Akéwì

Èmi lakéwì, mo lóyin létè. Mo kẹ̀tẹ̀ǹfẹ̀ ìmọ̀
Mo le sọrọ́ dòótọ́ bí n bá fẹ́! Bó wù mí, mo le sòótọ́ dòbu
Ajá akéwì kìí gbó láì rí. Àgbò akéwì èí kàn láì sí nǹkan!
Ọ̀gbun ninú Akéwì, ó gbodó, ó gbọlọ, o tún gba ládugbó
Akéwì lóju lóri, ó lójú lẹ́nu, ó tún lójú ní kọ́lọ́fín ara!
Ajẹ́ l’akéwì láwùjọ, ó le fẹnu pọmọjẹ kò métè ṣòfò ọ̀ràn kalẹ̀
Akéwi láfẹ́fẹ́ tí ń fẹ́ lẹ́lẹ́ kárí ilé, kári oko,
Òun l’ẹ̀fúùfù tí migi oko jìajìà.
Àǹjọ̀nú lákéwì, ó lójú lu kára bí ajere.
Ayékòótọ́ lakéwì tí ń kìlọ̀ ìwà!
Akéwì ní ń rí Sàmúúẹ̀lì tí ń lẹ̀dí mẹ́lẹ̀ nírònà Òṣíẹ̀lẹ̀
Tó e dórí Súfí tí ń fa Sẹ́lí láṣọ l’Ásùnnàrá
Bẹ́ bá r’Ákéwì, ẹ fún lówó lásọ
Ẹ f’Ákéwì lọ́ṣọ̀ọ́ tó dọ́ṣọ̀, kẹ ba lé bọ́ lọ́ṣọ́ akéwì lọ́nà ẹ̀sọ̀!
B’ákéwì bá ń ké, ká yáa tẹ́tí ló dára.
Akéwì lóju lóri, ó lójú lẹ́nu, ó tún lójú ní kọ́lọ́fín ara!

Ayée Kòró

Ayé ń yí, ayé ń lọ
Gbogbo wa là ń báyé yí
Ayé ti dòbírípo
Ìgbà sì tí dohun ìtàn
Itan ajá tí doúnjẹ fún lèmọ̀mù
Lèmọ̀mù nìkàn sì kọ́
Gbogbo jànmọ́ọ̀ abúlé wa ni
Léeridà ò lówó lọ́wọ́
Katikíìsì ò ní kọ́bọ̀ lápo
Aṣọ gẹrẹjẹ wá ń kọlu aṣọ gẹrẹjẹ
Asúnkàákàá ó fẹ́ sún mọ́
Alábẹ́rẹ́ ó ríhò tọ̀
Èélà tó là ò lójú
Ọmọge gúnmu, ọmú gbẹ
Ìdí a sò ìlẹ̀kẹ̀ mọ́ ò sì
Àtètè àtìbàdí wá kan bí ìbo
Òkú ń kú,
Alààyé ń jòkú
Jòkú jààyé ló pọ̀jù ṣá
Nínú ikú laráyé wá ń jẹ
Ẹkún gbalé gboko
Ìlú dìgbẹ̀
Ìgbẹ́ wá dígbo
Sọgbó dilé kan ò sí mọ́
Sààtàn dọjà ti rẹ̀yìn Ìgbẹ́tì
Gbélépa, gbọ́nà ti pa
Òkíríbítí gbégi dánà
Ológòmùgomù wọlé dé
Kòrónà wọ̀lù
Kárìnkápọ̀ wàyìí,
Ikú níi mu pani
Láyé Kòrò, òòṣà ọjà a bọ̀já lémú
Lágúnọ̀gọ̀ èègun tí sín pani.
Láyé Kòró, lá dáṣọ lémú, n lá dàdìnkanlẹ̀ bí ìrẹ̀

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí ìlú Abẹòkúta ni Ọ̀mọ̀wé Ṣégun Ṣóẹ̀tán í ṣe. Ó jẹ́ olùkọ́ àṣà àtí lítíréṣọ̀ Áfíríkà ní fáfitì ti Pennsylvania ní orílẹ̀-èdè Amẹ̀ríkà. Ó ti ṣiṣẹ́ olùkọ́ ní fáfitì Ìbàdàn sẹ́yìn kí ó tó dí akẹ́kọ́ọ̀ ní Fáfitì ti Winsconsin-Madison níbi tí ó tí kàwé gboyé àgbà (PhD). Ọmọwé Ṣóẹ̀tán tí kọ àwọn ìwé lítíréṣọ̀ Yorùbá bíi: Oyin Inú Àpáta, Eré Orí-Igi, àtí Eré- Egéle. Akéwì àti ayàwòrán ní i ṣe pẹ̀lú.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *