Mo ti pàdé ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ìwọ̀n ọdún tí mo tì lò láyé, sùgbọ́n sàsà ni èyí tí ó nípa bíi bàbá Àmọ̀pé. Ọkùnrin mẹ́ta fúnra ẹ̀!

Láti ìgbà tí mo ti wà ní ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ni mo ti máa ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Orísirísi ọ̀rọ̀ ni wọn máa ń sọ nípa rẹ̀. Wọ́n ní láràárọ̀ ni ó máa ń fi ìka ọwọ́ ìkókó panu, ẹ̀jẹ̀ aboyún ni ó sì fi ń wẹ̀. Àwọn míràn tún ní a máa di ejò, ẹni tí ó bá sì ti gbémì ti di ohun ẹbọ nù-un. Wọn a ní kí ọmọkọ́mọ má ṣe ta félefèle dé agbègbè rẹ̀. Ẹnu ò sì lè máa kun ènìyàn bẹ́ẹ̀ kí ó má sí òótọ́ díẹ̀ níbẹ̀. Ṣé gbogbo ará ìlú títí kan kábíèsí ni ó mọ̀ pé ajọ́mọgbé ni bàbá Àmọ̀pé. A máa yà mí lẹ́nu pé kò sí ẹnikẹ́ni tí ó gbé ìgbésẹ̀ láti dá a lẹ́kun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbọ́mọgbọ́mọ ni àwọn ará ìlú ti mú tí wọ́n sì ti dáná sun, kò yé mi ìdí tí tiẹ̀ fi yàtọ̀. Ó ní láti jẹ́ pé òògùn rẹ̀ lágbára gidi ni.

Nígbà tí mo pé ọdún méje, a kó lọ sí ilé wa tuntun ní àdúgbò ireákárí ní ibi tí bàbá Àmọ̀pé ń gbé. Ìyá wa sẹ̀sẹ̀ sàìsì ni, ojoojúmọ́ sì ni àbúrò mi máa n pé òun rí wọn. Bàbá mi lérò pé bí a bá kúrò nínú ilé náà, yóò sinmi à ń rí òkú. Ní kété tí a débẹ̀ ni bàbá mi kó wa lọ sí ilé rẹ. Ọmọ rẹ̀ ni a bá, ó sì pè é sí ìta fún wa. Nígbà tí ó jáde, níse ni mo lanu. Láti ìgbà tí mo ti gbọ́ pé ajọ́mọgbé ni ni mo ti lérò pé èèyàn dúdú bíi èédú tí ó ní eyín pupa ni. Bàbá Àmọ̀pé dára, ẹ̀gàn ni hẹ̀ẹ̀. Ó dúdú lóòótó àmọ́ ó fi dúdú wuni, eyín ẹnu rẹ̀ sì funfun pìn-ìn. Ó rí lẹ́gẹ́lẹ́gẹ́, bíi ẹni tí atẹ́gùn le dànù. Kò jọ ẹni tí ó lè máa ṣe irú iṣẹ́ burúkú bẹ́ẹ̀.

Bàbá mi ní “Àwa ni a sẹ̀sẹ̀ kó dé ile tuntun tí ó wà ní ẹ̀bá odò yẹn. Mo wá kì ọ́ nílọ̀ ni. Àwọn ọmọ méjéèjì yìí…”, ó nàka sí èmi àti àbúrò mi, “èèrà ò gbọdọ̀ rìn wọ́n o, mi ò sì gbọdọ̀ wá wọn tì.” Bàbá Àmọ̀pé rẹ̀rìn-ín músẹ́, o sì fi bàbá mi lọ́kàn balẹ̀: Ó ní kò sí ewu. Di òní yìí, mi ò mọ ohun tí ó ti bàbá mi lọ lérí sí i.

Báyìí ni ọjọ́ ń gorí ọjọ́ tí a sì ń bá ìgbé ayé wa lọ. Àmọ̀pé àti àwọn àbúrò rẹ̀ a máa wá ilé wa wáá seré ní àsìkò ìsinmi. Ìlú èkó ni wọ́n ti ń ka ìwé. Wọ́n mọ èdè gẹ̀ẹ́sì dójú, ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì máa n ṣe olùkọ́ nínú eré tí a báa ń ṣe. Wọ́n a máa fúnnu mọ́ ọ̀rọ̀ bíi àwọn aláwọ̀ funfun. Tí a bá ṣe bojúbojú tán, á á sì tún se ‘ten ten’. Bí a ti wá jẹ́ ọ̀rẹ́ tó yìí, a ò dé ilé wọn. Kìí se pé a ò fẹ́ẹ́ lọ, sùgbọ́n bàbá mi kò gbàwá láyè.

Ilé bàbá Àmọ̀pé ni ó kọ́kọ́ jóná lọ́sàn-án gangan. Ó ti jáde lọ ní àtàárọ̀, ó lọ ra àwọn èèlò ọjọ́ ìbí rẹ̀ tí ó fẹ́ẹ́ wáyé lọ́jọ́ kejì. Àtaya, àtọmọ, àtẹrù ni ó di eerú. Bí o se dé ni ó bú sẹ́kún, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ síní gbára dálẹ̀. Kò sí ẹni tí ó rẹ̀ é lẹ́kún, wọ́n ní oun tí ó jẹ ló yòo. Ẹkún ni ó sun tí ilẹ̀ fi sú tí oníkálùkù fi gba ilé wọn lọ. A kò rí i fún ìgbà díẹ̀ lẹ́yìn ọjọ́ burúkú yìí.

Lẹ́yìn osù mẹ́ta ni a sàdédé rí bàbá Àmọ̀pé ní ìsàlẹ̀ ọjà. Nísé ni ẹ̀jẹ̀ ń dà ní imú rẹ̀. Apá rẹ̀ kan ti gé, a sì rí àpá nínà ní ara rẹ̀. Irun orí rẹ̀ ti dọ̀tí, ó sì tún takókó. Àwọn èèyàn pé lée lórí, wọn ò sì káàánu rẹ̀ rárá. Wọ́n ní ọkọ̀ píjò kan ni ó jáa sílẹ̀ lórí eré tí ó sì bá tirẹ̀ lọ. Ó jọ bíi pé ó ti ya wèrè. Èmi àti bàbá mi kúrò níbẹ̀, a sì gba ilé lọ. Lẹ́yìn ò rẹyìn ni a gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá wá á gbée, sùgbọ́n ó ti kú kí wọ́n ó tó ó de.

Àwọn yorùbá bọ̀, wọ́n ní bí o bá láyà o sèkà, bí o rántí ikú Gáà o sòótọ́. Ohun tí a bá gbìn la ó ká. Bàbá Àmọ̀pé gbàgbé pé ọmọ ọwọ́ ọ̀tun olódùmarè ni ẹ̀san í ṣe. Bí a bá n se ibi, kí á rántí àtubọ̀tán.


Ọlájùmọ̀kẹ́ ọmọ Kọ́lápọ̀ jẹ́ ọmọ bíbí ìlú ìbàdàn ṣùgbọ́n ìlú ìsẹ́yìn ni a ti wò ó dàgbà. Ó jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga fáfitì ìbàdàn. Ó ń kẹ́kọ̀ọ́ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ. Ó fẹ́ràn láti máa ka àwọn ìwé àpilẹ̀kọ


Àwòrán

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *