Ojú lọ̀rọ́ wà, ètè kọ́

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lẹnu 

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lètè

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lẹnu

–Èdè ẹnu fun ìlù u bàtá

 

Kíni ìdí tí èdè Yorùbá fi dùn bí oyin láti sọ, dé ibi wípé àwọn tí ó kúndùn èdè e Yorùbá má a ń fi Ògún rẹ̀ gbárí wípé kò sí èdè tí ó wú ni lórí bí èdè Yorùbá ní gbogbo àgbáláayé? Àdììtú inú ìbéèrè yì í ni wípé èdè tí a mọ̀ọ́mọ̀ dá, àkàndá èdè pátápátá ni èdè Yorùbá jẹ́. Àwọn irúnmọlẹ̀ tí ó pilẹ̀ èdè Yorùbá ní ìgbà ìwásẹ̀ ni wọ́n gba ìmọ̀ pọ̀; wọ́n sì fi ògédé ohùn lásán hun òfì èdè tí ẹwà a rẹ̀ kò ní àfiwé. Ohùn orin ni á fi pa aró èdè Yorùbá, ìró ìlù lílù ni a fi wé orúkọ àti oríkì Yorùbá; ìdí ni à á fi í jókòó, ẹnu la á sì fi sọ ọ́.

Irú òwú wo ni a fi hun òfì aláràbarà tí a ń pè ní èdè Yorùbá, àní irúfẹ́ ọwọ́ wo ni a fi dì í, tí ó fi gún régé bí arè Ọbalúfẹ̀? Irú ẹnu wo ni a fi ń pe èdè yì í, irú etí wo sì ni a fi ń gbọ́ ọ, tí ó fi ń jẹ bí ó ti ń jẹ́, tí ó sì fi dùn ju àgbáyun lọ? Ní kúkúrú, ǹjẹ́ àbáṣepọ̀ ìjìnlẹ̀ kankan wà láàrin èdè yì í pẹ̀lú iṣẹ́ ọnà ní oríṣirísi tí àwọn Yorùbá ń ṣe? Oríṣìíríìṣí àwọn ìbéèrè báyìí ni àwọn ọ̀mọ̀wé má n yẹ̀ wò lóòrè, lóòrè.

Ìbéèrè wọ̀nyí kì í ṣe àpáta kọ̀rọ̀bìtì kọrọbiti tí kò ṣe é yí wò: ìkọ́ méjì péré ni ó so fánrán ohùn èdè e Yorùbá pọ̀. Èkíní ni ìkọ́ ohùn akọ, èkejì sì ni ìkọ́ ohùn abo, tí àwọn Gẹ̀ẹ́sì má a ń pè ní kọńsónáǹtì àti fáwẹ́ẹ̀lì. Àdàlú ìkọ́ ohùn méjèèjì ni a fi ń ro ẹ̀wà a ọ̀rọ̀ sísọ ní èdè e Yorùbá. Wẹ́lẹ́-wẹ́lẹ́ bí ẹni ń hun ẹní ẹwẹlẹ sì ni a ma ṣe ń fi ìkọ́ ohùn akọ la ìkó ohùn abo, bí a bá n sọ èdè e Yorùbá. Bí a bá ti fi ìkọ́ ohùn kan lẹlẹ̀, ìdàkejì rẹ̀ ni yíò tẹ̀lé e. Bí a fi akọ bẹ̀rẹ̀, abo ni yíò tẹ̀ lé e. A lè kó abo ìkọ́ ohùn méjì papọ̀ mọ́ra, Yorùbá kì í ṣe àmúlùmọ́là bí i kí a máa kó akọ ìkọ́ ohùn pọ, bí i ti èdè e Gẹ̀ẹ́sì. Eléyìí mú kí ará dẹ ètè tí bá ń sọ èdè e Yorùbá. Ara a má a ni ètè púpọ̀ bí a bá kó akọ ìkọ́ ohùn pọ̀ sí ojú kan náa. Sísẹ̀-ǹ-tẹ̀-lé bí ẹní ẹwẹlẹ tí Yorùbá ti ṣe ń hun ohùn ni ó jẹ́ kí èdè yì í dẹ̀ létí láti gbọ́, bí ìgbà tí ẹ̀fúùfù lẹ̀lẹ̀ bá ń fọn kàkàkí ọba. Ẹ jẹ́ kí á yẹ òkèlè ohùn kan péré wò, láti lè rí bí ẹní ẹwẹlẹ yì í ṣe rẹwà tó, àti irú iṣẹ́ ẹ kàyéfì tí ó ń ṣe ní káà èdè e Yorùbá.

Ẹ jẹ́ ká yẹ ohùn [agbon] wò nínú àsàyàn àpẹẹrẹ wònyíí:

 

Agbọ́n: kòkòrò tí ó máa ń fò
Àgbọ̀n: ìsàlẹ̀ ètè

Àgbọn: igi tí ó ń so àgbọn

Agbọ̀n: èyí tí a fi ń di ẹrù

Agbọ̀n (A gbọ̀n): pẹ̀lú ìbẹ̀rùbojo

Agbon (A gbọ̀n): bí ọyẹ́ bá mú, ọmọdé a gbòn gìrìrìrì

Agbọ̀n (A gbọn): bí ẹni ń gbọn òwú

Agbọn (A gbon): wọ́n gbọn aṣọ mọ olè lọ́rùn

Agbon (A gbọ́n): àwa ò gọ̀ mọ́ o

Agbon (A gbọ́n): A gbọ́n omi ìsàlẹ̀ inú ìkòkò

Ágbọ̀n (Á gbọ̀n): Ó má a ya ọ̀dẹ̀

Ágbọn (Á gbọn): Ó má a ya sí pẹ́rẹpẹ̀rẹ

Ágbọ́n (Á gbọ́n): Orí i rẹ̀ á pé

 

Kò sí ẹni tí ó yẹ àpẹẹrẹ wọ̀nyí wò tí ède Yorùbá kò ní í wú lórí. Ẹni tí ó bá fi làákàyè yẹ àpẹẹrẹ wọ̀nyí wò yíò rí i wípé a fi wọ́n so ọgbọ́n kọ́ ni. Èdè e Yorùbá jé èdè àdììtú. Baálẹ̀ ọrọ̀ inú èdè e Yorùbá ni àdììtú alábala ọ̀kànléerúgba erìgì tó forí sọlẹ̀ tí ò yọ–láti ẹnu ẹni tí ń sọ Yorùbá, àti sí etí ẹni tí ń gbọ́ ọ. Síbẹ̀síbẹ̀, ojú lọ̀rọ́ wà. Ẹni bạ́ ń wo ẹnu lásán, irọ́ ni wọ́n fi ń pa. Kò tó iṣẹ́ lọ́wọ́ ẹnu tí wọ́n fi í purọ́; iṣẹ́ etí àti ojú ni láti já ọmọ lẹ́hìn irọ́. Gbogbo ara la fi ń sọ Yorùbá, gbogbo ara sì la fi ń gbọ́ ọ. Ẹni tí ó bá mọ ìdí abájọ kò lè rí ojú wo inú abájọ. Ìdí abájọ ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tí a hun kalẹ̀ bí ẹlẹ́ní ẹwẹlẹ. Àwọn Yorùbá ka ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kún púpọ̀. Ohùn ẹnu, gbogbo ara kìkì ìtumọ̀ ni. Ní ìdí ìṣòwò Ògún, bí ẹjá bá sọ lódò, awó mọ ohun tó tó. Ojú inú tá fi i sọ ọ̀rọ̀ sùnnùkùn ná à la fi í wò ó, nítorí ọ̀rọ̀ kì í tóbi títí kí á fi ọ̀bẹ bù ú.

Ní ẹnu ọjọ́ mẹ́ta yì í, ojú inú bẹ̀rẹ̀ sí ní i sọnà fún wa wípé awon èlédè e Gẹ̀ẹ́sì ńṣe akitiyan, wọ́n sì ń pète pèrò láti   gba ọba lọwọ èdè e Yorùbá, kí wọn ó pa á, kí wọn ó kun ún, kí wọn ó sì pín in bí ẹran iléyá. Kò sí orílẹ̀ èdè tí èdé e Gẹ̀ẹ́sì fi ẹṣẹ̀ kàn, tí kò sọ ilé ọlá di ahoro fún èdè abínibí ìlú ná à. Ìwà yì í kò ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ti wá yé ọmọ tí ń sunkún, ó sì ti yé ìyá a rẹ̀ tí ń rẹ̀ ẹ́. A ti rí oríṣirísi àpẹẹrẹ ibi tí ète yì í ti fi ìdí múlẹ̀, pàápàá jù lọ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ Yorùbá. Àwọn olùkọ́ni ń kọ àwọn ọmọ wa láti tẹnu mọ́ sísọ èdè e Gẹ̀ẹ́sì, kí wọ́n sì pa èdè abínibí i Yorùbá tì, kí wọ́n sọ èdè e Yorùbá di igbá a pàńkàrà, èyí tí wọn ó má a fi kólẹ̀. Irú ìwà ajogun yì í ń ṣe ìpalára fún ìwadìí fíni-fíni sí ìtumọ̀ àti ìdí abájọ àṣà, ìmọ̀, ìrírí, àti ìṣe àwọn Yoruba. Eléyìí ni ó mú kí Baba Rowland Abíọdún sọ wípé a ò gbọdọ̀ fi iná sí orí òrùlé kí á sùn lọ—bí a ó tilẹ̀ fi ejò sórùlé kí á na ẹ̀yìn. Lẹ́hìn àádọ́ta ọdún tí Baba Abíọ́dún ti ń ṣe iṣẹ́ ìwádìí sí ìtumọ̀ àṣà ọnà àti iṣẹ́ àwòrán àwọn Yorùbá, wọ́n ṣe àkíyèsí wípé èdè e Gẹ̀ẹ́sì tí a fi ń túmọ̀ iṣẹ́ ọnà a Yorùbá kò wúlò fún àyẹ̀wò ojú inú tí ó péye fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀rọ̀ àṣà, ẹwà àti ìṣe àwọn Yorùbá. Ní ọdún 2014 ni Baba Abíọ́dún, tí wọ́n jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà in Amherst College, kọ ìwé e gbàkan-gbìì tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art.  Láti ìgbà tí ìwé yì í ti jáde, ẹnu kò sìn lára rẹ̀, bí i ti afọ́kèéèmù.

Ìwé tí Bàbáà wa Rowland Abíọdún kọ ni à bá pè ní Ẹlẹ́nu Rírì ló Lààmù Ìyá a Rẹ̀.[1] Kàyééfì ni ó jẹ́ wípe´ èdè gẹ̀ẹ́sì, faransé ati potokí fẹ́ ẹ́ dọ́gbọ́n fi èdè e wọn gba iṣẹ́ ọnà àwa aláwọ̀ dúdú lọ́wọ́ ọ wa. Bí kò bá sì ní ìdí, obìnrin kì í jẹ́ Kúmólú. Ohun tó ṣe ilá tílá fi kó, òun ló ṣe ikàn tó fi wẹ̀wù ẹ̀jẹ̀. Ohun tó dé tí ó fi jẹ́ wípé èdè gẹ̀ẹ́sì àti èdè àwọn aláwọ̀ funfun ni a fí ńtúmọ̀ iṣẹ́ ọnà àwa Káàárọ́-o-ò-jíire, àti iṣẹ́ ọnà àwọn èèyàn dúdú yìókù ní ilè Áfíríkà ní ìdí. Díẹ̀ nínú àwọn ìdí wọ̀nyìí ni mo fẹ́ mẹ́nu bà ní ṣókí nínú ọ̀rọ̀ ìṣáájú yìí.

Kìí kúkú ṣe wípé àwa Yorùbá kìí tàkurọ̀sọ nípa iṣẹ́ ọnà àti àwòrán yíyà kí ó tóó di wípé àwọn èèbó dé sí orílẹ̀ èdè e wa. Àmọ́ láti ìgbà tí wọ́n ti dé, àtìpá àtìkúùkù ni èèbó fí fẹ́ fi èdè gba akátà lọ́wọ́ akítì. Bí a bá ti ibi ìṣáná kíyè ṣóògùn, a ó rí i dájú wípé èdè èèbó ò ṣeé ronú láì ṣ̀inà, tàbí já sí kòtò, tàbí ká kọlu gegele, bí a bá fẹ́ ẹ́ sọ òtító ọ̀rọ̀ lorii àṣà àti iṣẹ́ ọnà awon Yoruba. Gẹ́gẹ́ bí ohùn tí Baba Awíṣẹ Wándé Abímbọ́lá kọ́ wa nígbàa rèwerèwe, wọ́n ni, “Ohun tí ó bá jọ ara ni à á fií wéra; èèpo ẹ̀pà ó jọ pósí ẹ̀lírí.”[2] Èèbó sísọ ní gbẹrẹfu ò ṣeé tú àdììtú ọ̀rọ̀ tí a ta ní kókó, tí àwọn ọlọ́nà dì bíi iṣu àna sínú iṣẹ́ ọwọ́, iṣẹ́ ojú, àti iṣẹ́ẹ làákàyè, tí a ń pè ní ọnà ní èdèe Yorùbá. Tí a ò bá níí tan ara wa jẹ, kò sí bí a ṣe lè sọ ọ̀rọ̀ kó pọ̀ tó, kò níí kún inú agbòn. Kò sí bí a ṣe lè fi èdè èèbó ṣe àpèjúwe àti àròfọ̀ tí ó lè múná dóko fún àǹfààní ìtumọ̀ ọnà àwọn Yorùba.

Bàbá Làmídì Ọlónàdé Fákẹ́yẹ́, akọni nínú àwọn ágbégilére gbogbo àgbáyé, (kí Olódùmarè ó dẹlẹ̀ fún wọn), ni wọ́n sọ ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ kan nígbà tí a ń dá wọn lọ́lá pẹ̀lú ìwé kan tí mo ṣe olóòtú rẹ̀ ni ọdún 1988.[3] Bàbá Fákẹ́yẹ wo ìwé yìí nígbà tí mo gbé e fún wọn yẹ̀wò, wọ́n rẹ́rìín. Mo ní kíló dé, baba? Baba ni, “Mọyọ̀, ọ̀rọ̀ àtàtà bí ìṣọkúṣọ. Ẹ̀yin alákọ̀wé, ẹ rọra máa purọ́ ojúkorojú.”
Mo ní, “Baba, kí lẹ rí?”
Baba dáhùn, wọ́n ní, “Èétijẹ́ Mọyọ̀! Gbà ràn mí ti se wá á dẹlẹ́rù. Jẹ́jẹ́ ni mo gbẹ́giì ní òpómúléró mọja àlekàn. Taní wa mọ̀ wípé èèbó rẹpẹtẹ báyìí ḿbẹ́ nínú igi osè! Àmọ́ sá, gbẹ́nàgbẹ́nà ti gbẹ́ igi tán o. Ó ku ti gbẹ́nugbẹ́nu.”

Mo dáhùn, mo ní, “Àkíìkà, baba.”

Baba Fákẹ́yẹ wáá ṣí ìwé ọwọ́ ọ wọn, wọ́n ní, “Kí ni gbogbo èèbó gbẹrẹfu tọ́ ọ wáá kọ kalẹ̀ yìí fi jọ iṣẹ́ ọnà tí mo gbẹ́?”

Mo ní, “Baba, ó kúkú jọra, lójúu tèmi o.”

Babá rẹ́rìín kèé-kèé. Babá ní, “Sé gbogbo èèbò inú ìwé yìí ṣeé túmọ̀ sí èdè Yoruba?”
N ò ronú lẹ́ẹ̀mejì tí mo fi fọhùn wípé, “Áwù, ṣebí kí wọ́n kàn túmọ̀ rẹ̀ lásán láti èdè Òyìnbó sí Yorùbá ni.”
Baba ní, “Mọyọ̀, kò rí bẹ́ẹ̀. Èdè èèbó kọ̀ jọ Yoòbá o. Bí èèbó bá ṣeé pòwe, ṣé ó ṣeé pọfọ̀? Bí ẹnà, bí ògèdè, bí àyájọ́, bí i èrèmọ̀jé ńkọ, ṣé ẹ lè fi èèbó ki oríkì ìdílé?”
Mo dáhùn, mo ní, “Ó kúkú ṣe é ṣe, baba. Ní Amẹ́ríkà, wọ́n ti ń fi Òyìnbó dáfá.”

Baba Fákẹ́yẹ ní, “Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni “Ilẹ̀ẹ káàárọ̀, o ò jíire” ní èdèe èèbó?”

Ìgbá yìí ni mo tó mọ̀ ibi tí baba ń lọ, láì mọ ibi tí babá ti ḿbọ̀.

Bí èdèe Yorùbá ò ti lè paradà lóòró dí èèbó, bẹ́ẹ̀ náà ni èèbó ò leè paradà di Yorùbá. Bí a bá ní ká dán an wò, a ò ní rí eégún mọ̀, mọ̀rìwò lásán ni aràn ojú ó máa jẹ.

Èkíní ni wípé èdè àti àṣà Yorùbá, Táyé àti Kẹ́hìndé ni wọ́n jẹ́. Bí ọ̀̀kán bá ti yẹ̀bá, ère ìbejì ni ó kù, èjìré ará Ìṣokùn ti relé ojú ọlọ́mọ ò tó o. Gẹ́gẹ́ bí Baba Fákẹ́yẹ ti wí, ẹní bá ń fi èdè èèbó túmọ̀ ọnà Yorùbá, ó ti ya Táyé kúrò lọ́dọ̀ Ọmọ́kẹ́hìndé. Àtamọ́ mọ́ àtamọ̀ ni ó kù, àfi bí Baba Fákẹ́yẹ bá jẹ́ ọ̀gbẹ̀rì nípa iṣẹ́ ọnà àwọn Yorùbá.

Èkejì ni wípé, gbogbo èdè ni ó ní ìdí àbájọ tí ó yàtọ̀ sí ara a wọn, tí ògbẹ̀rì ò mọ̀. Ìdí abájọ èdé dà bí òògùn tí ọmọdé rí tí ó wá ń pè ní ẹ̀fọ́. Bí a fi ewé èdè han àlejò, a ò gbọdọ̀ já a lé e lọ́wọ́; a sì leè já a lé e lọ́wọ́, kí á mọ́ sọ oọ́kọ tí ń jẹ́ fún un. Adífá fún àgbẹ̀ tó lóko, tí ò lọ́kọ́; bí okó bá kún ńkọ, kíni àgbẹ̀ yíò fi ro ó? Nítoríi kíní? Nítoríi lẹ́nà, lẹ́nà, là ń fọ èdè Yorùbá, gẹ́gẹ́ bí Baba Abíọ́dún ti wí nínú ìwé yìí. Baba Abíọ́dún ní ẹnà lo paradà tó dọnà; ọnà náà tún wá pawọ́dà, ó dẹnà, ó di ọ̀rọ̀ hùn-nù-hùn-nù.

 Kíni ẹnà tí ń bẹ nínú èdè gẹ̀ẹ́sì? Rìkísí ni. Alágbẹ̀dẹ èdèe gẹ̀ẹ́sì ò rí bébà ọnà Yorùba rọ. Bí ènìyàn bá ti bẹ̀rẹ̀ sí níí sọ èdè gẹ̀ẹ́sì, olúwa rẹ̀ ti kó sínú paḿpẹ́. Ẹ jẹ́ kí á ti ibi pẹlẹbẹ mú ọ̀ọ̀lẹ̀ jẹ, ká ti ibi ìṣáná kíyè sí òògùn. Kíni ìtumọ̀ “art” ní èdè Yorùbá? Ìbéèrè sákálá yìí kò kérémí rárá. Ní àkọ́kọ́, ìbéèrè yìí dàbíi ìgbà tí ènìyàn ń fi ẹran jẹ̀kọ. A lè wípé “ọnà” ni ìtumọ̀ “art” ní Yorùbá. Àmọ́ tí a bá fi làákàyè wo ìbéèrè náà, a ó rí i wípé inú pam̄pẹ́ ni ìbéèrè yì í ti ni sí. Kì í ṣe ìbéèrè tí ó wáyé rárá, nítorí ìbéèrè ẹ̀dẹ ni. Ìdáhùn tí ó yẹ ìbéèrè ẹ̀dẹ bẹ́ẹ̀ nìyíí: kíni ìdí tí àwọn Yorùbá fi ní láti ní ìtumò fún “art?” Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni ti bi àwọn gẹẹ́sì rí wípé kí ni ìtumọ̀ “Ìgunnu” ní èdèe Òyìnbó? Bí a bá ti bi ni wípé kíni ìtùmọ̀ “art” ní èdè Yorùbá, ó di wípé kí á wá má a fi ọwọ́ họrí, kí á má a wòkè, kí á má a làkàkà, nítorí pé ó dàbí ìgbà tí ó di dandan kí àwọn Yorùbá ní ìtumọ̀ fun “art” ní èdè abínibíi wọn. Àmọ́, tani ó ṣe òfin yìí wípé gbogbo àṣàkaṣà tí àwọn gẹ̀ẹ́sì bá ti dá ní ìmọ̀ràn, àwọn Yorùbá ní láti ní ìtumọ̀ fún, níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ wípé ẹnìkan kì í ka irú ẹbọ bẹ́ ẹ̀ fún àwọn èèbò?

Ohun tí ó fa irúfẹ́ ìrònú eléyìí ni wípé àwọn èèbò kọlọnáìsì àwọn Yorùbá. Mo mọ̀ọ́mọ̀ lo “kọlọnáìsì” ni.[4] Kíní ń jẹ́ “kọlọnáìsì” ní èdèe Yorùbá? Irọ́ funfun ni ó wà ní ìdí ọ̀rọ̀ ná à. Kókó inú ọ̀rọ̀ tí à ń pè ní “kọlọnáìsì” ni “kọ́lọ́nì.” Àwọn èèbó wá sí okoo baba à mi, wọ́n sọ ọ́ di “kọ́lọ́nìi” wọn. Ó dàbí ìgbà tí mo bá wo ẹ̀wù tí ẹ wọ̀ sọ́rùn báyǐ, tí mo wípé “Ewuu Mọyọ̀ nìyǐ.” Ńṣe ni ẹ ó wò mí tìyanu-tìyanu, tí ẹ ó sọ wípé, “Àbí o ti mu ṣẹ̀kẹ̀tẹ́ yó ni Mọyọ̀ṣọ́rẹ?” Ṣùgbón nítorí wípé èdèe gẹ̀ẹ́sì ni èèbó lò, tí wọ́n pe ilé e baba wa ní “kọ́lọ́nì,” ọ̀rọ̀ náà ò yé wa wípé ilé e baba wa kì í ṣe kọ́lọ́nì baba ńlá a wọn. Àmọ́ torí wípé gírámọ̀ọ gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ń sọ, kọ̀ pẹ́ kò jìnnà, tí wọ́n fi di “kọlọnáísà” tí ń ṣe “kọlọnaísésàn,” tí àwa ẹrú Ọlọ́run ná à sì di èrò tí wọ́n “kọlọnáìsì.” Àwọn akọ̀wée wa sì ti bẹ̀rẹ̀ sí níí kọ ìwé lóríi “positi-kòlóníá sitọdì.”[5] Ọ̀rọ̀ ná à wá di ìtàn àìtètèmólè, olè ń sá lọ! Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ó yẹ kí á tí sọ fún èèbó wípé, “Alàgbà, ṣé kìí ṣe wípé ẹ mu sìgáa kùkúyè? Ilée baba tèmi kì í ṣe ‘kọ́lọ́nì’ rẹ òo.” Gbogbo èmi ni “positi-kòlóníá sitọdì” ò tilẹ̀ níí wáyé, tàbí kí ó ní ìtumọ̀ kankan. Èdè òyìnbó ni ó dá “kọ́lọ́nì” sílẹ̀ níbi tí kò sí ǹkan tí ó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Òun náà ni ó sì fa wípé a wá á bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe “positi-kòlóníá sitọdi”̀ lọ́jọ́ òní. Irọ́ ní ń jẹ́ bẹ́ ẹ. Ṣùgbọ́n irọ́ yìí yíò jọ òótó bí a bá ń fi èdè Òyìnbó ronú. Ìdí rè é tí ọmọ Yorùbá kò gbọdọ̀ má a fi èdè èébó ronú, tí ò bá fẹ́ kó sí kòtò. Àrosọ́dọ̀ ni ọkọ́ èdè Òyìnbó ń roko.

Onírúurúu rìkísí àti àrosọ́dọ̀ ni èébó ti fi ọkọ́ èdèe wọn ro ní ilẹ̀ Afirika. Wọ́n kọ́kọ́ wò iṣẹ́ ọnàa Áfíríkà sùn-ùn, wọ́n bẹ̀rẹ̀ pẹlu “pìrìmítífú art.” Wọ́n kọ̀wé lọ jáǹtì rẹrẹ lóríi “pìrìmítífú art.” Paul S. Wingert (ní 1962)[6] ati Douglas Newton (ní 1978)[7] kọ ìwé bàm̀bà-bamba láti wípé “pìrìmítífú art” ni àwa ènìyàn-an Áfíríkà ń ṣe; láìpẹ́ wón ní iwa ìkà ni àwọ́n ń hù bí àwọ́n bá ń pe iṣẹ́ Áfíríkà ni “pìrìmítífú art,” àti wípé “tíráíbálí art” ni àwọn yíò má a pè é.  Láìpẹ́ yìí ni Jean-Baptiste Bacquart ṣe ìwé aláràbarà lóríi pípe iṣẹ́ ọnàa Áfíríkà ní “tíráíbálí art,” tí ó fi ọ̀kẹ́ àìmooye àwòrán ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.[8] Àmọ́ kè è sú wọn òo. Wọ́n tún wò lọ sàkùn, wọ́n ní àwọn ó bẹ̀rẹ̀ sí má a pe iṣẹ́ Áfíríkà ni “tiradíṣánná art.” Alàgbà John Picton, ní ọdún-un 1992,[9] ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàyé wípé kò bójú mu láti pe iṣẹ́ ọnàa Áfíríkà ní tiradíṣánná art. Àmọ́ bí aráyé bá gbọ́, wọn ò gbà. Wọn ò yéé pe iṣẹ́ẹ Áfíríkà ní tiradíṣánná art. Èèbó mìíràn a pè iṣẹ́ Áfíríkà ní ìsìtóríká art. Tàbí kílásíká art. Ọ̀rọ oókọ tí wọ́n ó máa pe iṣẹ́ Áfíríkà ti wáá dàrú bí ẹsẹ̀ẹ télọ̀. Kò tilẹ̀ yé àwọn èèbó mọ́; bí ó ṣe wu kówȧ ni kálukú ti ń ṣe. Aṣọ ò bá ọmọ́yẹ wọn mọ́. Ó ti rin ìhòhò wọjà.

Ohun tó ṣe ni ní kàyéfì ni wípé àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Áfíríkà naa ti wá ń fi ọkọ́ èdè gẹ̀ẹ́sì roko sí ọ̀dọ̀ àwọn Òyìnbó; wọ́n sọ ọkọ́o tiwọn sígbó, won ò lè dá inú rò mọ́. Bí èèbó bá ti wí náà ni ó tẹ́ won lọ́rùn. Bí èèbó bá ní “Jókǒ,” wọn a jókǒ; “dìde,” wọn á dìde, “lósǒ,” wọn á lósǒ. Ṣebí èdè èèbó ni wọ́n ń sọ; àṣà èèbó ni wọ́n ń dá. Elédùà má sọ wá di ajá èèbó.

Kò pẹ́ kò jìnnà, èèbó tún wípé abala kan nínú àwọn ayàwòrán ilẹ̀ẹ Áfíríkà yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí àwọ́n sọ ni “tiradíṣánnà,” nítorípé àwọ́n abala tí àwọ́n yà sọ́tọ̀ yìí lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìyàwòrán. Ṣé ogunlọ́gọọ èèbó ò kúkú gbà pé àwọn tí wọ́n kà kún tiradíṣánná lọ sí ilé ẹ̀kọ́ ìyàwòrán.  Èèbó bá bẹ̀rẹ̀ sí í tún pe abala yìí ní kọ̀ǹtẹ́ḿpórárì. Bí ó bá wù wọ́n, wọn a tún pe abala yìí ní mọ́dáànì (modern). Wọn a fọ èèbo títí bí ọ̀pẹ́ẹ̀rẹ̀, láì mú iná dóko.

Kì í kúkú ṣe wípé ìwà ìkà nìkan ni ìdí abájọ tí ọ̀pọ̀lọpò àwọn Èèbó fi ń dá àbá a gbàraǹmí dẹlẹ́rù.  Ogunlọ́gọ̀ ìgbà, bí àáyá bá ní kí òún tún ojú ọmọ ṣe, ìka níí tì bọ̀ ọ́, tí ojú yíò wá á di yíyẹ̀. Ó mú mi níran ikú u ọ̀mọ̀wé John Pemberton III, ẹni tí ó ṣaláìsí láìpẹ́. Mo ṣe alábǎpàdé wọn ní Ilé Ifẹ̀ ni 1984, ní ibi tí wọ́n ti ń fi gbogbo ara ṣe iṣẹ́ ìwádǐ pẹ̀lú u Bàbá Fakeye. Bi Pemberton tí ń nàró ni wọ́n ń kúrú láti ya fọ́tò pẹ̀rẹ̀-pẹ̀rẹ̀, tí wọ́n ń fi pẹ́ẹ̀nì hàǹtúrú ọ̀rọ̀ sórí ewé, tí wọ́n ń bèèrè àlàyé, tí wọ́n ń fi aṣọ nujú, tí òógùn sì bò wọ́n, bí wọ́n ṣe ń sọ́ Baba Fákẹ́yẹ, ẹni tí ń fẹran jẹ̀kọ gbẹ́ Osée Ṣàngó.

Jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni Baba Fákẹ́yẹ jókǒ, tí wọ́n ń rẹ́rǐn múṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́, láì tilẹ̀ wojúu Pemberton tí ó ti ilẹ̀ Amerika wá á ṣe iṣẹ́ ìwadǐ ní Ilé Ifẹ̀. Àmọ́ ṣá nígbàtí mo ka àròkọ tí Pemberton kọ sínú ìwé àkójọpọ̀ àwòrán kan tí orúkọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination, ògẹ̀dẹ̀ dúdú ni, kò yá bù sán.[10] Alákọ̌kọ́, emi ni ìtumọ̀ oókọ ìwé yǐ ní Yorùbá? Kí ní ń jẹ́ oracle, rituals àti divination ní ojúlówóo Yorùba? Láìsí àní-àní, Ọ̀mọ̀wé Alisa LaGamma, olóòtú àkójọpọ̀ àwòrán wọ̀nyí láti ilẹ̀ èèyàn dúdú) ń fi gẹ̀ẹ́sì ronú ni nígbàtí ó ṣa àwọn ère inú ìwé yǐ jọ. Ọkọ́ọ gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi ro gbogbo oko tí ḿ bẹ nínú iwe àkójopọ̀ yǐ. Láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ìwé yǐ kò yọ obì lápò, bẹ́ẹ̀ ni kò wú ni lórí tí a bá ń fi sùn-nù-kùn ojúu Yorùbá wò ó. Artifact, aesthetic qualities, ancestral spiritual realm, figurative àti gbogbo kókó ọ̀rọ̀ tí ḿ bẹ ní ojú ewé kǐnní nìkan ti tó láti mú inú run ọmọ Yoòbá tí ń fi èdè abínibí ronú. Kíni làbárìi “Dynamic Devices: Kinetic Oracles?” Kò lórí, kò nídǐ. Iconography, pluralistic vision, visual metaphor, human protagonists, abstraction, realism, àti àwọn ìkòkò ọ̀rọ̀ yìókù tí ḿ bẹ nínú ìwe yǐ kò se iṣu jinna ní èdèe Yorùbá.

Gbogbo pálapàla yìí ni alàgbà Rowland Abíọ́dún rí, tí wọ́n fi wípé, họ̀ọ́wù: bí a kò bá mọ ibi a ń lọ, ó ṣáà ní ibi tí a ti ḿbọ̀! Baba Abíọdu̇n ní, bí a bá ń sunkún à má a ríran. Ṣe bí àwa Yorùbá ní èdè wa tí a fi ń túmọ̀ àwọn iṣẹ́ ọnàa wa? Ṣe bí àwọn ọ̀mọ̀wé bíi Ọ̀jọ̀gbọ́n Àgbà Ọlásọpé Oyěláràn ti kọ́ wa láti kọ èdè Yorùbá sílẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn?[11] Àbí èèdì fẹ́ mú alásọ kan ni? Ṣe bí Yorùbá ní òwe, àdììtú èdè, orin, àlọ́, ìtàn, ìyẹ̀rẹ̀, èrèmọ̀jé, àyájọ́, ògèdè, àti orísirísi ẹwà èdè tí ó jẹ́ atúmọ̀ fún àwọn iṣẹ́ ọnà wọ̀nyí? Kí ló wá fa réderède bíi “pìrìmítífú, tíráíbálí, tiradíṣánnà, ìsìtóríká, kílásíká, kọ̀ǹtẹ́ḿpórárì, mọ́dáànì” àti gbogbo játijàti báun? Èése tí àwọn èèbó tí wọ́n mọ ìyá Ọ̀ṣọ́ ju Ọ̀ṣó wá ń dá orin, tí àwa ọ̀mọ̀wée Yorùbá ná à sì ḿ bá wọn gbè é, bí ẹni tí kò mọ ojú, tí kò mọ ara? Baba Abíọdún ní, ìka tí ó bá tọ́ sí imú la a ń fi ro imú. A kìí toríi gbígbó pajá. A kìí toríi kíkàn pa àgbò. Ẹnìkan kìi toríi wérewère pa òbúkọ. Élẹ́nu rírì ni ó ni ààmù ìyáa rẹ̀. Èdè, àṣà àti ìwàa Yorùbá ni ó bí iṣẹ́ ọnàa Yorùbá. Ẹní bá bí ni là á jọ. Baba Abíọdún ni, ó tó gẹ́ẹ́. Alubàtá kì í dárin. Ẹnìkan ò gbọdọ̀ gbé ọmọ Ọbà fún Ọ̀ṣun. Díẹ̀ ninu àwọn ìdí abájọ nìyíi tí Baba Abíọdún fi kọ ìwé tí gbogbo àgbáyé ńkà tí wọ́n ń mirí, tí a sì péjọ jókǒ láti yẹwò ní ọjọ́ òní. Baba Abíọ́dún kì í fọhùn, wọ́n ti ìka bọ̀ wọ́n lẹ́nu ni. Ọ̀rọ̀ ló kó mokó morò dé.
Ewé àti egbò tí ń bẹ nínú èdè e Yorùbá ni a fi ki àgbo tí ń bẹ nínú iṣẹ́ ọnà àwọn Yorùbá, gẹ́gẹ́ bí Baba Abíọ́dún ṣe kọ́ wa nínú ìwé tuntun yì í. Ìwée Baba Abíọ́dún rán ni létí orin tí akọrin olóhùn arò Ijẹ̀ṣà, Joni Haastrup, kọ ní ǹkan bí ogójì ọdún sẹ́hìn. Baba Haastrup la ẹnu kótó, wọ́n ní:

Ẹ má jẹ́ wọn ó kọ́ wa
L
’áṣà ilẹ̀ ẹ wa ò

Àṣà tí a ti mọ̀
Láti ọjọ́ aláyé ti dáyé
Òhun lẹ fẹ́ ẹ́ kọ́ wa
A ti mọ̀ ọ́ jù yín lọ.

Àwọn irúnmọlẹ̀ tí wọn ti òkè ọ̀rún sọ̀ kalẹ̀ wá sáyé ni ó ṣa ogunlọ́gọ̀ egbò wọ̀nyín mọ́ ewé láti fi pe ọ̀rọ̀ tí ó dá èdè e Yorùbá sílẹ̀. Bí wọ́n bá sì fa gbùrù ewé kan, fífà ní í fa igbó ewé mìíràn, a dá Ifá fún èèbó o Gẹ̀ẹ́sì tí ó fẹ́ fi èdè àjòjì pe oríkì iṣẹ́ ọnà àwọn Yorùbá, tó wá ń fi omi ojú ṣògbérè akọ. Ó wọrun yànyàn bí ẹni tí ò ní í kú mọ́ láyé, èèbó kọtí ọ̀gbọn-in sẹ́bọ. Èèbó ni Gẹ̀ẹ́sì pàṣẹ pé kí àwọn Yorùbá má a sọ, kí wọn ó sọ èdè abínibí wọn nù. Baba Abíọ́dún ni “Èèwọ̀ ni, èèdì kì í mú aláṣọ kan, kó bọ́ ọ.” Ijó ni Baba Abiodun ni kí awon Yoruba ó má a jó, ayọ̀ ni wọ́n ní ki won o má a yọ̀. Pẹ̀lú ìwé tuntun yì í, Baba Abíọ́dún ti fi bàtá kọrin fún gbogbo àwọn Yorùbá; wọ́n ní:

Ojú lọ̀rọ́ wà, ètè kọ́

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lẹnu 

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lètè

Ojú lọ̀rọ́ wà, ète lẹnu

 

Kọ̀wékọwúrà

Abimbola, Wande. 1975. Ed, Yoruba Oral Tradition (Ile-Ife: Department of African Languages and Literatures, University of Ife.
Abiodun, Rowland. 2014. Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art. New York: Cambridge University Press.
Bacquart, Bacquart. The Tribal Arts of Africa: Surveying Africa’s Artistic Geography. London: Thames and Hudson, 2002.

Bamgbose, Ayo. Yoruba Orthography: A Linguistic Appraisal With Suggestions for Reform. Ibadan: Ibadan University Press, 1965.
Bascom, William R. 1973. African Art in Cultural Perspective. New York: Norton.

Cornet, Joseph. 1971. Art of Africa, Treasures from the Congo, translated by Barbara Thompson. London: Phaidon.

Blier, Suzanne Preston. 2015. Art and Risk in Ancient Yoruba: Ife History, Power, and Identity c. 1300. New York: Cambridge University Press.

Drewal, Henry, and Pemberton, John, with Abiodun, Rowland. 1989. Yoruba: Nine Centuries of African Art and Thoughts. New York: Center ofAfrican Art and Harry N. Abrams.

Fagg, William, and John Pemberton. 1982. Yoruba Sculpture of West Africa, edited by Bryce Holcombe. New York: Knopf.
Joint Consultative Committee on Education.  1974. Revised Official Orthography for the Yoruba Language: Yoruba orthography. Lagos: The Committee.

LaGamma, Alisa, and Pemberton, John. 2000. Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination. New York, N.Y. Metropolitan Museum of Art Metropolitan.

Nardo, Don. 2010. The European Colonization of Africa. New York: Morgan Reynold, 2010.

Newton, Douglas. 1978. Masterpieces of primitive Art. New York: Knopf.
Okediji, Oladejo. 1969. Àjà Ló Lẹrù. Ibadan: Longman Nigeria Limited.

Olajubu, Oludare. 1972. Àkọ́jọpọ̀ Iwì Egúngún. Ibadan. Longman Nigeria Limited. John Picton, Picton, John. “On the Invention of ‘Traditional’ Art,” in Moyo Okediji, ed., Principles of `Traditional’ African Culture. Ibadan: Bard Book.
Oyelaran, Olasope. 1977. “Linguistic Speculations on Yoruba History.” Seminar Series, vol. I, Part II. Ile-Ife: Department of African Languages and Literatures, University of Ife: 624-51.

Wingert, Paul S. 1962. Primitive Art: Its Traditions and Styles. New York: Oxford University Press.
Young, Crawford. 2012. The Postcolonial State in Africa: Fifty Years of Independence, 1960–2010. Madison: University of Wisconsin Press.

[1] See Rowland Abiodun, Yoruba Art and Language: Seeking the African in African Art, (New York: Cambridge University Press, 2014).

[2] Èkejì òrìṣà ni Awíṣẹ Àgbáyé Wándé Abímbọ́lá jẹ́ nínú ẹ̀kọ́ èdèe Yorùbá. N kò lè gbàgbé láíláí ní ọjọ́ kan nínúu kíláàsìi ti Yunifásitì Ilé Ifẹ̀, ní ọdún un 1973, tí Awíṣẹ ń kọ́ wa ní Ifá, tí babá sọ wípé, “Géésù Kirisì, àbí ẹ ti ń pè é….” Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni mo jẹ́ nígbà náà. Ẹ̀rǔ bà mí nígbà tí Awíṣe fọhùn yìí. N kò gbọ́ irúwá ọ̀rọ̀ báyìí rí, gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ti fi ẹ̀sin àwọn Èèbó pa ní iyè lati pínnísín. Ṣe ni mo rò wípé àrá yíò sán lójijì láti pa gbogbo àwa tí a wà nínúu kíláàsì ná à. Baba Abímbọ́lá kàn ń dá obì jẹ ni, bí wọ́n ṣe ń kì wá láyà, tí wọ́n sì ń kọ́ wa ní àṣà, òrìṣà, àti ìlànà àwọn Yorùbá. Mo ríbá, mo ríbà o, Awíṣẹ Àgbáyé, ọmọ baba afàdá ọwọ́ ẹ pàjakùmọ̀.

[3] Moyo Okediji, ed., Yoruba Images; Essays in Honour of Lamidi Fakeye, (Ile Ife: Ife Humanities Society, Obafemi Awolowo University, 1988).

[4] Don Nardo, The European Colonization of Africa, (New York: Morgan Reynold, 2010).

[5] Crawford Young, The Postcolonial State in Africa: Fifty Years of Independence, 1960–2010, (Madison: University of Wisconsin Press, 2012).

[6] Paul S. Wingert, Primitive Art: Its Traditions and Styles, (New York: Oxford University Press, 1962).

[7] Douglas Newton, Masterpieces of primitive Art, (New York: Knopf, 1978).

[8] Bacquart, Jean-Baptiste. 2002. The Tribal Arts of Africa: Surveying Africa’s Artistic Geography. London: Thames and Hudson.

[9] John Picton, “On the Invention of ‘Traditional’ Art,” in Moyo Okediji, ed., Principles of `Traditional’ African Culture, (Ibadan: Bard Book, 1992).

[10] Alisa LaGamma, and John Pemberton, Art and Oracle: African Art and Rituals of Divination, (New York: N.Y. Metropolitan Museum of Art Metropolitan, 2000.

[11] Ayo Bamgbose, Yoruba Orthography: A Linguistic Appraisal With Suggestions for Reform, (Ibadan: Ibadan University Press, 1965); Joint Consultative Committee on Education, Revised Official Orthography for the Yoruba Language: Yoruba orthography, (Lagos: The Committee, 1974). Ọ̀jọ̀gbọ́n Ọlásọpé Oyěláràn ni wọ́n kọ́ mi ní ìkọsílẹ̀ èdèe Yorùbá ní Yunifásítì Ile Ife lati 1973 titi di 1977; mo ríbà o.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *