Yorùbá bọ̀ wón ní báyé ba ń yí kámáa bá’yé yí, bí ìgbà báńyí ká máa bá ìgbà yi torí ẹni tí kò bá bágbàyí dandan yóò bágbàlọ. Èyi dífá fuń ipò ọ̀làjú ìgbàlódé táa bá ara wa láyé òde òní.  Ìgbà dẹrùn, ayé tura, ìròrí sì ń lé kenkà si. Ó rọruǹ fuń ẹni tó ń gbé ní Àbújá láti bá ẹbi, ọ̀rẹ́ àti ojúlùmọ̀ rẹ̀ tó ń gbé l’ókè òkun sọ̀rọ̀ láì mú ìnira wá rárá nipa lílo ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀. Bákanáà, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, bàálù, ọkọ̀ ojú omi jẹ àwọn nǹkan ìriǹsẹ̀ tí àwọn ènìyaǹ fi ń fẹlá. Ìlera ńkọ? Ìwádìí fihaǹ wipe ikú ọ̀wọwọ̀ọ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ di ohun àfìsẹ́yiǹ tééguń n fisọ nipa ìlo àwon nǹkan ìlera ìgbàlódé. Ẹ̀tò ẹ̀kọ́ náà kò gbẹ́yiǹ. Nípa ìlo àwọn èlò amórípé bíi ẹ̀rọ ayára bí àsá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ètò ẹ̀kọ̀ ti di ohun àmúnyangàn. Mélòó la ó kà nínú eyín adípèlé, mélòó la fẹ́ẹ́ wí nípa àwon àǹfààni tí ọ̀làjú ti kó ran àwà ẹ̀dá l’órílẹ̀.

Ó wa ṣe ni láàánú wípé àdańwò ti òlàjú kó dé ju aǹfààní rẹ̀ lọ pàápàá lọ́dọ̀ọ àwa ọmọ káàárọ̀ oòjíire nípaa àṣejù tí a kì bọ ọ̀làjú táagbà. Ọgunlọ́gọ̀ ni àwon ọmọ yorùbá tó jẹ́ wípé wọń ti di èèbó tań nipa ìhùwàsí, ìṣesí, ìsọ̀rọ̀sí, ìjẹunsí, ìmúrasí àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ. Ipò tí a bá ara wa yìí jẹ́ nǹkan tó dágbádá àbùkù sí ọrun àṣà ilẹ̀ wa léyìí tó sì jẹ́pé bí aobá ṣọ́ra, àṣà ilẹ̀ wa yóò di ohun tí odó ti dé tí kò gbọdò rí ìta mọ́. Ọ̀rọ̀ Yorùbá tóní àbàmọ̀ níí gbẹ̀yiǹ ọ̀rọ̀ kí ó má baà ṣẹ mọ́wa lára.

Láyé àtijọ́, ìgbéyàwó jẹ́ nǹkan tó ṣe pàtàkì. Ẹni bá l’áya nílé ní ìtaǹ tó pọ̀ látii pa. Alárinà, ìwádìí, ìtọrọ, ìyọ̀ǹda, ìdánaa, ìgbéyàwó àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ jẹ́ àwọn èròjà tó gbọ́dọ̀ pé pérépéré kí géńdé tóólè máa tọ́ka sí obiǹrin kan gẹ́gẹ́ bíi ayaa rẹ̀. Ó sì gbọ́dọ̀ pa àrokò ẹ̀jẹ ìbálé sí àwon ẹbí ìyáwó rẹ̀ pé ọwọ́ ìbàjẹ̀ kò tíì kan ọjà tí òhun rà. Ìdí abájọ rèé tí ìgbéyàwó àná a máa gbòòrò, a màa ládùn lóyin, àwọn èso irú ìgbéyàwó bẹ́ẹ̀ a sì máa jẹ́ oun àmúyangaǹ. Bẹ́ẹ̀kọ́ lórí ní ti ìgbéyàwó ayé òde òní. Rẹ́rẹ́ ti run, nǹkan si ti bàjẹ́. Omi wọń ju ìgbéyàwó ayé òde òní lọ. Orí ẹ̀rọ ayélujára lọ̀pọ̀lọpó ọ̀dọ́ ti ń yan ìpiń wọnn l’óbiǹrin, kò sí oun kankan tó jẹ mọ ìwádìí tàbí alárinnà, èyí já sí ìdí tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbẹ́yàwó ayé òde òni ṣe ń forí sanpoń bíi àlòkù ọ̀kọ̀.

Èdè ilẹ̀ waa ńkọ́? Ó ń rèwàlẹ̀ àsà wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Agídí la fi máa ri ìdílé tó ń fii èdè Yorùbá kọ́ àwọn ọmọ wọn, fińriǹfińtì ni bíi kàa síǹkan. Bí ọmọ Yorùbá mìíraǹ bá fọ èèbó lẹ́nu láì rójú ẹni bẹ́ẹ̀, orúkọ tí ń jẹ́ ni a ó fi dáa mọ̀ pé tilẹ̀ẹ wa níísee (ìyẹn fún ẹni tó bá ka orúkọ Yorùbá kún). Ọ̀rọ̀ waa wáà dàbíi ẹni tí ó mọ ọ̀sọ́ ju ìyá ọ̀sọ́ lọ. Bẹ́ẹ̀, àinírònúu wa kò jẹ́ká lajú rí bí àwọn òyìnbó se ń kọ́ àsà Yorùbá ní kíkankìkan. Ẹníí lójú níí wòran, bí ènìyaǹ bá gbéra lọ sí ọgbà fásíti tilẹ̀ Ìbàdaǹ ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ nípa àṣà àti ìṣe, yóo ríran wò. Bí àwọn aláwọ̀ funfun ṣe ń lú ìlù yorùbá bíi pé àwọn ná sẹ̀dá ìlù bẹ́ẹ̀ ni wọń jó bí àgééré. Ó mú mi rańtí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ sími lọ́jọ́ kejìlá, osù kejì ọduń tó kọjá, èmi àti ọ̀réé mí pàdée òyiǹbó kan nínú ọgbà. Ó kí wa pẹ̀lú èdè Yorùbá tí àwaa síì da á lóhuǹ pẹ̀lú èdèe gẹ̀ẹ́sì, ẹẹ̀ rí ayé ẹrú ọ̀làjú bíí. Ó bi wá bóyá a kò kíń ṣe ọmọYorùbá léyìí táa dalóuǹ pé “bẹ́ẹ̀ni, Yorùbá ni wá.”  Ó sì rọ̀ wá pé kí á bá òhun se ìjíròrò ní èdèe Yorùbá. A bí pé kí ni orúkọ rẹ̀ẹ̀, ó sì dáhuǹ pé Títílayọ̀ ni orúkọ òhun. Ó ní òun ti kọ́ èdèe Yorùbá ní ìlú òun fuń ọduń bíi mẹ́fà sẹ́yiǹ, ó ní àsekágbá lòun wáá ṣe ní ìlú waa. Èmi àti ọ̀rẹ̀ẹ́ mi wojú ara wa, a sì mirí kíkankíkan. Ìwádìí jẹ́ ká mọ̀ pé Yorùbá ni èdè to gbòòrò jùlọ tí àwọn aláwọ̀ funfun ńkọ́. Àfaìmọ̀ọ̀ kí ó má jẹ́ pé àwon aláwọ̀ funfun ni yóò ma kọ́ wa ní èdèe abínibí waa lọ́jọ́ iwájú.

Àrań dà, sányań baba asọ dà, òfì dà? Gbogbo wọn ti fẹ́rẹ̀ re ìrìn àjò àrèmabọ̀ tań. Asọ ilẹ̀ waa kò jẹ wá lóguń mọ́. Okuǹ là ńtá mọ́ruǹ kiri bíi ẹran iléyá. Àwọn obiǹrin a sì fì sòkòtò tíńriń àti asọ másọmílẹ́nu gbésẹ́ elédùmarè jáde. Irun abiyì ayé àtijọ́ bíi ṣùkú, pàtẹ́wọ́, kọjúsọ́kọ, fáadán, ìpàkọ́ ẹlẹ́dè, adé ọba àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀lọ ti farasinko bí ẹni táa forò lé. Orí olórí là n lọ́ mọ́rí bíi tede, irun àwọn ọkuǹrin wa náà a sì dabíi ti saǹgó láì bọ olúkòso tàbí kó ga sókè bíi ilé alájà méje. Àwọn ewì àti ijó amórípé Yorùbá náà ti dohun àwátì. Pàlońgò ló kù, ayé wáá di rúdurùdu, àṣà ilẹ̀ẹ wa wáá dohun àmútayiń. Báyìí la wáá n se báíbàí sí àṣà ilẹ̀ waa, inú waa sì n duǹ, ìbàjẹ́ sì doge mọ́wa lọ́wọ́.

Wàyí ò, òòruǹ tó kù sì tó asọ́ ọ́ gbẹ. Ọjọ́ tí wèrè bá mọ̀ pé nǹkan ń se òhun, ọjọ́ náa ni ara rẹ̀ yóò dá. Lóòótọ́ ná, kìí tań lára ọmọ ọba kí ó má ku dàǹṣákì, èyí tó túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ oòduà tòótọ́ díẹ̀ sì ń gbé àṣà ga. Àmọ́ o, kí àwọn díẹ̀ náà tóó tán lórílẹ̀ kí àṣàa wa má baa wáá di ìtaǹ lẹ́yiǹwá ọ̀la, àti àwa tá a mọ̀ ibi tí bàtà ti ń ta wá lẹ́sẹ̀, ká sun oorun méje tí ọmọkuǹrin ń suǹ, ká rorí wa dáadáa. “Yorùbá yoyoyo bíi iná alẹ́, yorùbá rururu bíi omi òkun, yorùbá baba ni baba ńse. Bẹ́ẹ̀ni, ọ̀gá niwá lọ́jọ́kọ́jọ́. Orísun ni àṣà, odò tó bá sì gbàgbé orísun, gbígbẹ níí gbẹẹ.


Abọ́lájí ọmọ Babalọlá jẹ́ ọmọ ìpele kejì ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì ilẹ̀ Ìbàdaǹ ẹ̀ka ẹ̀kọ́ tó níise pẹ̀lúu ìmọ̀ oòguǹ òyiǹbó (Pharmacy). Ọmọ ọ̀ṣun ní ọdẹ-òmu ni. Ó fẹ́raǹ láti máa kọ́ nípa àṣà àti ìṣe yorùbá nítorí pé àṣa àti ìṣe wa kò láfiwé.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *