ẸFÚNṢETÁN
Ọya ṣe tán ó rà sílé 'rá Ṣàngó ṣe tán ó wọlẹ̀ní Kòso Ẹfún ṣe tán ó lójú orógbó Ẹfun ṣe tán ó wẹwù ìjà sọrùn Ohun ojú òkú ri ní popo Ẹ bere lọwọ ikú wò Ohun ṣàngó rí ní Kòso Ẹ bere lọwọ adóṣù wo Ohun ẹfún rí kó tó ṣèyí tán Ló mú ẹfun gẹgún ọ̀ràn Ẹfún tuná lójú bi ọká Ẹfún toró lẹnu bí eré Ẹfun ò déédé bínú Bí kò bá nídìí ìṣẹ kìí déédé ṣẹ Ẹfun ò déédé pajúdà o jàre Ẹfúnṣetán aníwúrà Ìyálóde ilẹ Ìbàdàn Abìwàpẹlẹ n dẹtù A -dú-máa-dán bíi kóró iṣin A-bẹ̀-rín pònyẹ̀kẹ̀ lórí ojú tó lé tìróò A-bo-rí-já-ko akọbìnrin Alówóńlé aníṣulóko Alẹrúlọgbà alówólódù Olówò ẹtù tí kìí jagun Ọ-pàṣẹ ogun fìdí mọlé Kí lèrè ẹní lókìkí tí ò lọmọ Tààgàn kọ ti ìgbéraga kọ́ Ojú ẹ fi ń wo ẹfúnṣetán ò ríbẹ o jàre Ẹní lówó lọwọ, tí ò lọmọ, ò lẹyìn Lójú ayé rẹ nìran rẹ̀ dópin Ẹrú wá ń bimọ, ẹní ó máà bínú Ọmọ tirẹ kú tòun tọlẹ̀ nínú Ojú pọn ẹfun ó lójú orógbó Ojú pọn ẹfun ó wẹwu ìjà sọrùn Ẹfún ṣe eléyìí tan Ó ń ṣojú koko sọmọlọmọ níkòó Ó ń wò hàùn pa tọmọ tiye Bóo bá ń gbọtàn tán Tóò tíì gbọ àrọbá tán Ìtàn ń tàn ọ lọwọ ni Nítorí àrọbá gan baba ìtàn kítàn Bóo bá wá ń kàtàn Lọ ka tẹfúnṣetán Kóo le mọ kókó ìdí ìtàn.
ÈKÓ AKÉTE
Orin; Èkó ooooo, Èkó ooo eee Èkó ooooo, Èkó ooo eee Èkó akéte ìlú ọgbọn Èkó akéte ìlú ìmọ̀ Èkó ooooo... Gbogbo igi ní ń bẹ nígbó Gbogbo rẹ kííṣe gbẹ gbẹdu Gbogbo ìlú ní ń bẹ ní Nàìjá Gbogbo wọn kííṣe mú yangàn bí Èkó Ọjọ ajé lòní Èkó ò gba gbẹrẹ rárá Ṣùgbọn síbẹ ó gbolè ó tún gbọlẹ Ló fi dirúwa ògìrì wá Tájèjì fi fẹ máa fọwọ lalẹ níbẹ̀ Èkó akéte a rọ ṣẹṣẹ mọmọ já lèkó Èkó a rómi sá lẹgbẹ-lẹgbẹ Alagbalúgbú omi ń bẹ nípìnlẹ Èkó Níbi táfárá ti ń gorí afárá kọjá Níbi tí márosẹ̀ ti ń lé tìróò Èkó takété sáàrin omi ni Ni wọn fi ń pèé lékòó akéte Lórígun mẹrin Èkó Tútù làá rọdẹ tútù làá rọ bàbà níbẹ̀ Gbogbo nǹkan ìgùn ló pé sílùú Èkó Ẹ jọwọ ẹ fún mi níwèé ìrìnnà Bó ṣọkọ akérò bó ṣọkadà Bó ṣe rélùweè bó ṣọkọ ojú omi Tàbí bàlúù Mo fẹ lọ gbélu Èkó sẹ́ Mo fẹ dówòrò kín n ṣòwò tó pé Mo fẹ gbàdúmọtà kín n tàtà jèrè náà o Ìlú táa ti ń kọgbọn ta máa lá ò gbọn rárá Ìlú táa ti ń lówó lọwọ ta máa lá ò ní ṣéńjì lápò Bóo bá gbóko tóò bá gbọn Tóo wá dékòó tóo tún gọ o jàre Óò leè gbọn mọ láyéè rẹ Nítorí Èkó a kóni mọra ni Èkó ilé ọgbọn, ilé ẹkọ , ilé ìmọ̀ Mo fe rìn rìn àjò lọ sílùú Èkó Èrò yà ẹ máa bá mi kálọ Ibí ni wọn pè lékòó Èkó ni wọn pè níbí Ère mẹta tí ń bẹ nípìnlẹ̀ Èkó Ọkan lóò gbọdọ rìndìnjù Ọkan lóò gbọdọ sùẹgbẹ̀ Ọkan lóò gbọdọ ya múgùn léèyàn Mo ti rókun tó já sókè òkun Mo ti rọsà tó já sókè ọya Bóo bá wọnú Èkó tán O le sọnù sórí ìrìn Níbi tílé ti ń jọra wọn Ilé aláwò ṣí fìlà ńlá-ńlá Mélòó la fẹ kà nínú eyín adípèlé Tinú ọrún tòde ọjọ Bójú ò bá tẹ̀yìn ìgbẹ̀tì Ojú ò le tèkó láyé Jẹjẹ lọmọ Èkó ń lọ Ọmọ onílùu a tẹẹ jẹjẹ Àjòjì ní ń tẹlẹ yí gànràn-gànràn.
ÈKÌTÌ KETE
A kìí wà láyé ká mọ lárùn kankan Ìjà gboro n tìbàdàn Owó òde ni tọyọ ile Máṣu mátọ̀ ni tèkó ile Agídí wọn pọ lékìtì kete Ìlú tó lé téńté sórí àpáta ni Àpáta lodi ràbàtà tó yékìtì ká ò eee. Kete rian nílu Ẹkìtì Kẹ bámí gúnyán tó fẹlẹ́ Mo fẹ wá ṣọdún ewì níbẹun Léyìn ìkọlé ayé àti ìkọlé ọrun Ìkọlé Èkìtì ló tún kàn Ẹ jẹ ká rèkọlé Èkìtì Kẹẹ wá wàpáta paara Kẹẹ wá wòke ìgbemì Àfonífojì tí ń móyì kọ́ ni Kẹẹ wá wo koto gìrìwò náà Lẹyìn Èkó akéte Èkìtì kete náà ló kàn Ìran Èkìtì ló lòkè gbemì Òkè pàràbàtà dúró gó gò gó Òkè yìí máa wó lónìí Òkè yìí máa wó lọ́la Òkè yìí ò ní wó mọ́ Ó kàn ń jọ bẹẹ náà ni Ọmọ alápata sàpátadowo Ọmọ ẹkùn ọmọ ọwá ọmọ lókè méjì Tètè bán gúnyán Bámi wálà ìkàsì pẹlé ẹja yinyan Mo fẹ gòkè ìmèsì Mo fẹ gòkè àtà Mo fẹ dòkè àpáta Kin tó pa dà sí ìgárá òkè Èrò jẹ á rèkogòsì Níbi omiígbóná àtomitútù Ti gbé ṣọrẹ ara wọn Lẹyìn ìkọlé ayé àti ìkọlé ọrun Ìkọlé Èkìtì ló tún kàn an
ẸDÚNJỌBÍ
Èjígbèmí ni wọ́n pè léjìogbè Awo méjì méjì rè mò ń bá wọn dá o Ọ̀kan ǹ bá bí, èjì ló wọlé tọ̀ mí wá Búmi kí n bá ọ relé Kìmí kí n padà lẹ́yìn rẹ Èjíwùmí fò kìṣì bí ẹlẹ́gà òkè Èjíwùmí ará òde ìlẹ́gà Ẹdun ò gbọdọ̀ jẹran ẹ̀gà Ẹdúnjọbí ọmọ kúlegun Èjíwùmí a gbórí igi réte Táyélolú èjìrẹ ará ìṣokùn Ọmọ kẹhìndé gbẹ̀gbọn Wíní-wíní lójú orogún Èjìwọ̀rọ̀ lójú ìyá ẹ̀ Àìtètè jí onílé gbalé Èjìrẹ̀ mọlé olówó kò lọ Èjìrẹ̀ mọlé ọlọlá kò lọ Ò bẹ kìṣì, bẹ kẹṣẹ́ Ó bẹ sílé alákìsà Ó salákisà donígba aṣọ Níjọ téjìrẹ ti dáyé, èjìrẹ ò jalè rí Lójú olóko ni wọn tii mú tiwọn jẹ Èjìrẹ òrílà máa bọ lọdọ̀ mi Mo lépo nile, mo lẹwà lọdẹ̀ Ìyàwó mí lè jó jó jó Èmi náà mo le sọ̀dí wùkẹ̀ Èjìrẹ tí mo bí, tí mo jó jó jó Èjìrẹ tí mo bí, tí mo máyọ̀ọ yọ̀ Ẹni èjìrẹ wù, kó yáa níwà tútù Òṣónú ilé àwa ò bíbejì Onínúure ní ń bẹdun Ẹdúnjọbí, èjíwùmi Èjíwùmí èjìwánwálé Èjìrẹ ọ̀kín ará ìṣokùn Ọmọ ẹdun tíí ṣeré orí igi Ẹ sọ fáráayé kí wọn ó gbọ́ Ẹdúnjọbí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà Tí wọn ta pákúnṣirín epo lé lórí Èjíwùmí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà Tí wọn da jiwin-ni-jìn àkísà bọ̀ lọ́rùn Ẹdúnjọbí ò kíí sàkúnlẹ̀bọ òòsà Tí wọn ń fìlù kójó kó jáde Taló fẹ bíbejì kó nawọ́ ọọọ.
ỌNÀ ÌLU WA
Ojú òpó kìí di Ẹnu isà kìí ṣẹ̀jẹ̀ Bígba ojúlé tií wọlé ikan Bígba ọ̀nà tií wọlé àwúrèbe Bẹ̀ lojú ọ̀run ń dán gbin rin Ọ̀nà ọ̀run ń yọ̀ kù làlà Ọ̀nà tóóró yọ̀ wá látọ̀run Tí kò ní gbòǹgbò Tí kò ní ìtàkùn Tí kò ní ìdágbẹ́ Inú aláboyún ni wọn pè bẹẹ Ọ̀nà tóóró ló yẹgbó Ọ̀nà tààrà ló yẹ̀gboro Gbogbo ọ̀nà wa bíi abúlé onígò ló rí Gbogbo ọkọ̀ ń rìn jẹjẹ́ Gbogbo ọkọ̀ tó bá rìn jàùjàù Olúwa rẹ̀ á kòyọnu ni Nítorí ọ̀nà ìlú wa tí kò dán kòòrò Ihò ń bẹ lọnà kó kò kó Kòtò ń bẹ ní márosẹ̀ gìrìwò Òpópó ilé ò ṣeé dúró sí Ọ̀nà tààrà ò ṣeé gbà dọjà Àyàfi ká máa pẹkọrọ Bíi aláàmù lébàá ògiri Omi ń yalé Ọ̀gbàrá ń yàgboro Kọ̀ǹkọ̀ àtàkèré ń fọhùn lọọ̀dẹ̀ Ilé ayé ni Mẹkà ń gbé Òpópó Mekà mọ roro Bíi díígí aláwòtúnwò Lọjọ wo nìjẹ̀bú Igbo fẹ dìjẹ̀bú òde Lọjọ wo nigbó gan án fẹ dìgboro Lọjó wo lọ̀nà tóóró fẹ di márosẹ̀ Àtolóṣèlú àtẹni wọn ṣèlú lé l'órí Àláà mi ò gbọdọ̀ kú Àláà mi ò gbọdọ̀ kútà Mo fẹ jí kí gbogbo ọ̀nà ti lé tìróò Mo fẹ jí kéku ó máa ké bíi eku Mo fẹ jí kẹyẹ ó máa ké bíi ẹyẹ Mo fẹ jí kọmọnìyàn ó máa fọhùn bíi ènìyàn.
