Èèmọ̀ Ní Pópó

Ẹ wá wo ohun tí mo rí 
Ẹ dákun ẹ wá Ṣẹ̀ídà.
Kàyéfì lohun tí mo rí
A gbọ́ sọgbá nù
A gbọ́ sorí kodò bí àdán.

Mẹ́wàá ń ṣẹlẹ̀ ní pópó
Èèmọ̀ ń ṣẹlẹ̀ níròna
Àánú ti dìgbà dẹrù
Ó ti kúrò láàrín adáríhunrun
Ẹ wá wo èèmọ̀ ní pópó!

Ṣé ọ̀dájú àbí ọ̀làjú ni ká pè èyí?
Kí ìjàǹbá ó ṣẹlẹ̀ lójú títì
Kàkà ká tètè sakítí mápá
Ká gbáwọn tó fara pa
Relé ìwòsàn kọ̀rọ̀ ó tó di bámíì.

Ẹ̀rọ alágbèéká lọ́pọ̀ ó yọ jáde
Àwòrán làwọn aláìbìkítà
Ó máa yà bí aláfiṣe.
Ká tó rí mọ́tò tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́
Ẹ̀mí ẹni ìjàǹbá ṣe ó ti fẹ́rẹ̀ bọ́.
Èèmọ̀ rèé Olódùmarè!

Bẹ́yẹ bá ṣe fò là ń soko ẹ.
Báwo nílé ó ṣe máa jó
Tẹni kan ó ma gbẹ́ gọ́tà
Bó bá jọra ẹ wí fún mi.
Àwọn òmùgọ̀ tí ò gbọ́n.

Èèmọ̀ ń bẹ ní pópó
Ká tó ṣẹ́jú pẹ́
Orí ayélujára tí kún fọ́fọ́
Kí lẹ fẹ́ gbà nínú èyí?
Àbí wọn fi ń gbowó ni?

Mo rò pé ó yẹ ká ronú
Ká pàdí ọrẹ́ dá.
Ká jáwọ́ lápọ̀n tí ò yọ̀
Ká dámi ilá kaná.

Ìkìlọ̀

Àyìndé tún dé tòun tàròfọ̀
Ẹyẹ akéwì mi bà lórùlé
Ojú kálé, ojú káko.
Ohun Àyìndé rí ni yóò fọ̀ létè
Bóyá ohun gbogbo a bọ̀ sípò.

Eré ọlà lọ̀pọ̀ ń sá
Èrò ká lówó lọ́pọ̀ ń rò
Iṣẹ́ ò níyì mọ́ ni dúníyàn
N bí wọ́n ní,
Àtẹ́lẹwọ́ ẹni kìí tan ni jẹ?

Ìwé kíkà ti dìfàkókò ṣòfò
Iṣẹ́ kíkọ́ tí dohun èérí
Tọ́rọ́ ni wọ́n fi ń bo sísì
Ọgbọ́n àlùmọ̀kọ́rọ́yí lù gboro
Iṣẹ́ gbéwiri lọ̀pọ̀ fi ń soge.

Ẹni ò níṣe kan pàtó
Lójijì ló dẹni tó ra ayọ́kẹ́lẹ́
N ló dẹni tó kọ́lé àwòdami-ẹnu
Ó ń náwó bí ẹlẹ́dà
Kò mọ ìlà tówó kọ.

Ayé alákátá ni wọ́n ń jẹ
Bí wọn délé fàájì
Ìwà wọn ò yàtọ̀ sí tí Dàróṣà
Wọn a náwó bí ẹní tẹwó
Wọn a máa jayé ọlọ́bà.

Ọ̀pọ̀ ló ń fọlá wọn tọrọ
Pé káwọn ó dàbí lágbájá
Wọn a fi búrùjí wọn yangàn
Nítorí ọkọ̀ tí wọ́n ń gùn.
Láìmọ̀ pé agbàlọ́wọ́ ọ méríìrí
Baálẹ̀ jòǹtolo ni wọ́n.

Bí wọn ò bá rí òyìnbó
Lù ní jìbìtì orí ayélujára
Ọgbọ́n ká fẹran sẹ́nu
Kó dàwátì ní wàràǹṣeṣà
Pọ̀ bí i yanrìn òkun lọ́wọ́ wọn.

Kò jọ olè kò jọ àfọwọ́rá
Ni wọ́n yàn láàyò
Wọn ń tafà sókè yídó borí
Wọn ń jálé onílé
Fi bo tiwọn lẹ́yìn.

Ẹni wọ́n bá bá lálejò
Ìyẹn ti kan roro nírù ń tiẹ̀
Irú wọ́n wọ gàù láìròtẹ́lẹ̀.
Wọn a já wọn sí kọ́tátò.
Wọn a já wọn sí kolobo.

Ìdájọ́ Wáídù kù sí dẹ̀dẹ̀
Kò sẹ́ni tó tajà erùpẹ̀ rí
Tí kìí gbowó òkúta.
Wọ́n sọra wọn di ewú
Tí kìí jáde lọ́sàn án.

Tìfura tìfura ni wọn ń rìn
Nítorí ìṣe òkùnkùn tí wọn ń ṣe.
Wọ́n ń gbénú òkùnkùn
Tafà sínú ìmọ́lẹ̀.
Wọn ti ṣohun ìtùfù
Ojoojúmọ́ ni wọn ń kíyè sẹ́kúlè.

Gọ̀gọ̀ tí ń kábì káwùsá
Ọjọ́ kan ni yóò ya.
Bọ́wọ́ agbófinró bá tẹ̀ wọ́n
Ìgbà yìí ni wọn ó mọ̀
Pẹran tá a fà tí ó já
Ní wọn ń pè ní námà.

Ọjọ́ ọ̀nà bá mú olè,
Tí ahéré mú olóko wọn.
Tí àkàrà iṣẹ́ ibi tú sépo
Ọjà wàràwàrà tí wọn ń nà
A dá páro ní mọna wáà!

Ẹni ẹ dà lágbo nù síná
Kò le è kọrin ire kì yín.
Ẹ̀ bá à ma wẹ̀ nínú agbo
Ewé ó sunko bó yá.
Ẹ gbà ìkìlọ̀ kí ọ̀rọ̀ ó tó pẹ́.

Nípa Òǹkọ̀wé

Ọmọ bíbí Abẹ́òkúta ní ìpínlẹ̀ Ògùn ni Sheriffdeen Adéọlá Ògúndípẹ̀. Ó kẹ́kọ̀ọ́ gboyè nínú Èdè Yorùbá àti Ẹdukéṣàn ní Yunifásítì Táí Ṣólàárín, Ìjagun, Ìjẹ̀bú Òde. Olùkọ́ èdè Yorùbá ni ní ilé ẹ̀kọ́ girama. Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa kọ ewì àti ìtan àròsọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *