Orí ire níí d'ádé owó
Orùn ire níi s'èdìgbà ìlèkè
Olóòtó ló ni ìgbádùn ayé
Irú won ní sìí jè'gbádùn ayé
L'élé báyìí ni oká n bú
Kè kè kè sìni àkìtàn n gbilè
Bí ó ti lè wù kí òtító kéré tó
Ìbá dàbí èèrà ilè
Ewà rè ò lè kúrò lára re
Òtító dàbí aso funfun nigín nigín l'áàfin olúfè
A lè fi wé òdòdó olóòórùn dídùn
Asòótó jé eni tí olódùmarè fé
Kódà wón wà nínú àwon àdììtú olódùmarè
Irú won ò wópò l'óde ayé
Òkan ni wón nínú egbàágbèje ènìyàn
Ìmólè ni iyì òsùpá
Òtító ni'yì èdá
Olótìítò ò le è te lójú òtító
Gbìyànjú láti jé òkan nínú àwọn àkàndá.