Àkọ́lé Ìwé: Ìgbà Èwe (Childhood)
Ònkọ̀wé: Emily R. Grosholz
Olùtúmọ̀ sí Èdè Yorùbá: Kọ́lá Túbọ̀sùn
Ọdún Tó Jáde: 2021
Olùtẹ̀wé: Ouida Books
ISBN: 978-978-990-701-4
Ní ayé òde òní, ìgbéga àti ìlọsiwájú èdè Yorùbá kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ní àwùjọ wa. Ìfàsẹ́yìn yìí kì í ṣe kèréémí, àti pé ó máa ń kọni lóminú láti ri pé àbùkù ń bá ará ilé àti ará oko. Ní inú ilé wa, àwọn òbí kò fi bẹ́ẹ̀ fi èdè Yorùbá bá àwọn ọmọ wọn sọ̀rọ̀ mọ́. Àrídájú tún wà pé kò sí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàrin àwọn ará ìlú àti ìjọba láti ṣe agbátẹrù èdè, àṣà àti ìṣe Yorùbá. Awọn Yorùbá sì bọ̀, wọ́n ní bí a bá fi wèrè sílẹ̀ kí o ṣe òkú ìyá rẹ̀ bí ó bá ṣe fẹ́, ǹkan ó wulẹ̀ bàjẹ́ ni. Èyí ló dífá fún Kọ́lá Túbọ̀sún, àgbà òǹkọ̀wé àti agbédèga tí ó yanrantí, tí ó fi ṣe aáyan ògbufọ̀ ìwé ewì Emily R. Grosholz tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Childhood” ní èdè gẹ̀ẹ́sì, tí àkọ́lé rẹ̀ sì ń jẹ́ “Ìgbà Èwe” ní èdè Yorùbá.
Ní àkọ́kọ́, ó yẹ kí á mọ̀ pé iṣẹ́ aáyan ògbufọ̀ kì í ṣe iṣẹ́ kékeré. Ó sì ṣe pàtàkì láti gbóṣùbà fún Kọ́lá Túbọ̀sún fún akitiyan rẹ̀ láti ri i pé èdè Yorùbá kò jó ijó àjórẹ̀yìn. Ó tún ṣe pàtàkì láti kí Emily kú iṣẹ́. Gẹ́gẹ́ bí àwa náà ṣe mọ̀ pé tí kò bá sí iṣu, kò lè sí iyán, àti pé àgbájọwọ́ la fi í sọ àyà; ẹnìkan kìí jẹ́ à wá dé.
Nínú ìwé yìí, tí àkọ́lẹ́ rẹ̀ jẹ́ “Childhood” ní èdè gẹ̀ẹ́sì, tí Yorùbá rẹ̀ sì jẹ́ “Ìgbà Èwe”, a rí bí Kọ́lá Túbọ̀sún ṣe fi èdè dárà àti bí ó ṣe gbé ẹwà ewì tí Emily kọ ní èdè gẹ̀ẹ́sì yọ. A rí ìbáṣepọ̀ tí ó wà láàrin èdè àti ìsọwọ́lo gírámà Kọla Túbọ̀sun. A rí lílo àwọn ẹwà èdè bí i àfiwé tààrà, àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́, ìfohùnpènìyàn, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Tí a bá ka ìwé náà dáradára, kò sí iyèméjì pé Emily kọ ewì tí ó bá ìgbà mu—pàápàá jùlọ bí ó ṣe jẹ mọ́ ìgbà èwe; ìgbà tí a kéré, tí òye ayé kò tí ì yé wa tó. Ìgbà èwe yìí ni ìgbà tí a ò tí ì mọ ọwọ́ ọ̀tún yàtọ̀ sí ọwọ́ òsì. Ìgbà yìí kan náà ni àwọn òbí máa ń ṣe wàhálà jù lórí ọmọ. Fún àpẹẹrẹ, Ìyá jẹ́ ẹnìkan tí ó gbọ́dọ̀ mójútó ọmọ dáradára, àtipé láti inú oyún ni ìyá tí ń tọ́jú ọmọ bọ̀. Láti inú oyún yìí náà ni jíjẹ àti mímu ọmọ ti bẹ̀rẹ̀. Tí ọmọ bá dé ilé ayé tán, ìtọ́jú tún tẹ̀ síwájú ni.
Ni inú ìwé ewì tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Ìgbà Èwe” yíì, àwọn òǹkàwé yóò ṣe alábapàdé àwọn ewì tí ó sọ̀rọ̀ nípa ìgbà tí ọmọ wà nínú oyún, ìrètí àwọn òbí nígbà tí ọmọ kò tí ì dáyé, ìdùnnú àwọn òbí– pàápàá jùlọ Ìyá ọmọ nígbàtí ọmọ bá ń dàgbà bọ̀. Nínú ìwé yìí náà ni a tún ti rí àwọn ǹǹkan tí ọmọ máa ń ṣe nígbà tí ó bá ń dàgbà bọ̀. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ọmọkékeré nífẹ sí eré púpọ̀, àti pé kò sí ǹǹkan tí wọn kò le è fi seré. Àwọn Yorùbá bọ̀, wọ́n ní arúgbó ṣ’oge rí àkísà lògbà rí. Àgbà wá búra bí èwe kò bá ṣe ọ́ rí.
Ewì àkọ́kọ́ nínú “Ìgbà Èwe” ni àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Listening” ni èdè gẹ̀ẹ́sì, tí ìtumọ̀ rẹ̀ ní Yorùbá sì jẹ́ “Ìtẹ́tísí”. Nínú ewì yìí, a rí bí Kọ́lá Túbọ̀sún ṣe fi èdè dárà nípa ṣíṣe aáyan ògbufọ̀ ewì náà láti èdè gẹ̀ẹ́sì sí èdè Yorùbá. Nínú ewì yìí bákan náà, a rin ìrìn àjò bí ọmọ ṣe wà nínú ikùn ìyá rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ìyá rẹ̀ ń gbọ́ ohun tí ọmọ náà ń sọ. Ìyá náà wà ní ipò ẹni tí ó ń retí ọmọ náà, àti pé nípa ọ̀rọ̀ sísọ, Ìyá náà ń gbáradì fún ọmọ náà. Ó ń ṣe ètò kalẹ̀ kí ọmọ náà tó dé. Ewì náà lọ báyìí:
Ọ̀rọ̀ l'étí mi, ẹnìkan àìrí
Kò tíì d'ènìyàn, ṣùgbọ́n ní ìdákẹ́jẹ́
Ó ń jípépé nínú mi;
Kò tíì l'órúkọ, síbẹ̀
Mò ń kọ́ ibùgbé fún-un láti inú ọ̀rọ̀ sísọ.
Díẹ̀ nínú ilé ayé ló dá dúró
Yàtọ̀ fún ohun tí a sọ síta, sùgbọ́n díẹ̀ á dúró
Bí a bá tẹ̀síwájú láti máa sọ̀rọ̀; ọ̀rọ̀ nìkan
Ló leè tún àwọn ọgbà ilé ayé dá.
- (Ojú ewé kẹta - 3)
Nínú ewì yìí, a tún lè sọ nípa pàtàkì ọ̀rọ̀, àti ìwúlò rẹ̀ ní àwùjọ wa. Ọ̀rọ̀ ni ó máa ń yọ obì lápò, òhun náà ló sì máa ń yọ idà lápó. Ọ̀rọ̀ ni Elédùà fi dá ilé ayé, àti pé ọ̀rọ̀ náà ni Elédùà yóò sọ nígbà tí ayé bá fẹ́ parẹ́. Sísọ ọ̀rọ̀ sí ọmọ dára, àtipé nínú oyún, ọmọ a máa mí nínú ìyá. Àwọn aláboyún míràn wulẹ̀ sọ pé àwọn a máa gbọ́ ohùn àwọn ọmọ àwọn. Àwọn míràn sọ nípa bí oyún inú ṣe máa ń fi ìpà gún àwọn nínú.
Nínú ewì míràn tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Thirty-six Weeks” ní èdè gẹ̀ẹ́sì tí Yorùbá rẹ̀ sì jẹ́ “Ọ̀sẹ̀ Mẹ́rìndínlógún” a rí ìbámu òǹkà náà pẹ̀lú oṣù mẹ́ẹ̀sán tí ọmọ yóò wáyé. Nínú ewì yìí ni akéwì ti sọ nípa ìdàgbàsókè ọmọ nínú oyún. Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ pé inú ikùn ìyá ni ọmọ yóò ma gbé títí tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ yóò fi pé, àti pé awọ inú ìyá ni ó bo ọmọ náà mọ́ lẹ̀. Ìyá ni ilé àti ọ̀nà fún ọmọ náà. Òun náà ni òrùlé àti ògiri rẹ̀. Akéwì náà sọ báyìí:
"Èmi l'òrùlé ẹ̀, ògiri ẹ̀, inú ilé ẹrù olóoru,
Tí a to ìgò àìlò ọtí wáìnì búlù yíká.
Etí òkun ẹ̀, àwọn owó ẹyọ ẹ̀
Tí a kọ sí ìrúsókè kékèké inú ibi ọmọ mi."
- (Ojú ewé Karùn-ún - 5)
Ní inú ewì yìí ni a ti ri kà pé ọmọ tí ó wà nínú ìyá rẹ̀ a máa gbọ́ ohùn ìyá àti bàbá rẹ̀. Ìdùnnú ńlá ni fún àwọn òbí méjéèjì pé àwọn ń retí ọmọ tuntun. Ní inú oyún, ipò ẹlẹgẹ́ ni obìnrin máa ń wà. Nínú ipò yìí, orísirísi ǹǹkan ni yóò ma wù wọ́n jẹ. Orísirísi ǹǹkan ni wọn yóò maa dojúkọ. Ní ìgbàmíràn ẹ̀wẹ̀, aláboyún yóò rí ìnira nípa ọmọ tí ó wà nínú rẹ̀. Àtipé ní àkókò tí obìnrin bá wà nínú oyún, ó gbọ́dọ̀ sinmi wàhálà ní ṣíṣe.
Kọ́lá Túbọ̀sún tẹ̀ síwájú nípa títú àwọn ewì tó kù nínú ìwé yìí sí èdè Yorùbá pẹ̀lú ojú àti ọkàn tí ó mọ èróńgbà Emily nípa àwọn ewì rẹ̀ ní èdè gẹ̀ẹ́sì. Nípa lílo orísirísi àwòrán ọmọ tuntun jòjòló àti ìyá rẹ̀ nínú ìwé náà, a rí àrídájú ìfẹ́ òǹkọ̀wé sí àwọn ọmọkékeré àti ìdàgbàsókè wọn. Ní inú ewì míràn nínú ìwé náà tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “After” ní èdè gẹ̀ẹ́sì, tí ìtunmọ̀ rẹ̀ ní èdè Yorùbá jẹ́ “Lẹ́yìnọ̀rẹyìn”, a rí ìgbìyànjú ìyá lórí ọmọ. Bí ọmọ kò sùn, ìyá kò le è fojú ko’run. Bí ọmọ kò jẹ, ìyá kò le è jẹ. Ní ìgbàmíràn, ọmọ yóò jí pẹ̀lú ẹkún àsunùndá ní òru. Kí á má parọ́, òbí ń jìyà lórí ọmọ. Ewì yìí múmi rántí orin tí a máa ń kọ ni ilé ìwé girama ní ayé àtijọ́ fún àwọn òbí wa. Orin náà lọ báyìí:
Ìyá ni wúrà iyebíye
Tí a kò lè fówórà
Ó lóyún mi fóṣù mẹ̀sán-án
Ó pọ̀n mí f'ọ́dún mẹ́ta…
Orin yìí jẹ́ orin tí àwọn ọmọ máa ń kọ láti mọ rírì àti ìlàkàkà àwọn ìyá wọn lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ṣe mọ̀ pé kúuṣẹ́ ló ń mú orí oníṣẹ́ yá, orin yìí jẹ́ orin ìwúrí àti orin ìfiẹ̀mí ìmoore hàn. Ní inú ewì tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Lẹ́yìnọ̀rẹyìn”, a ri kà báyìí:
Lálalẹ́ lo máa ń jí
Lóru, láago mẹ́ta, láago méje,
Láìjanpata, ṣùgbọ́n pẹ́lù ebi
Fún wàrà ọmú, àti fún mi.
- (Ojú ewé kẹtàlá - 13)
Kò sí iyàn jíjà nínú pé ọmọ tuntun jòjòló yóò da ìyá rẹ̀ láàmú. Èyí kò ṣe é sá fún. Èyí sì hàn nínú ewì náà pẹ̀lú bí ìyá ṣe ń ṣe àìsùn nítorí ọmọ ìkókó. Lára ewì tí Kọ́lá Túbọ̀sún tún tú sí èdè Yorùbá ni a rí èyí tí àkọ́lé rẹ̀ ń jẹ́ “Through the Darkness Be Thou Near Me” ní èdè gẹ̀ẹ́sì, tí Yorùbá rẹ̀ sì jẹ́ “Láàárín Òkùnkùn, Wà Lẹ́gbẹ̀ẹ́ Mi”. Ewì yìí sọ nípa ìfẹ́ àìlábàwọ́n tí ó wà láàrin Ìyá àti ọmọ. O sàlàyé nípa ìyá àti bí ó ṣẹ káràmásìkí ọmọ; eléyìí tí ó sì jẹyọ nínú bí ó ṣe dúró de ọmọ rẹ̀ kó sùn kì òun tó sùn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́pẹ́ ìyá yìí tún ní àwọn iṣẹ́ ilé láti ṣẹ, ó tún wà nínú òkùnkùn pẹ̀lú ọmọ rẹ̀. Ó dúró tí gbogbo ilé fi wà ní ìdákẹ́jẹ́jẹ́. Olùtúmọ̀ náà sọ báyìí:
Nígbà mìíràn, mo jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ nínú òkùnkùn
Bóo ṣe tẹ̀ síwájú súnmọ́ oorun,
Ibùsùn rẹ bí ọkọ̀ tó ń r'òkun
Lórí Serpentine.
Pẹ̀lú ìkọbiarasí àwọn iṣẹ́ mìíràn (ilé dídọ̀tí,
Ọ̀rọ̀ tí aà tíì kọ), síbẹ̀ mo fẹ́ràn dídúró náà
Nígbà tí gbogbo nǹkan bá dákẹ́, ìwọ gan,
Kóda àìlèmáradúró mi.
- (Ojú ewé kọkàndínlọ́gbọ̀n - 29)
Nínú àwọn ewì yóókù tí ó wà nínú ìwé yìí ni a ti rí àwọn èyí tí ó sọ nípa ṣíṣere ọmọ nínú òjò, ìṣàwárí pọ̀tọ̀pọ́tọ̀, kíkọ́ ọmọ ní ilé ìwé àti kíkọ́ ọmọ ní dùùrù títẹ̀, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Kò sì sí àṣàdànù nínú àwọn ewì náà. Gbogbo wọn ni wọ́n gbé oúnjẹ fún ẹgbẹ́, tí wọ́n sì tún gba àwo bọ̀. Wọ́n jẹ́ ewì tí Kọ́lá Túbọ̀sun ṣe iṣẹ́ dáradára lé lórí nípa aáyán ògbufọ́ tó ṣe lórí wọn. Èmi yóò rọ Kọ́lá Túbọ̀sun láti ma dáwọ́ iṣẹ́ gbígbé iná èdè Yorùbá káàkiri àgbáyé. Léẹ̀kan si, mo kan sáárá sí Emily Grosholz àti Kọ́lá Túbọ̀sún.
Nípa Olùtúmọ̀
A bí Kọ́lá Túbọ̀sún ni ọdún 1981 ní ìlú Ìbàdàn. Kọ́lá jẹ́ òǹkọ̀wé àti onímọ̀-èdè, tí ó sì gba àmì ẹ̀yẹ Premio Ostana Prize ni ọdun 2016 làtàrí àwọn iṣẹ́ tó ti ṣe fún ìgbélárugẹ èdè àti àṣà. Láìpẹ́ yìí, Kọ́lá jẹ oyè olùwádí Chevening, tí ó sì ṣíṣẹ́ ni British Library, lẹ́yìn náà ni ó di Olóòtú Ètò ni Yorùbá Academy ni Ibàdàn. Kọ́lá ti túmọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àwọ́n òǹkọ̀wé káàkiri, lára àwọn òǹkọ̀wé tó ti túmọ̀ iṣẹ́ wọn láàárin èdè Yorúbà sí èdè Gẹ̀ẹ́sì ni Ngugi wa Thiong’o, Chimamanda Adichie, Túbọ̀sún Ọládàpọ̀, Lánrewájú Adépọ̀jù, Sarah Ladipo-Manyika, Cervantes, James Baldwin àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Edwardsville by Heart jẹ́ àkójọpọ̀ ewì akọ́kọ́ oun alára tí ó kọ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n sì tẹ̀ẹ́ jáde ní ọdún 2018.
Nípa Olùgbéyẹ̀wò
Rasaq Malik Gbọ́láhàn jẹ́ akẹ́kọ̀ gboyè méjì nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì ní ilé ìwé gíga fásitì ilú Ìbàdàn. Ó wà lára àwọn ọ̀mọ̀wé tó gba Fulbright ní ọdún 2019 sí ọdún 2020 tí ó sì kọ́ àwọn òyìnbó ni Yorùbá ni Fásitì Kansas. Ó jẹ́ ẹni tí ó fẹ́ràn àṣà àti ìṣe, àti pé ó ní ìgbàgbọ́ pé èdè abínibí ni ọ̀nà tí a lè fi gbé ìlú lárugẹ. Ó tún jẹ́ ẹni tí ó máá ń kéwì, ó sì tún fẹ́ràn láti ma ka ìwé Yorùbá. Bótilẹ̀ jẹ́ pé ó ń ṣiṣẹ́ lórí ìtàn àròkọ rẹ̀ lọ́wọ́, o ti tẹ àkójọpọ̀ ewì méjì jáde ní èdè Gẹ̀ẹ́sì eléyìí tí àkọ́lé wọn ń jẹ́ No Home In this Land àti The Other Names of Grief.