Ẹ wí f’ẹ́ni tí ń sáré owó
Pélé t’ówó kọ a máa wọ́
Ẹ rò f’ẹni tí ń kànlẹ̀kùn ọlà
P’ọlà òní lè má dò̩la
B’ẹni lówó lọ́wọ́ tó r’ogún ẹ̩rú
Béèyàn lọ́lá lọ́là tó yọ́gbọ̀n ìwọ̀fà
Ikú tíí p’ẹrú níí pa wọ́n
Isà òkú wọn kìí jìn ju tìwọ̀fà
Ẹ̀ bá wí f’Ọláìítán p’ọ́lá a máa tán
Ẹ̀ bá rò f’Ówónikókó p’óníhun tíí ku ni kù
Ohun tíí sìí ku ni kù náà nìwà
Bó o bá torí àtilówó tó o hùwà àìtọ́
Bórí bá ọ́ ṣé tó o gbó, ìgbẹ̀yìn rẹ ò le tọ́
Bó o bá torí àtilọ́lá tó o hùwà ìkà
B’ọ́jọ́ bá d’alẹ́, ẹ̀san ìkà lo máa ká.
Káyọ̀dé Akínwùmí jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Yorùbá ní Yunifásítì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ́, ipele àṣekágbá. Káyọ̀dé fẹ́ràn ìtàn púpọ̀, a máa gbọ́ orin lọ́pọ̀ ó sì jẹ́ olùwòye lórí ọ̀rọ̀ tó ń lọ.