Ìtàn àròsọ yìí dálé ìtàn ìsẹ̀dálẹ̀ ìlú kan tí à ń pè ní ILÉ-OGBÓ ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun, ILÉ-OGBÓ wà ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ibẹ̀ náà sì ni Ayédire (Local Government) wà. ILÉ-OGBÓ sí Ìwó kò ju ìrìnàjò kìlómítà mẹ́rin lọ (4km). Láti Ọ̀yọ́ sí ILÉ-OGBÓ ó jẹ́ ìrìnàjò ogójì kìlómítà (40km).
Orí Kìn-Ín-Ní
Ní alẹ́ pátápátá tí òṣùpá mọ́lẹ̀ gbòò gẹ́gẹ́ bíi ọ̀sán, Baṣọ̀run Yaú Yaḿbà tó jẹ́ Baṣọ̀run fún Aláàfin Òjìgí ni ìlú Ọ̀yọ́ jókòó síta lábẹ́ àtíbàbà, ó ń gbà atẹ́gùn sára. Ó jókòó sórí àga àgbàntara lẹ́ni tí kò wọ ẹ̀wù ṣùgbọ́n ṣòkòtò dígò wà ní ìdí rẹ̀, Baṣọ̀run tí ń rẹjú lọ díẹ̀díẹ̀ lórí àga àgbàntara, lójijì ni ó ń gbọ́ wúrúwúrú nínú igbó tí ó wà lọ́wọ́ àlàáfíà rè, ó tà gìrì, ó gbé ọ̀pá Ògún tí ó fi tì sí apá ọ̀tún rẹ̀, ó ń retí ohun tó ń bẹ nínú igbó, tó ń dún mọ̀huru-mọ̀huru.
Lójijì ó fohùn réré pé “ìwọ wo ló wà níbẹ̀ un” kò gbọ́ kí ẹnikẹ́ni fọhùnb, ó tún wí bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi “ìwọ tí o bá wà ní inú igbó yìí tètè fara rẹ hàn ṣáájú kí ń tó rọ́ bájínátù fún ọ nínú ibi tó o bá búúbúú sí. Kí ó tó sọ̀rọ̀ yìí tán ni ohùn kan jáde pé ” Báàmi! Èmi ni ó, ẹ má yìnbọn o, Baṣọ̀run bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ pé irú ìwà wo ni o wá ń wù un? ṣe bí ó sì tètè sọ̀rọ̀ pé ìwọ ló wà níbẹ̀, Ọlákalẹ̀ fèsì pé” Ẹ má bínú bàbá, mò ń wo ẹran ẹtu tó ń sáré lọ ni kò jẹ́ kí n fọkàn sí ọ̀dọ̀ yín.
Baṣọ̀run sọ pé ǹjẹ́ kò wá yẹ kí o fàrokò ránṣẹ́ ṣáájú kí ó tó wá ni? Ọlákalẹ̀ wí pé mo ti dé abà lọ́hùn tẹ́lẹ̀ àwọn ará abà náà ni wọ́n sọ pé ẹ ti wá sí ibi, ohun tí mo sì bá wá lówúra púpọ̀ ju kí n má débí lónìí lọ. Baṣọ̀run sọ pé “ṣùgbọ́n ó yẹ kí o fojú mọ́mọ́ rìn ni torí òkùnkùn kò mọ ẹni ọ̀wọ̀, òun ló dífá fún ìwọ taa nìyẹn”, “bẹ́ẹ̀ ni bàbá ṣùgbọ́n ẹ̀yin àgbà náà ni ẹ sọ pé “ọ̀rọ̀ tó bá ń duni, kí a má dée mọ́ra, èyí ló fà á tí mo fi sọ pé ijọ́ tí a bá rí ibi ni ó yẹ kí ibi wọlẹ̀”. Baṣọ̀run fèsì pé, “ó dára kín ló ń tó ń gbé ẹ lọ́kàn tó lè tó bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ kì í tóbi kí á fi ọ̀bẹ bù ú, ẹnu la ó fi sọ ọ́, ìdí ni a yóò fi jókòó, bí ó bá fasọ ya, kò lè fẹnu ya”. Ọlákalẹ̀ fọhùn, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ó ní “bàbá mi, Baṣọ̀run gbogbo Ọ̀yọ́-ilé! Ó tún ti ṣẹlẹ̀ o, kín ló ṣẹlẹ̀? Baṣọ̀run bèrè lọ́wọ́ Lákálẹ̀. Lákálẹ̀ tẹ̀síwájú pé aya mi tuntun ti bímọ, Baṣọ̀run fò sókè fúyà, ó bèrè pé akọ ni àbí abo? Lákálẹ̀ sọ pé, aya mi fi orúnkún ọ̀tún kúnlẹ̀, ó fi tòsì dìde ṣùgbọ́n láàrin ìṣẹ́jú díẹ̀, omi dànù, agbè sì tún wà gẹ́gẹ́ bí i tàtẹ̀yìn wá.
Bí ó ṣe sọ̀rọ̀ yìí tán, inú Baṣọ̀run bà jẹ́ púpọ̀, ó dorí kodò, ojú rẹ̀ sí kọ́rẹ́ lọ́wọ́ púpọ̀. Ọlákalẹ̀ tún tẹ̀síwájú pé “lánàá ni mo lọ sí oko mi ní Jóbèlè, bí mo ṣe ń wọ inú oko ni ìpòrúru ọkàn ti bá mi, àáyá fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú oko, gbogbo iṣu tó wà lórí ebè ló ti gbẹ tán tòun tàgbàdo, bàbá mi! kò sí nǹkan kan nínú oko náà mọ́ o. Ohun gbogbo ti polúkúlúmusu fún mi” Ọlákalẹ̀ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pẹ̀lú omijé àti ẹ̀dùn ọkàn tó jindò.
Baṣọ̀run mí kanlẹ̀, ó dáké lọ fún ìgbà pípẹ́, ní gbẹ̀yìn ó fèsì pé “Ọlákalẹ̀ ọmọ Akin! Má banú jẹ́ lọ títí gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ọ yìí ni yóò dohun ìgbàgbé, àbòkò ìrẹ̀ má ráhùn pẹ́ títí, bó bá dalẹ́ á doní igba aṣọ. Àbíkú kò ní yalé ya ọ̀dẹ̀dẹ̀ rẹ̀ mọ́. Bí ó bá di àfẹ̀mọ́jú lọ́la, a yóò jọ padà lọ sí Ọ̀yọ́-ilé láti rí Ifáyẹmí, ohun tí a bá máa ṣe, ifá á sọ ọ́ fún wa.
Orí Kejì
Ní ìgbà tó di àfẹ̀mọ́jú tí ọ̀yẹ̀ ti ń là ni Baṣọ̀run àti Ọlákalẹ̀ gbéra lọ sí Ọ̀yọ́-ilé láti fi oókan kún ééjì lórí ìṣòro tí Ọlákalẹ̀ ń kojú, bí wọn ṣe dé Ọ̀yọ́-ilé, wọ́n lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ìyàwó Lákálẹ̀, Baṣọ̀run kí gbogbo wọn, ó sì pàrọwà fún wọn pé kí wọ́n bara jẹ́ mọ́. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ àgbà, ó ní “ìgbà ẹ̀rùn ni ìpọ́njú ń mọ oníyèré, bí ó bá di ìgbà òjò, á di onígba aṣọ” Ó kọjú sí ìyàwó rẹ̀ tó ń ṣe ìyá Lákálẹ̀, ó sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sí i létí, òun náà sì fi orí dáhùn.
Àwọn méjèèjì jáde lọ, wọ́n dé ọ̀dọ̀ Ifágbèmí, wọ́n bà á níbi tí ó ti ń bọ èṣù lọ́wọ́ tí ó sì ń ki èṣù náà. Baṣọ̀run kí Ifágbèmí pé” àbọrú-bọyè o, Ifá dáhùn pé” àbọyè-bọ-sísẹ̀, Ogbó-a-tọ́” Lẹ́yìn tí wọ́n kí ra tán wọn wọlé lọ, Baṣọ̀run Yaú Yaḿbà, Baṣọ̀run gbogbo Ọ̀yọ́-ilé, ṣé kò sí? mo rí yín o, Baṣọ̀run fèsì pé ó wà o, iná ń jó mi lábẹ́ aṣọ, Ọlákalẹ̀ ni àwọn ìṣòro ń kojú rẹ̀, Àbíkú ló ń jẹ́ ẹ lọ́wọ́ bákan náà ni àwọn ohun ọ̀gbìn rẹ̀ kò so èso rere fún un, èyí ló fà á tí a fi jọ wá sí bí, kí ifá sọ ohun tí a máa ṣe.
Ifágbèmí gbé ọ̀pẹ̀lẹ̀ jáde pẹ̀lú ọpọ́n ifá, ó ṣe ìbéèrè lọ́wọ́ ifá pẹ̀lú kíkí oríkì ifá:
Ifá Ẹlẹ́rìí ìpín, A tún orí ẹni tí kò sunwọ̀n ṣe, Bó bá ń bẹ nígbèrí òkun, kí ó sáré wálé, Bí ó bá ń bẹ nígbèrí ọ̀ṣà kí ó tara sàsà wá sílé.
Lẹ́yìn tí ó kí ifá tán, ó fi ọ̀pẹ̀lẹ̀ janlẹ̀ gbọ̀n, ó sì tún ki ojú odù tí ó jáde lójú ọpọ́n ifá.
Kèǹgbè so bí àdó dàgbà Ológùnsẹ̀sẹ̀ nii so Bí ẹni fi iyùn méjì kanra wọn A díá fún Ọ̀wọ̀n Yóò rí ire méjì lóòjọ́ Wọ́n ní kí Ọ̀wọ̀n ó rúbọ Wọ́n ní púpọ̀ nire rẹ̀...
Lẹ́yìn tí Ifágbèmí kí ifá yìí tán, ó sọ fún Ọlákalẹ̀ pé ire ń bọ̀ fún un ṣùgbọ́n kì í ṣe Ọ̀yọ́ tó wà ni yóò ti rí ire náà, ó ní kí ó jáde kúrò ní Ọ̀yọ́-ilé tẹrú-tẹrù, ó wí pé ibi tí ó bá ti rí ẹyẹ Àgbìgbò àti ẹyẹ Ẹ̀gà tó ń fi ẹnu rẹ̀ kó koríko sínú odò ni kí ó ti dúró, ó ní ibẹ̀ gan-an ni yóò ti bímọ tí yóò dàgbà tí yóò sì gbó.
Orí Kẹta
Nígbà tí Ọlákalẹ̀ àti Baṣọ̀run kúrò ní ọ̀dọ̀ Ifágbèmí tán, wọ́n darí sílé lọ́dọ̀ àwọn ìyàwó àti ìyá rẹ̀, wọ́n kàkì mọ́lẹ̀, wọ́n ṣe àlàyé ohun tí wọ́n bá bọ̀ fún gbogbo wọn. Ìbànújẹ́ gun orí ẹ̀mí ìyá Ọlákalẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀, wọ́n ní “àwọn yóò wá fi ibi tí ààyè ti gba àwọn sílẹ̀ láti lọ tẹ ìlú mìíràn dó. Ṣùgbọ́n wọ́n tún gbà fún kádàrá, wọ́n pa kítí mọ́lẹ̀, wọ́n sì pọkàn pọ̀ láti jáde.
Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, Ọlákalẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ jáde pẹ̀lú omijé lójú gbogbo wọn, Baṣọ̀run ń fi apá aṣọ rẹ̀ nu òógùn ara rẹ̀ nù, ṣe àgbà tó ń sọ̀rọ̀, tó ń làágùn, ẹkún ló ń sun. Ọlákalẹ̀ jáde nílùú pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀, wọ́n mórí lé ọ̀nà wọn, wọ́n ń wà ibi tí wọn yóò ti rí ẹyẹ Àgbìgbò àti ẹyẹ Ẹ̀gà èyí tí ó ń fi ẹnu kó koríko sínú odò. Nígbà tí wọ́n rin ìrìn ọjọ́ mẹ́ta lọ́nà wọ́n dé ibi kan, wọ́n pinu láti sinmi níbẹ̀, láìpẹ́ wọ́n tún gbéra láti tẹ̀síwájú nínú ìrìn àjò wọn. Ní kété tí wọ́n rìn díẹ̀ ni Ọlákalẹ̀ ṣe àkíyèsí ẹyẹ kan ti ó ń fi ẹnu sogi, ó dúró, ó ń wòye ẹyẹ náà, ní gbẹ̀yìn ó rí ẹyẹ Àgbìgbò pẹ̀lú Ẹ̀gà tí ó ń fẹnu kó koríko sínú odò.
Inú Ọlákalẹ̀ dùn, ó sì fi ohun tó rí hàn àwọn ìyàwó rẹ̀, Ọlákalẹ̀ pàgọ́ sínú igbó yìí ó sì sọ pé “ILÉ-OGBÓ mi ni mo dé yìí o”. Lẹ́yìn oṣù bíi mẹ́wàá, ìyálé Ọlákalẹ̀ bí ọmọ ọkùnrin, wọ́n sọ ọmọ náà ni Òkúsìnmídé ní torí ilà tí wọ́n kọ fún nǹkan nínú àwọn àbíkú rẹ̀ ni ó tún wà lójú ọmọ náà. Ọmọ yìí dàgbà, wọ́n sì tún bí òmíràn tẹ̀lé e. Ọlákalẹ̀ rí ilẹ̀ tó dára fi ṣe oko, nǹkan ọ̀gbìn rẹ̀ náà sì so èso rere. Ìdílé Ọlákalẹ̀ ni ó ń jọba ní ìlú yìí. Wọ́n sì sọ orúkọ ibi tí wọ́n tẹ̀dó sí yìí ní ILÉ-OGBÓ.
Gbogbo àwọn ẹbí Ọlákalẹ̀ ni wọ́n dàgbà dògbó gẹ́gẹ́ bí orúkọ ìlú yìí.
Nípa Ònkọ̀wé
Orúkọ òǹkọ̀wé yìí ni Uthman Yusuf Abiodun. Ọmọ bíbí ìlú ILÉ-OGBÓ ni òǹkọ̀wé yìí jẹ́. Ó ti kọ ìwé ìtàn àròsọ kan tẹ́lẹ̀ rí, èyí tí orúkọ ìwé náà ń jẹ́ “Ìjà Ò Dọlà”. Ó jẹ́ ẹni tó fẹ́ràn àṣà, ìṣe àti èdè Yorùbá dọ́bà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ilé ẹ̀kọ́ gíga ti olùkọ́ni Adeyemi College of Education, Oǹdó, ni òǹkọ̀wé yìí wà tí ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá (ipele kẹ́rin). Òun sì ni Ààrẹ fún gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ ìjìnlẹ̀ èdè Yorùbá, ẹka ti ilé ìwé Adeyemi College of Education, Òǹdó.
Bàbá a ọkọ ọ mí.
Ọmọ Kúta ni mo jẹ, ọkọ ọ mí si jẹ́ ọmọ Ile-Ogbo.