ỌMỌ YORÙBÁ
Lámi lámi ní ń ṣeré agbami Àfòpiná ní ń ṣeré ògunná Ọ̀gá ni káún láwùjọ òkúta Egungun bíi eyín ò sí lágbárí Nínú ayé yìí sẹ́ Ògbóǹtàrigì nilẹ̀ adúláwọ̀ Àràbà niwá nílẹ̀ẹ Nàìjá Láàrin gbogbo adúláwọ̀ to ku Ìran kan ń bẹ nílẹ̀ẹ Nàìjá Tí wọ́n tún gba sàdáńkátà Ọ̀kan ṣoṣo àràbà tí ń migbó kìji kìji Nìran Yorùbá jẹ nígboro Nàìjá Ọ̀gá niwá, aṣewẹrẹ jayé Alágẹmọ ni wá, Gbogbo aṣọ ìgbà ló bá wá lára mu Ilẹ̀kílẹ̀ tí Yorùbá bá jásí A gbóúnjẹ fẹ gbẹ a tún gbàwo bọ̀ A gbayì ní tìbú tòòró ayé ni Nínú ìmọ̀ wọn mọ̀ wá Nínú ọgbọn wọn gbọwá Nínú ìfaradà a rọkú Nínú ìbáṣepọ̀ a gbayì Àkìtàn niwá, ara wá gbẹ̀gbin Abẹrẹ niwá a ò lókùn nídìí Òkìtì ọ̀gán niwá, gbogbo ọ̀nà ló wọ̀lú wa Ọmọ oníyọ̀ tí ń jàtẹ́ Ọmọ ẹlẹran tí ń jeegun Òkèlè ń bẹ nílẹ̀, a ò rọbẹ̀ fi kàn Amúkùn-ún niwá, Ẹrù ti wọ láti ọwọ àwọn àgbààgbà Ọmọdé ilé là ń dẹ̀bi ọ̀rọ̀ rú o jàre Àbí kí la tún fàgbà ṣe tó ju káà fi rẹmọdé jẹ lọ Atẹgùn tín gbanú akéwì Ni mo ní kí n fẹ síta Ò lè ṣọyẹ, ó lè ṣooru Ṣé òtútù rẹ̀ ò mùu yin jù Ṣé oru rẹ̀ náà o máa pọ̀ lápọ̀ju
TÌRÓÒ Ọ̀BẸ̀
Ìgbàgbé ṣemí mi n ò lé tìróò Mo jáde tán, ojú wá rí gbaguẹ Ojú mi ò dára lágbárí Kò tún dára lára ẹlòmíràn Gbogbo ọwọ tí ń ròde ọ̀fún ẹ farabalẹ̀ Mo fẹ gbàdúrà ìdákẹjẹ́ Ẹní bá ń wíjọ á wúkọ́ Ẹní bá ń ṣàròyé á sín Ẹní bá ń pariwo á gbèsúkè Ìrìnàjò tí a fẹrìn a dọfun tòló. Kí a tó sebẹ̀, kó tó ta sánsán Ojú ní láti rí nǹkan Bó bá ṣerọ ni mo pá Ẹ bèrè lọwọ àlùbọsà Ẹ wojú ọbẹ̀ kẹẹ múyán Èsì ń bẹ lọwọ alásè Ẹmí tí ò jata, ẹ̀mí yẹpẹrẹ Ojú la ó ti mọbẹ̀ tí ò lépo Epo ọbẹ̀ gangan ni tìróò Bí ẹ bá sewébẹ̀ tí ò gbé ẹ̀gúsí. Ojú ọbẹ̀ ọ̀hún fọ́ Bí ẹ bá sewébẹ̀ tí ò lépo Ojú ọbẹ yẹn ò ní tìírò Bí ẹ bá fẹ káta ó rojọ́ Ẹ lọ ata ní ọlọ Kí ẹ gbáa sínú u pákúnṣirín epo N ò wá polówó magí níbí Ẹ kórú dà sọ bẹ̀ Bẹ ò rírú, ẹ wógìrì lọ Adití á gbóhùn ata. Afọjú á mọ̀ pérú wà lọbẹ̀ Ẹ̀ fàlùbọsà sọbẹ̀ Kóúnjẹ ó ma jóògùn Kóògùn ó ma jóúnjẹ Bí ẹ bá ń ròde ọ̀fun. Ẹ dákun ẹ má jàtẹ́ Ẹni ń jẹun tí ò lọsà Àtẹ ní ń jẹ Ọ̀lásúnkànmí ń se yátì lọbẹ̀ Ẹ wojú ọbẹ̀, ẹ tọbẹ̀ wòòòò
Ọ̀BẸ TÓDÙN
Àìdùn ọsàn ni n lè mu méjọ̀lá Bọsàn bá dùn n ó pada mugba Àìlówó lọwọ́ Lọbẹ̀ yí dùn kò wẹran Àìlówó lápò. Lọbẹ̀ yí dún kò wẹja Bówó bá ń bẹ lọwọ́ Tí kúnkúṣì bá ń bẹ lápò Ká sebẹ̀ tó pójú owó Bẹja ti ń jùrù lọbẹ̀. Kẹran ó máa tinú ẹran jáde Bí ẹ bá ń wọbẹ̀ tó dùn Pẹ̀lú òórùn tó le jí òkú ní pópó Pẹ̀lú adùn tó le mú ni járun Nílẹ̀ káàárọ̀ o ò jíire Níbi tí a ti ń fitan erin jẹyán Níbi ti a ti ń fitan ẹfọ̀n jọkà Pẹ̀lú ọbẹ̀ tí kò ṣe é fọwọ rọtì Ẹ pe ééyọ wá kó wá dási Ẹ pẹ̀fọ wá kó wá dárà Ṣe ẹ ti jewé ròkó Àbí ẹ ti jọ̀mùnú kókò Bẹ ò bá mọ̀gbó Ṣebí ẹ màbáláyé Ó yẹ kí ẹ le mọ ṣọkọ Ẹ mọ ṣaláì mọṣápá Nìtorí a máa toro mọyán Ẹfọ ni márúgbó ṣányán Ọ̀mọ ìyá efinrin Ewúro ọbẹ̀ Gbẹ̀gìrì ń bẹ lápá kan ọ̀tún Gbúre ń bẹ lápá àlàfíà mi Tẹ̀tẹ̀ kìí tẹ láwùjọ ẹ̀fọ́ Méjì lamúnútutù Bí a ti ń rí funfun Bẹẹ la ń rí pupa Níbo ni eéyọ wà ná Eéyọ́ nilá Eéyọ́ lọ̀runlá Eéyọ́ nìlasa. Ewédú òun ẹkù Ṣebí ẹ ti lá lúrú rí Ṣé ẹ ti jàpọ̀n náà rí Ọlásúnkànmí ń se yátì ẹ ò mọ̀ Òkèlè ń bẹ nílé. Ọ̀bẹ̀ ń bẹ nílẹ̀ Yorùbá Gbogbo wa la mọ̀ bẹ́ẹ̀.
Nípa Oǹkọ̀wé
Abdulkareem Ajimatanraẹjẹ jẹ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Èkó. O lọ sí ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ àti girama ní ìpínlẹ̀ Èkó ó sì kẹ́kọ̀ọ́ gboyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ (B.a Yorùbà) ní Ifáfitì Ọlábísí Ọnàbánjọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Oǹkọ̀wé, Olùkọ́, Oníṣẹ́ ọwọ́, Alátinúdá, atọ́kùn ètò lóríi rédíò àti tẹlifísàn ni Ọ̀gbẹ́ni AbdulKareem.
Baba ẹ kuu ohun oluwa yoo maa fun un yin se ooooo
E seun gan mr dollar
Ẹ kúuṣẹ́ takuntakun. Gbogbo ọ̀nà ni ẹ̀ ngbà láti ríi pé àṣà àti èdè Yòrùbá kò parun. Ọlọ́run á túnbọ̀ máa ràn yín lọ́wọ́
Amin oooo.
ati eyi na ooooo