinnu pé bí òun bá dàgbà iṣẹ́ olùkọ́ ni òun yóò yàn láàyò.

Ní ti bàbá rẹ̀, ṣàṣà ni ilé ẹ̀kọ́ tí ó ti ṣiṣẹ́ tí kìí ni orípa rere níbẹ̀ pàápàá nínú ìgbésí ayé ọmọ tí ó bá gba iwájú rẹ̀ kọjá. Ó ta mọ́ra ni tòótọ́ àmọ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí ó bá ti ṣe ohun tó yẹ, ààyò rẹ̀ ni irúfẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀. Èdè Yorùbá ni ó ń kọ́. Ó mọ̀ ọ́n dunjú. Kì í ṣe àwọn tí ó kàn gba ìwé ẹ̀rí lásán, olùkọ́ tí ó dáńgájíá ni. Kò sí ibi tí ó farasin fún un nínú iṣẹ́ yìí. Ọ̀pọ̀ ìdíje ni ó ti kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lọ, tí wọn sì fakọ yọ. Ó mójú tó iṣẹ́ olùkọ́ yìí débi pé ìṣáná ẹlẹ́ta ni.

Gbogbo akitiyan Ọdẹ́wálé yìí ni àwọn kan rí sí àṣejù láàrín àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ẹgbẹ́ rẹ̀. Bí èèyàn bá ń gbọ́ oúnjẹ bọ́ ìlú kò ní kí ó má ní ọ̀tá. Kò gba gbẹ̀rẹ̀. Kò sí akẹ́kọ̀ọ́ to lè gbójú wo ẹkùn rẹ̀ tí kò ní fẹ̀jẹ̀ wẹ̀. Bí ó ti ń ṣe èyí ni ó ti fi tún ayé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan tí ó jẹ́ ìsáǹsá àti àwọn tí kò gbájúmọ́ ẹ̀kọ́ wọn ṣe. Wọ́n tí yí padà di ọmọ gidi.

Àwọn àgbà bọ̀ wọn ní, “mo ṣoore kò gbè mí, ó lọ́wọ́ kan ìkà nínú ni”. Ibi ayẹyẹ ìgbéyàwó àbúrò ọ̀gbẹ́ni Ọdẹ́wálé ni ó wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí ó rí arákùnrin kan tí ó kàn ṣàdédé wó lulẹ̀ bí àpò gàárì. Onítọ̀hún dọ̀bálẹ̀ láìwo bí ó ṣe kàǹkà tó. Bí ó ti bojú wò òkè ló bá di Àyìndé Akóredé. Ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí ó kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ girama Àjùwọ̀n ní ìpínlẹ̀ Ògún. Ó ti di dókítà Oníṣègùn Òyìnbó ni ní òkè òkun. Lẹ́yìn tí wọn dìjọ fọ̀rọ̀-jomi-toro-ọ̀rọ̀,ó gba nọ́mbà ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ọ̀gbẹ́ni Ọdẹ́wálé. Ó sì pinnu pé òun yóò pè é.

Àyìndé Akóredé jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí kìí gbé kíláàsì nígbà tí ó wà nílé ẹ̀kọ́ àmọ́ àìdágunlá ọ̀gbẹ́ni Ọdẹ́wálé pẹ̀lú àtìlẹ́yìn Ọlọ́run ló sọ ọ́ dẹni tó ronú pìwàdà. Ọjọ́ kan ni ó pe ọ̀gbẹ́ni Ọdẹ́wálé lórí aago pé yóò wu òun láti wá bá òun naju lókè òkun. Ó ní kí ó má mikàn gbogbo owó tí yóò bá ná òun yóò pèsè rẹ̀. Lẹ́yìn oṣù kan tí wọ́n tara bọ ìgbésẹ̀ ìrìnàjò náà nǹkan gbogbo ètò tò. Bí ọ̀gbẹ́ni Ọdẹ́wálé náà ṣe di ará ìlú òyìnbó rèé. Kò pé ní Àyìndé mú ọ̀kan lára àwọn ọmọ olùkọ́ rẹ̀ mọ́ra. Nǹkan wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ́nuure fún ìdílé alàgbà Ọdẹ́wálé

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ. Òun ni olóòtú ìkànnì ÀTÙPÀ ÈDÈ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *