Àgbẹ̀ paraku ni Àkànó. Ìṣẹ́ àgbẹ̀ yí náà ni ó ń ṣe tí ó fi fẹ́ ìyàwó mérin tí ó wà ní ilé rẹ̀. Ohun àdììtú inú ọ̀rọ̀ Àkànó niwípé, gbogbo ìyàwó ‘lé rẹ̀ ni ò lóyún àárọ̀ dalẹ́ rí. Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti ń sáré sókè-sódò, tí èyíkéyìí nínú wọn kò bímọ ni ó bá pinu láti fi ọba lée, lóbá fẹ́ ìyá Folúṣọ́ . Ìbídùn kò mú oṣù àkọ́kọ́ jẹ. Eré ni, àwàdà ni,oṣù mẹ́sàán kò. Ọjọ́ tí Ìbídùn bí ọmọ rẹ̀ gan ni ọmọ padà. Báyìí ni Ìbídùn ṣe títí tí ọmọ Kẹjọ fi ṣe bẹ́ẹ̀. Ìkúnlẹ̀ mẹ́sàán ni ìyá Folúṣọ́ kún kí Folúṣọ́ tó dúró. Àbíkú sológùn dèké ni ó jẹ́, nítorí náà ni wọ́n bá kúkú fàá f’ólúwa. Ní ọjọ́ tí wọ́n sọ Fólúsọ́ lórúkọ, ayé gbọ́, ọ̀run mọ̀. Folúṣọ́ kúrò ní túnfúlù, ópa orúkọ dà, wọ́n ṣé é lámì. Báyìni Àkànó di baba ọmọ ní ọjọ́ ogbó.
Ọmọ ọdún mẹ́rin ni Folúṣọ́ wà tí ikú wọlé wá mú bàbá rẹ̀ lọ. Lẹ́yìn ikú ọkọ Ìbídùn, ọ̀rọ̀ bá di ọ̀rọ̀. Àwọn orogún bẹ̀rẹ̀ iná ọ̀tẹ̀ tí wọn ò dá lójú ayé ọkọ wọn. Iná ọ̀tẹ̀ yí ràn tóbẹ̀ tí Ìbídùn fi kójáde kúrò nílé fún wọn. Ó ní òun ò lè jẹ́ kí wọ́n gba ọmọ pa lọ́wọ́ òhun. “Mélòó n mobí.” Folúṣọ́ àti ìyá rẹ̀ kó lọ ilé bàbá ìyá’rẹ̀, nílé mosú. Ìrora ilé-mosú gan wá tún fẹ́rẹ̀ẹ́ ju tilé ọkọ gan lọ, nítorí bí’gbà tí ìyà ńlá bá gbé ní sánlẹ̀, tí kékeré ń gorí ẹ̀ ni. Oríṣiríṣi ọ̀rọ kòbákùngbé ni etí Ìbídùn gbọ́. Ṣé ti yẹ̀yẹ́ wípé ó torí owó kòkò fẹ́ arúgbó tó ń kó ẹrú kòtò ni kásọ, àbí ti oro ìfòyà wípé ọlọ́mọ kan ò kúrò lágàn tí wọ́n ń dá bà á? Nígbà tí àbùkù, ìwọ̀sí, àti ẹ̀gàn yí ò ṣe kó mọ́, Ìbídùn pinu láti kó jáde.
Ní ọ̀sẹ̀ tí wọ́n kó dé ilé tíwọ́n gbà gan ni àìsàn nawọ́ gán ìyá ọmọ ọdún mẹ́fà. Lórí àìsàn yìí ni gbogbo dúkìá wọn run lé. Wọ́n tà, tà, ta aṣọ ara wọn. Àìsàn yìí sọ wọ́n sí hòhò kolobo ni. Lẹ́yìn tí ìyà Fólúsọ́ ti ń yílọ, yíbọ̀ nínú ìgbèkùn àìsàn yìí ni ó bá sùn lọ́sàn án ọjọ́ kan, lóbá rí ọkọ rẹ̀ tó gbé ọṣẹ pẹ̀lú omi lọ́wọ́. Ni ọkọ rẹ bá pèé pé kó bẹ̀rẹ̀ kí òhun bá wẹ orí rẹ̀. Ìyàwó yìí kò kọ̀; o gbà. Ọkọ rẹ̀ sì wẹ orí rẹ̀. Yíyajú tí ó yajú pẹ̀lú orí tútù fún omi ni ara bá yá. Báyìí ni àìsàn náà dágbére fún àgò ara rẹ̀. Pírí ni olongo ìyá Folúṣọ́ bá tún jí.
Ní ósàn ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí àláfìa ti tóo lára ló bá bọ́sí odò, ó tọ́mi’ké, ó bomi sára. Ó wẹ̀ tán, ó kun osùn tán, lóbá ń wo ojú nínú dígí; ó ríi wípé ojú òun ti hun jọ. Ni ó bá rántí orúkọ ajá bàbà rẹ̀, ẹ̀yìnlàárò. Ìbídùn bá kánúkò, ó ní ìwọ̀nba èyí tókù fún òun lókè èpè, ọmọ òun lókù tí òun máa gbájúmọ́. Ìbídùn wo àpo rẹ̀, ó ní bí òun ò ti ẹ̀ lówó lọ́wọ́, ọmọ òun gbọ́dọ̀ nísẹ́ lọ́wọ́. Nígbà tí ó pẹ́, ni ìyá bá pe ọmọ rẹ, ó ní : “Folúṣọ́ Àjàyí, mògùnrè. Mo fẹ́ kí o mọ̀ wípé ẹnìkan tí ó jù ẹ́ lọ ní ẹni tódáyé, ọ̀run, àti gbogbo ohun tí ó bẹ nínú wọn. Ọmọ mi, Ọlọ́run nìkan ni ó jù ẹ́ lo. Báyìí, mofẹ́ kí o lọ ronú irú ìṣẹ́ tí o bá fẹ́ kọ́.” Ìbídùn ni,”ó wù mí kí o kàwé, ṣùgbọ́n Ọlọrun sá má kọ ìlérí. Sá lọ ronú sí ohùn tí mo bá ẹ sọ.
Àjàyí pe ìyá rẹ̀ ni àárọ̀ ọjọ́ Sátidé. Ó ní, “ní òru mójú ẹnì ni àró àti ọ̀dọ̀fin inú mi ríra. Wọ́n ní kí nsọ fún yín pé àwọn yọ̀nda iṣẹ́ báyà. Mo fẹ́ ma ra kòkó, èkùrọ́, àti kaṣú.” Ó ni,”ìyámi, àbí kòda ni?”
Ìdùnnú ni ìyá rẹ̀ fi fẹ̀sì. Ó ní, “ohùn ènìyàn ni ohùn Ọlọ́run. Tí n ò bá ní parọ́ fún ọ, ẹ̀sì rẹ yí ṣe déédéé èrò mi. Ọlọ́run yí ó ṣẹ́ ni ìrọ̀rùn. Yí o sì fi àlúbàríkà si. Ṣùgbọ́n ó, Folúṣọ́ ọkọ̀ mí, nítorí ọjọ́ orí ẹ, ó ní láti f’ara balẹ̀ dáada.
Báyìí ni Folúṣọ́ bẹ̀rẹ̀ isẹ́ kíkọ́ ọlọ́dún mẹ́fa. Ní àlàfo ọdún mẹ́rin àkọ́kọ́ Folúsọ́ lẹ́nu iṣẹ́, wàhálà tààràtà ni fún Folúsọ́ àti ìyá rẹ̀ nítorípé iṣẹ́-ilé tí fẹ́ di ti ìyá rẹ̀ nìkan. Wàhálà yí pọ̀, kìí se tàwàdà.
Nígbà tí Folúṣọ́ fi máa lo ọdún márùn-ún lẹ́nu iṣẹ́, ọkùnrin tí ń dé. Òun náà tí ń dá lọ sí ìgbèríko láti ra ọjà. Káwí, káfọ̀, ọdún mẹ́fà tipé.
Ní alẹ́ ọjọ́ kan ni Folúsọ́ dédé pe ìyá rẹ̀. Ó ní, “ìyá mi, ọdún mẹ́fà má ti pé e, ó mà ti kọjá oṣù kan báyìí.”
Ìyá rẹ̀ míkanlẹ̀, ó ní, “mo mọ̀. Kódà ọjọ́ kò tíì pé tí mo ti ń múra. Ṣùgbọ́n, ó kàn wá jẹ́ wípé…”
Folúsọ́ ni, “ìyá mi! Ẹ má sèyọ́nu. Ní kété tí mo
ti ńdá lọ ìgbèríko ni mo ti ń tiraka láti má
mú owó pamọ́. Ìyá mí! Mo láyọ̀ láti so funyín pé mo ti san owó iṣẹ́ àti ti ọ̀gá pẹ̀lú.”
Ìyá Folúṣọ́ yanu, kò lè pádé. Gbàá ló bú sẹ́kún. Nígbàtí Folúsọ́ rí pé ikun ti dàpọ̀ mọ́ omijé lẹ́rẹ̀kẹ́ ìyá rẹ̀, ó ní, “ìyá mi! Ẹ jẹ́ á dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọba tólayé. Ọba tóni kí ọgbọ́n tí ẹ dá ó má já sọ́pọ́n. Ẹ̀bẹ̀ ni ká má bẹ̀ẹ́ kí Ọlọ́run májẹ̀ kí ọgbọ́n ọ̀hún jáságọ̀.” Ìyá rẹ̀ ṣe àmín!
Ìyá Folúṣọ́ gbéra, ó gba agbolé ọkọ ẹ̀ lọ láti ṣe àlàyé bí iṣu ṣe kú, bọ́bẹ ṣe bẹ́ fún wọn. Nígbàtí ìyá Folúṣọ́ ó fi tú ọ̀rọ palẹ̀ tán ni baálé fi gba ọ̀rọ̀ lẹ́nu ẹ. Ó ní, kò sí àwíjàre kan, lórúkọ gbogbo ẹbí, àwọn tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ ìyá Fólúsọ́ àti Ẹlẹ́dàá òun àti ọmọ rẹ̀. Baálé ní, bí àwọn ò ti ẹ̀ lowo tí àwọn lè fi ran òun àti ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ó yẹ kí àwọn lè ná ìrìn ẹṣẹ̀. Baálé ni, “ah! Àsé lóòótọ́ ni pé ẹ̀yìnlàárọ́.” Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀, Ìyá Folúṣọ́ tọrọ ìyọ̀nda lọ́wọ́ olórí ẹbí pé kí wọ́n mú ọjọ́ ìgba òmìnira ọmọ wọn.
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, àwọn ẹbí ọkọ ránsẹ́ pé ìyá Folúṣọ́. Wọ́n sì pinnu ọjọ́ òmìnira náà.
Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà tí Folúṣọ́ ti di ọ̀gá ara rẹ̀ ni orúkọ ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ròó. Nígbà tí ọdún méjì máa fi pé, Fólúsọ́ tí di ẹni igba ojú mọ̀. Ó ti di gbajúmọ̀. Ó ti di gbajú-gbajà. Ó ti ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tọ̀rá-tọ̀rá kan fún ìyá rẹ̀, òun náà sì ń lo kòrólà kékeré kan.
Báyìí ni ìyá Folúṣọ́ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí gbénú ọlá sọlá títí tí ọlọ́jọ́ fi dé.
Lọ́jọ́ òkú ìyá Folúṣọ́, wọ́n gbọ́ lọ́run. Ọjọ́ méje ni wọ́n fi ṣe òkú ìyá Folúṣọ́. Òkú ìyá Folúṣọ́ gan ni òkú ọlọ́mọ, àṣeèsetán.
Nípa Òǹkọ̀wé
Ọládẹ̀jọ Hammed Ọ́. jẹ́ ọmọ bíbí Ifọ́n Ọ̀sun, ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀sun. Ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Fáṣitì Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀, Ilé-Ifẹ̀.
Àṣẹ lóri àwòrán ojú ìwé yìí jẹ́ ti Pinterest