I
Ènìyàn bí reluwé ni Alàgbà Sálù Jẹ́nwítèmi; kò ṣeé kọlù, bẹ́ẹ̀ni kò sì gbọ́dọ̀ kọlu ènìyàn. Kì í see wípé ó jé ènìyàn kan tí ó lágbára tó bẹ́ẹ̀ ní ti wípé ká ku ẹ̀sẹ́ tàbí ká lu ènìyàn, ṣùgbọ́n ó mọ àwọn ohun àṣírí àti májẹ̀ágbọ́. Àwọn ènìyàn tí ó gbọ́n ní ìlú a máa bọ̀wọ̀ fún un. Olú, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tuntun, ń bẹ nínú ilé, ó ń tún ilé se. Ó ń fẹ́ kí ọ̀gá òhun ri bí òhun se já fáfá tó. Ọ̀rẹ́ ọ̀gá rẹ̀ tí ó bá a wá isẹ́ yìí–Alàgbà Omílànà ní Ọmí Àdìo–ti wí fún un wípé isẹ́ náà kò gbọdọ̀ bọ́ mọ́ ọ lọ́wọ́.
Alàgbà Sálù Jẹ́nwítèmi kò sí nílé. Ó ti lọ gẹ́gẹ́ bíi ìṣe rẹ̀. Ó máa ń lọ sí ibi ìpàdé kan tàbí òmíràn nígbà tí ohunkóhun kò bá dáa dúró sílé, sí inú yàrá ìkàwé rẹ̀. Wọ́n sì lè kó àwọn ìpàdé wọ̀nyí wá bá a nílé. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀sẹ̀ tí ó lọ, àwọn mẹ́rin ni Alága Adésọjí rán láti wá bá ọ̀gá Olú ṣe ìpàdé bòńkẹ́lẹ́: Ìyáàfin Morẹ́nikẹ́ Ìránṣẹ́lowọ́, Àláájá Bọ́láńlé Àfòmọ́, Díákónì Jẹ́fútà Jésùtóyìnbó, àti Ààrẹ Ọ̀jẹ́níyì Badà. Gbogbo won jẹ omo ẹgbẹ́ Ọlọ́pẹ. Wọ́n ń fé láti mọ ọ̀nà tí eni tí ẹgbẹ́ wọn fà kalẹ̀ kò se ní lulẹ̀ nínú ìdìbò tí ń bọ̀. Ti àwọn olóṣèlú kọ́ ni ọ̀gá Olú bá jáde ní tòní. Ó ti lọ ibi ìpàdé tí wọ́n ń ṣe láti kó owó jọ fún àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ kòṣeégbé tí wọ́n jí gbé lọ́nà Abuja.
Olú ń ronú wípé: “ilé náà kò tóbi jù báyìí lọ. Bí mo bá tètè se tán, mo leè wo bọ́ọ̀lù Arsenal ti irole yi. Misiita Bayọ̀ yíò ti tẹ àwọn ayò tí ó leè jẹ síta ní orí Twitter báyìí.” Nǹkan ẹyọ kan yìí náà ni ó ba Àjàó Olú jẹ́: tẹ́tẹ́ títa. Olú ń bá isẹ́ rẹ̀ lọ, ó ń gbọn àwọn àga aláwọ tí wọ́n tò sí yàrá ìgbàlejó nù. Àwọn kàléńdà àtijó oríṣiríṣi wà ní ara ògiri. “Bàbá at 70” tí àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n ọ̀gá rẹ̀ ṣe fún bàbá wọn. Láàrin àwọn kàléńdà wọ̀nyí ni ti àjọ̀dún Kínní àwọn ẹgbẹ́ Kòṣeégbé—gbogbo wọn wọ aṣọ Up Nepa nínú àwòrán tí wọ́n fi síi. kàléńdà àwọn àlùfáà ìjọ CAC kan wà ní ègbẹ ti àwọn ẹgbẹ́ Kòṣeégbé. Wòlíì Ọbádáre nìkan ni Olú dá mọ̀ nínú wọn. Olú tún kàléńdà àjọ̀dún ọdún Kínní ti ẹgbẹ́ Kòṣeégbé yí wò. O wipe, “Kòṣeégbé. Ọ̀rọ̀ burúkú t’òhun t’ẹ̀rìn. Ǹjẹ́ àwọn ará ibí kò ní yí orúkọ ẹgbẹ́ padà báyìí?”
II
Ní yàrá ìkàwé ọ̀gá rẹ̀, Olú rí àwọn ìwé tuntun oríṣiríṣi ní èdè Yorùbá àti ti èdè òyìnbó. Àwọn ìwé Fágúnwá pẹ̀lú ti Oládẹ̀jọ Òkédìjí. Adébáyọ̀ Fálétí, Akínwùmí Ìṣọ̀lá àti Láwuyì Ògúnníran wà ní orí séèfù kan. Àwọn ìwé wọn f’ara ti àwọn ìwé Fọlàké Àrẹ̀mú àti ti Àrìnpé Adéjùmọ̀. Ìwé àwọn oǹkéwí ọmọ Nàìjíríà oríṣiríṣi kún séèfù míràn pẹlú àwọn ìwé onímọ̀ ní oríṣiríṣi. Arts of Being Yoruba, ìwé Ọ̀jọ̀gbọ́n Adélékè Adéẹ̀kọ́ ń bẹ lórí tábìlì pẹ̀lú ìwé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Karin Barber kọ nípa oríkì. Olú dá àwọn ìwé náà mọ̀. Òun ni ó bá ọ̀gá rẹ̀ já wọn kúrò nínú àpò ìwé ńlá tí wọ́n fi kó wọn ránṣẹ́.
Àwọn ìwé míràn tí kìí ṣe ìwé tí wọ́n ti tẹ̀ ń bẹ lórí tábìlì yí–àwọn dáyáàrì àtọdúnmọ́dún àti bébà funfun oríṣiríṣi tí wọ́n fi okùn àti irin tẹ́ẹ́rẹ́ dì papọ̀. Olú mọ̀ wípé ọ̀gá òun ń kọ àwọn ìwé ìtàn kéékèèké kan lọ́wọ́ tí ó fé fi ránṣẹ́ sí wọn ní ẹgbẹ́ Àtẹ́lẹwọ́ fún ìdíje ìwé kíkọ kí ọdún tó parí. Alàgbà Sálù Jẹ́nwítèmi ti ń jẹ ọ̀rọ̀ náà lénu fún bíi ọjọ́ mélòó kan báyìí. Ṣùgbọ́n Olú kó tíì rí àwọn ìwé náà. Ó ṣí ọkàn nínú àwọn ìwé ìtàn ọ̀gá rẹ̀ wọ̀nyìí. (Kò tíì fẹ́ sí dáyáàrì kànkan báyìí) Kálámù dúdú ni wọ́n fi kọ nǹkan inú wọn. Ó ń ka ojú ìwé Kínní èyí tí wọn kọ “Ìtàn àròsọ kéékèèké” sí níwájú. Àwọn àkòrí oríṣiríṣi ní Olú ń rí: Ìṣípayá; Àwọn Ọmọ wa; Deleuze and Guattari, tàbí orúkọ ìgbàlódé fún àwọn ọmọ ìbejì…
Ojú ewé tí wọ́n pè ní “Owó Èlé” ni Olú lọ sí
Owó Èlé
Títí àti Lọlá jọ ń sọ̀rọ̀ ní yàrá ìgbafẹ́ ilé ìtura Kògbagídí. Wọ́n ń fi ọtí wáìnì sára, wọ́n ń wo ère kan ní orí ẹ̀rọ ńlá amóhùnmáwòrán tí wọ́n gbé sórí tábìlì ńlá kan tí wọ́n fi ọ̀dà pupa kọ “tọ́jú èmi ẹ” sí lara. Títí ń sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ tí òun fi pẹ́ dé. “Ǹjẹ́ o rántí Fémi kan báyìí tí Àjọkẹ́ ń fẹ́, èyí tí ń ṣiṣẹ́ tísà ní Lúùkù mímọ́.” Lolá fèsì, ó ní “ǹjẹ́ kìí ṣe ẹni tí Àjọkẹ́ tìtorí rẹ̀ gba owó jọ nínú ẹgbẹ́ wa lọ́jọ́ sí.”
“Bẹ́ẹ̀ni. Ìfẹ́ a máa pani bí ọtí líle. Mọ rí Fẹ́mi òhún pẹ̀lú ẹlòmíràn níhìn-ín ní ìjẹta.”
“Hà, ǹjẹ́ o sọ fún Àjọkẹ́.”
“Bẹ̀ẹ́ni. Mo pàdé rẹ̀ lọ́nà ní ó jé kí n pé dé.”
“Dákun kí ló wí”
“Ó fi igbe ta. Ó ní kínni wọ́n wá se. Mo sì fi ọkàn dáa lóhùn wípé wọ́n wá ṣe ìṣojí ni.”
Ẹnìkan ń kan ilẹ̀kùn níwájú ilé lọ́hùń…
‘Gbénga Adéọba k’ẹ́kọ gboyè ni Fásitì Ìbàdàn. O kọ àrokọ yìí ranṣẹ lati ìlú Virginia ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.