Kíkorò Ewúro

Gbogbo ènìyàn ló mọ̀ pé
Adùn ló yẹ kí ó gbẹ̀yìn ewúro
Ṣùgbọ́n kò sẹ́ni tí ó ń
Bèrè nípa kíkorò tí ewúro ń korò.
Ilà ń mú ojú gún régé, ṣùgbọ́n 5
Kò sẹ́ni tó ń bèrè nípa títa ríro rẹ̀.
Elédùmarè ló fi àkókò pín aye é
Kò sì sẹ́ni tó mọ̀dí abájọ
Ohun tí a ṣá à mọ̀ nipé
Àsìkò ni gbogbo nǹkan láyé; 10
Àsìkò tí ẹ̀dá ń lówó lọ́wọ́
Àsìkò tí ẹ̀dá ń láṣọ lára
Àsìkò tí ẹ̀dá kò ní ní nǹkankan mọ́.
Ṣé ọbẹ̀ tí ó bá jiná layé ń jẹ
Ọwọ́ epo sì ni ayé ń bá ni lá 15
Kò yẹ kí ẹ̀dá gbàgbé àná
Ipò tí o bá ti bá ara rẹ lónìí
Múu lò dáadáa
Ó dáa, kò dáa
Ó ń bọ̀ wá dìtàn lọ́la. 20

Ìwọ nìkan kọ́ o

Wá ná!
Ọ̀rẹ́ẹ̀ mi!
Ṣé o rò pé ìwọ nìkan ni gbogbo nǹkan dálé lórí ni?
Ṣé o rò pé orí rẹ ni ayé ti bẹ̀rẹ̀ ni?
Àbí o rò pé orí rẹ ni ayé pin sí? 5
Ta ni ó gan àn?
Bí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀
Ilé tìrẹ ló dára jù
Ọ̀nà rẹ ló sunwọ̀n
Iṣẹ́ tìrẹ ló gbé pẹ́ẹ́lí 10
Ìwọ nìkan lo ò ní ìṣòro
Bí ó bá tún wa nínú làásìgbò gan.
Níṣe ni wà á fẹ̀ ẹ́ lójú
Igi kan kò lè di igbó
Ènìyàn kan kì í jẹ́ ọjà 15
Rántí pé ìwọ nìkan kọ́ ni gbogbo nǹkan dálé lórí
Kò sí olóríire ayérayé
Olóríire àsìkò ló wà.
Wọ́n ni àwọn náà fẹ́ kúrò nílẹ̀ yìí

Lálẹ́ àná ní ìlú yìí

Wọ́n ní ìlú yìí kò dára
Pé ìlú yìí kò sunwọ̀n
Orin kan ṣoṣo ni ó wà lẹ́nu wọn
Àtijẹ-àtimu ti dọ̀ràn
Àlááfíà ti dohun wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún 5
Wọ́n ni àwọn náà fẹ́ kúrò nílẹ̀ yìí
Wọ́n fẹ́ lọ bá àwọn òyìnbó gba yìnyín sára
Wọ́n fẹ́ máa jẹ ohun tó wù wọ́n
Bẹ́ẹ̀ni, ìlú yìí kò dára
Bẹ́ẹ̀ni, ìlú yìí kò sunwọ̀n 10
Ta ni kò yẹ kí ó máa gbàgbé ọ̀rọ̀ àná
Pé atẹ́gùn tí ń dààmú ológì
Ó ti sọ ayéé elélùbọ́ dòfo ò!
Ìyán mú nílé, ó mú lóko ni
Ṣèbí ó mọ̀ nípa ará-ilé rẹ 15
tí ó lọ ní ìjọsí
Tí ẹ ò tí ì gbúròó rẹ̀ dòní
Nínú ìròyìn ṣèbí à ń rí wọn;
Àwọn ènìyàn dúdú tí ń tara wọn
Féèbó ní Líbíyà, 20
Àwọn tí ń kú sí òkun ńlá
Kí wọ́n tó délùú ‘olóyin’
Àwọn tí wọ́n ti sọnù sí Sàhárà
Àwọn tí wọn ti tà sí oko aṣẹ́wó
Ṣé igbó tí ìwọ náà fẹ́ torí bọ̀ nìyí? 25
Ẹ̀mí kò láàrọ̀
Ibo ni kò ti sí ewu?
Ṣe titi bí wọ́n ṣe ń pa àwọn ènìyàn dúdú
Ni kí á kọ́kọ́ rò tàbí
Iṣẹ́ tí kò sí lọ́hùn-ún ni tàbí 30
pé kò sí ohun tí á jẹ́ tìrẹ ní dúkìà lọ́hùn-ún ni
Jẹ́jẹ́ layé gbà
Kò dìgbà tí ó bá kúrò nílùú rẹ
Kí ó tó rí tì ẹ ṣe o
Kò dìgbà tí ó bá pàdánù ẹ̀ẹ̀mí rẹ 35
kí ó tó là
Ẹ jẹ́ kí á tọ́jú orílẹ̀-èdè yìí
Kí ilé ṣe é dúró sí
Ẹ jẹ́ kí á tú ìlú wa ṣe
Ohun tí a bá fi sílẹ̀ ni 40
Ẹnu ewúrẹ́ ń to
Olóṣèlú, ìbàjẹ́ ìlú yìí ti tó
Aládùúrà, àdúrà nìkan kò le ṣe é
Ará-ìlú, ọ̀rọ̀ yìí kan yín
Ẹ tú ìlú yín ṣe 45
Ẹ paná orí òrùlé yín, ọjọ́ ń lọ.

Nípa Akéwì

Ìyanuolúwa Adénlé jẹ́ akéwì àti olùkọ̀tàn tí ó wá láti ìpínlẹ̀ Òsun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ó jẹ́ akéwì tí ó ti kọ onírúurú ewì ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, èyí tí wọ́n sì ti hàn (tàbí tí ó kù díẹ̀ kí wọ́n hàn) ní Kalahari Review, Africanwriter, Empty Mirror, The Hellebore, Onejacar àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ó máa ń se àgbéyẹ̀wò àwọn ohun tí ó ń lọ nínú àwùjọ tí ó wà. 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *