A dúpẹ́ fún àwọn ohun tí ẹ fi ṣowọ́ sí wa fun àtẹ̀jade Kínní. Àtẹ̀jade kejì yíò jẹ́ ìfisorí fún àwọn àgbà oǹkọ̀wé mẹ́ta tí wọ́n papòdà láì pẹ́ yìí. Àwọn ni Alàgbà Adébáyọ Fálétí, Òjọgbọ́n Akínwùmí Ìsọ̀lá, áti Olóyè Ọládẹ̀jọ Òkédìjí.

A ń fẹ́ ewì, ìtàn, àti ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ ni èdè Yorùbá. Wọn lé je ìfisorí fún èyíkéyìí nínú àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí, wón sì lé dá lórí ohun míràn. Ohun tí ó jẹ wá lógún ni ẹwà èdè àti ìgbé lárugẹ àṣà àti èdè Yorùbá.

A sì tún ń fẹ́ àwọn àwòrán, aáyan ògbufọ̀, àti rìfíù ìwé lóríṣiríṣi.

Gbogbo ohun tí ẹ bá fi ṣowọ́ gbọ́dọ̀ wà ní èdè Yorùbá. Ẹ le ri ẹ̀rọ ìṣàmì s’édè ní bí – http://blog.yorubaname.com/keyboards/

Ẹnikẹ́ni (àgbà, ọmọdé, ọkùnrin, àti obìnrin) ni ó lè fi èyíkéyìí nínú àwọn tí a dárúkọ wọ̀nyí ṣowọ́ sì wá.

Ẹ fi wọ́n ṣowọ́ sì atelewo.org@gmail.com

December 21 ni a yíò ká ṣẹ̀ ètò ìgbàwọlé yìí nílẹ̀.

Ìtọ́ka

  1. Ọ̀rọ̀ Olóòtú: Ìtọ́wò Àkójọpọ̀ Àtẹ́lẹwọ́
  2. Ìlànà fún Ìgbàwọlé: Àtẹ̀jáde Àtẹ́lẹwọ́ Apá kejì
  3. Ẹ̀rọ Ìránsọ | Kọ́lápọ̀ Ọlájùmọ̀kẹ́
  4. Ojúlarí | Rasaq Malik Gbọ́láhàn
  5. Nítàn kí o tó tán | Malik Adéníyì
  6. Lẹ́tà: Ọ̀rọ̀ Kẹ̀kẹ́ | ‘Gbénga Adéọba

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *