Olú ti d'ẹ́nu ní ìbúǹbú
Ó di dandan kó jẹun.
Ebi kìí wọnú kọ́rọ̀ míì ó wọ̀ ọ́
Òrìṣà bí ọ̀fun ò sí tipẹ́tipẹ́
Joojúmọ́ ní ń gbẹbọ lọ́wọ́ ẹni.
A dára má jẹun kan ò sí.
Ebi ọ̀gàjà f'ọwọ́ mẹ́kẹ́
Bó bá wọra tán ipá a pin.
Bó bá ranjú toto m'ọ́ni
A sọ̀ọ̀yàn di dìndìnrìn.
Èèyàn ò lè r'írú ọbẹ̀ yìí
Kẹ́nu ó má po itọ́ láíláí.
Háà! Ń ó jàkàṣù ẹ̀bà mẹ́fà.
Bó sì jẹ́yán funfun lẹ́lẹ́ ni mo rí.
N ó jẹ tó mẹ́ta bí ò bá tóbi jù.
Àgàgà kí n r'ọ́kà tó fẹ́lẹ́ bí etí
Àbí láfún to ń yọruku lálálá.
Bó sì jẹ́ sèmó tí kò lẹ́mọ́.
Pẹ̀lú ọbẹ̀ tó gbámúṣé yìí
Tìnrín ni yóò máa lọ lọ́fún.
Béèyàn bá jẹ atiláawí tán
Tó wá rọra rí atẹ́gùn ráńpẹ́
Téèyàn ríbi fẹ̀yìn lélẹ̀ sí
Tí oorun rọra mú ni lọ yẹ́ ẹ́
À-sùn-dọ́kàn loorun ọ̀hún máa jẹ́.
Oúnjẹ kúkú lọ̀rẹ́ àwọ̀ ó jàre
Bọ́bẹ̀ bá dùn l'étè, èèyàn ó ṣọkà jẹ
Bí tansánsán ọbẹ̀ bá dára nímú
Béèyàn ó fẹ́ jẹun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀
Ó di dóólè ká f'ìtọ́wò mọ dídùn rẹ̀.
Àtẹ́lẹwọ D’igi Àlọ́yè
Ẹni ńlá ní ń ṣohun ńlá
tó bá mọyì èèyàn
Ó tọ́ ká lù ú l'ọ́gọ ẹnu
Ó tọ́ ká lù ú l'ọ́gọ ẹnu
Ẹni tó lè dènà fún ni k'ẹ́rù
Ó dájú ó lè ja'gun ju'ni lọ.
Àtẹ́lẹwọ́ ti dàràbà láàrin igi
Àtẹ́lẹwọ́ ti dòṣùpá ọjọ́ kẹrìnlá
Tí ó ṣe é dawọ́ bò láíláí
Ó ti d'erin lákátabú nínú igbó
Ó ti di peregun etí odò.
Àtẹ́lẹwọ́ ń pitu méje t'ọ́dẹ ń pa nígbó.
Níbi ká gbédè àt'àṣà lárugẹ
Kánhún niwọ́n láàrin òkúta.
Níbi ká ṣe kóríyá f'áwọn Agbédègbẹyọ̀
Kò sẹ́ni ó le bá yínmíyínmí wọn dumí.
Agara kì í dá Olódùmarè láíláí
Agara kò ní dá gbogbo yín.
Eku k'éku kì í rùn kó b'orí ifọ́n.
Ọ̀tá kò ní rí i yín gbé ṣe
Ẹnìkan kìí rídìí ọmọ onígèlègélé
Aráyé ó ní r'ídìí yín láṣẹ Wáídù lókè.
Nípa Òǹkòwé
Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ni ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.
Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Orishirishi Kitchen