ÒWE

Ọsán já ọrún d’ọ̀pá.

 ÀKÍYÈSÍ

*Ọsán:- ohun èlò tí a fi ún se ǹkan ìjà tí a mò sí ọfà
*Ọrún:- orísi ọ̀pá kan tí ó seé ro sí òtún tàbí sí ósí, tí kò sì leè kán, bí óti lè wù kí a róo tàbí kí a tẹ̀ẹ́.

ÀLÀYÉ NÍ KÍKUN

Ọsán jẹ́ oríṣi okùn kan tí àwọn baba nlá wa fi máa ń ṣe ohun tí wón fi ń ta nkan ìjà tí a mò sí ọfà.
Ọrún ni ọ̀pá tí wón máa ń so ọsán mọ́, kíó tó di ohun tí won yóò fi máa ta ọfà.
Ẹ̀wẹ̀, Ọfà jé ohun ìjà olóró kan tí a pèsè pèlú igi pélébé elénu sónsó tí kò gùn jù ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà méjì àti ààbò.

ÌTUMỌ̀ ÒWE NÁÀ

Bí ọsán bá já kúrò l’ára ọfà, ọ̀pá lásán náà ni ọrún yóò dà; kò sì leè wúlò mọ́ gẹ́gẹ́ bíi ohun èlò tàbí nkan ìjà tí a fi ń ta ọfà.

ÀWỌN ÀKÓKÒ TÍ A MÁA ÚN LO ÒWE YÌÍ

Àwọn baba wa a máa pa owe yìí ní àkókò tí ènìyàn bá p’àdánù ẹni tí ójé igi-l’éyìn-ọgbà. Irúfẹ́ ẹni náà lè jẹ́ Bàbá tàbí ìyá ẹni; ó sì lè jẹ́ elòmíràn ti ó sún mọ́ ni pẹ́kípẹ́kí , gẹ́gẹ́ bíi olùrànl’ọ́wọ́ tàbí alábǎrò ẹni.
Bí ọrún se p’àdánù ànfààní rẹ̀ bí kò bá sí ọsán, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ènìyàn ṣe lè kọjú àwọn ìṣòro nínú ìgbìyànjú l’áti tẹ̀ Síwájú.

ÀLÀYÉ L’ÓRÍI ÀWON ÀSÀYÀN ÒRÒ INÚ ÀPILÈKO YÌÍ NÍ ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ

Ọsán:- a kind of tiny rope that is used for making a bow for arrows (it is also used for tying parts of a talking drum together.)
Ọrún:- a kind of flexible wooden stick to which a tiny rope (osán) is tied, in order to make a bow for arrows.
Ọfà:- an arrow that is being shot by a bow.
Òntàfà:- an archer; a person who shoot arrows with bow.

Comments

  1. Àkíyèsí pàtàkì!!!
    Ọ da wípé ẹ ṣe àṣìṣe ni bi “…ọ̀pá lásán náà ni “ọfà” yóò dà;”.
    Àtúnṣe
    Ni “ọrún” yóò da

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *