Ní ìlú kan tí à ń pè ní Bíkú, Bí-ikú-ilé-ò-pa-ni ni àjápè orúkọ ìlú yìí ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn fẹ́ràn láti máa ge kúrú sí Bíkú. Adé ìlú yìí jẹ́ gbajúmọ̀ láàrín àwọn ènìyàn nítorí ó ti fi ìgbà kan jẹ́ ọdẹ aperin, orúkọ rẹ̀ ni Ọba Adémọ́lá Adéoyè. Ọba yìí ní arẹwà ‘mọbìnrin kan ṣoṣo, Adébísí lorúkọ rẹ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé gbajúmọ̀ la bíi sí, síbẹ̀, ó ní ẹ̀kọ́ ilé, kìí ṣe òròjú, kìí ṣìwàhù, ìwà ìtẹríba àti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní pọ̀ jọjọ.
Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, ‘Débísí gbéra láti gbafé, ó rí èso àgbálùmọ̀ lọ́nà, ó bẹ̀rẹ̀ mujẹ nítorí ọ̀nà ọ̀fun ń pòùngbẹ làti jẹ ẹ́. Láì mọ̀ bóyá jíjẹ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó fi lánu tán láì kù kan.
Ibi tí ó ti ń jẹẹ́ ló ti dákú lọ gbáári. Kò sẹ́ni kankan ní itòsí tí yóò gbe. Ìgbà tí wọ́n retí-remú kí ó darí wálé l’Oba bá pàṣẹ láti wáa lọ.
Bí wọ́n ti ri ní ọ̀ọ́kán, àwọn ìránṣẹ́ ọba rò wípé ó ti dákẹ́ ṣùgbọ́n nígbà tí wón súnmọ pẹ́kí, wọ́n ri pé ẹ̀mí ṣì wà lára rẹ̀. Kíá, wọ́n gbé dé Ààfin. Àyà àwọn òbí Adébísí já, wọ́n pe oníṣègùn láti yẹ̀ẹ́ wò.
Oníṣegùn ní oun kan ṣoṣo tí ó lè wo ‘Débísí sàn ni ẹyẹlé olójú mẹ́rin tí òun yóò fi ṣe ìpèsè fún-un.
Ọ̀rọ̀ yìí só sí gbogbo wọn lẹ́nu, ó sì tún bu iyọ̀ síi. Pàbó ni gbogbo ìgbìyànjú àwọn ìránṣẹ́ Ọba lórí ọ̀ràn yí jásí.
Ọba wá ṣèkéde pé ẹnikẹ́ni, yálà onílé tàbí àlejò tí ó bá lè wá ẹyẹlé olójú mẹ́rìn-in rí ni yóò fẹ́ Adébísí ọmọ òun kan ṣoṣo.
Nì wàrànsèsà, àwọn ọmọ ìyá mẹ́ta kan wà nínú ìlú yìí rí orúkọ wọn ń jẹ́ Báòkú, Bádéjọ àti Bámgbọ́pàá. Báòkú ni àkọ́bí tí àwọn tó kù jẹ́ àwọn àbúrò rẹ̀. Wọ́n ti fi ìgbà kan gbìyànjú láti fẹ́ Adébísí. Nítorí náà, wọ́n wọnú ìgbẹ́ lọ.
Lọ́ọ̀tọ̀ọ̀, wọ́n wo tìfun-tẹ̀dọ̀ igbó Bíkú. Aríran ni bàbá wọn, ó sì ti fi oògùn síwọn lára kí ó tó jáde láyé.
Báòkú ni ó kọ́kọ lọ, orí ba ṣé, ó fojú gáání ohun táà ń wá níbi tí ó gbé bà lé orí igi lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò. Ó múu, ó mọ́nà rẹ̀ pọ̀n lọ sí ìlú. Bí ó ti ń lọ, ó pàdé baba arúgbó kan, onítọ̀ún bi Báòkú lérèè oun tó wà nínú àpò tó gbé kọ́rùn. Báòkú rẹ́rìn-ín ìyàngì, ó ní “baba, ekòló lásán ni ó wà níbẹ̀“. Baba ní kò burú. Wọ́n mú ọ̀nà wọn pọ̀n. Bí Baòkú ti dé ọ̀dọ̀ oníṣègùn láti mú ẹyẹlé jáde, ekòló méje ni ó rí.
Ọjọ kejì ni Bádéjọ tó dé sí ìlú, nítorí pé òun náà purọ́ fún baba arúgbó yìí lọ́nà, akàn ni ó kó jáde nínú àpò rẹ̀.
Yorùbá bọ̀, wọń ní ‘bí a bá wípé ó dọwọ́ọ babaláwo, babaláwo á ní ó dọwọ́ ifá; bí a bá ní ó dọwọ́ àgbà ìṣègùn, àgbà ìṣègùn á ní ó dọwọ́ ọ̀sanyìn’, bí Bámgbọ́pàá ti ń lọ l’óún képée Elédùmarè fún ìrànwọ́ àti àtìlẹ́yìn ẹlẹ́dàá bàbá rẹ̀ lọ́run.
Ọjọ́ kẹta ni ó tó rí ẹyẹlé olójú mẹ́rin níbi tó ń gbé musàn lórí igi. Ọ̀nà tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gbà kọ́ ni ó gbà, èyí ló jẹ́ kí ó pẹ́ ríi.
Bí Bámgbópàá ti rí baba arúgbó, ó kíi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, baba bèèrè ohun tó gbé kọ́rùn, ó ṣàlàyé fún baba pé ẹyẹlé ni àti pé ara ọmọ ọbatí kò dá ni wọ́n fẹ́ lòó fún. Baba ní kò burú, ó fun ní fèrè gbọọrọ kan pé yóò wúlò fún-un lọ́jọ́ iwájú.
Bámgbọ́pàá dé ọ̀dọ oníṣègùn, ewé jẹ́, oògùn jẹ́ pẹ̀lú, ara Adébísí yá ṣùgbọ́n ọba yẹ àdéhùn, ó ní òun kò fẹ́ kí táláká ó fẹ́ ọmọ òun.
Ọba wá ní àyàfi tí Bámgbọ́pàá bá lè mú eku oníbejì wá bá òun láàárọ̀ ọjọ́ kejì ló tó lè fẹ ẹ.
Ọ̀ràn yìí mú ìrònú báa, lọ́gán ló rántí fèrè tí baba arúgbó fún-un. Ó fọn fèrè yìí, lótìítọ́, eku oníbejì yọ síi. Kíá, ó gba Ààfin Ọba lọ, ẹni ta rò pé kò lè pàgọ́ tó kọ́lé ìgunnu lọ̀rọ̀ ọ̀hún rí lójú Ọba, ẹnu yàá púpọ̀púpọ̀, ó bèèrè ọ̀nà tí Bámgbópàá gbà tó fi pege dé fi wàrà jọkà, ó d’Ọ́ba lóùn p’órí ló b’óun ṣé.
Báyìí ni Bámgbópàá ṣe dọkọ Adébísí ọmọ ọba látàri òtítọ, ìwà ìtẹríba àti ìforítì rẹ̀, àwọn méjèèjì sì jọ ń gbé ní àláfíà.
Nípa Òǹkọ̀wé:
Ọláyàtọ Ọláolúwa jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè B.A nínu ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ẹ̀dá Èdè àti Èdè Yorùbá ní Ilé-ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì Adékúnlé Ajásin Àkùngbá Àkókó. Ònkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn Èdè àti Àṣà Yorùbá gidi gan.
Àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Nigeria Cultural Art Image:https://www.pinterest.de/pin/380694974750748626/