Olóko ń sun kún
Oní igba ewùrà ló nù ní ódẹ̀ òhun
Ará ilé mi ní:
òhun ò l'oko, bẹ́ẹ̀ l'òhun ò ká ewùrà.
Ará ọjà ń pariwó
Wọ́n ní èrè ọjà ò délẹ̀ kó tó tú
Ará ilé mi ní:
Ẹni bá l’ọ́jà ní káasọ̀
Ará ọ̀nà fi igbe ta
Wọ́n ní koríko tí di ejò s’ọ́nà
Ará ilé mi ní:
Ẹni bá re àjò ló n fi ojú kó'mí
Ará àdúgbò náà tún ké gbàjarè
Wọ́n ní ogójì adìye ti pòórá
Ará ilé mi ní:
Òhun ò L'ọ́gbà, bẹ́ẹ́ náà lọ̀hun ò sin adìyẹ
Ṣùgbọ́n ilẹ̀ ṣú
Agánrándì ará ilé mí ro gbáà
Ó ní ǹjẹ́ ilẹ̀kùn yàrá òun ló ṣí bí?
Ilẹ̀ mọ́ ará ilé mi káwó l'órí
Tòun ti omi ojú
Oní ìjì tó jà lésìí
Tó mú olóko sun kún
Ìjì tó jà lésìí tó mú ará ọjà pariwo
Ìjì tó jà lésìí tí ará ọ̀nà fi igbe taa
Ìjì tó jà lésìí tó mú ará àdúgbò ké gbàjarè
Ojúde oun ló fi àbọ̀ sí
Àṣé màkàn màkàn l'oyè ń kàn.
Ẹni tó kàn l'ómọ̀.
Àpọ́n
Àpón ni mí
Mi ò l'áya nílé
Àkùkọ gọ̀lọ̀tọ̀ mí múra tán
Ọ́ ge fìlà lórí sányán
Ọ́ ní òun re òde ìyàwó
Wọ́n ní tèmi ńkọ́
Mo ní Ọlódùmarè lọ́ ń ṣe aya
Àláwùràbí ní ń mú ni rìn nà kò'fẹ́
Àgbàlá mi pa lọ́lọ́
Sèbí eni bá láya, ní í l'ọ́tà á
Ẹni bá láya ní í gún iyán òwúrọ̀
Bàbá à mí wí wí wí
Ó ní kòsí òkóbó ní ìran àn mi
Ìyáàmi tò tò tò
Ó ní èyìn òhun gba igbá
Bẹ́ẹ̀ sì ló gba ire
Àpón jẹ́ kin gbé ọmọ jó
Àpón jẹ́ kin gbé ọmọ yọ̀
Mo pàdé òdòdó lọ́nà odò
Sùgbón òdòdó ò ṣe é mú re odò
Tó bá bó sí omi ń kọ́?
Kín to darí bọ̀
òdòdó ti bà ẹlòmíràn lọ ilé
Mọ́ pàdé òṣùpá ìfẹ́ lọ́nà oko
Sùgbón òṣùpá ìfẹ́ ò ṣe é mú re oko
Kín to daarí bọ̀
Òṣùpá ìfẹ́ ti wọ̀ sí abà ẹlòmíràn.
Nípa Oǹkọ̀wé
Ònkòwé àbínibí ni arákùnrin Olátúndé Àyìnlá jé, olóòtú àgbà sì lọ́jẹ́ lórí búlọ́ogì Yorùbá. Ìlú lárúbáwá ilẹ̀ Dubai ló ti fi àwọn iṣẹ́ yìí ránṣẹ́.