Ìlú Ìkìrun wà ní apá àríwá ìlà-oòrùn ti ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ìkìrun wà láàrin látítúùdì 7 dìgìríì ẹsẹ̀ 50, àríwá ti ìlà agbede-ayé àti lọ́gítúùdì 4 dìgìríì ẹsẹ̀ 40, ìlà-oòrùn ti “Greenwich meridian”. Ìlú Ìkìrun wà ní ààrin òkè méjì: Òkè Ọbaàgùn/Gbogí ní apá àríwá àti Òkè Ááfọ̀ ní apá gúúsù àti Aláròká àti Òkè Ìdí-Òló ní apá ìlà-oòrùn. Ìlú Ìnísà ní ìjọba ìbílẹ̀ Odò-Ọ̀tìn ni ó báa pààlà ní àríwá. Ní gúúsù, Ìlú Òsogbo, olú ìlú ìpínlè Ọ̀sun ni ó báa pààlà. Ìlú Ìrágbìjí ní ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Bórípẹ́ ni ó báa pààlà ní ìlà-oòrùn. Àti ní ìwọ̀-oòrùn ni ìlú Èkó-Eńdèé ní ìgbìmọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ Ìfẹ́lódùn ti báa pààlà. Wọ́n fojú bù ú pé àwọn olùgbé Ìkìrun jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún-lé-ní-ọ̀kẹ́-mẹ́ta dín lẹ́fà dín ní ọgọ́sàn án [60,826] (gẹ́gẹ́ bí ètò ìkànìyàn ti orílẹ̀-èdè, Ìkìrun).

Akinọ̀run, bí a bá perí akọni, à fidà lalẹ̀ gààràgà. Ọ̀kan ló jẹ́ nínú ọmọ Odùduwà nífẹ̀ Ọọ̀ni, Ifẹ̀ oòdáyé, ibi ojúrere ti mọ́ wáyé. Akinọ̀run, akinláyé, akinlórun. Ọmọ ọmọ Ọ̀rànmíyàn ni Akinọ̀run jẹ́, gẹ́gẹ́ bí òwe Yorùbá tó wí pé, ogún ọmọdé ò lè ṣeré fógún ọdún, Akinọ̀run gbéra láti Ifẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń jẹ́ Olúgbọ́n. Ibi tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀dó sí ni ‘Igbọ́n’ ní tòsí Ìbàdàn. Jagunjagun tí ó mú yányán ni Akinọ̀run nígbà náà tó jẹ wí pé arógunyọ̀ ni, ojojúmọ́ ní retí ogun, títí tí wọ́n fi ń pè é ní Àgùnbẹ́ torí pé orí ẹṣin ní tíí bẹ́ àwọn ọ̀tá lórí. Èyí ló mú kí Olúgbọ́n sọ fún Akinọ̀run àbúrò rẹ̀ pé kó lọ dá ibòmíràn tẹ̀. Akinọ̀run fi ìbínú fi Igbọ́n sílẹ̀, o sì lọ sí “Ìrán-ìn” lẹ́gbẹ̀ẹ́ “Òkò” ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́. Níbẹ̀ lAkinọ̀run kọ́kọ́ tún tèdó sí, kó tó wá máa bọ̀ ni Igbó Ìrẹ̀lẹ̀. Igbó Ìrẹ̀lẹ̀ yìí sì jẹ ti ìlú Ìkìrun. Dídé tó dé Igbó ìrẹ̀lẹ̀ yìí, Akinọ̀run ń bí síi, ó sí ń rẹ̀ síi. Igbó ìrẹ̀lẹ̀ yìí ni Akinọ̀run tí dágbére fún dúnníyàn pé ó dìgbà.

Bí iná bá kú, á feérú bojú. Bọ́gẹ̀dẹ̀ kú, á fọmọ rẹ̀ rọ́pò. Ọmọ márùn ún tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin ní Akinọ̀run fi sílẹ̀ kó tó rèwàlẹ̀ àṣà: Akinọlá, Akínbọ́lá, Laálakin, Oyèéjọlá àti Ọbaàrá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyàwó àti dúkìá ni Ọbaàrá ní, ṣùgbọ́n níse ni ó ń fi omi ojú sèráhùn ọmọ. Àìlárẹ̀mọ ò ṣéé dákẹ́, Ọbaàrá torí ọmọ sípò padà, o sì lo sí ‘Ọsìn’ lẹ́bàá ‘Àréke’ tí kò jìnnà sí Ìlọrin, pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tí ń jẹ́ Gbólẹ́rù. “Ọsìn” yìí ni orí sì ti sọ́ ọ́ dọlọ́mọ; Ó bírú, ó bígba. Àjò ò lè dàbí ilé. Báyìí ni Ọbaàrá tún gbéra padà sí Ìkìrun pẹ̀lú ẹ̀gbọ́n. Igbó ìrẹ̀lẹ̀ tí wọ́n ti púrò ló gbàlọ tààrà bí wọ́n se ń bọ̀ láti “Ọsìn”. Àsìkò yìí ni Ọbaàrá pàdé Basètán.

Basètán jẹ́ akíkanjú akọni ọdẹ láti ìlú Ìlá Ọ̀ràngún tí ó wá máa ń sọdẹ ní Ìkìrun. Ààrin gùngùn ìlú Ìkìrun tó di ojú ọjà lásìkò yìí ni ó se ààtàn ẹran rẹ̀ sí tó nílé tó ń gbé. Bí ó bá ti yan ẹran náà tán, yóò padà sí ìlú rere tíí se Ìlá Ọ̀ràngún. Ìkìrun ní tíí sọdẹ níjọ́hun, Ìlá Ọ̀ràngún níí kó ẹran lọ nígbà náà. Ó di ọjọ́kan ìtàn, ọjọ́kan ìrántí láíláí, Basètán roko ọdẹ, ó dẹ̀gbẹ́ títí ó rìnnà pàdé Ọbaàrá. Ní àsìkò yìí, ọ̀wọ́n omi ń bá wọn fíra ní Igbó Ìrẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ ibùdó Ọbaàrá àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

Basètán ní kí Ọbaàrá àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ó máa bọ̀ ní ibi tí òun tẹ̀dó sí nítorí àtilò omi. Ọbaàrá sì sọ fún un wí pé kò sí ibi tí àwọn yóò máa sùn tí àwọn bá dé. Basètán ní kí wọ́n ó máa bọ̀ nílé òun. Bí eré bí eré, wọ́n mojú ara wọn. Kò pẹ́ kò jìnnà, wọ́n ń se wọlé wọ̀de. Ẹni a bá lábà ni baba, wọ́n ní kí Basètán ó wá jẹ ọlọ́jà ó kọ̀. Láti ìgbà ọ̀hún ni wọ́n tií jẹ Éésà, tó jẹ́ igbákejìke Ọba. Idi niyi ti gbogbo Ọba tí ó bá jẹ gbọdọ̀ lo oṣù mẹ́ta ní ààfin Éésà tó jẹ́ ìran Basètán, àmọ́ tí ó ti di ọjọ́ mẹ́ta báyìí, kí ó tó lọ sí ààfin tirẹ̀. Ìdí Nìyí tí wọ́n ṣe ń kì wọ́n ní “ọmọ a ní ó wá jẹ ọlọ́jà tí ó kọ̀, ọmọ arílé-mọdájàsí”.

Orígun ìrántí kan wà ni Ọjà Ọba ní Ìkìrun títí di àsìkò yìí; “Basètán, ọdẹ tó tẹ ìlú Ìkìrun dó.

Ó tún di ọjọ́kan ìtàn, ọjọ́kan ìrántí láíláí, Basètán roko, ó pẹyẹ ńlá bọ̀ lábọ̀ oko. Ẹyẹ àkọ̀ fàáké kọ́rí ọwọ́ Basètán ò to. Ni wọ́n bá bií léèrè pé sé ó seé ré. Sé ó seé ré àbí kò seé ré? Ó wá dá wọn lóhùn wí pé “kò seé re”. Etí odò tó ti pẹyẹ náà ni wọ́n wá ń pè ní “Òsééré”. Òsééré yìí ló dà bí ẹni pé òhun ló pín ìlú Ìkìrun lọ́gbọọgba. Ọjà Ọba sì ni odò yìí wà. Òkè odò yìí sì ni wọ́n ń pè ní Òkè-Àkọ̀.

Ó tún di ọjọ́kan, alábiyamọ kásọ rẹ̀ yóò fọsọ. Ni wọ́n bá tún bi wọ́n léèrè wí pé kí ni wọ́n ó fasọ tà lẹ́sẹ̀ omi? Wọ́n ní, “ẹ tún ń bi wá ni, àmọ̀ràn bini Àgùnbẹ́. Ó dáa, à á fọ̀ ọ́, a ò sì ní saláì fọ̀ ọ́ mọ́”. Láti ìgbà yìí ní wọ́n ti ń pe omi náà ní Aáfọ̀. Ìkìrun Àgùnbẹ́ ò dédé máa jẹ́ onílẹ̀ obì, obì ń bẹ nÍkìrun. Gbàǹja ń bẹ lágùnbẹ́.

Èèwọ́ ni kí wọn ó peyán lórúko nÍkìrun Àgùnbẹ́ níjọ́sí torí pé kò sí ẹni tó mọ orúkọ babaláwo tó dífá fún wọn. Ó wá dijọ́kan, béníyán se gúnyán rẹ̀ tán, ó gbè é lọ́mọge lórí, ó ní kí ó bá òun tà á nÍkìrun. Ọmọ ń polówó iyán, ló bá dakitiyan. Ó ń ní “ẹ wojú ọbẹ̀, ẹ múyán o”. Ó kiri délé iyán ni babaláwo bá ké gbàjarè tọba lọ. Ó ní, “kí ni mo se tí ẹ fi ní kí wọn ó mú mi”. Láti ìgbà yìí ni ó ti di èèwọ̀ kí wọn ó peyán lórúkọ ní ìlú Ìkìrun. Isu-ewé niyán ń jẹ́ nÍkìrun.

Lẹ́yìn tí Ọbaàrá wàjà tán ni wọ́n fi Gbólẹ́rù tí ó jẹ ọmọ-ọmọ Akinọ̀run kẹta ní ìdílé Adérọ́pò jẹ Akìnrun. Orúkọ oyè ọba ìlú Ìkìrun ni ‘Akìnrun ti ìlú Ìkìrun’.

Ọdún Ìrẹ̀lẹ̀

Ọdún Ìrẹ̀lẹ̀ máa ń wáyé ní oṣù keje ọdọọdún láti se déédé pẹ̀lú ìkórè iṣu tuntun. Ní ìlú Ìkìrun, wọn kò gbọdọ̀ mú iṣu wá sí ọjà Ọba fún títà títí di ìgbà tí àjọ̀dún Ìrẹ̀lẹ̀ yóò wáyé. Àjọ̀dún Ìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n ń ṣe láti ṣe ìrántí ẹlẹgbẹ́ Olùdásílẹ̀ Ìkìrun. Ìtàn sọ wí pé Akinọ̀run gbé pẹ̀lú alábàágbépọ̀ kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìrẹ̀lẹ̀. Bíi Akinọ̀run, Ìrẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ alágbára ọdẹ àti jagunjagun. Àwọn méjéèjì kọ́kọ́ tẹ̀dó sí igbó kan tí ó jẹ́ ti Ìrẹ̀lẹ̀, tí wọn sì ń pe igbó náà ní igbó Ìrẹ̀lẹ̀. Ó pẹ́ tí wọ́n dé sí Igbó Ìrẹ̀lẹ̀ ni àìsàn ki Akinọ̀run. Ó pe alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ó sì fi ìṣàkóso náà lé Ìrẹ̀lẹ̀ lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà ó kú.

Ìṣàkóso ìlú àti gbogbo ohun tí Akinọ̀run fi sílẹ̀ wà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Akinọ̀run àti Ìrẹ̀lẹ̀. Ó gba ìpènijà náà nígbàkúùgbà tí ogun bá dé, tí yóò sì kojú ogun láì tìdí. Lẹ́yìn tí ojọ́ borí ọjọ́, tósù gorí oṣù; tọ́dún yí lu ara wọn, Ìrẹ̀lẹ̀ kéde ikú rẹ̀ tí ń bọ̀. Ó fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìtọ́ni kan tí wọ́n gbọdọ̀ tẹ̀ lé. Ó fún wọn ní àkàbà méjì pẹ̀lú ìtọ́ni pé kí wọ́n má ṣe ṣí i. Ó sì kó ọ̀pá ọ̀sanyìn sínú ilẹ̀ pẹ̀lú ìlànà pé nígbàkúùgbà tí ìkọlù bá dé, kí àwọn ènìyàn lọ síbẹ̀, kí wọ́n pe orúkọ rẹ̀, yóò sì jà fún wọn. Ó fi kún un pé nígbà tí òun bá kú, wọ́n gbọdọ̀ rúbọ ajá dúdú. Pẹ̀lú ìlànà yìí, Ìrẹ̀lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìtàn-akọni, wọlẹ̀.

Ìwúrí àwọn ohun tí Ìrẹ̀lẹ̀ se fún Ìkìrun nígbà tí ó wà láyé ni àwọn ènìyàn fi se òrìsà fún un, tí wọ́n sì dá májẹ̀mu pé àwọn yóò máa sìn in, àwọn yóò sì máa rúbọ fún un ní gbogbo ọdún nínú oṣù Keje nígbà ìkórè iṣu.

Ogun Ìkìrun

Ogun Ìkìrun, tí a tún mọ̀ sí Ogun Jálumi jẹ́ ogun ẹ̀jẹ̀ tí ìlú Ìbàdàn àti Ìkìrun jà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun àpapọ̀ Ìlọrin, Ìlá-Ọ̀ràngún, Èkìtì àti Ìjẹ̀sà ní ọjọ́ kìíní oṣù kọkànlá ọdún 1878, ní apá àríwá ìlà oòrùn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun òde òní.

Ní oṣù kẹfà ọdún 1878, ìlú Ìkìrun, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun òde òní, pè fún ìrànlọ́wọ́ Ìbàdàn láti dara pọ̀ mọ́ òun láti bá àwọn ọmọ ogun Èkìtì, Ìjẹ̀sà, Ìlá-Ọ̀ràngún àti àwọn Fúlàní ìlú Ìlọrin tí wọ́n ti dòyìká Ìkìrun jagun. Ìbàdàn kò lè rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nítorí wọ́n se ìrìn àjò lọ sí Mèkó, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Ògùn òde òní. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn padà dé ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kẹwa ọdún 1878, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n gbéra lọ sí ìlú Ìkìrun lábẹ́ àsẹ Balógun Àjàyí Ògbóríẹfọ̀n, tí ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n dé ìlú Ìkìrun láàrin ọjọ́ márùn ún.

Àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn doríkọ ìlú Ìkìrun, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún wọn láti kọjá odò Ọbà àti Ọ̀ṣun nítorí àsìkò òjò ni, odò sì kún. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ogun Ìbàdàn ni ó kú nígbà tí wọ́n ń sọdá odò méjéèjì. Àwọn ọmọ ogun Èkìtì àti Ìjẹ̀sà, (Èkìtì-parapọ̀) Ìlá-Ọ̀ràngún àti Ìlọrin ti lé àwọn ọmọ ogun Ìkìrun dé odi ìlú wọn, tí wọ́n sì ti ń sẹ́gun díẹ̀díẹ̀. Ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kẹwa, ọdún 1878, Balógun Ògbóríẹfọ̀n bá àwọn ọmọ ogun rẹ̀ dé ìlú Ìkìrun. Ó rí ipò tí Ìkìrun wà, ní wàrà-ǹ-sesà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní se ètò. Ó pín àsẹ pẹ̀lú alágbára mìíràn tí a ń pè ní Òsì Ìlọ̀rí.

Àwọn ọmọ ogun ọlọ́tẹ̀ náà kọlu Ìkìrun ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́ta: Ìlọrin (lábẹ́ àsẹ Àjíà) se àkọlù láti àríwá ìlà-oòrùn. Ògúnmọ́dedé àti Ayímóró ló darí àwọn ọmọ ogun Ìjẹ̀sà, tí wọ́n sì ṣe àkọlù láti ìlà-oòrùn nígbà tí Èkìtì (lábẹ́ àsẹ Fábùnmi Òkèmẹ̀sí) àti àwọn Ìlá (lábẹ́ Ọmọba Adéyalà) wà nítòsí. Ogun náà bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kìíní osù kọkànlá, ọdún 1878. Àwọn ọmọ ogun ọlọ́tẹ̀ náà kọlu Ìkìrun. Òsì Ìlọ̀rí kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ sí ìlà-oòrùn láti dìgbò lu àwọn Ìjẹ̀ṣà, nígbà tí Balógun Ògbóríẹfọ̀n bá àwọn Ìlọrin, Ìlá àti Èkìtì wọ̀jàkadì.

Àwọn Ìjẹ̀ṣà sẹ́gun Òsì Ìlọ̀rí àti àwọn ọmọ ogun rẹ̀, tí wọ́n sì mú un láàyè. Àwọn tó jàjàbọ́ padà lọ sí odi Ìkìrun, wọ́n sì ròyìn ìjákulẹ̀ wọn fún Balógun Ògbóríẹfọ̀n. Wọ́n tètè fi ọgbọn ṣe ìkọlù sí àwọn ọmọ ogun Ìjèṣà, wọ́n sì sẹ́gun. Balógun Ògbóríẹfọ̀n padà lọ dojúkọ àwọn ọmọ ogun Ìlọrin. Ó sẹ́gun àwọn ọmọ ogun Ìlọrin, ó sì lé wọn jáde kúrò ní àgọ́ wọn, ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ púpọ̀, wọ́n ti pa Òsì Ìlọ̀rí. Lẹ́yìn náà ó sẹ́gun Ìlá àti Èkìtì. Àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn lé àwọn ọmọ ogun Ìlọrin tí ó kù sí Ìnísà, ìlú kan láàrin Ọ̀fà àti Ìkìrun.

Nígbà tí ìròyìn kan àwọn ará ìlú Ọ̀fà pé àwọn Ìlọrin ti ń padà sí Ìnísà, wọ́n gé afárá tí ó gba orí odò Ọ̀tìn kọjá lẹ́yìn, tí wọ́n sì ṣé ọ̀nà mọ́ àwọn ọmọ ogun Fúlàní Ìlọrin tí wọ́n ti ń padà sílé. Àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn ká àwọn Fúlàní mọ́ etí odò Ọ̀tìn, wọ́n sì tì wọ́n sínú odò tí wọ́n sì rì sínú omi lápapọ̀. Ìdí nìyí tí wọ́n fi sọ ogun náà ní “Ogun Jálumi”.

Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ọmọ ogun Ìbàdàn dúró sí ìlú Ìkírun fún ìgbà díẹ̀. Wọ́n kúrò lẹ́yìn àdéhùn tó wáyé láàrin Ìkìrun àti Ìbàdàn. Èyí ló bí gbólóhùn “Kí ogun ó tó kúrò ní Ìkìrun, ọ̀rọ̀ ló tẹ́lẹ̀”.

Oríkì ìlú ìkìrun

Ìkìrun àgùnbẹ́ onílẹ̀ obì

Ẹrú wa wọn kì í dère

Ìwọ̀fà wa ò gbọdọ̀ dòtòǹpòrò

Ìdílé àgùnbẹ́ ni yóò gbepà lérí

Ọmọ isú jinná mo róhun mú bọnu

Òwò se rẹ̀rẹ̀ gbilẹ̀ nísàlẹ̀ sàn

Wọ́n ní a ò lóko, lódò níkìrun

Mo ní ta ló ni aáfọ̀, ta ló lòsééré

Ta ló ni onítokí, ta ló ladíbẹ́sin wọ̀ọ̀wọ

Àwa lọmọ ẹ̀yọ̀ tó ti múkìrun dòkun

Ọmọ ẹ̀yọ̀ tó ti múkìrun dọ̀sà

Ọmọ ẹ̀yọ̀ tó ti múkìrun dùn gbọ́ngbọ́n

Ọmọ a tóóse lọ́wọ̀

Ọmọ elégbèé òkun

Òkun dẹ̀dẹ̀ tẹrù tẹrù

Ọmọ aláràgbàyídá, ọmọ olóbì wíwọ́-ń-ti-wọ́

Ọmọ olóbì wọ̀wọ̀-ǹ-ti-wọ̀

Èyí tó bá fẹ́ tẹni a wọ̀ sínú ilé

Èyí tí ò fẹ́ tẹni a wọ̀ síjù

Ẹranko wẹ́wẹ́ á róhun mú jẹ

Ọmọ ohun tó sàgbìgbò tó fi dẹ́kun ẹ̀rin rínrín nínú igbó

Tó bá segúnnugún á wonkoko mórí ẹyin

Ọmọ ẹlẹ́rú níí sunlé

Ọmọ olóbì níí dùndẹ̀dẹ̀

Ọmọ oníyèré ò ríbi kẹ́rù sí

Ańlàgbá ọmọ ọjà obì

Ọmọ èkó ò pógún, ọ̀bà ò pọ́gbọ̀n

Ìrágbìjí ò pókòó, wọ́n ń gbókè odò sawuyewuye sọ́ba

Ọmọ síkan lẹ́gùn ún

Ọmọ agùnkàn má bẹ̀rù ìjà

Ìkìrun àgùnbẹ́, onílẹ̀ obì

Ọmọ òkúta mẹ́ta ń sète nílé ọba

Ọ̀kan kọ́mi lẹ́sẹ̀ lálọ, ọ̀kan kọ́mi lẹ́sẹ̀ lábọ̀

Ọ̀kan lémi lẹ wá délùú ète, ọ̀kan lémi lẹ wá délùú èrò

Ọ̀kan lémi lẹ wá deélùú ọ̀dájú, níbi wọ́n ti ń gbé dájú ara wọn bí ata

Ọmọ agbóòró pète, Ìkìrun àgùnbẹ́, agbóòró sèrò

A à tòsì bí agóòró mọ́

Orí òkúta la ti ń pète ara wa

Òní n làá dère nílé ọba, ìwọ̀fà wa ò gbọdọ̀ dòtòǹpòrò

Ìdílé Àgùnbẹ́ ni yóò gbépà lérí

Ọmọ isú jinná mo róhun mú bọnu

Òwò se rẹ̀rẹ̀ gbilẹ̀ nísàlẹ̀ sàn.

Àwọn Ọba Tí Ó Ti Jẹ N’íkìrun

Olasinde Obaara, Gboleru, Aye Munije, Adedeji I, Olusosun, Fatolu, Oyewole, Lalowo, Oyebode, Ola, Akadiri 1887 – 1917, Oba Kolawole 1917 -1940, Oba Kusamotu Oyewole, Oba Lawani Adeyemi Oyejola 1945 -1989 àti Ọba tí ó gbésẹ̀/wàjà gbèyìn, Ọba Abdul-Rauf Adewale Adedeji II 1991 – 2021.

Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí ìlú Ìkìrun ní ìpínlẹ̀ Ọ̀sun ni Sodiq Lawal jẹ́. Ọmọ Yorùbá tí ó mú èdè àti àsà àwọn baba rẹ̀ ní òkúnkúndùn níí ṣe. Orúkọ gègé rẹ̀ ni Orísun. Ó jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn ọ̀dọ́ òǹkọ̀wé Yorùbá tó ń gbé èdè àti àsà Yorùbá ga. Bí ó se ń kọ ewì, ló ń kọ ìtàn lọ́rọ̀ geere àti ní eré oníṣe.

Comments

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *