Ẹ̀rọ Omi
Báwo ni ó máa ń rí l’ára nígbà tí o bá ń gbìyànjú àti gba ẹlòmíràn là tí ìwọgan an wá di ẹni tó nílò ìgbàlà, nígbà tí èsúó bá pa ìdì dà tó ń lé ajá? Ojú a gba ni tì fún ara ẹni, ara ẹni a kọ́ tìọ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ó rí lára mi ní alẹ́ àná. Níṣe ni mo wà ní ibi àjọ̀dún àṣà àti ìṣe tó lárinrin kan. Nígbà tí ó yá, mó nílò láti gbọ̀nsẹ̀. Mo lọ sí ilé ìtọ̀ àwọn obìnrin láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà ti mo ṣetán, mo ṣí ẹ̀rọ omi láti fọ’wọ́, lẹ́yìn tí mo ti fi ọṣẹ s’ọ́wọ́. Omi kọ̀, kò yọ. Mo tún ṣi sí ọ̀nà míràn, omi ò yọ. Ọ̀rọ̀ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ Nàìjíríà wá kà mí láyà. Ǹjẹ́ ki ni ṣíṣe? Mo gbé ìgò omi mímu mi jáde láti inú àpamọwọ mi pé kí ń fi ṣan ọwọ́. Ìgbàyí gan ni arábìnrin kan náà jáde láti ilé ìgbọ̀nsẹ̀ láti fọ ọwọ́ rẹ̀ bákan náà. Arábìnrin yìí jẹ́ ọ̀kan lara àwọ́n àlejò pàtàkì níbi àjọ̀dún náà. Bẹ́ẹ̀, inú mi dùn láti jẹ́ olùgbàlàarẹ̀.
‘Ẹ má tíì fi ọṣẹ s’ọ́wọ́ o, omi kò yọ,’ mo wí fun.
Ó kọ́kọ́ wò mí ní ìwò àìkànisí
Mo tún ọ̀rọ̀ mi sọ.
‘Kò sí omi. Emi pàápàá ti fí ọṣẹ s’ọ́wọ́ kí n tó mọ̀’
‘Lòòtọ́?’ Ó bèèrè láì gbàgbọ́. O sì tẹ ẹrọ omi.
Omi yaaa!
Ọ̀rọ̀ pèsì jẹ. Mi ò mọ kí lààwí. Mo kàn ń wò sì!
Nígbà tí ó yá, mo ṣí ẹ̀rọ omi náà.
Omi!
Ẹ̀kọ́: Ẹ̀rọ omi títẹ̀ yàtọ̀ sí yínyìn.
Ẹ̀rù
Ẹ̀rù! Ẹ̀rù!Ẹ̀rù!
Ẹ̀rù a p’ọmọ kí ikú ó tó dé
Ẹ̀rù ní ò jẹ́ k’ọ́lẹ́ ó gbìn
A ò mọ̀ b’ójò ó rọ̀
Ẹ̀rù ni ò jẹ́ k’ójo o bọ́ sóde
A ò mọ̀ bí kìnìún ń bẹ l’óde
Ẹ̀rù ni ò jẹ́ k’ọ́kùnrin ó k’ọnu ìfẹ́
A ò mọ̀ bí bẹ́ẹ̀ni ni ó jẹ̀ẹ́ àbí bẹ́ẹ̀kọ́
Ẹ̀rù ni ò j’óbìnrin ó jẹ́hẹn
Tó bá tún lọ rí bi ti ìjọ́sí
Ẹ̀rù ni ò j’ópó ó fẹ́ ẹlòmíràn
A ò mọ̀ b’éléyìí náà á tún sánkú
Ẹ̀rù ni ò jẹ́ ka jẹun yó lònìí
Kí ni ó kù ta ó jẹ l’ọ́la
Ẹ̀rù ni ò jẹ́ ká kúrò níle mèrẹ́ntì
Níbo la f’owó sí?
Ẹ̀rù ló le bàbá Mẹ́ta lọ
Níbo la f’owó sí?
Ọ̀gá ń bọ̀, ọ̀gá ń bọ̀ nií pa ọmọṣẹ́
Ẹ̀rù ní b’óun bá ti wọlé ká pa lọ́lọ́
Kí jìnìjìnì bo ilẹ̀
Kí gbogbo àfojúsùn fò síta
Kí gbogbo ìgbàgbọ́ yọ dànù
Kí ìgboyà ó dohun ìgbàgbé
Kí àìnírètí gbà ìjọba
Ẹ̀rù!Ẹ̀rù!Ẹ̀rù!
Ẹ̀rù á rán ọmọ lọ s’íbojì l’ọ́jọ́ àìpẹ́
Ẹ̀rù ò bímọ re
Ẹ̀rù ò bí ǹkan re.
Mof’Ólúwawò O MojọláOlúwa jẹ́ amòfin àti ònkọ̀wé. O ti ko ọ̀pọ̀lọpọ̀ ewì àti ìtàn àròsọ ti a ti tẹ̀ jáde lórísirísi ní ilẹ̀ Áfíríkà, ní inú onírúurú ìwé àkójọpọ̀ ewì àti ìtàn pẹlu lori ayélujára. Ó féràn láti máa kọ ìtàn àti ewì, àti láti maa ya àwòrán. Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ewì/ìtàn rẹ̀.
Eṣe púpọ̀ ẹgbẹ Atelewo