Ẹ jógun ó mí, ẹ ṣìmẹ̀dọ̀ n’ìyáàlù ń ké. Àmọ́ ọ̀rọ Nìjéè só síni lẹ́nu, ó tún buyọ̀ si. Iyọ̀ àlàáfíà ò sé tu dànù bẹ́ẹ̀ nisóo ìdìtẹ̀ gbàjọba ò sé gbémì. Kẹ́ẹ sì ma wòó, ọ̀rọ̀ kìí tóbi jù ká y’àdá tìí, ẹnu alábẹ sékélé náà lá fi sọ́.

Àtọmọ tí ńké àti ìyá rẹ̀ tí ń pasẹ̀ fun, ọ̀rọ́ jọ yé ra wọn ni. Àwọn tó fi sakabùlà kálùbọ́sà ààrẹ alágbádá ò fi toríi Ọlọ́run dìtẹ̀ gbàjọba. Ìfun kììmọ̀ wọn ló ń tì wọ́n nítìkutì. Sé àwọn tí wọ́n fi òórọ̀ ayée wọn kọ́ isẹ́ẹ ogun àmọ́ tí wọ́n ò leè jagun ségun sùmọ̀mí ni yóò rí ìjọba ṣe? Kìí kú se pé ìjọba alágbádá sòro bẹ́ẹ̀. Àmọ́ àwọn tó fi agbára káká wápò gan ò tíì rójútùú è, ká má wá sọ àwọn kan tí wọn kàn já wá láì lókún lọrùn. Àwọn -ìyẹn àwọn olóṣèlú- tó jẹ́ pé bí wọ́n ṣe ń sáré síwá ni wọ́n sáa sẹ́yìn. Bí wọ́n ń sé bọ̀sun ni wọ́n b’ọbà. Àwọn wòlíì èké wọn ò yé sọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni tùràrí ò jó tán nílée àfáà. Wọ́n á fẹ̀jẹ̀ alátakò wẹ̀ bíi omi kọ́n lè baà dépò. Àmọ́ kí wọ́n má tíì goríi àpèrè tán ni, ọpọlọ wọ́n a sùn lọ bíi Jónà. Àti gbájúmọ́ ìṣèjọba á dogun. Wọ́n á gbádàá lé mẹ̀kùnù lẹyìn, wọ́n á sì wọ́ agbada ẹran gbogbo ìlú sábẹ́. Sé, tí ón’kakí bá wá sọ Jònájóna wọn sínúu okun, só burú ni?

Sùgbọ́n ọ̀rọ̀ ò lọ tààrà báyẹ̀n. Tí àwọn ọmọ Nìjéè bá mọ̀ ni, wọn ò ní gbàlù gbajó sayọ̀ nínúu réderède. Ìjẹkújẹ àti ìmukúmu tí ọgá sọ́jà se kù ní bárékì náà ló fẹ́ rawólé ní iléjọba Nìámì. Alágbádá kú ti júwe ibi isasùn tẹ́lẹ̀ rí. Kólógbò kẹ́ran jẹ ló kù. Ẹ má sì jẹ̀ẹ́ ká fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ níbi táa dé yìí rárá, àwọn aládaríi ẹkùn ìwọ̀-oòrùn Àfíríkà pọ̀ nínúu ìṣòro ẹkùn wa. Wọn ò ma darí bíi ẹni tó níran tàbí tó ti ẹ ní èrò nípá ọ̀la ilẹ̀ẹ wa. Sé tí àwọn olórí ní Nìjéè àti Málì àti Bọ̀kínà bá ṣe iṣẹ́ wọn bíi iṣẹ́ ni, ǹjẹ́ àwọn kọ̀lọ̀rọ̀sí yìí á gbérí bí? Wọ́n bayé jẹ́ débi pé, àwọn ọmọ ìlú ò kọ àjàgà líle. Wọ́n sún wọn kan ògiri débi pé wọ́n polongo èèrí bí pé iyán oníbejì ni.

Àánu ààrẹ Tinúubú tiẹ̀ ṣe mí. Gẹ́gẹ́ bíi aládarí ẹkùn, ọ̀rọ Nìjéè tún mú kí ìdààmú ọmọ àlájà di púpọ̀. Iná ogun ń bẹ nílé tí baba Sèyí ò rí pa, sé báálé tí ò rílé rẹ̀ tò a máa jẹ báálẹ bí? Sùgbọ́n ikú tí ń pa ojúgbà ẹni, ò pòwe bíntín. Bí Tinúubú àti àwọn aládárí ẹkùn yòókù ò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi sàdàá kò sí gbà tí mákùú wọn ò ní kú o. Lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ yìí Sẹ̀nẹ̀gà ò fẹ́ fararọ, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ iná ọ̀tẹ̀ ń jó lọ. Ká tọ̀ sẹ́jú báyìí, àwọn sọ́jà a gbàjọba tán o. Láì ṣe àní, nisẹ́ẹ àwọn akọni wa á bá já sá sán pátápátá. Bí Tinúubú bá sakin, tó fohùn lẹ́ẹ̀, kò burú. Fún ìdí èyí, òkò ọ̀rọ̀ sàkàsàkà tí àwọn kan láti òke ọya lóríi ọ̀rọ̀ yìí ń sọ gba pẹ̀lẹ́ o. Sé ló fẹ́ dà bíi pé a fẹ́ túlé agbọ́n ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yà mẹ̀yà -tí wọn fi se wá- míì lẹ́ẹ̀ ni o. Ọ̀rọ Nìjéè ò sì gbọdọ̀ di gbàrànmí di ẹlẹrù. Olórun á bá àwọn aládarí ẹkùn yanjú ọ̀rọ̀.

Àmọ́ láì ṣe àní, ogun ìdìtẹ̀ gbàjọba le di tọ́rọ́ fọ́n kálé tí a ò bá múra. A sì lè tètè bàá níwọ̀ọ́ báa bá sẹ̀tọ́ọ́. Ẹ jẹ́ á fi òótọ́ àti òdodo sàkọ́kọ́, ká náàni gbogbo èèyàn láì fí ẹ̀tọ̀ wọn dùwọ̀n. Àwọn aládarí gbọdọ̀ se ìjọba alákóyawọ́, kí adìrẹ funfun wọn ó mọra rẹ̀ lágbà. Àì se èyí, ewu oko lóńgẹ́ ni o. Lóńgẹ́ sì rèé, babá ńlá tírọ́bù.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọláyínká jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní fásitì LAUTECH, Ògbómọ̀ṣọ́. Ó fẹràn láti máa kọ ìtàn àti àròkọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Yorùbá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *