È̩RÍN ÀRÍNTÀKÌTÌ L’ÉKÌTÌ

Ìpínlè̩ Èkìtì jé̩ ò̩kan pàtàkì lára àwo̩n ìpínlè̩ t íÌjo̩ba Ológun dásílè̩ ní 1996 lábé̩ ìs̩è jo̩ba Ò̩gágun Sanni Abacha. Láti ara ìpínlè̩ Oǹdó ijó̩un niwó̩n ti s̩è̩dá ìpínlè̩ Èkìtì. Yàtò̩ sí pé Èkìtì jé̩ilè̩ tó lé̩tù lójú, èyí tó farahàn nínúu bíwó̩n ti ńsis̩é̩ àgbè̩ tó níbè̩ àti àwo̩n òkè tóyí ìpínlè̩ náàká, Èkìtì tún gbajú gbajà gé̩gé̩ bí ìpínlè̩ tóní àwo̩n ò̩mò̩wé jù níilè̩ Yorùbá. Àmó̩ ju gbogbo è̩ lo̩, ohun tí ó mú Èkìtìdi ìpínlè̩ àpèwááwò lé̩nu ló̩ó̩ló̩ó̩ yìíni ò̩rò̩ òs̩èlú wo̩n.

Ní o̩dún 1999 tí Nàìjíríà padà sí ètò ìjo̩ba àwarawa, ìpínlè̩ Èkìtì, pè̩lú àwo̩n ìpínlè̩ Ìwò̩-oòrùn Gúsù Nàìjíríà yòókù dìbò fún àwo̩n olùdíje e̩gbé̩ Alliance for Democracy. Níyì Adébáyò̩ ni gómìnà Èkìtì ní  sáàyí. Ìgbà tó di 2003, tí e̩gbé̩ òs̩èlú PDP gba àwo̩n ìpínlè̩ Ìwò̩-oo­­̀rùn Gúsù ló̩wó̩  AD (àfiìpínlè̩Èkó), Ayò̩délé Fáyòs̩e di gómìnà Èkìtì. Sáà yìí ganni a lè so̩pé ìran òs̩èlú ìpínlè̩Èkìtì bè̩rè̩ síí dùn-únwò.

Nío̩dún 2005 ni Àjo̩ tó ń gbógun ti ìwàìbàjé̩ nídì íìs̩úná (EFCC) gbé Gómìnà Fáyòs̩e lo̩síilé-e̩jó̩lórí è̩sùn lílu ìlú ní jìbìtì owó tó lé ni bílíò̩nù kan Náírà pè̩lú ètò ò̩sìnadìe̩. Ìgbà tó di o̩jó̩ ke̩rìndínlógún os̩ù ke̩wàá o̩dún 2006, ilé ìgbìmò̩ as̩òfin ìpínlè̩ Èkìtì yo̩ Fáyòs̩e àti igbákejì rè̩ nípò. Olóyè Friday Adérè̩mí tíís̩e abe̩nugan ilé ìgbìmò̩ as̩òfin ìpínlè̩ náà gba ìs̩àkoso gé̩gé̩ bíi adelé gómìnà. Àtunbò̩tán èyíni bí Ààre̩ nígbà náà, Olóyè Olús̩é̩gun O̩básanjó̩ s̩eso̩ ìpínlè̩ Èkìtì di ìpínlè̩ pàjáwìrì ní o̩jó̩ kejìdínlógún os̩ù ke̩wàá o̩dún 2006 kannáà. Èyí jé̩ ohun ìyàlé̩nu torí kòsí ohun tó­­­­­­­jo̩ rúkè rúdò ní ìpínlè̩náà, àfi bíi sinimá àgbéléwò apanilé̩rìn-ín.

Ò̩gágun-fè̩yìntì Olúrìn ni olùs̩àkóso tí ìjo̩ba àpapò̩ yàn sí ìpínlè̩ Èkìtì, ósì di ipò náà mú títí di os̩ù ke̩rin o̩dún 2007 tí Tó̩pé̩ Adémilúyì di adelé gómìnà títí Olús̩é̩gun Òní tí ódíje tó sì wo̩lé lábé̩ àsìá e̩gbé̩ òs̩èlú PDP fi gba ìjo̩ba ní o̩jó̩ ko̩kàndínló̩gbò̩n os̩ù karùn-úno̩dún 2007. Olùdíje lábé̩ àsìá AC, Ò̩mò̩wé Káyò̩dé Fáye̩mí kò f’ò̩rò̩ m’O̩ló̩run, ótako èsì ìbò nílée̩jó̩. Lé̩yìn o̩dún mé̩ta àjàkú akátá, àti àtúndììbò ní os̩ùke̩rin o̩dún 2009,ilé e̩jó̩ kotemilorun to kale si Ilorin da èsì ìbò tó gbé Òní wo̩lé nù, wó̩n sì kéde pé Fáye̩mí ló wo̩lé. O̩jó̩ ke̩è̩dógún os̩ù ke̩wàá 2010 nilé e̩jó̩ dá Fáye̩mí láre, o̩jó̩ kejì niwó̩n búrafún un gé̩gé̩bíi gómìnà ìpínlè̩ Èkìtì. Àmó̩s̩á o, o̩dún 2013 tíilé e̩jó̩ tógajùlo̩ lórílè̩ èdè yìi da e̩jó̩ tí S̩é̩gun Òní túnpè nù, ni ará tó ro̩ okùn tí aráro̩ adìe̩ Fáye̩mí àti àwo̩n ará ìpínlè̩ Èkìtì lórí e̩ jó̩ ojoojúmó̩.

Ò̩rò̩ e̩jó̩ yìí àti ìdáláre Fáye̩míní 2010 kò jé̩kí ìdìbò gómìnà Èkìtì b’é̩gbé̩mumó̩. Os̩ù ke̩fà o̩dún 2014 ni àjo̩ tó ńs̩ètò ìdìbò fi ìbò gómìnà Èkìtì sí. Fáye̩mí ńdíje àtiwo̩lé lé̩è̩kansíi lábé̩ àsìá e̩gbé̩ òsèlú tuntun, APC. Láàrin 2006 sí 2014 náà, àgbò Ayò̩ Fáyòs̩e tótàdí mé̩yìn ti lo̩mágbárawá, òunsìni olùdíje lábé̩ àbùradà PDP. Ètò ìdìbò 2014 ò̩hún wáwà láàrin Káyò̩dé Fáye̩mí àti Ayò̩ Fáyòs̩e. Ojú iná kó̩ ni ewùrà tií hurunni Fáyòs̩e àti PDP fi ò̩rò̩ náà s̩e. Gbogbo ìjo̩ba ìbílè̩ mé̩rè̩è̩rìndínlógún tówàní ìpínlè̩ náà ló ti gbe̩ye̩ ló̩wó̩ Fáye̩mí. Tò̩húnnáà ò sì wulè̩ janpata, ókí Fáyòs̩e kú oríire. Àmó̩ e̩gbé̩ òs̩èlú rè̩ gbé ò̩rò̩ náà r’elée̩jó̩, níbi wó̩n gbé dá Fáyòs̩e láre.

Nínú ètò ìdìbò síipò ààre̩ tó wáyé ní 2015, nínú èyí tí Ò̩gágun-fè̩yìntì Muhammadu Buhari ti fè̩yìn ààre̩ àná, Goodluck Jonathan bé̩lè̩, ìpínlè̩ Èkìtì nìkan ni e̩gbé̩ òs̩èlú PDP ti wo̩lé ní Ìwò̩-oòrùn Gúsù Nàìjíríà. Èyí, àti àwo̩n àríwísí Fáyòs̩è sí Buhari àti ìs̩èjo̩ba rè̩ so̩ ìpínlè̩ Èkìtì di ìpínlè̩ alátakòfún Ìjo̩ba àpapò̩. Bé̩è̩sì ré, ìjo̩ba àpapò̩ ń fi gbogbo ìgbàrán Fáyòs̩e létí àwo̩n e̩jó̩ ìwàìbàjé̩ tíkòtíì jé̩tán. Àmó̩ èyíkòturunlára rè̩, e̩nu rè̩kòrò̩ ó̩. Bóyá ógbà gbé pé ohun tíítánni o̩dún eegún. Kè̩rè̩kè̩rè̩, ètò ìdìbò gómìnà fún sáà mìíràn tún dé. Fáye̩mí tó ti gba is̩é̩ mínísítà lábé̩ ìjo̩ba Buhari tún padà wá láti díje lé̩è̩kan síi. S̩é Fáyòs̩e òsì le díjemó̩, lóbáfa igbákejì rè̩, Ò̩jò̩gbó̩n Olús̩o̩lá E̩lé̩ka kalè̩. E̩gbé̩ òs̩èlú méjèèjì, PDP àti APC lós̩ètò ìdìbò abé̩lé láti yan olùdíje. Fáye̩mí, tòun tà tìlé̩yìn ìjo̩ba àpapò̩ jáwé olúborí ní APC. Alátakò rè̩ ijó̩sí, tíwó̩n ti jo̩wàní APC báyìí, S̩é̩gun Òní túntako èsì ìdìbò abé̩lé yìí ní lée̩jó̩. Fáye̩mí tún jàrebò̩. Fáyòs̩e ní tirè̩ fo̩wó̩ tí E̩lé̩ka lé̩yìn bíi gba e̩ké̩ ti ńfo̩wó̩ tilé tíigba aláàmú ńfo̩wó̩tògiri, E̩lé̩ka náà s̩e bé̩è̩ jáwé olúborí ní PDP. Bíkò tilè̩ dùnmó̩ àwo̩n o̩mo̩ e̩gbé̩ ò̩hún kan nínú, tíwó̩n sì fi e̩gbé̩ ò̩hún sílè̩ bó̩sí APC.

Ètò ìdìbò ò̩húnwá di ìfiga gbága láàrin ìjo̩ba àpapò̩, tó ti Fáye̩mí lé̩yìn àti alátakò wo̩n tí wó̩n ti ńwó̩nà àti pa lé̩nu mó̩, ìye̩nFáyòs̩e. Kò níyani lé̩nu pé a fé̩è̩ mágbó̩ ò̩rò̩kankan lé̩nu E̩lé̩ka fúnra rè̩, torí Fáyòs̩e gbé ò̩rò̩ ìbò náà lórí ju e̩ni tó ńdíje lo̩. Àpe̩e̩re̩ gbígbò̩ràndùn jue̩ní lò̩ràn lo̩ yìí ni bí Fáyòs̩es̩e ńfó̩nnu lórí ètò orí te̩lifísàn kan tíwó̩n pè ésí ló̩sè̩ tí ìdìbò náà wáyé. Dípòkó sò̩rò̩ lórí ohun tí E̩lé̩ka àti e̩gbé̩ PDP níí s̩e fún Èkìtì, ò̩rò̩ bós̩e wo̩lé ìbò gómìnà lé̩è̩mejì ò̩tò̩ò̩tò̩ ló ń so̩. Ò̩rò̩náà tilè̩ wá dórí góńgó ní o̩jó̩rú, o̩jó̩ ko̩kànlá os̩ù keje, o̩jó̩ mé̩rin sí o̩jó̩ ìbò, nígbà tí Fáyòs̩e bó̩sí ìta pè̩lú apá kíká àti o̩rùn ríró̩ àti omilójú. Àfi bí o̩mo̩ kékeré tí wó̩n gbà lóúnje̩. S̩é bé̩è̩ làpátas̩e ńdomi? Ohun tí Fáyòs̩e so̩ nipé àwo̩n o̩ló̩pàákògbérèégbè lós̩e bé̩è̩ na òun, óní ò̩kan gbá òun lójú, òmíràn fìdìí ìbo̩n gbá òun ló̩rùn. Taani òmò̩pé asunkún rojó̩, ilé níítú. È̩rín màdùn-únrín l’Ékìtì o.

Tòun te̩nu è̩, o̩jó̩ ìdìbò pé. Oníkálùkù wá ń fi è̩sùn kan ra wo̩n. PDP ní APC ń jí àpótí ìbò gbé, pé wó̩n ń dún kokò mó̩ àwo̩n o̩mo̩ e̩gbé̩ àwo̩n, pé wó̩n ń fowó ra ìbò. APC ní PDP ń pín owó àti oúnje̩ fún àwo̩n olùdìbò. Nígbà tí ìdìbò ó fi tán, Fáye̩mí àti APC jáwéolúborí. Kódà, wó̩n fè̩yìn PDP bé̩lè̩ ní ìjo̩ba ìbílè̩ Fáyòs̩e. PDP ti ní àwo̩n ògbà, pé ìpàdé di ilé e̩jó̩. Àbí, a jé̩ pé ìrantúnkù tí a óríwò l’Ékìtì. Kòpé̩  lé̩yìn ìdìbò náà n iàwòrán tíkè̩è̩t ìo̩kò̩ òfuurufú pè̩lú orúko̩ Fáyòs̩e níbè̩. Ójo̩ pé ófé̩ lo̩fún ìsinmi lókèòkun. Àmó̩ àjo̩ tó ńgbógun ti ìwà ìbàjé̩ nídìíìs̩úná ti ńs̩ètòfúnun. Ìranòs̩èlú màdùn-únwò o. S̩ùgbó̩n kílèrè àwo̩n olùdìbò l’Ékìtì? Hùn, ibi erin méjì bá gbé ńjàni, koríko màkú ìró̩jú o. Àbí iboni wó̩n ròpé owó t íàwó̩n gbàní gbà ìbò ti wá. Owó Àbú kó̩ niwó̩n ní a fi ńs̩e Àbú l’álejò. È̩rín àrín tàkìtì ni l’Ékìtìooo.


Káyọ̀dé Akínwùmí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ́, ipele àṣekágbá. Káyọ̀dé fẹ́ràn ìtàn púpọ̀, a máa gbọ́ orin lọ́pọ̀ ó sì jẹ́ olùwòye lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *