Nígbà kan rí, àwọn ẹranko kéréjekéréje bi Eèrà, Ìjàlọ, Eku, Aáyán, Ikán àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ yan Ìjàlọ kó máa ṣe olorí wọn. Wọ́n ṣe èyí ní ìbámu  òfin pé àwọn náà gbọ́dọ̀ ṣe bí àwọn ẹranko ńlá.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìjàlọ ni wọn yàn, síbẹ̀, wọn kò fi tàràtárá gbà pé òun ni ó kúnjú òṣùwọ̀n. Ìdí ni pé lọ́jọ́ náà lọ́ǔn, wọn kò fìbò yàn-án sípò bí àwọn ẹranko ńlá ti ṣe àti pé alágbára, olówó òun ọlọ́lá ni wọ́n fi ń ṣe olórí. Ìgbà tí ọjọ́ ń gorí ọjọ́, tó’ṣù ń gorí oṣù, tí ọ̀làjú ń la ojú àwọn ẹranko ni wọ́n ri pé kò tọ̀nà kí wọ́n fi irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀ yan olórí mọ́ ọ́n.

Nítorí ìdí èyí ni wọ́n fi ń kùn kiri pé kí wọ́n wá ọ̀nà mìíràn láti yan olórí àti pé ọba Ìjàlọ ti lo ọdún méje lórí àléfà, a kìí fi ìtìjú kárùn. Ọ̀nà tí wọ́n sì fẹ́ gbà yan Olórí ni kí ẹnìkan ṣe’hun tẹ́nìkan kò gbé ṣe rí.

Ọ̀pọ̀ ẹjọ́ ọba Ìjàlọ ni wọ́n ma fi ń sun Ọba Kìnìṹ; gẹ́gẹ́ bí olórí ńlá, àṣẹ tí Kìnìṹ bá ti pa náà labẹ́ gé.

Mo rántí ‘hun tó ṣe bí ìjà láàrín Eèrà àti Ìjàlọ lọ́jọ́ náà. Ọba Ìjàlọ fẹ́ fi Eèràwùnmí ṣe aya. Omọ náà rẹwà púpọ̀, tẹ̀gàn ni hẹ̀!

Ó ní kí ọmọ náà lọ pe bàbá rẹ̀ wá sí Ààfin. Kí Eèrà tó dé Ààfin ni ó ti ń ro ìdí tí irú ìpè bẹ́ẹ̀ fi wáyé, ó ṣe bí ọ̀rọ̀ ìdàgbàsókè ìlú ni ó pe òun fún.

Ọba Ìjàlọ ki ẹnu bọ̀rọ̀. Eèrà fárí gá pé kò lè ṣe é ṣe. Ó ní lótìtọ́ ni pé ọba ba lé ohun gbogbo ṣùgbọ́n báyìí là á ṣe é, èèwọ̀  ni nílẹ̀ bòmíì. Ó jẹ́ kó yé e pé àwọn ènìyàn gidi bí i Àjàyí, Délé, Tòkunbọ̀ àti bẹ́ẹ̀ ni Eèràwùnmi yóò fi ṣọkọ.

Bí ó ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀gbin yìí, ó lanu sílẹ̀, kò le paádé,  inú rẹ ru. Kò mọ èsì tó yẹ kó fun. Kò fẹ́ ṣèdájọ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀.  

Ìgbà tí Eèrà ri bí ojú Ọba ti ń kọ mọ́namọ̀na ló ní kí ọba fún òun níṣẹ̀jú mẹ́ta lọ ṣẹ̀yọ́. Ìfẹ́ a féwé! Ó ti fẹ́rẹ̀ délé rẹ̀, wọ́n ní kí ojú má ríbi, gbogbo ara loògùn rẹ̀.

Ọ̀rọ̀ yìí kò tán nínú Ọba Ìjàlọ. Ó gbà pé àbùkù ni Eèrà fi kan òun. Kò sẹ́ni tí kò mọ̀ pé Ọba Ìjàlọ burú ju Ọba Fáráò inú Bíbélì lọ. Kódà, Ṣàpọ̀nná ni láàrín àwọn ẹranko kéréjekéréje, oró rẹ̀ ju ti Àkeèké lọ. Ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò ní lọ láì jìyà lọ́dọ̀ Ọba Ìjàlọ.

Ọba pàṣẹ kí wọ́n lọ gbé Eèràwúǹmí lọ́jọ́ kejì lẹ́yìn tí àwọn òbí rẹ̀ ti ròde ìkómọjáde kan. Kò ṣe méní,  kò ṣe méjì, ó ta Eèràwùnmí pa títí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀. Ó ní òun yóò ma wo ẹni tí á fi òkú ọmọ rẹ̀ ṣèyàwó.

Ọ̀ràn tí ọba dá yìí dá gbọ́nmisi-omi-ò-to sílẹ̀. Eèrà àti àwọn ẹbi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀. Níṣe ló ń gbéra rẹ̀ ṣánlẹ̀ bí ẹni tí wárápá ń dà láàmú. Bí ó ti ń tutọ́ sókè ló ń fojú gbàá ṣùgbọ́n ẹ̀pa kò bóró mọ́, ewé ti sunko. Ẹni tí kò gba kádàrá á gba kodoro.

Ó gbà sí kámú lẹ́yìn oṣù méjì àbọ̀. Gbogbo àwọn ẹranko kéréjekéréje tó kù tilẹ̀ dìde láti gbèjà Eèra ọ̀rẹ́ wọn. Wọ́n lọ rojọ́ fún Ọba Kìnìṹ tíí ṣe olórí gbogbo wọn lápapọ̀. Ọ̀rọ̀ náà dun Kìnìṹ  púpọ̀ nítorí onírẹ̀lẹ̀ ni Eèrà í ṣe, kìí bá ẹnikẹ́ni ta. Ọba tẹ̀lé òfin ìlú, láì fọ̀tá pè, Ó pàṣẹ pé ibikíbi tí wọ́n bá ti rí Ìjàlọ àti ẹbí rẹ̀, pípa ni kí wọ́n máa pa wọ́n àti pé àrà tó bá wun Eèra ni kí ó fi òkú rẹ̀ dá. Àṣẹ yìí sì mulẹ̀ títí di òní.  

Níṣe ni Ìjàlọ ń wò pàkò bi orí ẹran nígbà tí wọ́n rọ̀ọ́ lóyé. Lẹ́yìn ọdún kan tí iná ìjà láàrín Ìjàlọ àti Eèrà kú, àwọn ẹranko ṣèpàdè láti yan olórí tuntun. Wàyí, wọn kò fẹ́ ẹni tí yóò máa ṣe bó ṣe wùn-ún mọ́. Wọ́n fẹ́ mọ ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n nípasẹ̀ ṣíṣe ‘hun tẹ́nìkan kò ṣe rí láti fi lè mọ̀ ọ́.

Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, gbogbo àwọn ẹranko jòkòó ní òbìrìkítí. Wọ́n ń rẹ́rìn-ín lórí àwọn àwàdà ọ̀kan-ò-jọ̀kan.

Eegbọn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Ta ti ẹ̀ l’ẹ̀gbọ́n láàrín wa bí a bá tilẹ̀ fi ojú inú àt’ọ̀làjú wò ó?” Gbogbo wọn rẹ́rìn-ín ìyàngì.

“Aáyán lẹ̀gbọ́n“. Ìdun ló dáhùn, bí Aáyán bá ń rìn, tó ń fò, kò sẹ́ni tí kìí mọ̀, àwọn ènìyàn pàápàá maá ń ní ìmọ̀sílára”.

“Ó dáa, ta ló wá ṣàì lẹ́sẹ̀ńlẹ̀ nínú wa o?” Àkekèé ló bèrè bẹ́ẹ̀. “Hà! Ta ni kò mọ̀ pé Kọ̀ǹkọ̀ kékeré yìí ni’’. Ikán ló fọhùn bẹ́ẹ̀, gbogbo wọn bú sẹ́rìn-ín lẹ́ẹ̀kan náà. Kúlúsọ fèsì,  ó ní bí Kọ̀ǹkọ̀ bá ń sọ̀rọ̀, kò sẹ́ni gbọ́’hun tí ń wí, dípò kí ó ma rìn, níṣe ló ma ń tọ kébé lẹ̀ mọ́ ògiri kiri bí ẹni ẹsẹ̀ ń dùn.

Ọ̀rọ̀ yìí wọ akínyẹmí ara Kọ̀ǹkọ̀. Ó bi nínú púpọ̀ ṣùgbọ́n ó fi ṣe osùn, kò jẹ́ kó hàn lójú rẹ̀. Ó sọ ọ́ nínú ara rẹ̀ pe “orúkọ ta ó sọ ọmọ ẹni, inú ẹni ni í gbé”. Kò gbà pé Aáyán l’ẹ̀gbọ́n rárá àti rárá.

Bí Kọ̀ǹkọ̀ ti ń lọ sí ìpàdé ẹbí lọ́jọ́ kejì, ó pàdé Aáyán lọ́nà. Kọ̀ǹkọ̀ dọ̀bálẹ̀ kíi ṣùgbọ́n Aáyán kò fi taratara dáhùn. Ó wòó tẹ̀gbin tìkà.

Kọ̀ǹkọ̀ ní ‘‘káàárọ̀ o bùrọ̀dá Aáyán, jọ̀wọ́, mo fẹ́ bẹ̀ẹ́ lẹ́bẹ̀ kan’’. Aáyán ní “kí ni ò?”.  Kọ̀ǹkọ̀ bá kẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “mo gbà pé ìwọ l’ẹ̀gbọ́n bí àwọn ọ̀rẹ́ wa tó kù kò bá gbà bẹ́ẹ̀”. ‘’Lákọ̀kọ́ọ́, o dé ayé sáájú mi, o sì tún ga jù mí lọ. Wàá ṣàkíyèsí pé nígbà tí Ikán ń sọ̀rọ̀, mi ò fèsì. Ohun tí mo fẹ́ ni pé kí a jẹ́ ọ̀rẹ́ kòríkòsùn k’áwọn tókù máa jowú wa, máa mu mi jáde k’émi náà ó lè máa rìn fáfá bíi tìrẹ, (àbí ta ni kò mọ̀ pé Kọ̀ǹkọ̀ ń rìn fáfá ju Aáyán lọ? ).

Ọ̀rọ̀ yìí dùn létí Aáyán. Níṣe ló ń sọ̀jìká wúkẹ́wúkẹ́ bí ẹni tó fẹ́ b’ọ́ṣọ lọ́rùn, bẹ́ẹ̀ ló ń juwọ́ méjèèjì sókè bí ẹni tí ń kọrin allelúíà nínú ìjọ mímọ́.

Aáyán ní òun yóò gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ àyàfi tí ó bá lè mú bùrọ̀dá Ejò tó ń gbé lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò wá láàye kí òun ri. Àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí àwọn méjèèjì ti ń takùrọ̀sọ; Òwìwì, Ọ̀pọ̀lọ́ àti Adìyẹ bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Kọ̀ǹkọ̀ ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n mọ̀ pé iṣẹ́ ńlá ni Aáyán gbé le láyà, kò sì lè rọgbọ fún-un láti ṣe, kò sẹ́ni ṣe èyí ri, ẹni tó bá ṣe ohun tẹ́nìkan kò ṣe rí, ó di dandan kó rí’hun tẹ́nìkan kò rí rí.  Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ó fún Aáyán lésì láì mikàn pé òun yóò ṣe ‘hun tó fẹ́.

Lówùrộ ọjọ́ ajé, Kọ̀ǹkọ̀ jòkó síta ilé rẹ̀, ó ń ronú ọ̀nà tí yóò gbé ọ̀rọ̀ náà gbà. Ìgbà tó pẹ́ tọ́rọ̀ náà ń mì níkùn rẹ̀, ó rí ọ̀nà àbáyọ.

Lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, kọ̀ǹkọ̀ fi imọ̀ ọ̀pẹ tín-ín-ín kan so àjàrà, ó kó irú èso kan tí Ejò fẹ́ràn láti máa mu sétí ọ̀nà ibẹ̀, lẹ́yìn èyí, ó pamọ́ síbì kan. Láìpẹ́ rẹ̀, ẹni à ń wí dé! Ejò rí àwọn èso kàǹkà-kàǹkà náà. Bí ó ti fẹ́ máa jẹ èso náà ni kọ̀ǹkọ̀ ti fẹ́ yára fa igi tó fi sé ilẹ̀kùn náà sọ̀kalẹ̀ láti lè tilẹ̀kùn mọ́ Ejò láti ìta. Pàbo ló jásí, ilẹ̀kùn kò tì, ilẹ̀kùn kọ́, ilẹ̀kùn ni. Ejò ti mọ̀ pé ẹnìkan fẹ́ tilẹ̀kùn mọ. Ó fi gbogbo èso lánu, ó bá tirẹ̀ lọ. Gbogbo ara kìkì ọgbọ́n!   Èyí ká kọ̀ǹkọ̀ lára tó bẹ́ẹ̀ tí kò lè jẹun tàbí sùn lálẹ́ ọjọ́ náà.

Kọ̀ǹkọ̀ tún ro ọgbọ́n míràn láti mú Ọ̀gbẹ́ni Ejò ní Ọjọ́ru.Ọgbọ́n kìí tán láyé ká rọ̀run.  Ó gbẹ́ kòtò jínjìn, ó jẹ́ kí ẹ̀gbẹ̀gbẹ́ rẹ̀ máa yọ̀ pẹ̀lú gírísì. Ó fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ wẹ́wẹ́ tí Ejò fẹ́ràn sí ìsàlẹ̀ ihò yìí. Nígbà tó ṣèyí tán, ó lọ lúgọ̌ síbì kan. Ó ṣèyí ní ìbámu ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ní ‘’ohun tí èèyàn bá mọ̀ọ́ jẹ ló ń ṣekú pa á’’. Bí Ejò ti ń lọ lọ́nà, ebi ń paá, òùngbẹ sì ń gbẹ ẹ́ pẹ̀lú. Bí ó ti tajú kán, ó rí ọ̀gẹ̀dẹ̀ nínú ihò ṣùgbọ́n ó fojú inú wòó pé òun lè lọ ṣubú níbẹ̀.

Ó kọ́kọ́ wo ọgbọń tó lè gbà jẹ ọ̀gẹ̀dẹ̀ náà láì fara pa. Ó wé ara rẹ̀ mọ́ ìti igi. Ó wọ inú ihò náà lọ, ó fi ọ̀gẹ̀dẹ̀ lánu, orin bámúbámú ni mo yó ló ń kọ. Lẹ́yìn tí ó jẹun yó tán, o gbé ara rẹ̀ sóké, ó bá tirẹ̀ lọ láì mọ̀ bóyá ẹnìkan ń wẹkún mu. Kọ̀ǹkọ̀ ti pàdánù Ejò òun ọ̀gẹ̀dẹ̀, Ejò lọ́wọ́ nínú!!!

Alákọrí kò ì tí ì rọ́nà àbáyọ. Ọ̀sẹ̀ kan sì ti fẹ́ pé. Ó fi odindi ọjọ́ méjì gbáko ṣe ìṣirò bí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ bẹ̀rẹ̀ okòwò lọ́jà gbági.

Ìgbà tó di ọjọ́ Àbámẹ́ta, ó gbafẹ́ rìn dé iwájú ilé Ejò. Ó ri bí ó ti ń wo ìtànsán oòrùn lórí òkè gíga.

‘’Oò jíire bí? ọ̀rẹ́ mi Ejò’’, Kọ̀ǹkọ̀ ló sọ bẹ́ẹ̀. ‘’Kòǹkọ̀ pẹ̀lẹ́ o’’, Ejò dáhùn pẹ̀lú ojú kíkorò. ‘’Mò ń bínú sí ẹ gidigidi, odindi ọ̀sẹ̀ kan lo ti ń wá ọ̀nà láti rí mi mú, gbogbo àwọn ète tó o lò ni mo mọ̀, bí mo bá fẹ́ ṣe tèmi padà ń kọ́, wọ́n á ní Ejò lóró nínú’’.

‘’Hà! Ọlọ́gbọ́n ni ọ́ o’’, Kọ̀ǹkọ̀ ló ń sọ̀rọ̀, ‘’arínúróde mà ni ọ́ pẹ̀lú, ọgbọ́n tó o ní pọ̀ jọjọ, òtítọ́ mà lọ̀rọ̀ tó o sọ. Mo ti ń wá ọ̀nà láti mú ọ ṣùgbọ́n kìì ṣe fún ikú o. Mo mọ̀ pé mo jẹ̀bi, ní báyìí, kò sí ẹ̀rí fún mi pé ìwọ ni ẹranko tó gùn ju igi ọparun lọ lágbǎyé, àwọn kan tilẹ̀ sọ pé àgùfọn ni ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀nà ni mo fi ń gbèjà rẹ. Ìdí nìyí tí mo fi ń wá ọ kiri, n kò sì mọ ọ̀nà tí màá gbe gbà’’.

Bí Ejò ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, níṣe ni ó dàbí ìgbà tí wọ́n bá dami tútù si lọ́kàn. Inú rẹ̀ dùn, kò lè pa á mọ́ra. Ó ni ‘’mo ti dáríjì ẹ́, òtítọ́ lo sọ, kò sírú káún láwùjọ òkúta, bẹ́́ẹ̀ ni kò sí irú iyọ̀ láwùjọ eèpè’’.

‘’Bí ó bá má a di ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn, bóyá kí n lọ gbé ọparun wá kí a fi ojú inú wo ọ̀rọ̀ náà’’, Kọ̀ǹkọ̀ ló sọ èyí. Ejò ní “kò séwu lóko àfi gìrì àparò”.

Kò ṣe méní, kò ṣe méjì, ọparun ti dé. Ajá tó rí mọ́tò tó dúró fi ara ẹ̀ bọ̀gún lọ̀rọ̀ Ejò àti Kọ̀ǹkọ̀. Wọ́n mà ṣàfiwé gígùn Ejò àti Ọparun, igi imú jìnà sórí ṣùgbọ́n ọ̀gbẹ́ni Ejò kò gbà pé Ọparun jù-un lọ. Kòǹkọ̀ ní tó bá dàbí àfojúdi kí Ejò nà gbalaja sórí Ọparun kí Ejò lè ráyè nàgà. A ní ká wá ẹni tó lẹ́hìn ká fọmọ fun, abuké ní òun rèé; ti gànnàkù ẹ̀hìn-in là á  ń wí? Bẹ́ẹ̀ là á ǹ pe ẹranko tó ního, Ìgbín ń yọjú lọ̀rọ̀ Ejò. Ó tún gbọ́ sí Kọ̀ǹkọ̀ lẹ́nu, kò ṣe méní,  kò ṣe mẹ́fà, kíá ló nà gbalaja tó ń garùn bí ẹni fẹ́ fògànná.

Ká má fọ̀rọ̀ gùn, báyìí ni Kọ̀ǹkọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tó fokùn so Ejò mọ́ Ọparun. Kàyéfi ńlá ló jẹ́ nígbà tí Aáyán rí wọn. A kò mọ bí àwọn tó kù ṣe gbọ́, ẹsẹ̀ wọn ti pésẹ̀ n’torí ó jọ gáté kó jọ gàté lójú wọn, wọn ò kúkú mọ̀dí ọ̀ràn tó sun dé mímú Ejò wá láàyè.  

Ejò ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbà pé àfojúdi kò dára,  kò sẹ́ni lè ma dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ Kọ̀ǹkọ̀ mọ́, ó ti ṣehun tẹ́nìkan ò ṣe rí,  ọ̀ranyàn ni láti da lọ́lá.

Ìwúrí yìí mú kí Ọba Kìnìṹ dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ìwà jàgídíjàgan Ejò ná fi ń wá a, àfi bi olè Ìbàdàn. Ó ní kí Kọ̀ǹkọ̀ ó bèrè ohun ǹnkan, bẹ́ẹ̀ ni yóò sì rí.

Ojú gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ló ti bèrè pé kí a gbé ipò Ọ̀gbẹ́ni Aáyán fún òun. Níṣe ni gbogbo wọn ń wóju ara wọn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n ti ṣe bẹ́ẹ̀, kò sẹ́ni kóyán rẹ̀ kéré láàrín àwọn tó kù láti ìgbà náà lọ. Nítorí ìdí èyí,  gbogbo wọn ló fọwọ́ si pé Kọ̀ǹkọ̀ l’ẹ̀gbọ́n  àwọn ẹranko kéé-kèè-kéé.  Pàkò l’Ejò ń wò bi Imàlúù rọ́bẹ. Ó ní bí orí bá lè kó òun yọ nínú ọ̀ràn tóhun wọ̀ yí, àtẹni tó mọ̀dí àtẹni tí kò mọ̀dí ẹ̀ lòhun á máa bùṣán lọ.

Látì ìgbà náà lọ ni Kọ̀ǹkọ̀ ti ń kọrin “mo ṣe’hun tẹ́nìkan ò ṣe ” kiri.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọláyàtọ̀ Ọláolúwa jẹ́ ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Oǹdó. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀dá-èdè àti èdè Yorùbá ní ilé- ẹ̀kọ́ gíga Fásitì Adékúnlé Ajáṣin ní Ákùngbá Àkókó. Oǹkọ̀wé ni, ó sì fẹ́ràn èdè àti àṣà Yorùbá.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *