Báwo ni a ṣe fẹ́ pe káńbó tí a kò nì í júbà imú. Báwo ni a ṣe fẹ́ pe orí olóólà tí a kò nì í ké sí abẹfẹ́lẹ́. Kò sí bí a ṣe fẹ́ sọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ìlú Ìbàdàn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kò ní jẹ yọ. Kò sí bí a ṣe fẹ́ pe orí akọni tí a kò nì í fi idà la ilẹ̀ gàràgà. Ìbàdàn gba àlejò, bẹ́ẹ̀ ló gba onílé. Bí ọmọdé bá gbé igbá, àwọn àgbà wọn a gbé àwo. Bí ìyàwó bá gbé ẹrù ìsàlẹ̀, ọkọ á gbé tòkè. Ní ọjà-ọba ní ààfin Olúbádàn gúnlẹ̀, ní ẹ̀gbẹ́ ààfin ní mọ́sálásí tó jẹ́ olórí fún gbogbo mọ́sálásí ní ilẹ̀ Ìbàdàn f’ara ro sí. Èrò kábìtì ní gbogbo ọjọ́, pàápàá jùlọ ní gbogbo ọjọ́ ẹtì tí í ṣe ọjọ́ jímọ̀. Àsìkò yìí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ Mùsùlùmí láti orísìírísìí Àdúgbo máa ń wá jọ́sìn ní mọ́sálásí ńlá náà. Ṣùgbọ́n yàtọ̀ sì í ilé ìjọsìn yìí, ọjà tí wọ́n fi orúkọ àgbègbè yìí sọrí jẹ́ ọjà tí kò ṣe é fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nílẹ̀ Ìbàdàn bií o ba fẹ́ ra oúnjẹ tútù bíi Ìrẹsì, ẹ̀wà, gàárì, àgbàdo, àlùbọ́sà, ata, pọ̀nmó, ẹran, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ní apá ibòmíràn ní ẹ̀bá mọ́sálásí ńlá náà, àwọn ọlọ́jà tó wà níbẹ̀ a máa ta tùràrí onílọ́fínńdà, tùràrí onígi, kùránì, tẹ̀súbà, jàlámìa, tírà oríṣiríṣi àti àwọn nǹkan mìíràn tí àwọn Mùsùlùmí fi ń ṣe ìjọsìn. Ní àyè mìíràn, àwọn oníbárà tò lọ bíi ilẹ̀ bíi ẹní, lórí ìjókòó, àwọn a máa retí àwọn tí wọ́n yóò tawọ́n lọ́ọrẹ owó tàbí oúnjẹ tàbí aṣọ. Bí í èèyàn bá wá gbé ojú wo ọ̀nà ìsàlẹ̀, níbẹ̀ ni àwọn aláàgbo gbé ń ṣe òwò ti wọn. Ìsọ̀ ti wọn ni orí eku wà. Bí o bá rí aláǹgbá gbígbẹ ní apá kan, èyí tó tutù yóò wà ní apá mìíràn. Èèpo ọ̀bọ̀ àti àwọn èèpo igi mìíràn. Ewé rẹ́ẹ̀rínkòmí àti àwọn mìíràn. Ìkókó dúdú àti funfun. Orí ọká pẹ̀lú awọ ẹkùn. Máa ṣe jẹ́ kó jẹ́ oun ìyàlẹ́nu fún ìwọ bí o bá rí babaláwo tàbí alàgbà ìjọ pẹ̀lú àlùfáà onítẹ̀súbà tí wọ́n ń dúnàá-dúrà lọ́dọ̀ àwọn aláàgbo yìí. Kó dáa àwọn a máa jà sí ojú olóńgbò bí ó bá sọ̀wọ́n lọ́jà. Láti ọjà-ọba bí èèyàn bá lọ ọwọ́ ìsàlẹ̀ sí i, ènìyàn ó kan ìdí arẹrẹ tó rọ̀ mọ́ odò kúdẹtì.
Ọrẹ́ wa, ayé ó lọ bíi ọ̀pá ìbọn. Adédibú tó mi ìlú Ìbàdàn Lọ́jọ́ sí, àwọn èèyàn a ké pe Lamidi. Àwọn a ní òun ni Aláàfin mọ̀lété. Àwọn a ní òun ni olóòṣà mọ̀lété. Níbo ní bàbá wà Lọ́jọ́ tòní? Ikú ti gba aṣọ lára ewúrẹ́. Ṣùgbọ́n o, Adédibú lọ, mọ̀lété dúró digbí. Àwọn Ìṣọ̀ Adìẹ kan wà ní mọ̀lété, ìwọ wá wòran ní ọjọ́ ọdún yàtọ̀ sí ọjọ́ lásán. Ẹnu kọ sísọ. Bí ìtùnu àwẹ̀ bá ku ọjọ́ kan, tàbí ọdún iléyá, àwọn ẹbí tí wọ́n kò lágbára àti pa màálù, àgbò, òbúkọ—àwọn a bọ́ sí ìsọ̀ adìẹ náà, pàápàá jùlọ ní ọdún Kérésìmesì, oníkálukú á tọ́ka sí adìẹ tó bá wùn wọ́n. Lójú ẹsẹ̀ náà ni i àwọn tó ń ta adìẹ á ti fọ̀bẹ sí adìẹ tí orí rẹ̀ bá gbàbọ̀dè lọ́rùn. Àwọn a sì gba ìyẹ́ ara adìẹ náà pẹ̀lú omi gbígbóná. Àwọn a pọ́ ìfun rẹ̀. Àwọn a sì ṣe ááyan rẹ kí wọ́n tó gbé e fún oníbàára wọn. Àti oníbàára àti aládìẹ, inú wọn a sì dùn dé ìdí. Olúwa nìkan ló mọ oun tó ń lọ nínú àwọn adìẹ yòókù tí orí wọn ń padà bọ̀ wá gbàbọ̀dè. Akẹ́yinjẹ kò kúkú mọ̀ pé ìdí ń ro adìẹ.
Ṣùgbọ́n bí èèyàn gbójú sókè ọjà-ọba, níbẹ̀ ni òkè-Màpó dúró sí. Òkè yìí jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára àwọn òkè tí wọ́n fí ń pe ìlú Ìbàdàn ní ìlú olókè méje. Lẹ́yìn òkè Màpó ní òkè-àdò fí àyà balẹ̀ sì í, agboolé fọ̀kọ̀ sí ǹ ru pẹ̀lú èéfín igbó lẹ́ẹ̀bá rẹ̀, òpópónà reluwé náà wà ní apá kan, bí èèyàn bá tọ òpópónà yìí, èèyàn ó ṣe alábàápàdè kòkó-haòsì—ilé gogoro àwòṣìífìlà. Dùgbẹ̀ aláàwo kò jìnnà síbẹ̀. Ní ìsàlẹ̀ ni Ọjà Agbeni àti ògùnpa ti wọnú ara wọn; inú ọjà yìí ní ìyá tó bí èmi lọ́mọ ti ń ṣe òwò àtẹ. Èmi a máa ran ìyá mi lọ́wọ́ nígbà mìíràn. Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ sorí pẹ̀lú àwọn ọmọ yòókù tí ìyà wọn ní ìṣọ̀ nínú ọjà yìí. Aṣọ alárànbarà, ṣe ti ìgbàlódé ni tàbí tiwa n tiwa, Gírísì ni èèyàn fẹ́ ni tàbí oun ọ̀ṣọ̀ àwòdamiẹnu- gbogbo èyí ló kún inú ọjà yìí. íwájú ni òkè-sápátì dẹ ẹ̀bìtì àyà sì í, òkè yìí ló kọ ìdí sí Bẹẹrẹ tó sí gbẹ́nu lé láyípo—bí ìwọ bá dán ẹnu pé ìwọ mọ Ìbàdàn, ǹ jẹ́ ìwọ mọ láyípo? Ṣé ìwọ mọ òkè-Ààrẹ lọ sí bọ́ọ́nú-fọto? Òkè-Bíòkú àti òkè-bọ́là kò gbẹ́yìn. Ṣebí òkè-páádì ni èmi kú máa ń gbà lọ ilé láti lòyólà ní géètì, bí èmi pẹ̀lú àbúrò mi bá ti náá owó ọkọ̀ wa láti ilé ìwé, a maa bá ẹsẹ̀ wa sọ̀rọ̀, láti géètì dé òkè-páádì, lọ sí òde ajé títí tó fi dé adékilẹ̀, guduwílí ọlọ́ọ̀lẹ̀, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ la bá dé ilé ìwé aperin bọ́íìsì, ní oríta-aperin pẹ̀lú òógùn ní gbogbo ara. Àwọn òbí wa kò gbọ́dọ̀ mọ èyí. Èmi pẹ̀lú àbúrò mi k’éwe, ìgbà ewe ni. Ṣùgbọ́n bí a kò bá rin ìrìn ìyà náà, báwo ni máa ṣe kó ìrírí yìí jọ débi pé màá sọ ọ́ di àkọsílẹ̀.
Àdúgbo odínjó ni mo ti lo ìgbà èwe mi. Ní ilé ọba, èmi pẹ̀lú àwọn èwe tó kù a máa yọ́ tẹ̀lé éégún lémọjágbà. Ṣebí a kò nì í oun tí à ń fi inú rò. Àwa a máa tẹ̀lé éégún náà lọ òde ìgè lọ sí àkátáàpá. Nígbà mìíràn a máa tẹ̀lé éégún náà lọ ọ̀nà Adélagun tó fi dé múslímù. Lọ́jọ́ tí àwọn òbí wa bá ká wa pé a tẹ̀lé éégún, ìyà tí kò lópin ni fún wa.
Ní Bẹẹrẹ, èmi ò jẹ́ rẹ̀pẹ̀tì. Pàápàá jùlọ tí Òòrùn bá ti ń wọ̀. Bí ọjọ́ bá ti ń re’bi ànà, tó sì jẹ́ pé agbègbè Bẹẹrẹ ni mò ń gbà lọ Ibikíbi, èmi a máa pa àpò mi mọ. Èmi a máa tọ́jú ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ mi dáadáa, pẹ̀lú àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì sí mi. Bákan náà ni mo máa ń pa ara mọ́ ní agbègbè ìwó-roòdù. Nítorí bí ẹnia bá gọ ara rẹ̀, àwọn ọmọ tó ń fẹ́wọ̀ le è gba omijé lójú èèyàn. Àwọn a rẹ́ àpò Ṣòkòtò tàbí àpamọ́wọ́ rẹ, o kò sì ní fura. Àwọn a kò gbogbo owó pẹ̀lú nǹkan tó wúlò fún ọ lọ, bóyá bí o bá délé ní wà á tó ké gbàjarè. Ṣùgbọ́n kò sí oun tí ìwọ fẹ́ ṣe, torí pé aṣọ kò b’ọ́mọ́yẹ mọ́ ọmọ́yẹ ti rin ìhòòhò w’ọjà.
Ìbàdàn ò sì mọ alákọ̀wè. Àti alákọ̀wè pẹ̀lú ìyá onípọ̀nmọ ní a jọ ń wọ ọkọ̀ kabúkabú míkírà. Bí omi pọ̀nmó bá ta sí ìwọ akọ̀wé lára, kó yàrá gba ẹgbin náà mọ́ra. Bẹ́ẹ̀ náà sì ni ìyá oní fùfú pẹ̀lú ẹ̀gẹ́ rírẹ̀ nínú ọkọ kán náà. Àti omi ẹ̀gẹ́ pẹ̀lú omi pọ̀nmó, alákọ̀wè tó bá kúrò ní sẹkitérìàtì tàbí ẹ́sítéètì bódíìjà tó ń lọ sí òjè tàbí ọjà bódíìjà gbọ́dọ̀ mú òórùn náà mọ́ra. Bí alákọrí kò bá gba pẹ̀lẹ́ tàbí kó kó ara dúró, ọ̀rọ̀ tí ikún gbọ́ tí etí rẹ̀ fi di, alákọ̀wè máa fi etí gbọ́ ọ̀rọ̀ tó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Àwọn ará Ìbàdàn ó gba gbẹ̀rẹ̀, bí o bá ṣe mọ́namọ̀na, àwọn a bú ọ bíi ẹni ń láyin.
Ojú òpópónà Ìbàdàn sí èkó ni àwọn awakọ́ kabúkabú míkírà aláìgbọràn kún sí. Ṣebí àìmọye ìgbà ní ìjọba ti kéde lórí ẹ̀rọ-agbóhùnsáfẹ́fẹ́ pẹ̀lú amóhùn-máwòrán pé kí òní-míkírà rọra sáré l’òpópónà, ṣùgbọ́n kàkà kó sàn lára wọn, pípeléke ló ń peléke. Àwọn a máa sáré àsápajúdé. Àwọn a máa gba ìpè bí wọ́n bá ń sá eré yìí. Àwọn a máa bá ọkọ̀ bọ̀gìnnì wọ̀dìmú. Àwọn a máa sáré pẹ̀lú ọkọ Àjàgbé tàbí tírélà, àwọn a lejú kankan bíi àkọ́bí ṣàngó, wọ́n á ti mu pẹlẹbẹ bíi ọgbọ́n, iṣan ọrùn àti agbárí wọn yóò ràn. Àwọn a súré gba iwájú ọkọ̀ tírélà láì fọn fèrè, wọ́n á bójú w’ẹ̀yìn, àwọn a sì sọ fún awakọ́ tí wọ́n ń bá wọ̀dìmú pé—”ṣé ó pọ́ ọ̀ rọ́wọ́ mi ni?”
Àwọn tí kò mọ̀ wá ní Ìbàdàn máa ń sọ wípé olè ni wá. Àwọn a ní ṣebí ìwà olè jẹyọ nínú oríkì ìlú wa. Àwọn a ní Ìbàdàn tí kò jalè ojú ló ń rọ́. Àwọn a ní ibi olè gbé ń jàre olóhun, wọ́n ní Ìbàdàn yóò sọ fún olóhun pé òun náà ṣe gbé ẹrù rẹ̀ síbi tó gbé e sí. Ẹ̀rín a pa mí tí mo bá gbọ èyí. Ṣùgbọ́n ó, èmi a jẹ́ kó yé wọn pé àkànlò èdè ni àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú oríkì yìí. Ṣe bí ẹ mọ̀ wípé gbogbo èèyàn ni Ìbàdàn kó mọ́ra. Ohun tí àwọn àkànlò èdè yìí túmọ̀ sí ni pé kí onílé àti àlejò kíyè sí ara, kí wọ́n má ṣe rẹ̀pẹ̀tẹ̀. Ìlú Ìbàdàn fẹ́ jẹ́ kí o dúró déédéé, kí ẹni tí o kò mọ̀ máá ṣe da yèrùpẹ̀ sí inú gàárì rẹ, ojú àpá kò ní dà bíi ojú ara mọ.
Ọ̀rọ̀ Nípa Òǹkọ̀wé
Káyọ̀dé jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ lítírésọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó nífẹ̀ẹ́ sí lítírésọ̀ ilẹ̀ adúláwọ̀. Àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí jẹyọ ní àpèrè àtẹ́lẹwọ́, BBPC anthology, icefloepress, Olongo, isele abbl. Ẹ le e rí ní ojú òpó Twitter @KayodeAyobamii.