Ọdún tí ọwọ́ tẹ Ẹ́fáansì ajínigbé

Ọjọ́bọ̀. Ọjọ́ kẹ̀jọ, Oṣù Agẹmọ.

Gbogbo bí wọ́n ṣe nkígbe níle Kejì, hun ò kúkú yọjú. Wọ́n ni àgbà to jìn sí kòtò, o kọ́ ará ‘yòókù lọgbọ́n. Irú igbe bayìí kọ ni Àlàbí gbọ níjeèló to t’ẹsẹ̀ b’ọsẹ̀ tó ní ò n lọ bawọn làjà nibi àwọn alákọrí gbe ń pín owó tí Alága kánsù gbé fún àwọn ọ̀dọ́? Àwọn to lọ bẹjú wo ni Ilé ìwòsàn Ìleralọrọ̀ ni iwọ̀n bándejìi tí wọ́n fi wé lawàní fun kò niye.

Ẹtì. Ọjọ́ Kẹsán, Oṣù Agẹmọ.

Bí mo bá ti rántí èyí to pe ara rẹ̀ ni Dafídì hun, ẹ̀rín a sì maa pamí. Ayee àbí kinni o pe orin òfò to kọ. Kò fẹ́ dìsáinà, ko fẹ́ fẹ̀rárì. Họwù, K’eyàn sì maa tan ara rẹ̀ jẹ! Orin rẹ̀ yìí kò yẹ níbi gbogbo. Nibi a gbe ń ta díráfutì lánàa ni mo ti gbọ́ pe Lábísí fi Àlàbí le bá Remọ́ndì alayọkẹle lọ. Ni Lábísí ti Alabi ti tori rẹ̀ gba kopuretifu nijelo. Ọ̀dẹ̀ Ìbàrìbá àdúgbò wọn ni wọ́n pe o ri nibi tó jókòó sí lóòrọ̀ tí ń sukún.

Àbámẹta. Ọjọ́ kẹwàá Oṣù Agẹmọ.

Kínní mo tii sọ tí Olóyè fi bú sẹ́kún? Pe mo rí ọmọ wọn nibi to ti ń fi ìwé ile wọn ta tẹ́tẹ́? Ẹni ẹlẹni ti ọmọ rẹ gún lọbẹ lori Náirà Bẹẹ̀tì ńkọ́? Ọjọ́ rèé bi àná tí Wàsíù n sọ fún wọn níle ẹmu pe ki wọn jẹ ọmọ naa kàwé tàbí kí o k’ọṣẹ́. Pe ọmọ tí a ò bá kọ́ a maa gbe ilé tà bo dọ̀la. Ṣèbí niṣe ni olóyè lááli rẹ. Ká ṣà máa ṣe dáadaa.


‘Gbénga Adéọba k’ẹ́kọ gboyè ni Fásitì Ìbàdàn. O kọ àrokọ yìí ranṣẹ lati ìlú Èkó.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *